Jèhófà Ń bù Kún Àwọn Onígbọràn, Ó Sì Ń Dáàbò Bò Wọ́n
Jèhófà Ń bù Kún Àwọn Onígbọràn, Ó Sì Ń Dáàbò Bò Wọ́n
“Ní ti ẹni tí ń fetí sí mi, yóò máa gbé nínú ààbò, yóò sì wà láìní ìyọlẹ́nu lọ́wọ́ ìbẹ̀rùbojo ìyọnu àjálù.”—ÒWE 1:33.
1, 2. Kí nìdí tí ìgbọràn sí Ọlọ́run fi ṣe pàtàkì? Ṣàpèjúwe.
ÀWỌN òròmọdìyẹ aláwọ̀ ìyeyè, tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gúnyẹ̀ẹ́, ń jẹ̀ ní pápá, láìmọ̀ rárá pé àwòdì ń rà bàbà lókè. Kíá ni ìyá wọn figbe bọnu, tó ń kì wọ́n nílọ̀, tó sì na ìyẹ́ apá rẹ̀. Àwọn òròmọdìyẹ náà sáré tọ ìyá wọn lọ. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́ẹ́, wọ́n ti kó sábẹ́ ìyẹ́ apá rẹ̀. Ni àwòdì ọ̀hún bá dẹ̀yìn lẹ́yìn wọn. a Kí la lè rí kọ́ nínú èyí? Pé ìgbọràn lè gba ẹ̀mí wa là!
2 Ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n yẹn ṣe pàtàkì gan-an, àgàgà fáwọn Kristẹni òde òní. Nítorí pé Sátánì ti pinnu pé òun ò ní dẹ̀yìn lẹ́yìn àwọn èèyàn Ọlọ́run. Ó lóun máa fi wọ́n ṣèjẹ ṣáá ni. (Ìṣípayá 12:9, 12, 17) Ó fẹ́ láti ba ìgbàgbọ́ wa jẹ́, ká lè pàdánù ojú rere Jèhófà àti ìrètí ìyè ayérayé. (1 Pétérù 5:8) Àmọ́ tá a bá sún mọ́ Ọlọ́run pẹ́kípẹ́kí, tá a sì ń yára tẹ̀ lé ìtọ́ni tá à ń rí gbà nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ àti ètò rẹ̀, ìdánilójú wà pé yóò ràdọ̀ bò wá. Onísáàmù náà kọ̀wé pé: “Òun yóò fi àwọn ìyẹ́ rẹ̀ àfifò dí ọ̀nà àbáwọlé sọ́dọ̀ rẹ, ìwọ yóò sì sá di abẹ́ ìyẹ́ apá rẹ̀.”—Sáàmù 91:4.
Orílẹ̀-Èdè Aláìgbọràn Di Ẹran Ìjẹ
3. Kí ni ìwà àìgbọràn tí Ísírẹ́lì hù léraléra yọrí sí?
3 Nígbà tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ń ṣègbọràn sí Jèhófà, ààbò Jèhófà kì í yẹ̀ lórí rẹ̀. Ṣùgbọ́n, ó mà ṣe o, pé àìmọye ìgbà làwọn èèyàn náà fi Ẹlẹ́dàá wọn sílẹ̀, tí wọ́n lọ ń bọ òrìṣà igi àti òkúta—àwọn nǹkan tó jẹ́ “òtúbáńtẹ́ . . . tí kò ṣàǹfààní, tí kì í sì í dáni nídè.” (1 Sámúẹ́lì 12:21) Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ìṣọ̀tẹ̀ wọn, ìpẹ̀yìndà orílẹ̀-èdè náà burú débi pé ọ̀ràn wọn kọjá àtúnṣe. Ìyẹn ló jẹ́ kí Jésù pohùn réré ẹkún lé wọn lórí, pé: “Jerúsálẹ́mù, Jerúsálẹ́mù, olùpa àwọn wòlíì àti olùsọ àwọn tí a rán sí i lókùúta,—iye ìgbà tí mo fẹ́ láti kó àwọn ọmọ rẹ jọpọ̀ ti pọ̀ tó, ní ọ̀nà tí àgbébọ̀ adìyẹ fi ń kó àwọn òròmọdìyẹ rẹ̀ jọpọ̀ lábẹ́ àwọn ìyẹ́ apá rẹ̀! Ṣùgbọ́n ẹ kò fẹ́ ẹ. Wò ó! A pa ilé yín tì fún yín.”—Mátíù 23:37, 38.
4. Báwo ló ṣe hàn gbangba lọ́dún 70 Sànmánì Tiwa pé Jèhófà ti pa Jerúsálẹ́mù tì?
4 Pípa tí Jèhófà pa Ísírẹ́lì ọ̀dàlẹ̀ tì hàn gbangba nígbà tí wọ́n kàgbákò lọ́dún 70 Sànmánì Tiwa. Lọ́dún yẹn, àwọn ọmọ ogun Róòmù gbé àsíá wọn tó ní àwòrán ẹyẹ idì dání, wọ́n sì já wá ṣòòròṣò bí ẹyẹ idì, wọ́n pa àwọn ará Jerúsálẹ́mù nípa ìkà. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, àwọn tó wá ṣe àjọ̀dún Ìrékọjá kún ìlú yẹn dẹ́múdẹ́mú nígbà yẹn. Gbogbo ẹbọ tí wọ́n sọ pé àwọn ń rú kò mú kí wọ́n rí ojú rere Ọlọ́run. Tẹ̀dùntẹ̀dùn lèyí ránni létí ọ̀rọ̀ tí Sámúẹ́lì sọ fún Sọ́ọ̀lù Ọba aláìgbọràn nì, pé: “Jèhófà ha ní inú dídùn sí àwọn ọrẹ ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ bí pé kí a ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà? Wò ó! Ṣíṣègbọràn sàn ju ẹbọ, fífetísílẹ̀ sàn ju ọ̀rá àwọn àgbò.”—1 Sámúẹ́lì 15:22.
5. Irú ìgbọràn wo ni Jèhófà ń fẹ́, báwo la sì ṣe mọ̀ pé irú ìgbọràn bẹ́ẹ̀ ṣeé ṣe?
5 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà kò fọwọ́ kékeré mú ọ̀ràn ṣíṣègbọràn sóun, síbẹ̀ ó mọ ibi tágbára àwa ẹ̀dá aláìpé mọ. (Sáàmù 130:3, 4) Ohun tó ń fẹ́ ni òótọ́ inú àti ìgbọràn tá a gbé ka ìgbàgbọ́, ìfẹ́ àti ìbẹ̀rù àtọkànwá láti yẹra fún ṣíṣe ohun tó máa bí i nínú. (Diutarónómì 10:12, 13; Òwe 16:6; Aísáyà 43:10; Míkà 6:8; Róòmù 6:17) A rí ẹ̀rí pé irú ìgbọràn bẹ́ẹ̀ ṣeé ṣe nínú àpẹẹrẹ “àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí tí ó pọ̀” rẹpẹtẹ tí wọ́n gbé ayé kí ẹ̀sìn Kristẹni tó dé, tí wọ́n pa ìwà títọ́ mọ́ lójú àdánwò líle koko, kódà lójú ikú pàápàá. (Hébérù 11:36, 37; 12:1) Àwọn wọ̀nyí mà kúkú múnú Jèhófà dùn o! (Òwe 27:11) Àmọ́ o, àwọn kan tó jẹ́ olóòótọ́ níbẹ̀rẹ̀ wá dẹ́kun ṣíṣègbọràn nígbà tó yá. Ọ̀kan lára irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni Jèhóáṣì Ọba Júdà ìgbàanì.
Ọba Kan Tí Ẹgbẹ́ Búburú Ṣàkóbá Fún
6, 7. Irú ọba wo ni Jèhóáṣì nígbà ayé Jèhóádà?
6 Díẹ̀ kín-ún ló kù kí wọ́n pa Jèhóáṣì Ọba nígbà tó wà ní kékeré jòjòló. Nígbà tí Jèhóáṣì wá pé ọmọ ọdún méje, Jèhóádà Àlùfáà Àgbà fìgboyà mú un jáde láti ìpamọ́, ó sì fi í jọba. Ọ̀dọ́mọdé olùṣàkóso náà “ń bá a nìṣó ní ṣíṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ Jèhóádà àlùfáà,” torí pé Jèhóádà olùbẹ̀rù Ọlọ́run ń ṣe bíi bàbá àti olùdámọ̀ràn fún Jèhóáṣì.—2 Kíróníkà 22:10–23:1, 11; 24:1, 2.
7 Ara iṣẹ́ rere tí Jèhóáṣì gbé ṣe ni títún tẹ́ńpìlì Jèhófà ṣe—ìyẹn ìgbésẹ̀ kan tó “wà ní góńgó ọkàn-àyà Jèhóáṣì.” Ó rán Jèhóádà Àlùfáà Àgbà létí pé kí ó máa gba owó orí fún tẹ́ńpìlì láti Júdà àti Jerúsálẹ́mù, èyí tí ‘Mósè pa láṣẹ,’ kí wọ́n lé rówó fi ṣe àtúnṣe náà. Láìsí àní-àní, Jèhóádà ti fún ọ̀dọ́mọdé ọba yìí níṣìírí láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Òfin Ọlọ́run, kí ó sì máa pa á mọ́. Ìdí nìyẹn tí iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe lórí tẹ́ńpìlì àtàwọn ohun èlò tẹ́ńpìlì fi parí kíákíá.—2 Kíróníkà 24:4, 6, 13, 14; Diutarónómì 17:18.
8. (a) Kí lohun pàtàkì tó fa ìṣubú Jèhóáṣì nípa tẹ̀mí? (b) Kí ni ìwà àìgbọràn ọba náà sún un ṣe nígbà tó yá?
8 Ó bani nínú jẹ́ pé nígbà tó yá, Jèhóáṣì dẹ́kun ṣíṣègbọràn sí Jèhófà. Kí ló fà á? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ fún wa pé: “Lẹ́yìn ikú Jèhóádà, àwọn ọmọ aládé Júdà wọlé wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí tẹrí ba fún ọba. Ní àkókò yẹn, ọba fetí sí wọn. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n fi ilé Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn sílẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sin àwọn òpó ọlọ́wọ̀ àti àwọn òrìṣà, tí ó fi jẹ́ pé ìkannú wá wà lòdì sí Júdà àti Jerúsálẹ́mù nítorí ẹ̀bi wọn yìí.” Ipa búburú táwọn ọmọ aládé Júdà ní lórí ọba náà mú kó kọ etí ikún sáwọn wòlíì Ọlọ́run, tí Sekaráyà ọmọ Jèhóádà jẹ́ ọ̀kan lára wọn, ẹni tó fi tìgboyà-tìgboyà bá Jèhóáṣì àtàwọn èèyàn náà wí nítorí ìwà àìgbọràn wọn. Kàkà kí Jèhóáṣì ronú pìwà dà, ńṣe ló ní kí wọ́n sọ Sekaráyà lókùúta pa. Áà, Jèhóáṣì ọjọ́sí ló wá di ìkà àti aláìgbọràn yìí—ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ tó ń kó ló sì sọ ọ́ dà bẹ́ẹ̀ o!—2 Kíróníkà 24:17-22; 1 Kọ́ríńtì 15:33.
9. Báwo ni àtúbọ̀tán Jèhóáṣì àtàwọn ọmọ aládé náà ṣe fi hàn pé ìwà àìgbọràn kì í bímọọre?
9 Nísinsìnyí tí Jèhóáṣì ti fi Jèhófà sílẹ̀, kí ló ṣẹlẹ̀ sí òun àtàwọn ọmọ aládé burúkú tó ń bá kẹ́gbẹ́? Ẹgbẹ́ ogun Síríà—tí ‘wọ́n jẹ́ ìwọ̀nba díẹ̀ níye’—gbógun ti Júdà, ‘wọ́n sì run gbogbo ọmọ aládé àwọn ènìyàn náà.’ Àwọn ọmọ ogun náà tún fipá gba àwọn ohun ìní ọba lọ́wọ́ rẹ̀ àti wúrà àti fàdákà tó wà ní ibùjọsìn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhóáṣì yè é, ó di ẹdun arinlẹ̀ àti olókùnrùn. Àìpẹ́ lẹ́yìn náà làwọn kan lára ìránṣẹ́ òun fúnra rẹ̀ dìtẹ̀ pa á. (2 Kíróníkà 24:23-25; 2 Àwọn Ọba 12:17, 18) Ẹ ò rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Ísírẹ́lì, pé: “Bí ìwọ kò bá ní fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run rẹ nípa kíkíyè sára láti tẹ̀ lé gbogbo àṣẹ rẹ̀ àti ìlànà àgbékalẹ̀ rẹ̀ . . . , kí gbogbo ìfiré wọ̀nyí pẹ̀lú wá sórí rẹ, kí wọ́n sì dé bá ọ”!—Diutarónómì 28:15.
Akọ̀wé Tí Ìgbọràn Gba Ẹ̀mí Rẹ̀ Là
10, 11. (a) Kí nìdí tó fi dáa láti ronú lórí ìmọ̀ràn tí Jèhófà fún Bárúkù? (b) Ìmọ̀ràn wo ni Jèhófà fún Bárúkù?
10 Ǹjẹ́ agara máa ń dá ọ nígbà míì, nítorí pé àwọn èèyàn díẹ̀ lára àwọn tí ò ń bá pàdé nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni ló ń tẹ́tí sí ìhìn rere náà? Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ǹjẹ́ o máa ń jowú àwọn tó rí já jẹ, kí ayé ìjẹkújẹ tí wọ́n ń jẹ sì wá máa dá ọ lọ́rùn? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, fara balẹ̀ gbé ọ̀ràn Bárúkù akọ̀wé Jeremáyà yẹ̀ wò, kí o sì ronú lórí ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà fún un.
11 Bárúkù ń múra àtiṣe àkọsílẹ̀ ìhìn àsọtẹ́lẹ̀ kan nígbà tí Jèhófà darí àfiyèsí sí òun fúnra rẹ̀. Èé ṣe? Torí pé Bárúkù bẹ̀rẹ̀ sí ráhùn nípa báyé òun ṣe rí. Àkànṣe àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tí Ọlọ́run fún un kò tẹ́ ẹ lọ́rùn mọ́. Nígbà tí Jèhófà rí ìrònú òdì yìí, ó fún Bárúkù ní ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ tó sojú abẹ níkòó. Ó ní: “Ìwọ ń wá àwọn ohun ńláńlá fún ara rẹ. Má ṣe wá wọn mọ́. Nítorí kíyè sí i, èmi yóò mú ìyọnu àjálù wá sórí gbogbo ẹran ara, . . . èmi yóò sì fi ọkàn rẹ fún ọ bí ohun ìfiṣèjẹ ní gbogbo ibi tí ìwọ bá lọ.”—Jeremáyà 36:4; 45:5.
12. Kí nìdí tó fi yẹ ká yẹra fún wíwá “ohun ńláńlá” fún ara wa nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí?
12 Ǹjẹ́ o ò rí i nínú ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Bárúkù pé Ó ṣàníyàn gidigidi nípa ọkùnrin dáadáa yìí, tó ti fi tọkàntọkàn àti tìgboyà-tìgboyà sìn ín ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú Jeremáyà? Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ lónìí, Jèhófà ń ṣàníyàn gidigidi nípa àwọn tí ọkàn wọn ń fà sí dídi ọlọ́rọ̀ nínú ètò àwọn nǹkan yìí. A dúpẹ́ pé, bíi ti Bárúkù, ọ̀pọ̀ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ń gba ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ látẹnu àwọn arákùnrin tó dàgbà dénú nípa tẹ̀mí. (Lúùkù 15:4-7) Bẹ́ẹ̀ ni o, ǹjẹ́ kí gbogbo wa mọ̀ dájú pé kò sí ọjọ́ ọ̀la kankan fún àwọn tó ń wá “ohun ńláńlá” fún ara wọn nínú ètò yìí. Yàtọ̀ sí pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kì í ní ayọ̀ tòótọ́, èyí tó tún wá burú jù ni pé láìpẹ́ láìjìnnà wọ́n máa bá ayé àti gbogbo ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀ lọ.—Mátíù 6:19, 20; 1 Jòhánù 2:15-17.
13. Ẹ̀kọ́ wo ni ìtàn Bárúkù kọ́ wa nípa ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀?
13 Ìtàn Bárúkù tún kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ gidi nípa ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Kíyè sí i pé kì í ṣe Jèhófà alára ló bá Bárúkù wí, Jeremáyà ló rán. Bárúkù á sì ti máa rí gbogbo àléébù àti kùdìẹ̀-kudiẹ Jeremáyà. (Jeremáyà 45:1, 2) Ṣùgbọ́n Bárúkù kò jẹ́ kí ẹ̀mí ìgbéraga kó sí òun nínú; ó fi tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ gbà pé ọ̀dọ̀ Jèhófà gan-an ni ìmọ̀ràn yẹn ti wá. (2 Kíróníkà 26:3, 4, 16; Òwe 18:12; 19:20) Nítorí náà, bí a ‘bá ṣi ẹsẹ̀ gbé ká tó mọ̀,’ tá a sì rí ìbáwí yíyẹ gbà látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ẹ jẹ́ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìwà àgbà, òye tẹ̀mí àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ Bárúkù.—Gálátíà 6:1.
14. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣègbọràn sáwọn tó ń mú ipò iwájú láàárín wa?
14 Níní irú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ á tún jẹ́ kó rọrùn fáwọn tó fẹ́ fún wa nímọ̀ràn. Hébérù 13:17 sọ pé: “Ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín, kí ẹ sì jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba, nítorí wọ́n ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn yín bí àwọn tí yóò ṣe ìjíhìn; kí wọ́n lè ṣe èyí pẹ̀lú ìdùnnú, kì í sì í ṣe pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn, nítorí èyí yóò ṣe ìpalára fún yín.” Ẹ wò ó, àìmọye ìgbà mà làwọn alàgbà ń fi tọkàntọkàn gbàdúrà sí Jèhófà, pé kó fún àwọn ní ìgboyà, ọgbọ́n àti òye tó gbà, láti lè ṣe apá tó nira yìí nínú iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn! Ẹ jẹ́ ká “máa mọyì irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀.”—1 Kọ́ríńtì 16:18.
15. (a) Báwo ni Jeremáyà ṣe fi hàn pé òun fọkàn tán Bárúkù? (b) Ẹ̀san wo la san fún Bárúkù nítorí bó ṣe fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ ṣègbọràn?
15 Ó hàn gbangba pé Bárúkù tún èrò rẹ̀ ṣe, torí pé ẹ̀yìn ìgbà náà ni Jeremáyà rán an níṣẹ́ kan tó le bí ojú ẹja. Ó ní kó lọ sínú tẹ́ńpìlì, kó lọ fẹnu ara rẹ̀ ka ìhìn ìdájọ́ tí òun alára kọ sílẹ̀ látẹnu Jeremáyà sókè ketekete. Ǹjẹ́ Bárúkù ṣe bẹ́ẹ̀? Ó kúkú ṣe é. “Gbogbo ohun tí Jeremáyà wòlíì . . . pa láṣẹ fún un” ló ṣe. Kódà, ó ka ìhìn kan náà sétígbọ̀ọ́ àwọn ọmọ aládé Jerúsálẹ́mù, èyí sì gba ìgboyà gidi. (Jeremáyà 36:1-6, 8, 14, 15) Nígbà tí ìlú náà ṣubú sọ́wọ́ àwọn ará Bábílónì ní nǹkan bí ọdún méjìdínlógún lẹ́yìn náà, fojú inú wo bí inú Bárúkù á ti dùn tó pé a dá ẹ̀mí òun sí, nítorí pé òun kọbi ara sí ìkìlọ̀ Jèhófà, tóun sì dẹ́kun wíwá “ohun ńláńlá” fún ara òun!—Jeremáyà 39:1, 2, 11, 12; 43:6.
Ìgbọràn Gba Ẹ̀mí Là Nígbà Ìgbóguntini
16. Báwo ni Jèhófà ṣe yọ́nú sáwọn Júù tó wà ní Jerúsálẹ́mù nígbà tí Bábílónì gbógun ti ìlú yẹn lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa?
16 Nígbà tí òpin Jerúsálẹ́mù dé lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, Ọlọ́run tún yọ́nú sáwọn onígbọràn. Nígbà tí àwọn ọmọ ogun ọ̀tá há wọn mọ́ gádígádí, Jèhófà sọ fáwọn Júù pé: “Kíyè sí i, mo ń fi ọ̀nà ìyè àti ọ̀nà ikú síwájú yín. Ẹni tí ó jókòó jẹ́ẹ́ sínú ìlú ńlá yìí yóò tipa idà àti ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn kú; ṣùgbọ́n ẹni tí ó jáde kúrò tí ó sì ṣubú ní tòótọ́ sọ́wọ́ àwọn ará Kálídíà tí wọ́n ń sàga tì yín ni yóò máa wà láàyè nìṣó, dájúdájú, ọkàn rẹ̀ yóò sì jẹ́ tirẹ̀ bí ohun ìfiṣèjẹ.” (Jeremáyà 21:8, 9) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìparun tọ́ sí àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù, síbẹ̀ Jèhófà yọ́nú sáwọn tó ṣègbọràn sí i, kódà ní wákàtí ìkẹyìn yẹn tíná ti jó dóríi kókó. b
17. (a) Ọ̀nà méjì wo la gbà dán ìgbọràn Jeremáyà wò nígbà tí Jèhófà ní kó lọ sọ fáwọn Júù tí wọ́n gbógun tì pé kí wọ́n lọ ‘ṣubú sọ́wọ́ àwọn ará Kálídíà’? (b) Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú bí Jeremáyà ṣe fi tìgboyà-tìgboyà ṣègbọràn?
17 Láìsí àní-àní, sísọ fáwọn Júù pé kí wọ́n gbé ara wọn lé ọ̀tá lọ́wọ́ dán ìgbọràn Jeremáyà alára wò. Ìdí kan ni pé ó ní ìtara fún orúkọ Ọlọ́run. Kò fẹ́ káwọn ọ̀tá gan orúkọ yẹn nípa sísọ pé àwọn òrìṣà bọrọgidi tí àwọn ń sìn ló jẹ́ káwọn ṣẹ́gun. (Jeremáyà 50:2, 11; Ìdárò 2:16) Ìyẹn nìkan kọ́ o, Jeremáyà mọ̀ pé ikú lòun fi ń ṣeré, bóun ṣe ń sọ fáwọn èèyàn náà pé kí wọ́n lọ túúbá fáwọn ọ̀tá, nítorí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa sọ pé ọ̀rọ̀ ọ̀tẹ̀ lòun ń sọ lẹ́nu. Síbẹ̀, kò bẹ̀rù, ṣùgbọ́n ó fi ìgbọràn kéde ọ̀rọ̀ Jèhófà. (Jeremáyà 38:4, 17, 18) Bíi ti Jeremáyà, ọ̀rọ̀ àwa náà ò tà létí àwọn èèyàn. Ṣebí ìhìn kan náà yìí ló jẹ́ kí àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí tẹ́ńbẹ́lú Jésù. (Aísáyà 53:3; Mátíù 24:9) Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ ká ‘wárìrì nítorí ènìyàn,’ ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bíi ti Jeremáyà, ẹ jẹ́ ká fi tìgboyà-tìgboyà ṣègbọràn sí Jèhófà, ká gbẹ́kẹ̀ lé e pátápátá.—Òwe 29:25.
Ìgbọràn Nígbà Tí Gọ́ọ̀gù Bá Kógun Dé
18. Kí làwọn nǹkan tí ń bẹ níwájú tó máa dán ìgbọràn àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà wò?
18 Láìpẹ́, gbogbo ètò búburú Sátánì ni yóò pa run nígbà “ìpọ́njú ńlá” aláìláfiwé. (Mátíù 24:21) Ó dájú pé kó tó bẹ̀rẹ̀ àti nígbà tó bá ń lọ lọ́wọ́, a óò dán ìgbàgbọ́ àti ìgbọràn àwọn èèyàn Ọlọ́run wò gidigidi. Bi àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ fún wa pé Sátánì, ìyẹn “Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù,” yóò gbé ìjà àjàkú akátá ko àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà. Àwọn ọmọ ogun tó ń kó jọ ni a pè ní “ẹgbẹ́ ológun tí ó pọ̀ níye . . . , bí àwọsánmà láti bo ilẹ̀ náà.” (Ìsíkíẹ́lì 38:2, 14-16) Àwọn èèyàn Ọlọ́run tí wọn ò dira ogun, tí wọ́n sì kéré níye yóò sá di “ìyẹ́” Jèhófà, tí yóò nà láti fi ràdọ̀ bo àwọn onígbọràn.
19, 20. (a) Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì gan-an pé kí Ísírẹ́lì ṣègbọràn nígbà tí wọ́n wà ní Òkun Pupa? (b) Báwo ni fífi tàdúrà-tàdúrà ronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Òkun Pupa ṣe lè ṣàǹfààní fún wa lónìí?
19 Ipò yìí rán wa létí ìgbà Ìjádelọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì. Lẹ́yìn tí Jèhófà fi ìyọnu ńlá mẹ́wàá kọlu Íjíbítì, ló wá kó àwọn èèyàn rẹ̀ jáde. Kò kó wọn gba ọ̀nà tó yá jù lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí. Kàkà bẹ́ẹ̀ ọ̀nà Òkun Pupa ló darí wọn gbà, níbi táwọn èèyàn náà ti lè máa bẹ̀rù àtikó sọ́wọ́ ọ̀tá. Téèyàn bá fojú ológun wò ó, bí ẹní dìídì forí lé ọ̀nà eléwu ni. Ká ní o wà níbẹ̀, ǹjẹ́ ò bá ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ Jèhófà látẹnu Mósè, kí o fi ìgbọ́kànlé kíkún forí lé Òkun Pupa, nígbà tó o sì mọ̀ pé ọ̀tọ̀ lọ̀nà Ilẹ̀ Ìlérí?—Ẹ́kísódù 14:1-4.
20 Bí a ṣe ń bá ìtàn náà lọ nínú Ẹ́kísódù orí 14, a rí i bí Jèhófà ṣe fi agbára ẹlẹ́rù jẹ̀jẹ̀ gba àwọn èèyàn rẹ̀ là. Irú ìtàn bẹ́ẹ̀ mà máa ń fún ìgbàgbọ́ lókun o, ìyẹn bá a bá fara balẹ̀ kà á, tá a sì ṣàṣàrò lé e lórí! (2 Pétérù 2:9) Ìgbàgbọ́ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀, ẹ̀wẹ̀, ń jẹ́ ká fi tọkàntọkàn ṣègbọràn sí Jèhófà, kódà nígbà tó bá jọ pé àwọn ohun tó ní ká ṣe kò bá ọ̀nà ìrònú ènìyàn mú. (Òwe 3:5, 6) Nítorí náà, bi ara rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ mò ń sapá láti gbé ìgbàgbọ́ mi ró nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì aláápọn, àdúrà àti àṣàrò, àti nípa pípàdépọ̀ déédéé pẹ̀lú àwọn èèyàn Ọlọ́run?’—Hébérù 10:24, 25; 12:1-3.
Ìgbọràn Ń Jẹ́ Ká Ní Ìrètí
21. Àwọn ìbùkún wo làwọn tó ń ṣègbọràn sí Jèhófà yóò ní, nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú?
21 Àní lọ́wọ́ tá a wà yìí, àwọn tó ti sọ ọ́ dàṣà láti máa ṣègbọràn sí Jèhófà ń rí ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ inú Òwe 1:33, pé: “Ní ti ẹni tí ń fetí sí mi, yóò máa gbé nínú ààbò, yóò sì wà láìní ìyọlẹ́nu lọ́wọ́ ìbẹ̀rùbojo ìyọnu àjálù.” Ẹ wo ìmúṣẹ àgbàyanu tí ọ̀rọ̀ ìtùnú wọ̀nyí yóò ní lọ́jọ́ ẹ̀san Jèhófà tí ń bọ̀! Jésù tilẹ̀ sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Bí nǹkan wọ̀nyí bá ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹlẹ̀, ẹ gbé ara yín nà ró ṣánṣán, kí ẹ sì gbé orí yín sókè, nítorí pé ìdáǹdè yín ń sún mọ́lé.” (Lúùkù 21:28) Dájúdájú, kìkì àwọn tó bá ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run ni ọkàn wọn yóò balẹ̀ láti pa ọ̀rọ̀ wọ̀nyí mọ́.—Mátíù 7:21.
22. (a) Kí nìdí táwọn èèyàn Jèhófà fi ní ìgbọ́kànlé? (b) Kí làwọn nǹkan tí a óò jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
22 Ìdí mìíràn fún níní ìgbọ́kànlé ni pé “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ kì yóò ṣe ohun kan láìjẹ́ pé ó ti ṣí ọ̀ràn àṣírí rẹ̀ payá fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì.” (Ámósì 3:7) Lónìí, Jèhófà kì í mí sí àwọn wòlíì bíi ti ayé ọjọ́un; kàkà bẹ́ẹ̀, ó ti yan ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ kan pé kí ó máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí àsìkò fún agboolé òun. (Mátíù 24:45-47) Ẹ wo bó ṣe ṣe pàtàkì tó pé ká máa ṣègbọràn sí “ẹrú” yẹn! Gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ tó kàn yóò ṣe fi hàn, irú ìgbọràn bẹ́ẹ̀ tún ń fi ojú tá a fi ń wo Jésù ọ̀gá “ẹrú” yẹn hàn. Òun lẹni tí “ìgbọràn àwọn ènìyàn . . . jẹ́ tirẹ̀.”—Jẹ́nẹ́sísì 49:10.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn sọ pé àgbébọ̀ adìyẹ lójo, ìwé kan tí àjọ tó ń dáàbò bo àwọn ẹranko ṣe, sọ pé “àgbébọ̀ adìyẹ ò kọkú nígbà tó bá ń jà láti dáàbò bo àwọn ọmọ rẹ̀.”
b Jeremáyà 38:19 fi hàn pé àwọn Júù kan ‘ṣubú sọ́wọ́’ àwọn ará Kálídíà, wọ́n sì bọ́ lọ́wọ́ ikú, àmọ́ wọn ò bọ́ lọ́wọ́ lílọ sí ìgbèkùn. A ò mọ̀ bóyá ńṣe ni wọ́n ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ Jeremáyà, tí wọ́n sì gbé ara wọn lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́. Bó ti wù kó rí, lílà tí wọ́n là á já fi hàn pé ọ̀rọ̀ wòlíì náà nímùúṣẹ.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí ni ìyọrísí ìwà àìgbọràn tí Ísírẹ́lì hù léraléra?
• Ipa wo làwọn tí Jèhóáṣì Ọba bá kẹ́gbẹ́ ní lórí rẹ̀, nígbà kékeré rẹ̀ àti nígbà tó dàgbà?
• Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú ọ̀ràn Bárúkù?
• Kí nìdí tí kò fi yẹ kí ẹ̀rù ba àwọn tó ń ṣègbọràn sí Jèhófà bí ètò ìsinsìnyí ti ń sún mọ́ òpin rẹ̀?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Jèhóáṣì ọ̀dọ́ ṣègbọràn sí Jèhófà nígbà tí Jèhóádà ń tọ́ ọ sọ́nà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ẹgbẹ́ búburú ló sún Jèhóáṣì pàṣẹ pé kí wọ́n pa wòlíì Ọlọ́run
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ǹjẹ́ ò bá ti ṣègbọràn sí Jèhófà, kó o sì rí agbára ẹlẹ́rù jẹ̀jẹ̀ tó fi gbani là?