Jẹ́ Onígbọràn Bí Òpin Ti Ń Sún Mọ́lé
Jẹ́ Onígbọràn Bí Òpin Ti Ń Sún Mọ́lé
“Ìgbọràn àwọn ènìyàn yóò sì máa jẹ́ [ti Ṣílò].”—JẸ́NẸ́SÍSÌ 49:10.
1. (a) Nígbà àtijọ́, kí ni ìgbọràn sí Jèhófà sábà máa ń wé mọ́? (b) Àsọtẹ́lẹ̀ wo ni Jékọ́bù sọ nípa ìgbọràn?
ṢÍṢE ìgbọràn sí Jèhófà sábà máa ń wé mọ́ ṣíṣe ìgbọràn sáwọn aṣojú rẹ̀. Àwọn áńgẹ́lì, àwọn baba ńlá ìgbàanì, onídàájọ́, àlùfáà, wòlíì àtàwọn ọba sì wà lára àwọn aṣojú wọ̀nyí. Kódà ìtẹ́ Jèhófà la pe ìtẹ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì. (1 Kíróníkà 29:23) Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn alákòóso Ísírẹ́lì ló ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ mú àjálù wá sórí ara wọn àtàwọn ọmọ abẹ́ wọn. Ṣùgbọ́n Jèhófà kò fi àwọn tó dúró ṣinṣin tì í sílẹ̀ láìní ìrètí; ó tù wọ́n nínú nípasẹ̀ ìlérí kan tó ṣe pé òun yóò fi Ọba òdodo kan jẹ, tí àwọn olódodo yóò máa ṣègbọràn sí tọkàntọkàn. (Aísáyà 9:6, 7) Nígbà tí Jékọ́bù, baba ńlá ìgbàanì ń kú lọ, ó sọ tẹ́lẹ̀ nípa ọba lọ́la yìí, pé: “Ọ̀pá aládé kì yóò yà kúrò lọ́dọ̀ Júdà, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá àṣẹ kì yóò yà kúrò ní àárín ẹsẹ̀ rẹ̀, títí Ṣílò yóò fi dé; ìgbọràn àwọn ènìyàn yóò sì máa jẹ́ tirẹ̀.”—Jẹ́nẹ́sísì 49:10.
2. Kí ni ìtumọ̀ “Ṣílò,” ibo sì ni ìṣàkóso rẹ̀ máa nasẹ̀ dé?
2 Ọ̀rọ̀ náà “Ṣílò” wá látinú èdè Hébérù, ó sì túmọ̀ sí “Oníǹkan,” tàbí “Ẹni Tí Ó Jẹ́ Tirẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni o, Ṣílò ni yóò jogún gbogbo ẹ̀tọ́ láti ṣàkóso, èyí tí ọ̀pá aládé dúró fún, àti gbogbo agbára láti pàṣẹ, èyí tí ọ̀pá àṣẹ dúró fún. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìṣàkóso rẹ̀ kò ní jẹ́ láàárín àtọmọdọ́mọ Jékọ́bù nìkan, ṣùgbọ́n yóò nasẹ̀ dé ọ̀dọ̀ “àwọn ènìyàn” gbogbo. Èyí bá ìlérí tí Jèhófà ṣe fún Ábúráhámù mu, pé: “Irú-ọmọ rẹ yóò sì gba ẹnubodè àwọn ọ̀tá rẹ̀. Nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ sì ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé yóò bù kún ara wọn.” (Jẹ́nẹ́sísì 22:17, 18) Jèhófà fi ẹni tí “irú-ọmọ” náà jẹ́ gan-an hàn lọ́dún 29 Sànmánì Tiwa, nígbà tó fi ẹ̀mí mímọ́ yan Jésù ará Násárétì.—Lúùkù 3:21-23, 34; Gálátíà 3:16.
Ìjọba Tí Jésù Kọ́kọ́ Gbà
3. Ìjọba wo la fún Jésù nígbà tó gòkè re ọ̀run?
3 Kì í ṣe gbàrà tí Jésù gòkè re ọ̀run ló gba ọ̀pá àṣẹ láti máa ṣàkóso lórí gbogbo ayé. (Sáàmù 110:1) Àmọ́, a fún un ní “ìjọba” kan láàárín àwọn ọmọ abẹ́ tó ń ṣègbọràn sí i. Ìjọba yìí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí nígbà tó kọ̀wé pé: “[Ọlọ́run] dá wa [àwọn Kristẹni tá a fẹ̀mí yàn] nídè kúrò lọ́wọ́ ọlá àṣẹ òkùnkùn, ó sì ṣí wa nípò lọ sínú ìjọba Ọmọ ìfẹ́ rẹ̀.” (Kólósè 1:13) Ìdáǹdè yìí bẹ̀rẹ̀ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, nígbà tá a tú ẹ̀mí mímọ́ sórí àwọn olóòótọ́ ọmọlẹ́yìn Jésù.—Ìṣe 2:1-4; 1 Pétérù 2:9.
4. Báwo làwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ìjímìjí ṣe fi hàn pé àwọn jẹ́ onígbọràn, orúkọ wo ni Jésù sì pè wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan?
4 Gẹ́gẹ́ bí “adípò fún Kristi,” àwọn ọmọlẹ́yìn tá a fẹ̀mí yàn fi ìgbọràn bẹ̀rẹ̀ sí kó àwọn mìíràn tí wọn yóò “jùmọ̀ jẹ́ aráàlú” nínú ìjọba tẹ̀mí yẹn jọ. (2 Kọ́ríńtì 5:20; Éfésù 2:19; Ìṣe 1:8) Ní àfikún sí i, àwọn wọ̀nyí ní láti jẹ́ àwọn tá a so “pọ̀ ṣọ̀kan rẹ́gírẹ́gí nínú èrò inú kan náà àti nínú ìlà ìrònú kan náà,” kí wọ́n lè rí ojú rere Jésù Kristi Ọba wọn. (1 Kọ́ríńtì 1:10) Gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan, àwọn ló para pọ̀ jẹ́ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” tàbí ẹgbẹ́ olóòótọ́ ìríjú.—Mátíù 24:45; Lúùkù 12:42.
A Bù Kún Wọn Nítorí Pé Wọ́n Ń Ṣègbọràn sí “Ìríjú” Ọlọ́run
5. Báwo ni Jèhófà ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ láti ìjímìjí?
5 Jèhófà kò fi àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀ láìní olùkọ́ rí. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn táwọn Júù padà dé láti Bábílónì, Ẹ́sírà àtàwọn ọkùnrin mìíràn tó tóótun kò wulẹ̀ ka Òfin Ọlọ́run sí àwọn èèyàn náà létí nìkan, wọ́n “làdí” òfin náà, ‘wọ́n fi ìtumọ̀ sí i, wọ́n sì mú káwọn èèyàn lóye’ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Nehemáyà 8:8.
6, 7. Báwo ni ẹgbẹ́ ẹrú náà ṣe ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí lásìkò nípasẹ̀ Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso rẹ̀, èé sì ti ṣe tó fi yẹ ká máa ṣègbọràn sí ẹgbẹ́ ẹrú yẹn?
6 Ní ọ̀rúndún kìíní, nígbà tí àríyànjiyàn dìde lórí ọ̀ràn ìdádọ̀dọ́ lọ́dún 49 Sànmánì Tiwa, ẹgbẹ́ olùṣàkóso tó ń ṣojú fún ẹgbẹ́ ẹrú ìjímìjí yẹn, gbé ọ̀ràn náà yẹ̀ wò tàdúrà-tàdúrà, wọ́n sì dórí ìpinnu kan tó bá Ìwé Mímọ́ mu. Nígbà tí wọ́n gbé ìpinnu wọn jáde nínú lẹ́tà, àwọn ìjọ ṣègbọràn sí ìtọ́ni tí wọ́n rí gbà, Ọlọ́run sì bù kún wọn ní jìngbìnnì. (Ìṣe 15:6-15, 22-29; 16:4, 5) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ lóde òní, ẹrú olóòótọ́ ti tipasẹ̀ Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso rẹ̀ ṣe àlàyé yékéyéké lórí àwọn ọ̀ràn pàtàkì bíi wíwà láìdásí tọ̀tún tòsì gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, ìjẹ́mímọ́ ẹ̀jẹ̀ àti lílo àwọn oògùn líle àti tábà. (Aísáyà 2:4; Ìṣe 21:25; 2 Kọ́ríńtì 7:1) Jèhófà ti bù kún àwọn èèyàn rẹ̀ nítorí tí wọ́n ń ṣègbọràn sí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti sí ẹrú olóòótọ́ náà.
7 Àwọn èèyàn Ọlọ́run tún ń fi hàn pé àwọn ń tẹrí ba fún Jésù Kristi Ọ̀gá wọn nípa ṣíṣègbọràn sí ẹgbẹ́ ẹrú náà. Irú ìtẹríba bẹ́ẹ̀ túbọ̀ ṣe kókó lóde òní nítorí àfikún ọlá àṣẹ tí Jésù ti rí gbà, gẹ́gẹ́ bí Jékọ́bù ti sọ tẹ́lẹ̀ nígbà tó ń kú lọ.
Ṣílò Di Ẹni Tí Ìṣàkóso Ayé Jẹ́ Tirẹ̀
8. Báwo ni àṣẹ Kristi ṣe gbòòrò sí i, ìgbà wo sì ni?
8 Àsọtẹ́lẹ̀ Jékọ́bù sọ pé “ìgbọràn àwọn ènìyàn” yóò máa jẹ́ ti Ṣílò. Ó hàn gbangba pé ìṣàkóso Kristi kò ní mọ sórí Ísírẹ́lì tẹ̀mí. Ibo ni yóò nasẹ̀ dé? Ìṣípayá 11:15 dáhùn, ó ní: “Ìjọba ayé di ìjọba Olúwa wa àti ti Kristi rẹ̀, yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba títí láé àti láéláé.” Bíbélì fi hàn pé Jésù gba ọlá àṣẹ yẹn lópin “ìgbà méje” tá a sọ tẹ́lẹ̀—ìyẹn ni “àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè”—lọ́dún 1914. a (Dáníẹ́lì 4:16, 17; Lúùkù 21:24) Ọdún yẹn ni “wíwàníhìn-ín” Kristi gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà Ọba bẹ̀rẹ̀, ìgbà yẹn ló sì bẹ̀rẹ̀ sí “ṣẹ́gun lọ láàárín àwọn ọ̀tá” rẹ̀.—Mátíù 24:3; Sáàmù 110:2.
9. Kí ni Jésù ṣe nígbà tá a gbé Ìjọba lé e lọ́wọ́, kí sì ni èyí fà wá bá ọmọ aráyé, àgàgà àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù?
9 Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ tí Jésù gbé lẹ́yìn tó di ọba ni pé ó fi ọ̀gá àwọn aláìgbọràn—ìyẹn Sátánì—àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ “sọ̀kò sísàlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé.” Látìgbà yẹn làwọn ẹ̀mí burúkú wọ̀nyí ti ń fa ègbé tí a ò rírú rẹ̀ rí fọ́mọ aráyé, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n tún ń mú kó ṣòro gan-an láti ṣègbọràn sí Jèhófà. (Ìṣípayá 12:7-12; 2 Tímótì 3:1-5) Àwọn ẹni àmì òróró Jèhófà, “tí ń pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́, tí wọ́n sì ní iṣẹ́ jíjẹ́rìí Jésù,” àti “àwọn àgùntàn mìíràn” tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn wà lára àwọn tí Sátánì dìídì ń dojú ìjà kọ.—Ìṣípayá 12:17; Jòhánù 10:16.
10. Ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì wo ló mú un dá wa lójú pé ìjà àjàpòfo ni Sátánì ń bá àwọn Kristẹni tòótọ́ jà?
10 Àmọ́, gbogbo làlà koko fẹ̀fẹ̀ Sátánì, irọ́ ńlá ló máa já sí, nítorí pé “ọjọ́ Olúwa” la wà yìí, kò sì sẹ́ni tó lè dí Jésù lọ́wọ́ ‘píparí ìṣẹ́gun rẹ̀.’ (Ìṣípayá 1:10; 6:2) Bí àpẹẹrẹ, yóò rí i dájú pé òun fèdìdì di gbogbo ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tẹ̀mí. Yóò sì dáàbò bo “ogunlọ́gọ̀ ńlá, tí ẹnì kankan kò lè kà, láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n.” (Ìṣípayá 7:1-4, 9, 14-16) Àmọ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí yàtọ̀ sí àwọn ẹni àmì òróró alábàákẹ́gbẹ́ wọn ní ti pé orí ilẹ̀ ayé ni wọn yóò wà gẹ́gẹ́ bí ọmọ abẹ́ àkóso Jésù. (Dáníẹ́lì 7:13, 14) Wíwà tí wọ́n ti wà lórí ilẹ̀ ayé báyìí jẹ́ ẹ̀rí gidi pé lóòótọ́, Ṣílò ti di Olùṣàkóso lórí “ìjọba ayé.”—Ìṣípayá 11:15.
Àkókò Rèé Láti “Ṣègbọràn sí Ìhìn Rere”
11, 12. (a) Kìkì àwọn wo ni yóò la òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí já? (b) Kí ni ìṣesí àwọn tó bá ní “ẹ̀mí ayé”?
11 Gbogbo àwọn tó bá ń fẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun gbọ́dọ̀ kọ́ ìgbọràn, nítorí Bíbélì là á mọ́lẹ̀ pé “àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa” kò ní la ọjọ́ ẹ̀san Ọlọ́run já. (2 Tẹsalóníkà 1:8) Ṣùgbọ́n, gbogbo nǹkan burúkú tí ń lọ láyé àti ẹ̀mí ìṣọ̀tẹ̀ sí òfin àti ìlànà Bíbélì ti jẹ́ kó ṣòro gan-an láti ṣègbọràn sí ìhìn rere.
12 Bíbélì pe ẹ̀mí ìṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run yìí ní “ẹ̀mí ayé.” (1 Kọ́ríńtì 2:12) Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń ṣàlàyé ipa tó ń ní lórí àwọn èèyàn, ó kọ̀wé sáwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní nílùú Éfésù, pé: “Ẹ ti rìn ní àkókò kan rí ní ìbámu pẹ̀lú ètò àwọn nǹkan ti ayé yìí, ní ìbámu pẹ̀lú olùṣàkóso ọlá àṣẹ afẹ́fẹ́, ẹ̀mí tí ń ṣiṣẹ́ nísinsìnyí nínú àwọn ọmọ àìgbọ́ràn. Bẹ́ẹ̀ ni, ní àkókò kan, gbogbo wa hùwà láàárín wọn ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ẹran ara wa, ní ṣíṣe àwọn ohun tí ẹran ara fẹ́ àti ti àwọn ìrònú, a sì jẹ́ ọmọ ìrunú lọ́nà ti ẹ̀dá àní bí àwọn yòókù.”—Éfésù 2:2, 3.
13. Báwo làwọn Kristẹni ṣe lè dènà ẹ̀mí ayé, pẹ̀lú ìyọrísí rere wo?
13 Ó múni láyọ̀ pé àwọn Kristẹni tí ń bẹ ní Éfésù kò jọ̀wọ́ ara wọn fún ẹ̀mí àìgbọràn yẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n di onígbọràn ọmọ Ọlọ́run, wọ́n fi ara wọn sábẹ́ ìdarí ẹ̀mí rẹ̀, wọ́n sì ń gbádùn èso rere tó ń so lọ́pọ̀ yanturu. (Gálátíà 5:22, 23) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ló rí lónìí, ẹ̀mí Ọlọ́run—tí í ṣe ipá lílágbára jù lọ láyé àti lọ́run—ń ran ọ̀kẹ́ àìmọye lọ́wọ́ láti ṣègbọràn sí Jèhófà, ó sì jẹ́ kí ó ṣeé ṣe fún wọn láti ní “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdánilójú ìrètí náà títí dé òpin.”—Hébérù 6:11; Sekaráyà 4:6.
14. Báwo ni Jésù ṣe ta gbogbo Kristẹni tí ń gbé ní ọjọ́ ìkẹyìn lólobó nípa àwọn ìṣòro pàtó tí yóò dán ìgbọràn wọn wò?
14 Tún rántí pé gbágbáágbá ni Ṣílò ń tì wá lẹ́yìn. Òun àti Bàbá rẹ̀ kò ní jẹ́ kí ọ̀tá èyíkéyìí—ì báà jẹ́ ẹ̀mí èṣù tàbí ọmọ aráyé—dán ìgbọràn wa wò ré kọjá ohun tá a lè mú mọ́ra. (1 Kọ́ríńtì 10:13) Àní, láti ràn wá lọ́wọ́ nínú ìjà tẹ̀mí tí à ń jà, Jésù mẹ́nu kan àwọn ìṣòro pàtó kan tí a ó dojú kọ ní ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí. Ó mẹ́nu kan ìṣòro wọ̀nyí nínú lẹ́tà méje kan, tí àpọ́sítélì Jòhánù kọ látinú ìran tí Jésù fi hàn án. (Ìṣípayá 1:10, 11) Láìsí àní-àní, lẹ́tà wọ̀nyí ní ìmọ̀ràn pàtàkì nínú fáwọn Kristẹni ìgbà yẹn, àmọ́ àwa tó ń gbé ní “ọjọ́ Olúwa” tó bẹ̀rẹ̀ látọdún 1914 ni ọ̀ràn náà kàn jù lọ. Nítorí náà, ẹ ò rí i pé ó yẹ ká fiyè sí àwọn ìhìn wọ̀nyí! b
Yẹra fún Ẹ̀mí Ìdágunlá, Ìṣekúṣe, Ìfẹ́ Ọrọ̀ Àlùmọ́ọ́nì
15. Kí nìdí tó fi yẹ ká yẹra fún ìṣòro tí ìjọ Éfésù ní, báwo la sì ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? (2 Pétérù 1:5-8)
15 Ìjọ Éfésù ni Jésù kọ lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ sí. Lẹ́yìn tí Jésù gbóríyìn fún ìjọ náà nítorí ìfaradà rẹ̀, ó sọ pé: “Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, mo ní èyí lòdì sí ọ, pé ìwọ ti fi ìfẹ́ tí ìwọ ní ní àkọ́kọ́ sílẹ̀.” (Ìṣípayá 2:1-4) Bákan náà ló rí lóde òní, àwọn Kristẹni kan tó jẹ́ onítara tẹ́lẹ̀ ti jẹ́ kí ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí wọ́n fìgbà kan ní fún Ọlọ́run tutù. Tí ìfẹ́ yìí bá tutù, àjọṣe téèyàn ní pẹ̀lú Ọlọ́run lè bà jẹ́, nítorí náà èèyàn gbọ́dọ̀ tètè wá nǹkan ṣe sí ọ̀ràn náà. Báwo lèèyàn ṣe lè koná mọ́ ìfẹ́ yẹn? Nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, lílọ sípàdé, gbígbàdúrà àti ṣíṣàṣàrò ni. (1 Jòhánù 5:3) Lóòótọ́, èyí ń béèrè “ìsapá àfi-taratara-ṣe,” ṣùgbọ́n ó tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. (2 Pétérù 1:5-8) Bí a bá yẹ ara wa wò fínnífínní, tá a sì rí i pé ìfẹ́ wa ti tutù, á dáa ká tètè wá nǹkan ṣe sí i, níbàámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìyànjú Jésù, pé: “Rántí inú ohun tí o ti ṣubú, kí o sì ronú pìwà dà, kí o sì ṣe àwọn iṣẹ́ ti ìṣáájú.”—Ìṣípayá 2:5.
16. Àwọn wo ló ń kó èèràn ranni nípa tẹ̀mí nínú ìjọ Págámù àti Tíátírà, èé sì ti ṣe tí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ sí wọn fi kàn wá lónìí?
16 A gbóríyìn fáwọn Kristẹni tí ń bẹ ní Págámù àti Tíátírà nítorí ìwà títọ́, ìfaradà àti ìtara wọn. (Ìṣípayá 2:12, 13, 18, 19) Síbẹ̀, a kó èèràn ràn wọ́n látọ̀dọ̀ àwọn kan tó ní irú ẹ̀mí burúkú tí Báláámù àti Jésíbẹ́lì ní, àwọn tó fi ìṣekúṣe àti ìjọsìn Báálì kó èèràn ìwà ìbàjẹ́ ran Ísírẹ́lì ìgbàanì. (Númérì 31:16; 1 Àwọn Ọba 16:30, 31; Ìṣípayá 2:14, 16, 20-23) Àmọ́ lóde òní, tí í ṣe “ọjọ́ Olúwa” ńkọ́? Ǹjẹ́ àwọn kan ṣì ń kó irú èèràn bẹ́ẹ̀ ranni? Bẹ́ẹ̀ ni o, àní ìwà pálapàla takọtabo ni ẹ̀ṣẹ̀ tí ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ti à ń yọ lẹ́gbẹ́ láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run ń dá. Ẹ ò wá rí i pé ó ṣe pàtàkì láti yàgò fún ẹnikẹ́ni tó lè kó èèràn ranni—ì báà jẹ́ nínú ìjọ tàbí lóde ìjọ! (1 Kọ́ríńtì 5:9-11; 15:33) Àwọn tó bá fẹ́ jẹ́ ọmọ abẹ́ Ṣílò á tún ta kété sí eré ìnàjú tí ń kọni lóminú àti ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè tí wọ́n ń tẹ̀ sínú ìwé tàbí tí wọ́n ń kó sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.—Ámósì 5:15; Mátíù 5:28, 29.
17. Kí ni èrò àti ìṣesí àwọn tó wà ní Sádísì àti Laodíkíà, ní ìfiwéra pẹ̀lú ojú tí Jésù fi wo ipò tí wọ́n wà nípa tẹ̀mí?
17 Yàtọ̀ sí àwọn èèyàn díẹ̀ nínú ìjọ Sádísì, a kò gbóríyìn fún ìjọ yẹn lódindi rárá. Ó ní “orúkọ,” tàbí ìrísí pé òun wà láàyè, ṣùgbọ́n ó ti jingíri sínú ìwà ìdágunlá nípa tẹ̀mí débi tí Jésù fi sọ pé ó ti “kú.” Ìgbọràn tí wọ́n sọ pé àwọn ń ṣe sí ìhìn rere náà kò dénú rárá. Ìdálẹ́bi yìí mà gbóná o! (Ìṣípayá 3:1-3) Irú ipò yẹn náà ni ìjọ Laodíkíà wà. Ó ń fi nǹkan ìní ti ara yangàn, ó ń sọ pé, “Ọlọ́rọ̀ ni mí,” àmọ́ lójú Kristi, “akúùṣẹ́ ni . . . àti ẹni ìkáàánú fún àti òtòṣì àti afọ́jú àti ẹni ìhòòhò.”—Ìṣípayá 3:14-17.
18. Báwo lèèyàn ṣe lè yẹra fún dídi ẹni tó ń fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú nǹkan tẹ̀mí lójú Ọlọ́run?
18 Lóde òní, àwọn Kristẹni kan tó jẹ́ olóòótọ́ tẹ́lẹ̀ rí ti di aláìgbọràn pẹ̀lú. Bóyá wọ́n ti jẹ́ kí ẹ̀mí ayé sún wọn dẹwọ́, tí wọ́n sì wá ń fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àdúrà, àwọn ìpàdé Kristẹni àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. (2 Pétérù 3:3, 4, 11, 12) Ẹ wo bó ṣe ṣe pàtàkì tó pé kí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ṣègbọràn sí Kristi nípa wíwá ọrọ̀ tẹ̀mí—àní sẹ́, kí wọ́n wá ra “wúrà tí a fi iná yọ́ mọ́ lọ́dọ̀” Kristi! (Ìṣípayá 3:18) Irú ojúlówó ọrọ̀ bẹ́ẹ̀ wé mọ́ jíjẹ́ ‘ọlọ́rọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtàtà, kí wọ́n jẹ́ aláìṣahun, kí wọ́n múra tán láti ṣe àjọpín.’ Bí a bá ń to dúkìá tẹ̀mí wọ̀nyí jọ, a óò máa ‘fi àìséwu to ìṣúra ìpìlẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ jọ fún ara wa de ẹ̀yìn ọ̀la, kí á lè di ìyè tòótọ́ mú gírígírí.’—1 Tímótì 6:17-19.
A Gbóríyìn fún Wọn Nítorí Ìgbọràn Wọn
19. Ìgbóríyìn àti ọ̀rọ̀ ìyànjú wo ni Jésù fún àwọn Kristẹni tó wà ní Símínà àti Filadẹ́fíà?
19 Ìjọ Símínà àti Filadẹ́fíà jẹ́ àpẹẹrẹ títayọ nínú ọ̀ràn ìgbọràn, nítorí pé Jésù kò bá wọn wí rárá nínú lẹ́tà tó kọ sí wọn. Ó sọ fáwọn tó wà ní Símínà pé: “Mo mọ ìpọ́njú àti ipò òṣì rẹ—ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ ni ọ́.” (Ìṣípayá 2:9) Wọ́n mà yàtọ̀ pátápátá sí àwọn tó wà ní Laodíkíà o, àwọn tó ń fi dúkìá tara yangàn, ṣùgbọ́n tí wọ́n jẹ́ òtòṣì paraku! Láìṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ ọ́, inú Èṣù kì í dùn sí ẹnikẹ́ni tó jẹ́ olóòótọ́ àti onígbọràn sí Kristi. Ìyẹn ló jẹ́ kí Jésù kìlọ̀ pé: “Má fòyà àwọn ohun tí ìwọ máa tó jìyà rẹ̀. Wò ó! Èṣù yóò máa bá a nìṣó ní sísọ àwọn kan nínú yín sí ẹ̀wọ̀n kí a lè dán yín wò ní kíkún, kí ẹ sì lè ní ìpọ́njú fún ọjọ́ mẹ́wàá. Jẹ́ olùṣòtítọ́ àní títí dé ikú, dájúdájú, èmi yóò sì fún ọ ní adé ìyè.” (Ìṣípayá 2:10) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Jésù gbóríyìn fáwọn tó wà ní Filadẹ́fíà, ó sọ pé: “Ìwọ . . . pa ọ̀rọ̀ mi mọ́ [tàbí pé, o ṣègbọràn sí mi], ìwọ kò sì já sí èké sí orúkọ mi. Mo ń bọ̀ kíákíá. Máa bá a nìṣó ní dídi ohun tí ìwọ ní mú ṣinṣin, kí ẹnì kankan má bàa gba adé rẹ.”—Ìṣípayá 3:8, 11.
20. Báwo ni ọ̀kẹ́ àìmọye ṣe ń pa ọ̀rọ̀ Jésù mọ́ lónìí, láìka ipò wo sí?
20 Ní “ọjọ́ Olúwa,” tó bẹ̀rẹ̀ ní 1914, ni àṣẹ́kù olóòótọ́ àtàwọn àgùntàn mìíràn alábàákẹ́gbẹ́ wọn, tí wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ àìmọye báyìí, ti ń pa ọ̀rọ̀ Jésù mọ́ nípa fífi ìtara ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà àti nípa dídi ìwà títọ́ mú gírígírí. Bíi tàwọn arákùnrin wọn ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn kan ti jìyà nítorí pé wọ́n ń ṣègbọràn sí Kristi, àní wọ́n ti sọ àwọn kan sẹ́wọ̀n àti sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ pàápàá. Àwọn mìíràn ti pa ọ̀rọ̀ Jésù mọ́ nípa jíjẹ́ kí ‘ojú wọ́n mú ọ̀nà kan,’ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìfẹ́ ọrọ̀ àti ìwọra yí wọn ká. (Mátíù 6:22, 23) Àní sẹ́, nínú gbogbo àyíká àti ipò táwọn Kristẹni tòótọ́ wà, wọ́n ń bá a lọ ní mímú inú Jèhófà dùn nípa jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ onígbọràn.—Òwe 27:11.
21. (a) Ojúṣe tẹ̀mí wo ni ẹgbẹ́ ẹrú náà yóò máa ṣe nìṣó? (b) Báwo la ṣe lè fi hàn pé lóòótọ́ a fẹ́ máa ṣègbọràn sí Ṣílò?
21 Bí ìpọ́njú ńlá ti ń sún mọ́lé, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” kò juwọ́ sílẹ̀ nínú ṣíṣègbọràn sí Kristi Ọ̀gá náà. Èyí wé mọ́ pípèsè oúnjẹ tẹ̀mí lásìkò fún agboolé Ọlọ́run. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa bá a lọ ní mímọrírì ètò àgbàyanu Jèhófà àti ohun tó ń pèsè. Bí a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a óò máa fi hàn pé à ń ṣègbọràn sí Ṣílò, ẹni tí yóò fi ìyè àìnípẹ̀kun san èrè fún gbogbo ọmọ abẹ́ àkóso rẹ̀.—Mátíù 24:45-47; 25:40; Jòhánù 5:22-24.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún àlàyé lórí “ìgbà méje” náà, wo orí kẹwàá ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, èyí tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.
b Fún kúlẹ̀kúlẹ̀ ìjíròrò nípa lẹ́tà méjèèje náà, jọ̀wọ́ wo ìwé Ìṣípayá—Òtéńté Rẹ̀ Títóbi Lọ́lá Kù Sí Dẹ̀dẹ̀!, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde, bẹ̀rẹ̀ látojú ewé 33.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Ipa wo ni Jésù máa kó, níbàámu pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ tí Jékọ́bù sọ nígbà tó ń kú lọ?
• Báwo la ṣe ń fi hàn pé a gbà pé Jésù ni Ṣílò náà, irú ẹ̀mí wo la sì gbọ́dọ̀ yẹra fún?
• Ìmọ̀ràn tó kàn wá lóde òní wo ló wà nínú àwọn lẹ́tà tá a kọ sí ìjọ méje inú ìwé Ìṣípayá?
• Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fara wé àwọn tó wà nínú ìjọ Símínà àti Filadẹ́fíà?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Jèhófà ń bù kún àwọn èèyàn rẹ̀ nítorí pé wọ́n ń ṣègbọràn sí “ìríjú” rẹ̀ olóòótọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Sátánì ń jẹ́ kí ṣíṣègbọràn sí Ọlọ́run nira gan-an
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ onígbọràn