Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Máa Kọ́ Ara Rẹ”

“Máa Kọ́ Ara Rẹ”

“Máa Kọ́ Ara Rẹ”

TÍTÚBỌ̀ mọ eré sá, títúbọ̀ mọ̀ ọ́n fò, àti títúbọ̀ lágbára sí i! Ohun táwọn eléré ìdárayá ilẹ̀ Gíríìsì àti Róòmù ìgbàanì ń lépa nìyẹn. Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ni wọ́n ti ń ṣe àwọn eré ìdárayá tó fa kíki tí wọ́n máa ń ṣe pẹ̀lú “ìtìlẹyìn” àwọn ọlọ́run wọn, tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún òǹwòran sì máa ń wò ó ní Olympia, Delphi, àti Nemea àti ní Isthmus ti Kọ́ríńtì. Kéèyàn tó lè láǹfààní láti kópa nínú àwọn eré ìdárayá wọ̀nyí, á ti kọ́kọ́ fi ọ̀pọ̀ ọdún ṣiṣẹ́ àṣekára. Àwọn tó bá borí máa ń gba ògo fún ara wọn àti ìlú wọn.

Nínú irú àyíká tí àṣà ìbílẹ̀ ti gbòde bẹ́ẹ̀, kò yani lẹ́nu pé àwọn tó kọ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì fi eré ìje tẹ̀mí táwọn Kristẹni ń sá wé eré ìje tàwọn sárésáré. Àpọ́sítélì Pétérù àti Pọ́ọ̀lù lo àpèjúwe àwọn eré àṣedárayá náà lọ́nà olóye láti fi kọ́ni láwọn kókó pàtàkì kan. Eré ìje Kristẹni kan náà ṣì ń bá a lọ lákòókò tiwa yìí. Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní kojú ètò àwọn nǹkan Júù; àwa tá a wà lóde òní náà ‘dojú kọ’ ètò àwọn nǹkan jákèjádò ayé tó ti sún mọ́ bèbè ìparun báyìí. (2 Tímótì 2:5; 3:1-5) Àwọn kan lè rí i pé “eré ìje ìgbàgbọ́” wọn ń mu wọ́n lómi gan-an, ó sì ń tán wọn lókun. (1 Tímótì 6:12, The New English Bible) Tá a bá gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára àwọn ọ̀nà tí Bíbélì gbà fi eré ìje Kristẹni àti tàwọn sárésáré wéra yóò ṣe wá láǹfààní gan-an.

Olùdánilẹ́kọ̀ọ́ Tó Dáńgájíá

Àṣeyọrí eléré ìdárayá kan wà lọ́wọ́ ẹni tó ń dá a lẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tí ìwé Archaeologia Graeca ń sọ nípa eré ìdárayá ìgbàanì, ó ní: “Àwọn olùdíje ní láti búra pé àwọn ti dánra wò fún oṣù mẹ́wàá gbáko láti fi múra sílẹ̀.” Àwọn Kristẹni náà nílò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kíkankíkan. Pọ́ọ̀lù gba Tímótì, tó jẹ́ Kristẹni alàgbà, níyànjú pé: “Máa kọ́ ara rẹ pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìfojúsùn rẹ.” (1 Tímótì 4:7) Ta ló ń dá Kristẹni “eléré ìdárayá” kan lẹ́kọ̀ọ́? Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni o! Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Ọlọ́run inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí gbogbo . . . yóò fúnra rẹ̀ parí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yín, yóò fìdí yín múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in, yóò sì sọ yín di alágbára.”—1 Pétérù 5:10.

Gbólóhùn náà ‘yóò parí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ rẹ’ wá látinú ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì kan tí ìwé atúmọ̀ èdè Theological Lexicon of the New Testament sọ pé ó túmọ̀ sí “láti mú kí nǹkan kan [tàbí èèyàn kan] tóótun fún ète kan, láti múra rẹ̀ sílẹ̀ àti láti mú kí ó bá ohun tá a fẹ́ lò ó fún mu.” Bákan náà ni ìwé atúmọ̀ èdè Greek-English Lexicon tí Liddell àti Scott ṣe jáde sọ pé a lè túmọ̀ ọ̀rọ̀ ìṣe yìí sí “mímúra sílẹ̀, kíkọ́ni, tàbí mímúni gbára dì dáadáa.” Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà ń gbà ‘múra wa sílẹ̀, tó ń kọ́ wa, tàbí tó ń mú wa gbára dì dáadáa’ fún eré ìje Kristẹni tó ń tánni lókun? Láti lóye ìfiwéra yìí, ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára àwọn ọ̀nà táwọn tó ń dáni lẹ́kọ̀ọ́ ń gbà ṣe é.

Ìwé náà, The Olympic Games in Ancient Greece, sọ pé: “Àwọn tó ń dá àwọn èwe lẹ́kọ̀ọ́ ní ọ̀nà méjì pàtàkì tí wọ́n gbà ń ṣe é. Èkíní nínú ète wọn ni láti fún ẹni tí wọ́n ń dá lẹ́kọ̀ọ́ náà níṣìírí pé kó sa gbogbo ipá rẹ̀ pátápátá láti rí i pé òun borí, èkejì sì ni pé kí ó mú kí ọgbọ́n àti ọ̀nà tó ń gbà ṣe nǹkan sunwọ̀n sí i.”

Bákan náà ni Jèhófà ń gbà wá níyànjú, tó sì ń fún wa lókun láti lo gbogbo agbára wa àti láti mú kí òye wa sunwọ̀n sí i nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Bíbélì, ètò àjọ rẹ̀ ti orí ilẹ̀ ayé, àti àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa tó dàgbà dénú ni Ọlọ́run wa ń lò láti fi okun kún okun wa. Nígbà mìíràn, ó máa ń lo ìbáwí láti fi kọ́ wa. (Hébérù 12:6) Àwọn ìgbà mìíràn sì wà tó máa ń fàyè gba onírúurú àdánwò àti ìṣòro láti dé bá wa ká lè mọ béèyàn ṣe ń ní ìfaradà. (Jákọ́bù 1:2-4) Ó sì máa ń pèsè okun tá a nílò.Wòlíì Aísáyà sọ pé: “Àwọn tí ó ní ìrètí nínú Jèhófà yóò jèrè agbára padà. Wọn yóò fi ìyẹ́ apá ròkè bí idì. Wọn yóò sáré, agara kì yóò sì dá wọn; wọn yóò rìn, àárẹ̀ kì yóò sì mú wọn.”—Aísáyà 40:31.

Lékè gbogbo rẹ̀, Ọlọ́run ń fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ lọ́pọ̀ yanturu, èyí tó ń fún wa lókun láti máa bá iṣẹ́ ìsìn ṣíṣètẹ́wọ́gbà tí à ń ṣe fún un nìṣó. (Lúùkù 11:13) Ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti fara da àdánwò ìgbàgbọ́ lílekoko tí kò sì tán bọ̀rọ̀. Àwọn tó ti ṣe bẹ́ẹ̀ kì í ṣe abàmì ẹ̀dá, àwọn ọkùnrin àtobìnrin bíi tiwa làwọn náà. Àmọ́ gbígbé tí wọ́n gbára lé Ọlọ́run pátápátá ló mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti fara dà á. Láìsí àní-àní, ‘agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá jẹ́ ti Ọlọ́run, kì í ṣe èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ àwa fúnra wa jáde.’—2 Kọ́ríńtì 4:7.

Olùdánilẹ́kọ̀ọ́ Tó Lẹ́mìí Ìbánikẹ́dùn

Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé ọ̀kan lára iṣẹ́ ẹni tó ń dáni lẹ́kọ̀ọ́ láyé ìgbàanì ni “kí ó mọ irú ìdánrawò tí eléré ìdárayá kan nílò fún eré ìdárayá kan pàtó àti iye ìgbà tó yẹ kó fi ṣe é.” Bí Ọlọ́run ṣe ń kọ́ wa, ó ń wo ipò ẹnì kọ̀ọ̀kan wa, ó ń wo òye wa, irú èèyàn tá a jẹ́ àti ibi tí agbára wa mọ. Láàárín àkókò tí Jèhófà ń kọ́ wa, àìmọye ìgbà là ń bẹ̀ ẹ́ bíi ti Jóòbù pé: “Jọ̀wọ́, rántí pé láti inú amọ̀ ni ìwọ ti mọ mí.” (Jóòbù 10:9) Báwo ni olùkọ́ wa tó lẹ́mìí ìbánikẹ́dùn ṣe fèsì? Dáfídì kọ̀wé nípa Jèhófà pé: “Òun fúnra rẹ̀ mọ ẹ̀dá wa, ó rántí pé ekuru ni wá.”—Sáàmù 103:14.

Àìsàn líle koko kan lè máa yọ ẹ́ lẹ́nu kíyẹn sì wá dín ohun tó o lè ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà kù, tàbí kẹ̀ kó o máa ronú pé o ò já mọ́ nǹkan kan. Bóyá ò ń sapá láti jáwọ́ nínú àṣà búburú kan, tàbí kó o máa rò pé kò lè ṣeé ṣe fún ọ láti borí ẹ̀mí ṣe-ohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe ní àdúgbò rẹ, níbi iṣẹ́ tàbí nílé ìwé. Ipòkípò tó o lè wà, má ṣe gbàgbé láé pé Jèhófà lóye àwọn ìṣòro rẹ ju ẹnikẹ́ni mìíràn lọ—ó lóye rẹ ju ìwọ alára pàápàá! Gẹ́gẹ́ bí olùdánilẹ́kọ̀ọ́ tó bìkítà, gbogbo ìgbà ló múra tan láti ràn ọ́ lọ́wọ́ tó o bá sún mọ́ ọn.—Jákọ́bù 4:8.

Àwọn tó ń dá àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ láyé ọjọ́un “máa ń dá àárẹ̀ tàbí àìlera tí ìdánrawò ń fà mọ̀ yàtọ̀ sí èyí tí àwọn nǹkan mìíràn bí ìrònú, ìbànújẹ́, ìsoríkọ́ àtàwọn nǹkan míì ń fà . . . Ọlá àṣẹ àwọn tí ń dáni lẹ́kọ̀ọ́ náà gbòòrò débi pé wọ́n lè tojú bọ ọ̀ràn tó jẹ́ nǹkan àṣírí nípa àwọn eléré ìdárayá náà kí wọ́n sì dá sí i níbi tí wọ́n bá rí i pé ó pọn dandan láti ṣe bẹ́ẹ̀.”

Ṣé ó máa ń rẹ̀ ọ́ tẹnutẹnu nígbà mìíràn tàbí àárẹ̀ máa ń mú ọ nítorí pákáǹleke àti ìdẹwò inú ayé yìí? Gẹ́gẹ́ bí olùdánilẹ́kọ̀ọ́ rẹ, Jèhófà bìkítà fún ọ gan-an ni. (1 Pétérù 5:7) Kíá ló máa ń fòye mọ àmì èyíkéyìí tó bá jẹ ti àìlera tàbí àárẹ̀ nípa tẹ̀mí tó bá hàn lára rẹ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà máa ń ro ti òmìnira tá a ní láti ṣe ohun tó wù wá àti bá a ṣe láǹfààní láti yan ohun tá a fẹ́, síbẹ̀ ó ń pèsè ìrànlọ́wọ́ àti ìtọ́sọ́nà tá a nílò nígbà tó bá pọn dandan láti ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé ó ní ire wa ayérayé lọ́kàn. (Aísáyà 30:21) Lọ́nà wo? Ó máa ń lo Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde tá a gbé ka Bíbélì, àwọn alàgbà tẹ̀mí nínú ìjọ, àti ẹgbẹ́ àwọn ará wa onífẹ̀ẹ́.

“Ìkóra-Ẹni-Níjàánu Nínú Ohun Gbogbo”

Àmọ́ ṣá o, kíkẹ́sẹjárí tún sinmi lórí nǹkan mìíràn ju wíwulẹ̀ ní olùdánilẹ́kọ̀ọ́ tó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́. Èyí tó pọ̀ jù lọ níbẹ̀ sinmi lórí eléré ìdárayá náà fúnra rẹ̀ àti bó ṣe múra tán láti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó lágbára ọ̀hún. Ìlànà tí yóò máa tẹ̀ lé kò rọrùn rárá nítorí pé ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà ní kéèyàn ta kété sí àwọn nǹkan bí ìbálòpọ̀ àti ọtí líle nínú, ó sì gba kéèyàn máa ṣọ́ oúnjẹ jẹ. Horace, akéwì kan ní ọ̀rúndún kìíní ṣááju Sànmánì Tiwa, sọ pé àwọn tó ń kópa nínú ìdíje máa “ń ta kété sí àwọn obìnrin àti wáìnì” kí “ọwọ́ wọn lè tẹ góńgó tí wọ́n ti ń wọ̀nà fún tipẹ́.” Gẹ́gẹ́ bí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ nì, F. C. Cook, ṣe sọ ọ́, àwọn tó ń kópa nínú eré ìdárayá náà ní láti lo “ìkóra-ẹni-níjàánu [kí wọ́n sì] máa ṣọ́ oúnjẹ jẹ . . . fún oṣù mẹ́wàá gbáko.”

Ìfiwéra yìí ni Pọ́ọ̀lù lò nígbà tó kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì, ìyẹn ìlú ńlá tí wọ́n ti mọ Eré Ìdárayá Isthmus dáadáa, ó ní: “Olúkúlùkù ènìyàn tí ń kó ipa nínú ìdíje a máa lo ìkóra-ẹni-níjàánu nínú ohun gbogbo.” (1 Kọ́ríńtì 9:25) Àwọn Kristẹni tòótọ́ ń yẹra fún ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, ìṣekúṣe, àti ọ̀nà ìgbésí ayé ẹlẹ́gbin táwọn èèyàn ń gbé nínú ayé. (Éfésù 5:3-5; 1 Jòhánù 2:15-17) A gbọ́dọ̀ bọ́ àwọn ìṣesí tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run àti Ìwé Mímọ́ mu sílẹ̀, ká sì fi àwọn ànímọ́ bíi ti Kristi rọ́pò wọn.—Kólósè 3:9, 10, 12.

Báwo la ṣe lè ṣe èyí? Lọ́nà kan, kíyè sí àpèjúwe tó lágbára tí Pọ́ọ̀lù fi fèsì, ó ní: “Mo ń lu ara mi kíkankíkan, mo sì ń darí rẹ̀ bí ẹrú, pé, lẹ́yìn tí mo bá ti wàásù fún àwọn ẹlòmíràn, kí èmi fúnra mi má bàa di ẹni tí a kò tẹ́wọ́ gbà lọ́nà kan ṣáá.”—1 Kọ́ríńtì 9:27.

Kókó tí Pọ́ọ̀lù mú jáde níhìn-ín mà lágbára o! Kò sọ pé kéèyàn dá ọgbẹ́ sí ara rẹ̀ lára. Dípò ìyẹn, ńṣe ló ń fi hàn pé òun alára máa ń bá ara òun ja ìjàkadì. Àwọn ìgbà mìíràn wà tó máa ń ṣe àwọn ohun tí kò fẹ́ ṣe, ìgbà mìíràn sì rèé kò ní í ṣe àwọn ohun tó wù ú láti ṣe. Àmọ́ ó sapá gidigidi kí àìlera náà má lè borí òun. Ó ‘lu ara rẹ̀ kíkankíkan,’ ó ń làkàkà láti borí àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti ìṣesí ti ara.—Róòmù 7:21-25.

Ohun tó ṣe yìí ló yẹ kí gbogbo Kristẹni ṣe. Pọ́ọ̀lù sọ nípa ìyípadà tí àwọn kan ní Kọ́ríńtì ṣe, ìyẹn àwọn tó ti fìgbà kan ń lọ́wọ́ nínú àgbèrè, ìbọ̀rìṣà, ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀, olè, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Kí ló mú kí wọ́n yí padà? Agbára Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni àti ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú bí wọ́n ṣe pinnu láti ṣe ohun tó fẹ́. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ṣùgbọ́n a ti wẹ̀ yín mọ́, ṣùgbọ́n a ti sọ yín di mímọ́, ṣùgbọ́n a ti polongo yín ní olódodo ní orúkọ Olúwa wa Jésù Kristi àti pẹ̀lú ẹ̀mí Ọlọ́run wa.” (1 Kọ́ríńtì 6:9-11) Pétérù kọ ohun kan náà nípa àwọn tó ti jáwọ́ nínú àwọn àṣà búburú bẹ́ẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, gbogbo wọ́n ló ti yí padà tọkàntọkàn.—1 Pétérù 4:3, 4.

Ìsapá Tí A Darí Dáradára

Pọ́ọ̀lù ṣàpèjúwe bí òun ṣe ń pọkàn pọ̀ tí ojú òun sì ń mú ọ̀nà kan nínú lílépa àwọn góńgó tẹ̀mí, nípa sísọ pé: “Bí mo ti ń darí àwọn ẹ̀ṣẹ́ mi jẹ́ láti má ṣe máa gbá afẹ́fẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 9:26) Báwo ni akànṣẹ́ kan ṣe ń darí àwọn ẹ̀ṣẹ́ rẹ̀? Ìwé náà, The Life of the Greeks and Romans dáhùn pé: “Kì í ṣe kó kàn máa fi gbogbo agbára rẹ̀ ju ẹ̀ṣẹ́ là ń sọ, ó tún ní láti fojú sílẹ̀ dáadáa kó sì wo ibi tí àìlera ẹni tí wọ́n jọ ń jà wà. Bákan náà ni jíjẹ́ ọ̀jáfáfá ti wọ́n máa ń kọ́ni láwọn ilé ẹ̀kọ́ ìjàkadì àti títètè gbọ́n já ẹni tí wọ́n jọ ń jà tún ṣe pàtàkì gan-an.”

Ẹran ara aláìpé àwa fúnra wa jẹ́ ọ̀kan lára àwọn nǹkan tá à ń bá jìjàkadì. Ǹjẹ́ a ti mọ ohun tó jẹ́ “àìlera” àwa fúnra wa? Ǹjẹ́ à ń fẹ́ láti wo ara wa lọ́nà tí àwọn ẹlòmíràn gbà ń wò wá—àgàgà bí Sátánì ṣe lè máa wò wá? Ìyẹn béèrè yíyẹ ara ẹni wò dáadáa láìṣàbòsí, kéèyàn sì fẹ́ láti ṣe àtúnṣe. Ó rọrùn gan-an láti tan ara ẹni jẹ. (Jákọ́bù 1:22) Ó rọrùn gan-an fúnni láti wá àwíjàre fún ìwà òmùgọ̀ kan téèyàn hù! (1 Sámúẹ́lì 15:13-15, 20, 21) Ìyẹn ò sì yàtọ̀ sí bí ìgbà téèyàn ń “gbá afẹ́fẹ́.”

Láwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí, àwọn tó fẹ́ múnú Jèhófà dùn, tí wọ́n sì fẹ́ jèrè ìyè àìnípẹ̀kun kò gbọ́dọ̀ lọ́ tìkọ̀ láti ṣe yíyàn láàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́, láàárín ìjọ Ọlọ́run àti ayé tó ti dómùkẹ̀. Wọ́n gbọ́dọ̀ yẹra fún ṣíṣe ségesège, ìyẹn ni jíjẹ́ ‘aláìnípinnu, aláìdúrósójúkan ní gbogbo ọ̀nà wọn.’ (Jákọ́bù 1:8) Wọn ò gbọ́dọ̀ fi agbára wọn ṣòfò lórí àwọn ìlépa ohun asán. Nígbà tí èèyàn bá ń tọ ipa ọ̀nà ìdúró ṣánṣán yìí, tó sì pọkàn pọ̀, irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́ aláyọ̀ ‘ìlọsíwájú rẹ̀ yóò sì hàn kedere fún gbogbo ènìyàn.’—1 Tímótì 4:15.

Dájúdájú, eré ìje Kristẹni ń bá a nìṣó. Jèhófà—Olùdánilẹ́kọ̀ọ́ wa Atóbilọ́lá—ń fi tìfẹ́tìfẹ́ pèsè ìtọ́ni àti ìrànlọ́wọ́ tá a nílò láti lè fara dà á ká sì lè jagun mólú níkẹyìn. (Aísáyà 48:17) Bíi ti àwọn eléré ìdárayá ìgbàanì, a gbọ́dọ̀ kára wa lọ́wọ́ kò, ká ní ìkóra-ẹni-níjàánu, ká sì pọkàn pọ̀ nínú ìjà tí à ń jà fún ìgbàgbọ́. Ìsapá wa tá a darí dáadáa yóò ní èrè jaburata.—Hébérù 11:6.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 31]

‘Fi Òróró Pa Á’

Ẹni tí ń fi òróró pani lára máa ń kópa nínú ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó wà fáwọn eléré ìdárayá nílẹ̀ Gíríìsì ìgbàanì. Iṣẹ́ rẹ̀ ni pé kó fi òróró wọ́ra fún àwọn ọkùnrin tó fẹ́ ṣe eré ìmárale náà. Ìwé The Olympic Games in Ancient Greece sọ pé, àwọn tí ń dáni lẹ́kọ̀ọ́ “ti kíyè sí i pé wíwọ́ni lára dáadáa kí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó bẹ̀rẹ̀ máa ń ṣàǹfààní tó pọ̀, àti pé fífi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wọ́ra fún àwọn eléré ìdárayá lẹ́yìn ìdálẹ́kọ̀ọ́ fún àkókò gígùn máa ń jẹ́ kí ara wọ́n nà kí eegun wọ́n tò, kí ara wọn sì padà bọ̀ sípò.”

Bí fífi òróró pa ẹnì kan lára ṣe lè tu onítọ̀hún lára, tó lè jẹ́ kí ara rẹ̀ nà, tó sì lè wò ó sàn, bẹ́ẹ̀ náà ni lílo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti fi ṣèrànwọ́ fún Kristẹni “eléré ìdárayá” kan tó ti rẹ̀, ṣe lè tọ́ ọ sọ́nà, kó tù ú nínú, kó sì wò ó sàn. Ìdí nìyẹn tí a fi gba àwọn àgbà ọkùnrin tó wà nínú ìjọ níyànjú lábẹ́ ìtọ́sọ́nà látọ̀dọ̀ Jèhófà pé kí wọ́n gbàdúrà lé irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ lórí, kí wọ́n “fi òróró pa á ní orúkọ Jèhófà” lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Èyí tó jẹ́ ọ̀nà pàtàkì kan láti múni padà bọ̀ sípò nípa tẹ̀mí.—Jákọ́bù 5:13-15; Sáàmù 141:5.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Lẹ́yìn tí wọ́n bá rúbọ tán, àwọn eléré ìdárayá á wá búra pé àwọn ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ fún oṣù mẹ́wàá

[Credit Line]

Musée du Louvre, Paris

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 29]

Gbogbo ẹ̀tọ́ jẹ ti British Museum