Mo Dúpẹ́ fún Àǹfààní Kíkópa Nínú Ìmúgbòòrò Iṣẹ́ náà Lẹ́yìn Ogun
Ìtàn Ìgbésí Ayé
Mo Dúpẹ́ fún Àǹfààní Kíkópa Nínú Ìmúgbòòrò Iṣẹ́ náà Lẹ́yìn Ogun
GẸ́GẸ́ BÍ FILIP S. HOFFMANN ṢE SỌ Ọ́
Ogun Àgbáyé Kejì ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ní May 1945 ni. Lóṣù December ọdún yẹn, Nathan H. Knorr, tó ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé, ṣèbẹ̀wò sí Denmark, tòun ti akọ̀wé rẹ̀, Milton G. Henschel, tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà yẹn. A lọ rẹ́ǹtì gbọ̀ngàn ńlá kan fún àbẹ̀wò tí à ń fi ìháragàgà wọ̀nà fún yẹn. Ọ̀rọ̀ Arákùnrin Henschel ru àwa ọ̀dọ́ sókè gan-an, torí pé ojúgbà wa ni, ohun tó sì fi ṣe ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni: “Ranti ẹlẹda rẹ nisisiyi li ọjọ ewe rẹ.”—Oníwàásù 12:1, Bibeli Mimọ.
NÍGBÀ àbẹ̀wò yẹn, a gbọ́ pé oríṣiríṣi ohun amóríwú ló ń ṣẹlẹ̀ láti mú kí iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé tẹ̀ síwájú, wọ́n sì sọ pé àwa náà lè nípìn-ín nínú ayọ̀ náà. (Mátíù 24:14) Bí àpẹẹrẹ, a gbọ́ pé wọ́n ti ṣí ilé ẹ̀kọ́ tuntun kan ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, fún dídá àwọn ọ̀dọ́kùnrin àti ọ̀dọ́bìnrin lẹ́kọ̀ọ́ láti di míṣọ́nnárì. Arákùnrin Knorr tẹnu mọ́ ọn pé bí wọ́n bá pè wá fún ilé ẹ̀kọ́ yẹn, “lílọ tá a bá lọ, ká má retí àtipadà sílé o,” torí pé a ò ní mọ ibi tí wọ́n máa rán wa lọ tá a bá ṣe tán. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwa kan forúkọ sílẹ̀ fún ilé ẹ̀kọ́ náà.
Kí n tó dẹ́nu lé àwọn ohun tójú mi rí lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, ẹ jẹ́ kí n bẹ̀rẹ̀ ìtàn náà láti ìgbà tí wọ́n ti bí mi lọ́dún 1919. Àwọn nǹkan kan ṣẹlẹ̀ ṣáájú ogun náà àti nígbà ogun náà tó ní ipa ńláǹlà lórí ìgbésí ayé mi.
Ẹni Ìtanù Nínú Ìdílé Ló Mú Òtítọ́ Bíbélì Wá
Nígbà tí ìyá mi lóyún èmi tí mo jẹ́ àkọ́bí rẹ̀, àdúrà rẹ̀ ni pé bí mo bá jẹ́ ọkùnrin, kí n di míṣọ́nnárì. Ọkùnrin tí wọ́n bí màmá mi lé jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn orúkọ tá à ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn, ṣùgbọ́n
ẹni ìtanù làwọn aráalé ka ọkùnrin yìí sí. Ilé wa ò jìn sílùú Copenhagen, nítorí náà tí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá wá ṣe àpéjọ ọdọọdún níbẹ̀, màmá mi máa ń ní kí Thomas ẹ̀gbọ́n rẹ̀, tó ń gbé lọ́nà jíjìn, wá dé sọ́dọ̀ wa. Nígbà tó fi máa di ọdún 1930, ìmọ̀ jíjinlẹ̀ tó ní nípa Bíbélì àti bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe mọ́gbọ́n dání tó, mú kí màmá mi di Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.Màmá mi fẹ́ràn Bíbélì. Níbàámu pẹ̀lú àṣẹ tó wà nínú Diutarónómì 6:7, ó máa ń kọ́ èmi àti àbúrò mi obìnrin ‘nígbà tó bá jókòó nínú ilé rẹ̀, nígbà tó bá ń rìn lójú ọ̀nà, nígbà tó bá dùbúlẹ̀ tàbí nígbà tó bá dìde.’ Bí àkókò ti ń lọ, mo bẹ̀rẹ̀ sí wàásù láti ilé dé ilé. Mo máa ń gbádùn jíjíròrò àwọn kókó bí àìleèkú ọkàn àti iná ọ̀run àpáàdì, tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ń fi kọ́ni. Mo máa ń fi yé wọn yékéyéké látinú Bíbélì pé ẹ̀kọ́ èké làwọn ẹ̀kọ́ yẹn.—Sáàmù 146:3, 4; Oníwàásù 9:5, 10; Ìsíkíẹ́lì 18:4.
Ìdílé Wa Tún Padà Ṣọ̀kan
Lẹ́yìn àpéjọ kan nílùú Copenhagen lọ́dún 1937, wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ fúngbà díẹ̀ níbi tí ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Denmark ń kó ìwé sí. Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ tán nílé ẹ̀kọ́ṣẹ́ òwò ni, mi ò sì ní bùkátà tí mò ń gbé, nítorí náà mo yọ̀ǹda ara mi láti lọ ṣiṣẹ́ nílé ìkówèésí náà. Nígbà tíṣẹ́ ibẹ̀ parí, wọ́n ní kí n kúkú wá máa bá àwọn ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka iléeṣẹ́. Láìpẹ́ lẹ́yìn ìyẹn ni mo fi ilé sílẹ̀, tí mo kó lọ sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa nílùú Copenhagen, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò tíì ṣèrìbọmi lákòókò yẹn. Bíbá àwọn Kristẹni tó dàgbà dénú rìn lójoojúmọ́ ràn mí lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Ọdún tó tẹ̀ lé e, ìyẹn ní January 1, 1938, ni mo ṣèrìbọmi láti fi hàn pé mo ti ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run.
Ogun Àgbáyé Kejì bẹ́ sílẹ̀ ní September 1939. Ẹ̀yìn ìyẹn làwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Jámánì gba Denmark ní April 9, 1940. Níwọ̀n bí wọ́n ti fún àwa ọmọ Denmark lómìnira fàlàlà, iṣẹ́ ìwàásù wa ń bá a lọ láìsọsẹ̀.
Ohun alárinrin kan wá ṣẹlẹ̀. Bàbá mi di ògbóṣáṣá Ẹlẹ́rìí olóòótọ́, èyí sì mú kí ayọ̀ ìdílé wa kún. Nítorí náà, nígbà tí wọ́n pe èmi àtàwọn arákùnrin mẹ́rin mìíràn láti Denmark wá sí kíláàsì kẹjọ Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, ìdílé mi lódindi tì mí lẹ́yìn. Ọgbà iléèwé tó lẹ́wà gan-an nítòsí South Lansing, ní ìpínlẹ̀ New York la ti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ olóṣù márùn-ún ọ̀hún, èyí tó bẹ̀rẹ̀ ní September 1946.
Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ní Gílíádì àti Lẹ́yìn Náà
Gílíádì fún wa ní àǹfààní alárinrin láti ní àwọn ọ̀rẹ́ tuntun. Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan tí èmi àti Harold King ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ń gbatẹ́gùn kiri ọgbà iléèwé, a bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ nípa ibi tó ṣeé ṣe kí wọ́n rán wa lọ tá a bá parí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ wa. Harold sọ pé: “Mo mọ̀ pé mo ṣì máa padà rí àwọn òkè funfun Dover ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.” Ó ṣì rí i lóòótọ́, àmọ́ ó gba ọdún mẹ́tàdínlógún gbáko kó tó tún fojú gán-án-ní àwọn ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ yẹn, inú ọgbà ẹ̀wọ̀n àdáwà ní ilẹ̀ China ló sì ti lo ọdún mẹ́rin àtààbọ̀ lára ọdún mẹ́tàdínlógún yẹn! a
Lẹ́yìn tá a kẹ́kọ̀ọ́ yege, wọ́n rán mi lọ sílùú Texas, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, pé kí n lọ máa sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò níbẹ̀, kí n máa bẹ ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wò láti ràn wọ́n lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. Wọ́n gbà mí tọwọ́ tẹsẹ̀. Inú àwọn ará ní Texas dùn pé ọ̀dọ́ ará Yúróòpù tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ló ń bẹ̀ wọ́n wò. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn oṣù méje péré ní Texas, wọ́n ní kí n máa bọ̀ ní orílé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn, New York. Nígbà tí mo débẹ̀, Arákùnrin Knorr ní kí n máa ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì, ó ní kí n máa fojú sí bí iṣẹ́ ṣe ń lọ sí ní gbogbo ẹ̀ka iṣẹ́ Bẹ́tẹ́lì. Màá wá fi ohun tí mo kọ́ sílò nígbà tí mo bá padà dé Denmark, màá rí i dájú pé gbogbo nǹkan tá à ń ṣe níbẹ̀ ló bá ti Brooklyn mu. Ohun tí wọ́n ń fẹ́ ni pé kí ètò ìṣiṣẹ́ ní àwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́ kárí ayé bára mu, kí gbogbo nǹkan lè máa lọ déédéé. Nígbà tó ṣe, Arákùnrin Knorr ní kí n lọ ṣiṣẹ́ ní Jámánì.
Fífi Ìtọ́ni Sílò Láwọn Ẹ̀ka Iléeṣẹ́
Nígbà tí mo dé ìlú Wiesbaden, ní Jámánì, ní July 1949, ọ̀pọ̀ ìlú Jámánì ló ṣì jẹ́ ahoro. Àwọn tó ti fojú winá inúnibíni látìgbà tí Hitler ti gbàjọba lọ́dún 1933 ló ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù náà. Àwọn kan lára wọn ti lo ọdún mẹ́jọ sí mẹ́wàá tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ pàápàá lẹ́wọ̀n àti ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́! Irú àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí mo bá ṣiṣẹ́ fọ́dún mẹ́ta àtààbọ̀ nìyẹn. Àpẹẹrẹ títayọ wọn rán mi létí ọ̀rọ̀ òpìtàn ará Jámánì nì, Gabriele Yonan, tó kọ̀wé pé: “Ká ní kò sí àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni wọ̀nyí tó dúró ṣinṣin lábẹ́ àṣẹ oníkùmọ̀ ti Ẹgbẹ́ Òṣèlú Násì ni, à bá máa ṣiyèméjì nípa bóyá ó tiẹ̀ ṣeé ṣe rárá láti tẹ̀ lé àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Kristẹni tí Jésù fi kọ́ni, àgàgà lójú ohun tó ṣẹlẹ̀ nílùú Auschwitz àti Ìpakúpa Rẹpẹtẹ náà.”
Irú iṣẹ́ tí mo ṣe ní Denmark ni mo tún wá ṣe ní ẹ̀ka yìí: mò ń kọ́ wọn ní ọ̀nà tuntun, tó bára mu tí à ń tẹ̀ lé nínú àwọn ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ìṣètò. Gbàrà táwọn ará ní Jámánì rí i pé àtúnṣe náà kì í ṣe láti bẹnu àtẹ́ lu iṣẹ́ wọn—bí kò ṣe pé àkókò ti tó láti túbọ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀ka yòókù àti orílé iṣẹ́, tìtara-tìtara ni wọ́n fi tẹ́wọ́ gbà á, pẹ̀lú ẹ̀mí ìfọwọ́sowọ́pọ̀.
Lọ́dún 1952, lẹ́tà kan dé látọ̀dọ̀ Arákùnrin Knorr tó sọ pé kí n kọjá sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa nílùú Bern, ní Switzerland. Wọ́n yàn mí ṣe alábòójútó ẹ̀ka yẹn, bẹ̀rẹ̀ láti January 1, 1953.
Ayọ̀ Mi Tún Kún Sí I ní Switzerland
Kò pẹ́ tí mo dé Switzerland ni mo bá Esther pàdé nígbà àpéjọ kan, bá a ṣe bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ra wa sọ́nà nìyẹn. Ní August 1954, Arákùnrin Knorr
sọ pé kí n máa bọ̀ ní Brooklyn, níbi tí wọ́n ti ṣàlàyé iṣẹ́ tuntun kan tó jẹ́ amóríyá fún mi. Níwọ̀n bí iye àwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́ ti pọ̀ sí i, tí wọ́n sì ti fẹ̀ sí i kárí ayé, ìṣètò tuntun kan ti délẹ̀. Wọ́n pín àgbáyé sí àwọn ìpínlẹ̀ ńláńlá, tí alábòójútó ìpínlẹ̀ ńlá á máa bẹ̀ wò. Wọ́n ní kí n lọ bẹ méjì wò lára ìpínlẹ̀ ńlá wọ̀nyí: ìyẹn Yúróòpù àti àgbègbè Mẹditaréníà.Láìpẹ́ lẹ́yìn àbẹ̀wò ráńpẹ́ tí mo ṣe sí Brooklyn, mo padà sí Switzerland, mo wá palẹ̀ mọ́ láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìbẹ̀wò ẹlẹ́kùnjẹkùn. Èmi àti Esther ti ṣègbéyàwó, a sì jọ ń sìn ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa ní Switzerland. Ibi tí mo kọ́kọ́ lọ bẹ̀ wò ni àwọn ilé míṣọ́nnárì àtàwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa ní Ítálì, Gíríìsì, Kípírọ́sì, àtàwọn orílẹ̀-èdè tí ń bẹ ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn àtàwọn tó wà ní etíkun Àríwá Áfíríkà, àti Sípéènì àti ilẹ̀ Potogí—orílẹ̀-èdè mẹ́tàlá lápapọ̀. Kò pẹ́ tí mo padà dé sí Bern, tí mo tún forí lé gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ní Yúróòpù tó wà ní ìwọ̀ oòrùn àwọn àgbègbè tí ilẹ̀ Rọ́ṣíà ń ṣàkóso. Ní ọdún àkọ́kọ́ ìgbéyàwó wa, odindi oṣù mẹ́fà ni mi ò fi sí nílé, tí mò ń sin àwọn Kristẹni arákùnrin wa.
Ipò Nǹkan Yí Padà
Lọ́dún 1957, Esther rí i pé òun ti lóyún, níwọ̀n bí kò ti sáyè fáwọn òbí ọlọ́mọ wẹ́wẹ́ ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa, a pinnu pé a ó padà sí Denmark, bàbá mi sì ní ká máa wá gbé lọ́dọ̀ òun. Esther ń tọ́jú Rakel, ọmọbìnrin wa àti bàbá mi, èmi ní tèmi ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́. Mo jẹ́ olùkọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà àti Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, mo tún ń sìn nìṣó gẹ́gẹ́ bí alábòójútó ìpínlẹ̀ ńlá.
Iṣẹ́ bíbẹ ìpínlẹ̀ ńlá wò ń béèrè pé kí n máa rìnrìn àjò ọlọ́jọ́ gbọọrọ, ó dùn mí pé, kò jẹ́ kí n ráyè fara mọ́ ọmọbìnrin wa. Èyí sì dá ìṣòro tirẹ̀ sílẹ̀. Ìgbà kan wà tí mo dúró pẹ́ díẹ̀ nílùú Paris, nígbà tá à ń ṣètò iléeṣẹ́ èrọ ìtẹ̀wé kékeré kan. Bí Esther àti Rakel ṣe wọ ọkọ̀ ojú irin láti wá rí mi nìyẹn, wọ́n sì gúnlẹ̀ sí ibùdókọ̀ Gare du Nord. Èmi àti Arákùnrin Léopold Jontès láti ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa la lọ pàdé wọn. Rakel dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà ní ibùdókọ̀ náà, ó kọ́kọ́ wo Léopold, ó wá wò mí, ó tún padà wo Léopold, bó ṣe fò mọ́ Léopold nìyẹn!
Ìyípadà ńlá tó tún wáyé ni pé, nígbà tí mo di ẹni ọdún márùndínláàádọ́ta, mo fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún
sílẹ̀ láti lọ ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, kí n lè gbọ́ bùkátà ìdílé mi. Ìrírí tí mo ní gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ kí n lè ríṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi mọ́níjà tí ń bójú tó àwọn ẹrù tí wọ́n ń kó ránṣẹ́ sí ilẹ̀ mìíràn. Lẹ́yìn tí mo bá iléeṣẹ́ yẹn ṣiṣẹ́ fún nǹkan bí ọdún mẹ́sàn-án, tí Rakel sì ti jáde iléèwé, a pinnu pé a ó tẹ̀ lé ìṣírí náà láti ṣí lọ síbi tí àìní fún àwọn oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run gbé pọ̀.À ń wò ó bóyá á ṣeé ṣe láti ṣí lọ sí Norway. Fún ìdí yìí, mo kàn sí àjọ kan tí ń báni wáṣẹ́ bóyá màá lè ríṣẹ́ níbẹ̀. Kò jọ pé ó máa bọ́ sí i. Kò jọ pé ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́ta á ríṣẹ́ níbẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, mo kàn sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa nílùú Oslo, mo sì rẹ́ǹtì ilé sítòsí ìlú Drøbak, pẹ̀lú ìrètí pé àǹfààní iṣẹ́ á yọ. Ó sì yọ lóòótọ́, bá a ṣe bẹ̀rẹ̀ sí gbádùn iṣẹ́ ìsìn Ìjọba náà ní Norway nìyẹn o.
Àwọn àkókò tí a gbádùn iṣẹ́ náà jù lọ ni ìgbà tí ọ̀pọ̀ jù lọ nínú ìjọ wa máa ń rìnrìn àjò lọ sí àríwá láti lọ ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ tí a kò pín fúnni. A máa ń háyà àgọ́ táwọn èèyàn pa, a sì máa ń bẹ àwọn èèyàn wò ní àwọn oko tó wà káàkiri òkè ẹlẹ́wà wọ̀nyẹn. Ohun ayọ̀ gidi ló jẹ́ láti sọ nípa Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn oníwà-bí-ọ̀rẹ́ wọ̀nyí. A máa ń fìwé síta gan-an, àmọ́ ọdún kan á kọjá ká tó lè ṣe ìpadàbẹ̀wò. Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn náà ò gbàgbé wa o! Esther àti Rakel ṣì máa ń rántí ìgbà tá a padà lọ, tí wọ́n dì mọ́ wa bí aráalé wọn tí wọ́n ti rí tipẹ́. Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta ní Norway, a padà sí Denmark.
Ayọ̀ Jíjẹ́ Onídìílé
Láìpẹ́ ni Rakel àti Niels Højer, tó jẹ́ aṣáájú ọ̀nà alákòókò kíkún, bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ra wọn sọ́nà. Lẹ́yìn ìgbéyàwó wọn, Niels àti Rakel ń bá iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà nìṣó kó tó di pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bímọ. Niels jẹ́ ọkọ rere àti bàbá rere, tí kò fi ọ̀ràn ìdílé rẹ̀ ṣeré rárá. Láàárọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ kan, ó gbé ọmọkùnrin rẹ̀ sórí kẹ̀kẹ́ lọ sí etíkun láti lọ wo yíyọ oòrùn. Ará àdúgbò wọn kan béèrè ohun tí wọ́n lọ ṣe níbẹ̀ lọ́wọ́ ọmọ yìí. Ó dá a lóhùn pé: “A lọ gbàdúrà sí Jèhófà ni.”
Ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, èmi àti Esther wà níbi ìrìbọmi àwọn méjì tó dàgbà jù lọ lára àwọn ọmọ-ọmọ wa, ìyẹn Benjamin àti Nadja. Niels wà lára èrò ìwòran, ó sì ṣàdédé wá dúró níwájú mi kí ojú wa lè ṣe mẹ́rin. Ó sì sọ pé: “Ẹni tá a bá ń pè lọ́kùnrin kì í sunkún o.” Ṣùgbọ́n, ọ̀rọ̀ yẹn ò tíì kúrò lẹ́nu rẹ̀ tí àwa méjèèjì fi gbára wa mú, tá a sì bẹ̀rẹ̀ sí sunkún. Ẹ wo bó ṣe jẹ́ ohun ayọ̀ tó láti ní àna tẹ́ ẹ lè jọ rẹ́rìn-ín pa pọ̀, tẹ́ ẹ sì lè jọ sunkún pa pọ̀!
A Ṣì Ń Bá Àwọn Ipò Tuntun Yí
Ìbùkún míì tún dé nígbà tí wọ́n ní kí èmi àti Esther padà sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa ní Denmark. Àmọ́, nígbà yẹn wọ́n ti ń ṣètò láti kọ́ ẹ̀ka mìíràn tó tóbi gan-an sílùú Holbæk. Mo láǹfààní láti kópa nínú bíbójútó iṣẹ́ ìkọ́lé náà, iṣẹ́ tó jẹ́ pé àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láìgbowó ló ṣe gbogbo rẹ̀ pátá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òtútù pọ̀ gan-an nígbà yẹn, nígbà tó máa di ìparí ọdún 1982, a ti parí èyí tó pọ̀ jù lọ nínú iṣẹ́ náà, inú wa sì dùn láti ṣí lọ sí ẹ̀ka tó fẹ̀ sí i, tó sì dáa ju ti tẹ́lẹ̀ lọ!
Kò pẹ́ tí mo tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ọ́fíìsì, iṣẹ́ tí mo gbádùn gan-an. Esther ní tirẹ̀ ń ṣiṣẹ́ dídáhùn ìkésíni orí tẹlifóònù. Àmọ́ bí àkókò ti ń lọ, wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ kan fún un láti pààrọ̀ ìgbáròkó rẹ̀, nígbà tó sì di ọdún kan àtààbọ̀ lẹ́yìn náà, wọ́n tún ṣe iṣẹ́ abẹ míì lórí àpò òróòro rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ka iléeṣẹ́ gba tiwa rò, a pinnu pé ohun tó máa dáa jù ni pé ká fi ẹ̀ka iléeṣẹ́ sílẹ̀. A padà sí ìjọ tí ọmọbìnrin wa àti ìdílé rẹ̀ ń dara pọ̀ mọ́.
Ara Esther ò fi bẹ́ẹ̀ le mọ́ báyìí o. Ṣùgbọ́n, mo lè sọ tọkàntọkàn pé jálẹ̀ gbogbo ọdún iṣẹ́ ìsìn wa pa pọ̀, pẹ̀lú ipò àwọn nǹkan tí kò dúró sójú kan rárá, igi-lẹ́yìn-ọgbà àti alábàárò tó dáńgájíá ni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ara ti ń di ara àgbà, àwa méjèèjì ṣì ń ṣe ìwọ̀n tá a lè ṣe nínú iṣẹ́ ìwàásù náà. Nígbà tí mo bá ronú nípa ìgbésí ayé mi, pẹ̀lú ọpẹ́ ni mo máa ń rántí ọ̀rọ̀ onísáàmù náà, pé: “Ọlọ́run, ìwọ ti kọ́ mi láti ìgbà èwe mi wá.”—Sáàmù 71:17.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Ilé Ìṣọ́, July 15, 1963 (èdè Gẹ̀ẹ́sì), ojú ìwé 437 sí 442.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
À ń já ẹrù ìwé ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa tí à ń kọ́ lọ́wọ́ ní Jámánì lọ́dún 1949
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Lára àwọn Ẹlẹ́rìí tá a jọ ṣiṣẹ́ ni àwọn wọ̀nyí tó ti lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ bọ̀
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Èmi àti Esther lónìí àti lọ́jọ́ ìgbéyàwó wa ní Bẹ́tẹ́lì ti Bern, ní October 1955