Àkókò Láti Dáwọ̀ọ́ Ìdùnnú Ní Àwọn Orílẹ̀-Èdè Balkan
Àkókò Láti Dáwọ̀ọ́ Ìdùnnú Ní Àwọn Orílẹ̀-Èdè Balkan
Ọdún 1922 mà ni o. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n ń pè ní Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Onítara nígbà yẹn, ṣèpàdé kan nílùú Innsbruck, ní Austria. Franz Brand, ọ̀dọ́mọkùnrin tó wá láti Ìlú Apatin tó wà lágbègbè Vojvodina ní Serbia, wà ní àpéjọ yìí. Bí ẹni tó ń sọ̀rọ̀ lórí pèpéle ṣe pe Jèhófà, ìyẹn orúkọ Ọlọ́run báyìí làwọn jàǹdùkú kan bẹ̀rẹ̀ sí pariwo débi pé olùbánisọ̀rọ̀ náà ò lè sọ̀rọ̀ mọ́, ibẹ̀ sì ni ìpàdé ọ̀hún parí sí. Àmọ́, ohun tí Franz gbọ́ wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wàásù ìhìn rere Ìjọba náà ní ìlú rẹ̀. Ìbẹ̀rẹ̀ ìdàgbàsókè tẹ̀mí tó ń wúni lórí lèyí jẹ́ láwọn orílẹ̀-èdè Balkan.
BÍ Ọ̀PỌ̀ èèyàn bá gbọ́ orúkọ náà Yugoslavia lónìí, ohun tó máa wá sọ́kàn wọn ni ogun àti ìpakúpa. Ohun mìíràn tó ń bani nínú jẹ́ tó tún máa ń wá sọ́kàn èèyàn ni àwọn púpọ̀ rẹpẹtẹ tí wọ́n pa nípakúpa, àwọn olùwá-ibi-ìsádi táyé ti sú, àwọn ilé tó bà jẹ́ àtàwọn ọmọ òrukàn tí palaba ìyà ń jẹ. Ìrora tí ò ṣe é fẹnu sọ àti ìyà ńláǹlà ni ogun tó jà níbi Ìyawọlẹ̀ Omi Balkan lọ́dún 1991 sí 1995 fà bá àgbègbè náà, ó sì mú kí gbogbo ìrètí pé ìsapá ẹ̀dá èèyàn á mú kí ọjọ́ ọ̀la tuni lára já sófo. Ogun yìí ló fà á tí palaba ìyà fi ń jẹ àwọn tó wà ní ilẹ̀ Yugoslavia tẹ́lẹ̀ rí nítorí ètò ọrọ̀ ajé wọn tó ti dẹnu kọlẹ̀ àti inú ipò òṣì lílékenkà tí wọ́n wà. a
Pẹ̀lú báwọn èèyàn ṣe ń jẹ palaba ìyà lágbègbè yìí, ẹnì kan ò lè retí pé káwọn tó wà níbẹ̀ máa dáwọ̀ọ́ ìdùnnú. Àmọ́, ó yani lẹ́nu pé irú àwọn èèyàn tó ń dáwọ̀ọ́ ìdùnnú bẹ́ẹ̀ wà níbẹ̀. Kódà, ọjọ́ àkànṣe kan wà táwọn èèyàn aláyọ̀ yìí fi dáwọ̀ọ́ ìdùnnú nígbà tó kù díẹ̀ kí ọ̀rúndún ogún parí. Báwo ni ayọ̀ náà ṣe kan Franz Brand, ìyẹn ọ̀dọ́mọkùnrin tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀?
Ìdàgbàsókè Tẹ̀mí ní Àwọn Orílẹ̀-Èdè Balkan
Inú Franz Brand dùn gan-an fún òtítọ́ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́ náà ó sì pinnu pé dandan òun gbọ́dọ̀ tan ìhìn rere náà kálẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe iṣẹ́ bábà ní Maribor, ìyẹn ìlú kan ní Slovenia tó wà níbi ààlà Austria. Ó sì máa ń wàásù fáwọn oníbàárà rẹ̀, àwọn yẹn á sì fara balẹ̀ gbọ́ ìwàásù tó ń ṣe bó ṣe ń gẹrun fún wọn. Àbájáde ìsapá tó ṣe ni pé àwùjọ
kékeré kan bẹ̀rẹ̀ sí pòkìkí Ìjọba náà ní Maribor lápá ìparí àwọn ọdún 1920. Inú ilé àrójẹ kan ni wọ́n ti ń sọ àsọyé Bíbélì. Nígbà tó yá, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí pe ilé àrójẹ náà ní Novi svet tó túmọ̀ sí Ilé Àrójẹ (Ayé Tuntun), orúkọ ọ̀hún sì yẹ ẹ́.Láìpẹ́, ìhìn rere náà tàn kárí gbogbo ilẹ̀ náà. Àwòrán “Photo-Drama of Creation” [Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá] (sinimá oníwákàtí mẹ́jọ tó ń gbé fọ́tò àti ohun jáde) kó ipa ńláǹlà nínú títan ìhìn rere náà kálẹ̀. Nígbà tó di àwọn ọdún 1930, tí wọ́n gbé inúnibíni líle koko dìde sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Jámánì, àwọn aṣáájú ọ̀nà tí wọ́n sá kúrò ní Jámánì wá sí Yugoslavia ṣèrànwọ́ ńláǹlà fáwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀. Wọ́n pa ìgbádùn àti ìgbésí ayé oníyọ̀tọ̀mì tì, wọ́n sì sapá láti lọ wàásù láwọn àgbègbè tó jìnnà rére ní orílẹ̀-èdè olókè náà. Níbẹ̀rẹ̀, ńṣe ló dà bí ẹni pé àwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ gba ọ̀rọ̀ wọn. Kìkì àádọ́jọ akéde péré ló ròyìn níbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1940.
Ní 1941, inúnibíni tó gbóná janjan bẹ̀rẹ̀, ó sì ń bá a lọ títí di ọdún 1952. Àmọ́ ìdùnnú ṣubú layọ̀ nígbà tí ìjọba Kọ́múníìsì lábẹ́ Ọ̀gágun Tito fìdí iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà múlẹ̀ lábẹ́ òfin ní September 9, 1953! Iye akéde ìhìn rere náà lọ́dún yẹn jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ó lé mẹ́rìnlá [914], iye náà sì ń ròkè sí i. Nígbà tó fi máa di 1991, iye akéde ti di ẹgbẹ̀rún méje, ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti ogún [7,420], iye àwọn tó wá sí Ìṣe Ìrántí lọ́dún yẹn jẹ́ ẹgbàájọ àti àádọ́rin ó lé méjì [16,072].
August 16 sí 18, 1991, ni wọ́n ṣe àpéjọ àgbáyé kìíní ní orílẹ̀-èdè yìí nílùú Zagreb, ní Croatia. Ẹgbàá méje, ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti mẹ́rìnlélọ́gọ́rin [14,684] ni iye èèyàn tó wá sí àpéjọ náà láti orílẹ̀-èdè yìí àti láti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Àpéjọ mánigbàgbé yìí ló mú àwọn èèyàn Jèhófà gbára dì de wàhálà tí ń bẹ níwájú. Ọkọ̀ tó ń gbé àwọn tó wá sí àpéjọ náà láti Serbia padà sílé wà lára àwọn ọkọ̀ tó kọjá kẹ́yìn níbi táwọn ọlọ́pàá ti ń yẹ ọkọ̀ wò láàárín Croatia àti Serbia. Bí ọkọ̀ tó gbẹ̀yìn ṣe kọjá báyìí ni wọ́n ti ẹnu ibodè pa tí ogun sì bẹ̀rẹ̀.
Ó Yẹ Kí Àwọn Èèyàn Jèhófà Máa Yọ̀
Àkókò àdánwò ńláǹlà làwọn ọdún tí ogun fi jà jẹ́ fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní àwọn orílẹ̀-èdè Balkan. Síbẹ̀, ó yẹ kí wọ́n máa yọ̀ nítorí pé Jèhófà ti fi ìbísí rẹpẹtẹ bù kún àwọn èèyàn rẹ̀ tó wà lágbègbè yìí. Láti ọdún 1991, iye akéde Ìjọba náà lágbègbè Yugoslavia tẹ́lẹ̀ rí ti fi ohun tó lé ní ìdá ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún ròkè sí i. Iye tó ròyìn lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2001 pọ̀ ju ti ìgbàkigbà rí lọ, wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlá, irínwó àti méjìléláàádọ́rin [13,472].
Ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Zagreb àti Belgrade (Serbia) ló máa ń ṣe kòkáárí iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ibi tá à ń pè ní Yugoslavia tẹ́lẹ̀. Àmọ́ pípọ̀ tí wọ́n ń pọ̀ sí i àti ìyípadà tó wáyé ní ti ètò ìṣèlú mú kó di dandan láti ṣí ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun sí Ljubljana (Slovenia), àti Skopje (Makedóníà), ìwọ̀nyí á jẹ́ àfikún sáwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun tí wọ́n ṣí sí Belgrade àti Zagreb. Nǹkan bí ogóje [140] èèyàn ló ń ṣiṣẹ́ láwọn ọ́fíìsì yìí. Ọ̀dọ́ ló pọ̀ jù nínú wọn, wọ́n nítara wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Ọ̀pọ̀ lára wọn ń túmọ̀ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí èdè Croatia, Makedóníà, Serbia àti Slovenia. Ìbùkún ńlá gbáà ló jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn ìwé ìròyìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láwọn èdè wọ̀nyí
àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn ni wọ́n ń tẹ̀ jáde lẹ́ẹ̀mejì lóṣù bíi ti ẹ̀dà Gẹ̀ẹ́sì! Àwọn ìtẹ̀jáde yìí fún ọ̀pọ̀ èèyàn ní ìtùnú àti ìrètí.Ìdí mìíràn fún ayọ̀ ni bí ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ alákòókò kíkún ṣe ń ti orílẹ̀-èdè mìíràn wá láti ṣèrànwọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù náà. Ọ̀pọ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba tó lẹ́wà la ti kọ́ láwọn ọdún ẹnu àìpẹ́ yìí, èyí tún pa kún ayọ̀ àwọn ará. Àmọ́, kékeré ṣì ni gbogbo ìyẹn o, ayọ̀ tó ju ayọ̀ lọ ṣì ń bọ̀ lọ́nà. Èwo tún nìyẹn?
Iṣẹ́ Kan Tí Ò Lẹ́gbẹ́
Ọ̀pọ̀ akéde ló ń ṣe kàyéfì pé, ‘Ǹjẹ́ a máa ní Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè wa báyìí?’ Ọdọọdún ni wọ́n máa ń retí láti gbọ́ ìfilọ̀ nípa èyí ní àpéjọ àgbègbè. Àmọ́ báwo ni wọ́n á ṣe lè ṣe iṣẹ́ bàǹtà-banta bẹ́ẹ̀ nígbà tó jẹ́ pé kò tíì pẹ́ tí wọ́n dá ẹ̀ka tó ń túmọ̀ èdè sílẹ̀, tí iye àwọn òǹtú kò sì fi bẹ́ẹ̀ tó nǹkan?
Lẹ́yìn tí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò, wọ́n sọ pé kí ẹgbẹ́ òǹtú ní èdè Croatia, Makedóníà àti Serbia pawọ́ pọ̀ ṣiṣẹ́ náà, pé ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wọn á jẹ́ kí wọ́n lè jàǹfààní látinú àbá tí ẹnì kọ̀ọ̀kan bá mú wá. Ẹgbẹ́ òǹtú èdè Croatia ló máa ṣe kòkáárí iṣẹ́ ọ̀hún.
Ọjọ́ Tí Ìdùnnú Ṣubú Layọ̀
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní àwọn orílẹ̀-èdè Balkan ò lè gbàgbé July 23, 1999 láé. Wọ́n fẹ́ ṣe àwọn Àpéjọ Àgbègbè “Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run” lẹ́ẹ̀kan náà ní Belgrade, Sarajevo (Bosnia-Herzegovina), Skopje, àti Zagreb. Kò kọ́kọ́ dáni lójú bóyá àpéjọ náà á wáyé ní Belgrade nítorí pé kò sáyè fún àpéjọ èyíkéyìí ní gbogbo ìgbà tí àjọ NATO fi ń rọ̀jò àdó olóró síbẹ̀. Béèyàn gẹṣin nínú àwọn ará kò lè kọsẹ̀ nítorí bínú wọn ṣe dùn tó pé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, àwọn á lè jọ pàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin! Àṣé ohun tí wọ́n á bá pàdé ju ohun tó wà lọ́kàn wọn lọ.
Lọ́sàn-án Friday, wọ́n ṣe ìfilọ̀ àkànṣe kan ní ìlú mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí wọ́n ti ń ṣe àpéjọ náà. Gbogbo ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlá, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó dín mẹ́ta [13,497] èèyàn tó wà níbi àpéjọ náà ló pa lọ́lọ́ láti gbọ́ ìfilọ̀ náà. Nígbà tí olùbánisọ̀rọ̀ náà wá ṣèfilọ̀ ìmújáde Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun lédè Croatia àti Serbia tó tún sọ fún àwùjọ pé iṣẹ́ ń lọ lọ́wọ́ lórí ti èdè Makedóníà, ara àwọn ará kò gbà á mọ́. Àtẹ́wọ́ wàá-wòó tí wọ́n ń pa kò jẹ́ kí olùbánisọ̀rọ̀ lè parí ìfilọ̀ náà. Níbi àpéjọ ti Sarajevo, ńṣe làwọn èèyàn ṣàdédé pa lọ́lọ́, nítorí pé ìyanu gbáà lọ́rọ̀ náà jẹ́ fún wọn. Lẹ́yìn náà ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí pàtẹ́wọ́ àpaàpatán. Pòròpòrò ni omijé ayọ̀ ń dà lójú àwọn ará ní Belgrade, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pa àtẹ́wọ́ àpatúnpa kí olùbánisọ̀rọ̀ náà tó parí ìfilọ̀ rẹ̀. Ńṣe ni ìdùnnú ṣubú layọ̀ fún gbogbo èèyàn!
Ohun tó jẹ́ káwọn ará túbọ̀ mọrírì ẹ̀bùn yìí ni pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti gbàṣẹ láti tẹ Bíbélì jáde lédè Croatia àti èdè Serbia. Èyí ló mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti tẹ Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun àti Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù lọ́kọ̀ọ̀kan àwọn èdè yìí pa pọ̀ sójú kan. Ìyẹn nìkan kọ́, lẹ́tà ìkọ̀wé Roman àti Cyrillic, èyí táwọn èèyàn náà ń lò ni wọ́n fi kọ Bíbélì èdè Serbia.
Àwọn èèyàn Jèhófà ní àwọn orílẹ̀-èdè Balkan dúpẹ́ fún ẹ̀bùn àgbàyanu àti ìtọ́sọ́nà tí wọ́n rí gbà yìí, wọ́n sì gbà pé òótọ́ làwọn ọ̀rọ̀ Dáfídì pé: “Bí mo tilẹ̀ ń rìn ní àfonífojì ibú òjìji, èmi kò bẹ̀rù ohun búburú kankan, nítorí tí ìwọ [Jèhófà] wà pẹ̀lú mi.” Pẹ̀lú bí ipò nǹkan ò ṣe rọrùn fún wọn tó, wọ́n pinnu láti máa fi ‘ìdùnnú Jèhófà ṣe odi agbára wọn.’—Sáàmù 23:4; Nehemáyà 8:10.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Orílẹ̀-èdè olómìnira mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló wà ní ilẹ̀ Yugoslavia tẹ́lẹ̀ rí—Bosnia-Herzegovina, Croatia, Makedóníà, Montenegro, Serbia, àti Slovenia.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Àwùjọ àwọn akéde àkọ́kọ́ láti ìlú Maribor, ní Slovenia, ń wàásù láwọn ìpínlẹ̀ tó jìnnà gan-an