Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ǹjẹ́ kì í ṣe àmúlùmálà ìgbàgbọ́ ni ká ra ilé táwọn ẹlẹ́sìn mìíràn ń lò ká wá sọ ọ́ di Gbọ̀ngàn Ìjọba?
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe irú ìdúnàádúrà bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀sìn mìíràn. Bí a bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, irú ìdúnàádúrà yìí lè máà túmọ̀ sí àmúlùmálà ìgbàgbọ́. A lè kà á sí òwò. Ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í forí korí pẹ̀lú àwọn ẹ̀sìn mìíràn láti kọ́ ilé ìjọsìn táwọn méjèèjì á jọ máa lò.
Kí wá ni àmúlùmálà ìgbàgbọ́ lójú Jèhófà? Ronú nípa ìtọ́ni tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fúnni pé: “Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́. Nítorí àjọṣe wo ni òdodo àti ìwà àìlófin ní? Tàbí àjọpín wo ni ìmọ́lẹ̀ ní pẹ̀lú òkùnkùn? Síwájú sí i, ìbáramu wo ni ó wà láàárín Kristi àti Bélíálì? Tàbí ìpín wo ni olùṣòtítọ́ ní pẹ̀lú aláìgbàgbọ́? Ìfohùnṣọ̀kan wo sì ni tẹ́ńpìlì Ọlọ́run ní pẹ̀lú àwọn òrìṣà? . . . ‘Nítorí náà, ẹ jáde kúrò láàárín wọn, kí ẹ sì ya ara yín sọ́tọ̀,’ ni Jèhófà wí, ‘kí ẹ sì jáwọ́ nínú fífọwọ́kan ohun àìmọ́’; ‘dájúdájú, èmi yóò sì gbà yín wọlé.’” (2 Kọ́ríńtì 6:14-17) Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nípa gbólóhùn náà “àjọṣe” àti “àjọpín”?
Ó ṣe kedere pé àjọṣe tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn níbí ní bíbá àwọn abọ̀rìṣà àtàwọn aláìgbàgbọ́ ṣe ìgbòkègbodò tẹ̀mí pa pọ̀ nínú. Ó kìlọ̀ fáwọn ará Kọ́ríńtì pé wọn ò gbọ́dọ̀ “ṣalábàápín . . . tábìlì àwọn ẹ̀mí èṣù.” (1 Kọ́ríńtì 10:20, 21) Fún ìdí yìí, ohun tó túmọ̀ sí àmúlùmálà ìgbàgbọ́ ni pé kéèyàn máa bá ètò ẹ̀sìn mìíràn jọ́sìn tàbí kó máa bá wọn ṣe nǹkan tẹ̀mí pa pọ̀. (Ẹ́kísódù 20:5; 23:13; 34:12) Tá a bá ra ilé kan tí ètò ẹ̀sìn mìíràn ń lò tẹ́lẹ̀, kìkì ilé náà la fẹ́ rà láti fi ṣe Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ká sì tó bẹ̀rẹ̀ sí í lò ó fún ète yẹn, gbogbo nǹkan tó wà níbẹ̀ tó ní í ṣe pẹ̀lú ìsìn èké la máa kó dà nù pátá. Lẹ́yìn gbogbo àwọn àtúnṣe yìí, a óò yà á sí mímọ́ fún Jèhófà a ó sì máa lò ó fún kìkì ìjọsìn rẹ̀ nìkan ṣoṣo. Kò sí àjọṣe kankan tàbí àjọpín èyíkéyìí láàárín ìjọsìn tòótọ́ àti ìjọsìn èké.
Nígbà ìdúnàádúrà láti ra irú ilé bẹ́ẹ̀, wọléwọ̀de pẹ̀lú àwọn tó fẹ́ tà á kò gbọ́dọ̀ pọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ, gbogbo ìjíròrò sì gbọ́dọ̀ dá lórí ríra ilé náà. Àwọn ará nínú ìjọ Kristẹni gbọ́dọ̀ fi ìkìlọ̀ Pọ́ọ̀lù sọ́kàn láti má ṣe fi “àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a kì í ka ara wa sí ẹni tó ṣe pàtàkì ju àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn yàtọ̀ sí tiwa, síbẹ̀ a kì í bá wọn ṣe wọléwọ̀de, bẹ́ẹ̀ ni a kì í gbà wọ́n láyè láti mú kí wọ́n fà wá sínú ìjọsìn wọn. a
Tó bá jẹ́ pé ilé tí ètò ẹ̀sìn kan kọ́ ni ìjọ fẹ́ háyà láti máa lò ńkọ́? Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ sábàá máa ń jẹ́ káwọn ará àtàwọn ẹlẹ́sìn mìíràn máa ríra nígbà gbogbo, èyí ò sì bọ́ sí i. Kódà, kó tiẹ̀ jẹ́ pé ayẹyẹ kan ni wọ́n torí ẹ̀ fẹ́ háyà irú ilé bẹ́ẹ̀, ẹgbẹ́ àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ gbé àwọn ìbéèrè yìí yẹ̀ wò: Ṣé àwọn ère tàbí àwọn àwòrán ìsìn máa wà nínú ilé náà tàbí ní ìta rẹ̀? Irú ojú wo làwọn ará àdúgbò á fi wo lílò tá a fẹ́ lo ilé náà? Ǹjẹ́ lílo irú ilé bẹ́ẹ̀ lè mú ẹnikẹ́ni kọsẹ̀ nínú ìjọ? (Mátíù 18:6; 1 Kọ́ríńtì 8:7-13) Àwọn alàgbà á gbé àwọn ìbéèrè yìí yẹ̀ wò wọ́n á sì ṣèpinnu tó tọ́. Wọ́n tún gbọ́dọ̀ ronú nípa ẹ̀rí ọkàn tiwọn àti tàwọn ará nínú ìjọ láti mọ̀ bóyá ó bọ́gbọ́n mu fún wọn láti ra irú ilé bẹ́ẹ̀ kí wọ́n wá sọ ọ́ di Gbọ̀ngàn Ìjọba.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ìsọfúnni nípa ṣíṣe òwò lọ́nà tó tọ́ pẹ̀lú àwọn ètò ìsìn tí Jèhófà kò tẹ́wọ́ gbà, wo Ilé Ìṣọ́, April 15, 1999, ojú ìwé 28 àti 29.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Sínágọ́gù ni ilé yìí tẹ́lẹ̀, àwọn ará rà á wọ́n sì sọ ọ́ di Gbọ̀ngàn Ìjọba