Ṣé Kì Í Ṣe Pé Àwọn Ẹ̀mí Èṣù Ló Ń Ṣiṣẹ́ Yìí?
Ṣé Kì Í Ṣe Pé Àwọn Ẹ̀mí Èṣù Ló Ń Ṣiṣẹ́ Yìí?
“Ọkàn gbogbo ayé ti pòrúurùu. Ńṣe ló dà bí ẹni pé agbára òkùnkùn mọ̀ọ́mọ̀ ń dí gbogbo ọ̀nà àbáyọ.”—Akọ̀ròyìn Jean-Claude Souléry.
‘Béèyàn ò ti lè ta pútú lè mú ká máa ronú pé ẹ̀mí búburú kan ló wà lẹ́yìn rẹ̀’.—Òpìtàn Josef Barton.
JÌNNÌJÌNNÌ táwọn apániláyà fà nígbà tí wọ́n ṣọṣẹ́ ní September 11, 2001, ló mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ro àròjinlẹ̀ báyìí. Nígbà tí Michael Prowse ń kọ̀wé nínú ìwé ìròyìn ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà Financial Times, ó sọ pé: “Ẹranko gan-an ò lè hùwà lọ́nà tó burú tó bẹ́ẹ̀, kò tiẹ̀ jẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ ni.” Ọ̀rọ̀ olóòtú kan nínú ìwé ìròyìn New York Times sọ pé ká tiẹ̀ yọ ti bí wọ́n ṣe múra sílẹ̀ tó fún iṣẹ́ ibi yìí kúrò, “ó tún ṣe pàtàkì láti ronú lórí bí ìkórìíra àwọn èèyàn náà ṣe pọ̀ tó tí wọ́n fi lè hu irú ìwà ìkà bẹ́ẹ̀. Ìkórìíra yìí kọjá èyí tó sábà máa ń fa ogun, ìkórìíra tí ò láàlà ni, kò sì mọ pé èèyàn ń tijú ẹnì kan.”
Àwọn ẹlẹ́sìn lóríṣiríṣi bẹ̀rẹ̀ sí ronú pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn ẹ̀mí búburú ló ṣiṣẹ́ yìí. Ọ̀gbẹ́ni oníṣòwò kan ní Sarajevo tó rí ọṣẹ́ tí ìkórìíra ẹ̀yà ṣe ní Bosnia sọ pé: “Lẹ́yìn ọdún kan tí ogun ti ń jà ní Bosnia, mo gbà pé Sátánì ló fa gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀. Ìwà wèrè gbáà lèyí.”
Nígbà tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ òpìtàn Jean Delumeau bóyá ó gbà pé Èṣù wà, ó dáhùn pé: “Báwo ni mo ṣe lè sọ pé agbára òkùnkùn ò sí nígbà tí mo ráwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ àtèyí tó ti ṣẹlẹ̀ látìgbà tá a ti bí mi: Ogun Àgbáyé Kejì, tó gbẹ̀mí èèyàn tó lé ní ogójì mílíọ̀nù; pípa tí wọ́n pa àwọn èèyàn nípakúpa nílùú Auschwitz; ìpẹ̀yàrun tó wáyé ní Cambodia; ìjọba Ceauşescu tó gbẹ̀mí àwọn èèyàn; yíyàn tí ọ̀pọ̀ ìjọba yan fífìyàjẹni láàyò lọ́pọ̀ ibi kárí ayé. Mélòó la fẹ́ kà nínú ìwà ìkà ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ yìí. . . . Nítorí náà, a ò ṣì sọ tá a bá ní ‘iṣẹ́ èṣù’ làwọn nǹkan wọ̀nyí. Kì í ṣe Èṣù abìwo-lórí-bipátákò-lẹ́sẹ̀ la sọ pé ó ń ṣiṣẹ́ yìí o, àmọ́ Èṣù tó ń darí àwọn ẹni ibi àti agbára òkùnkùn nínú ayé ni.”
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ronú bíi ti Jean Delumeau, pé “iṣẹ́ èṣù” làwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ tó ń kó jìnnìjìnnì báni láwùjọ ẹ̀dá lónìí, tó bẹ̀rẹ̀ látorí ìdílé títí tó fi dé orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn. Kí wá ni gbogbo èyí túmọ̀ sí? Ṣé agbára kan tí a mọ̀ sí ibi ni ká sọ pé ó ń fà á ni, àbí àwọn ẹ̀mí búburú kan wà ní ti gidi tó ń ti ẹ̀dá èèyàn láti hu àwọn ìwà tó burú bàlùmọ̀ bẹ́ẹ̀ tó ré kọjá àwọn ìwà tó kù díẹ̀ káàtó táwọn èèyàn sábà máa ń hù? Ṣé ọ̀dàrà, ìyẹn Sátánì Èṣù ló ń darí àwọn ẹ̀mí yìí tó sì ń ṣe kòkáárí ohun tí wọ́n ń ṣe?
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Àwọn ọmọdé: Fọ́tò U.S. Coast Guard