Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ẹ Kọ Ojú Ìjà Sí Èṣù”

“Ẹ Kọ Ojú Ìjà Sí Èṣù”

“Ẹ Kọ Ojú Ìjà Sí Èṣù”

“Ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín.”—JÁKỌ́BÙ 4:7.

1. Kí la lè sọ nípa ayé ìsinsìnyí, kí sì nìdí tí àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn ẹlẹgbẹ́ wọn fi ní láti wà lójú fò?

 “ỌLỌ́RUN ò sí mọ́, àmọ́ Èṣù ṣì wà.” Àwọn ọ̀rọ̀ tí òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Faransé nì, André Malraux, sọ yẹn bá bí nǹkan ṣe rí nínú ayé tá à ń gbé yìí mu wẹ́kú. Ó dájú pé iṣẹ́ ọwọ́ àwọn èèyàn ń gbé ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ Èṣù yọ ju bó ṣe ń gbé ìfẹ́ inú Ọlọ́run yọ lọ. Sátánì ń tan àwọn èèyàn jẹ “pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ agbára àti àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn àmì àgbàyanu irọ́ àti pẹ̀lú gbogbo ẹ̀tàn àìṣòdodo fún àwọn tí ń ṣègbé.” (2 Tẹsalóníkà 2:9, 10) Àmọ́, ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” wọ̀nyí, Sátánì ń sa gbogbo ipá rẹ̀ lórí àwọn ìránṣẹ́ tó ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run, ó ń gbógun ti àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, ìyẹn “àwọn ẹni tí ń pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́, tí wọ́n sì ní iṣẹ́ jíjẹ́rìí Jésù.” (2 Tímótì 3:1; Ìṣípayá 12:9, 17) Àwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyí àtàwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tó ní ìrètí gbígbé lórí ilẹ̀ ayé gbọ́dọ̀ wà lójúfò.

2. Báwo ni Sátánì ṣe sún Éfà dẹ́ṣẹ̀, ẹ̀rù wo ni Pọ́ọ̀lù sì sọ pé ó ń ba òun?

2 Ẹlẹ̀tàn ni Sátánì ní gbogbo ọ̀nà. Ó tipasẹ̀ ejò tan Éfà jẹ débi tíyẹn fi ronú pé gbígba òmìnira kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run yóò jẹ́ kí ayọ̀ òun túbọ̀ kún sí i. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6) Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́rin lẹ́yìn ìyẹn ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ẹ̀rù ń ba òun pé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà ní Kọ́ríńtì lè di ẹni tí Sátánì fi ọgbọ́n àrékérekè rẹ̀ mú. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Mo ń fòyà pé lọ́nà kan ṣáá, bí ejò ti sún Éfà dẹ́ṣẹ̀ nípasẹ̀ àlùmọ̀kọ́rọ́yí rẹ̀, a lè sọ èrò inú yín di ìbàjẹ́ kúrò nínú òtítọ́ inú àti ìwà mímọ́ tí ó tọ́ sí Kristi.” (2 Kọ́ríńtì 11:3) Sátánì ń ba èrò inú àwọn èèyàn jẹ́, ó sì ń sọ ìrònú wọn dìdàkudà. Bó ṣe sún Éfà dẹ́ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ló lè mú kí àwọn Kristẹni ronú lọ́nà èké, kí wọ́n sì máa fojú inú wò ó pé ohun tí Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ ò tẹ́wọ́ gbà ló lè fún àwọn láyọ̀.

3. Irú ààbò wo ni Jèhófà ń dá bò wá kúrò lọ́wọ́ Èṣù?

3 A lè fi Sátánì wé pẹyẹpẹyẹ kan tó dẹ pańpẹ́ láti mú àwọn ẹyẹ tí kò fura. Tá ò bá fẹ́ kó sínú pańpẹ́ Sátánì, a ní láti máa ‘gbé ibi ìkọ̀kọ̀ Ẹni Gíga Jù Lọ,’ ìyẹn ni ibi ààbò ìṣàpẹẹrẹ tí Jèhófà pèsè fáwọn tó mọyì ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ láyé àti lọ́run nínú ohun tí wọ́n ń ṣe. (Sáàmù 91:1-3) A nílò gbogbo ààbò tí Jèhófà ń pèsè nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ẹ̀mí rẹ̀, àti ètò àjọ rẹ̀ kí a “lè dúró gbọn-in gbọn-in lòdì sí àwọn ètekéte Èṣù.” (Éfésù 6:11) Ọ̀rọ̀ tí Gíríìkì lò fún “ètekéte” la tún lè túmọ̀ sí “ọgbọ́n àrékérekè.” Láìsí àní-àní, Èṣù ń lo ọ̀pọ̀ ọgbọ́n àrékérekè níbi tó ti ń sapá láti dẹkùn mú àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà.

Àwọn Pańpẹ́ Tí Èṣù Dẹ fún Àwọn Kristẹni Àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀

4. Inú irú ayé wo ni àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ gbé?

4 Àwọn Kristẹni tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kìíní àti ọ̀rúndún kejì Sànmánì Tiwa gbé ní àkókò tí Ilẹ̀ Ọba Róòmù dé òtéńté agbára rẹ̀. Pax Romana, ìyẹn àlàáfíà Róòmù mú kí ọrọ̀ ajé gbèrú gan-an. Aásìkí yìí jẹ́ kí àwọn tó rí já jẹ rí àkókò fún fàájì, àwọn tó ń ṣàkóso sì rí i pé àwọn aráàlú ní ọ̀pọ̀ eré ìnàjú láti ṣe kí wọ́n má bàa ṣọ̀tẹ̀ síjọba. Àwọn sáà kan wà tó jẹ́ pé bí iye ọjọ́ táwọn èèyàn fi ń ṣiṣẹ́ ṣe pọ̀ náà ni iye ọjọ́ tíjọba fi ń fún gbogbo gbòò nísinmi lẹ́nu iṣẹ́ ṣe pọ̀. Àwọn aṣáájú ń lo owó ìjọba láti fún àwọn èèyàn ní oúnjẹ, àwọn ìran àpéwò ìta gbangba sì wà fún wọn láti wò, kí wọ́n lè jẹ àjẹkì kí ọkàn wọn sì pínyà.

5, 6. (a) Èé ṣe tí kò fi bọ́gbọ́n mu fáwọn Kristẹni láti máa lọ sáwọn ibi eré orí ìtàgé àtàwọn gbọ̀ngàn àpéjọ ńlá tó wà ní Róòmù? (b) Ọgbọ́n arúmọjẹ wo ni Sátánì dá, kí ló sì lè kó àwọn Kristẹni yọ?

5 Ǹjẹ́ ipò yìí kì í ṣe ewu fún àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀? Tá a bá wo ìkìlọ̀ táwọn òǹkọ̀wé tó gbé ayé kété lẹ́yìn àkókò àwọn àpọ́sítélì kọ, ìyẹn àwọn bíi Tertullian, a ó rí i pé èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn fàájì tí wọ́n ń ṣe nígbà yẹn ló kún fún ewu nípa tẹ̀mí àti ti ìwà híhù fún àwọn Kristẹni tòótọ́. Ìdí kan ni pé èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn àjọyọ̀ ìta gbangba àti àwọn eré àṣedárayá wọn ni wọ́n ń ṣe láti bọlá fún àwọn òrìṣà kèfèrí. (2 Kọ́ríńtì 6:14-18) Kódà láwọn ibi ìwòran, ọ̀pọ̀ lára àwọn eré tó lókìkí jù lọ níbẹ̀ ló dá lórí ìṣekúṣe paraku tàbí ìwà ipá tó kún fún ìtàjẹ̀sílẹ̀. Bí àkókò ti ń lọ, àwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ìran náà mọ́, ìyẹn ló wá mú kí wọ́n fi ijó òun orin tó burú jáì rọ́pò wọn. Òpìtàn Jérôme Carcopino sọ nínú ìwé Daily Life in Ancient Rome, pé: “Nínú àwọn eré wọ̀nyí, wọ́n máa ń gba àwọn òṣèré láyè láti bọ́ra síhòòhò goloto . . . Ìtàjẹ̀sílẹ̀ ibẹ̀ ò ṣeé fẹnu sọ. . . . [Eré ìfaraṣàpẹẹrẹ náà] kún fún ìwà pálapàla tó ti gba àwọn tó ń gbé olú ìlú náà lọ́kàn. Irú àwọn ìran amúnigbọ̀nrìrì bẹ́ẹ̀ kì í kó wọn nírìíra mọ́ nítorí ó ti pẹ́ tí ìwà ipá àti ìtàjẹ̀sílẹ̀ bíbanilẹ́rù tí wọ́n máa ń fi hàn ní gbọ̀ngàn àpéjọ ńlá ti pa ìmọ̀lára wọn kú, tó sì ti sọ èrò inú wọn dìdàkudà.”—Mátíù 5:27, 28.

6 Ní àwọn gbọ̀ngàn àpéjọ ńlá, àwọn tí ń ja àjàkú-akátá máa ń bá ara wọn jà dójú ikú ni, tàbí kí wọ́n bá àwọn ẹranko búburú jà, yálà kí wọ́n pa àwọn ẹranko náà tàbí kó jẹ́ pé ẹranko náà ló máa pa onítọ̀hún. Àwọn ọ̀daràn tí wọ́n ti dájọ́ ikú fún àti ọ̀pọ̀ Kristẹni ni wọ́n jù sí àwọn ẹranko rírorò bẹ́ẹ̀. Kódà ní àkókò ìjímìjí wọ̀nyẹn, ọgbọ́n tí Sátánì ń dá ni pé káwọn èèyàn máà rí ohun tó burú nínú ìṣekúṣe àti ìwà ipá títí dìgbà táwọn nǹkan wọ̀nyí fi wá di ti tajátẹran tó sì wá di ohun tí gbogbo gbòò ń nífẹ̀ẹ́ sí. Ọ̀nà kan ṣoṣo téèyàn ò fi ní bọ́ sínú pańpẹ́ yẹn ni pé kéèyàn má lọ sáwọn ibi eré orí ìtàgé àti àwọn gbọ̀ngàn àpéjọ ńlá wọ̀nyẹn.—1 Kọ́ríńtì 15:32, 33.

7, 8. (a) Èé ṣe tó fi máa jẹ́ ìwà òmùgọ̀ fún Kristẹni kan láti lọ sí ibi ìdíje fífi kẹ̀kẹ́ ogun sáré? (b) Báwo ni Sátánì ṣe lè fi ilé ìwẹ̀ àwọn ará Róòmù dẹ pańpẹ́ fún àwọn Kristẹni?

7 Ó dájú pé àwọn ìdíje fífi kẹ̀kẹ́ ogun sáré tí wọ́n máa ń ṣe láwọn pápá ìṣiré tó gùn gbọọrọ máa ń dùn ún wò gan-an ni, àmọ́ kò tọ́ fáwọn Kristẹni nítorí pé àwọn èrò sábà máa ń hùwà ipá níbẹ̀. Òǹkọ̀wé kan tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kẹta ròyìn pé àwọn òǹwòran kan máa ń bára wọn jà, Carcopino náà sọ pé: “Ibi ìṣòwò àwọn awòràwọ̀ àti tàwọn aṣẹ́wó” wà lábẹ́ ilé tí wọ́n kọ́ fún ìran àpéwò ìta gbangba náà. Láìsí àní-àní, àwọn ibi ìran àpéwò ìta gbangba àwọn ará Róòmù kì í ṣe ibi tó yẹ káwọn Kristẹni máa lọ.—1 Kọ́ríńtì 6:9, 10.

8 Àwọn ilé ìwẹ̀ lílókìkí táwọn ará Róòmù ń lò ńkọ́? Ká sọ tòótọ́, kò sóhun tó burú nínú kéèyàn wẹ̀ kí ara rẹ̀ lè mọ́ tónítóní. Àmọ́ èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ilé ìwẹ̀ Róòmù ló jẹ́ àwọn ilé ńlá tó ní àwọn yàrá tí wọ́n ti ń wọ́ ara, gbọ̀ngàn ìṣeré ìfarapitú, àwọn yàrá tí wọ́n ti ń ta tẹ́tẹ́, àtàwọn ibi téèyàn ti lè jẹ kó sì mu. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlànà ibẹ̀ ni pé àkókò tí àwọn ọkùnrin máa wẹ̀ yàtọ̀ sí àkókò táwọn obìnrin máa wẹ̀, síbẹ̀ wọ́n fàyè gba tọkùnrin tobìnrin láti wẹ̀ pa pọ̀. Clement ti Alẹkisáńdíríà kọ̀wé pé: “Ilé ìwẹ̀ náà wà ní ṣíṣí sílẹ̀ fún tọkùnrin tobìnrin; wọ́n sì máa ń wà níhòòhò goloto níbẹ̀ láti ṣe ohun tó wù wọ́n.” Ìyẹn túmọ̀ sí pé ohun tí wọ́n ṣe fún àǹfààní àwọn aráàlú lè wá di ohun tí Sátánì ń lò gẹ́gẹ́ bíi pańpẹ́ fún àwọn Kristẹni. Àwọn tó jẹ́ ọlọgbọ́n kì í lọ sírú ibẹ̀ yẹn.

9. Kí ni àwọn pańpẹ́ táwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ní láti yẹra fún?

9 Tẹ́tẹ́ títa jẹ́ eré ìnàjú táwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí gan-an lákòókò tí Ilẹ̀ Ọba Róòmù dé òtéńté agbára rẹ̀. Ọ̀nà táwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ lè gbà yẹra fún kíkọ́ iyàn tó máa ń wáyé láwọn ibi ìdíje fífi kẹ̀kẹ́ ogun sáré ni pé kí wọ́n má lọ sí àwọn ibi ìran àpéwò ìta gbangba bẹ́ẹ̀. Àwọn ibi kéékèèké tí wọ́n ti ń ta tẹ́tẹ́ lọ́nà tí kò bófin mu wà káàkiri láwọn yàrá inú lọ́hùn-ún láwọn ibi tí wọ́n ti ń ta ọtí fáwọn èèyàn mu. Àwọn òṣèré máa ń kọ́ iyàn nípa lílo iye òkúta tí kò ṣeé pín sí méjì tàbí iye tó ṣeé pín sí méjì èyí tó máa ń wà lọ́wọ́ ẹnì kejì tí wọ́n fẹ́ jọ díje. Tẹ́tẹ́ títa máa ń fi kún adùn ìgbésí ayé àwọn èèyàn nítorí pé ó máa ń fúnni nírètí àtidi oníbú owó láìlàágùn. (Éfésù 5:5) Láfikún sí i, àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin tí wọ́n jẹ́ aṣẹ́wó ló sábà máa ń ta ohun mímu nírú àwọn ibi bẹ́ẹ̀, èyí sì lè mú kéèyàn kó sínú ewu ìwà pálapàla takọtabo. Irú nǹkan wọ̀nyí ni díẹ̀ lára àwọn pańpẹ́ tí Sátánì dẹ fún àwọn Kristẹni tó gbé inú àwọn ìlú ńlá Ilẹ̀ Ọba Róòmù. Ṣé àwọn nǹkan ti yàtọ̀ lóde òní?

Àwọn Pańpẹ́ Tí Èṣù Ń Lò Lóde Òní

10. Báwo ni ipò nǹkan lóde òní ṣe fara jọ ipò tó gbòde kan ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù?

10 Lápapọ̀, ọgbọ́n àrékérekè Sátánì kò tíì yí padà láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá. Kí “Sátánì má bàa fi ọgbọ́n àyínìke borí” àwọn Kristẹni tó ń gbé ní ìlú ńlá Kọ́ríńtì tó ti dómùkẹ̀ ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe fún wọn nímọ̀ràn tó lágbára. Ó ní: “Àwa kò ṣe aláìmọ àwọn ète-ọkàn [Sátánì].” (2 Kọ́ríńtì 2:11) Bí ipò nǹkan ṣe rí láwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà lóde òní fara jọ ohun tó gbòde kan nígbà tí Ilẹ̀ Ọba Róòmù dé òtéńté agbára rẹ̀. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé àkókò tí wọ́n fi ń ṣe fàájì nísinsìnyí ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Kódà àwọn tẹ́tẹ́ oríire tí ìjọba dá sílẹ̀ ń fún àwọn òtòṣì ní ìrètí díẹ̀. Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn eré ìnàjú tí kò fi bẹ́ẹ̀ gbówó lórí ló ń gba àwọn èèyàn lọ́kàn. Pápá ìṣeré ń kún àkúnya, àwọn èèyàn ń ta tẹ́tẹ́, àwọn èrò tó wá wòran máa ń hùwà ipá láwọn ìgbà mìíràn, àwọn eléré ìdárayá fúnra wọn máa ń ṣe bẹ́ẹ̀. Orinkórin làwọn èèyàn ń gbọ́, ìwà pálapàla sì ni àwọn eré orí ìtàgé ń gbé lárugẹ, òun náà ni wọ́n ń fi hàn nínú sinimá àti lórí tẹlifíṣọ̀n. Àwọn ilé ìwẹ̀ tí tọkùnrin tobìnrin ti ń wẹ̀ wà láwọn orílẹ̀-èdè kan, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ìsun omi gbígbóná tún wọ́pọ̀ níbẹ̀ pẹ̀lú, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tàwọn tó ń wà níhòòhò goloto nígbà tí wọ́n bá ń wẹ̀ láwọn etíkun kan. Bíi ti àwọn ọ̀rúndún tí ẹ̀sìn Kristẹni ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni Sátánì ṣe ń gbìyànjú láti ré àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lọ nípasẹ̀ fàájì.

11. Àwọn ìdẹkùn wo ló wà nínú kéèyàn máa wá bóun ṣe máa ní àkókò ìgbádùn?

11 Nínú ayé kan tí másùnmáwo ti wọ́pọ̀, ó bọ́gbọ́n mu kéèyàn wá bó ṣe máa fi ọkàn ara rẹ̀ balẹ̀ tàbí kó tiẹ̀ wá bó ṣe máa ní àkókò ìgbádùn. Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí àwọn ilé ìwẹ̀ Róòmù ṣe jẹ́ ohun tó lè fa ewu fún àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ibi téèyàn ti lè lo ìsinmi jẹ́ pańpẹ́ tí Sátánì ti lò láti sún àwọn Kristẹni òde òní sínú ìwà pálapàla àti àmujù. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì pé: “Kí a má ṣì yín lọ́nà. Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́. Ẹ jí sí orí pípé lọ́nà òdodo, ẹ má sì sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà, nítorí àwọn kan wà láìní ìmọ̀ nípa Ọlọ́run.”—1 Kọ́ríńtì 15:33, 34.

12. Kí ni díẹ̀ lára àwọn pańpẹ́ tí Sátánì ń lò láti dẹkùn mú àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní?

12 A ti rí i bí Sátánì ṣe fi ọgbọ́n àrékérekè rẹ̀ ba ìrònú Éfà jẹ́. (2 Kọ́ríńtì 11:3) Lónìí, ọ̀kan lára pańpẹ́ tí Èṣù ń lò ni láti mú kí àwọn Kristẹni máa ronú pé bí àwọn bá ṣe gbogbo ohun táwọn lè ṣe láti bá ayé dọ́gba káwọn èèyàn lè rí i pé kò sí ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi yàtọ̀ sáwọn ẹlòmíràn, ìyẹn yóò jẹ́ kó ṣeé ṣe fún àwọn láti fa àwọn èèyàn wá sínú òtítọ́ Kristẹni. Nígbà mìíràn, àwọn tó nírú èrò bẹ́ẹ̀ máa wọnú ayé gan-an débi pé òdì kejì ni ọ̀rọ̀ wọn máa ń já sí. (Hágáì 2:12-14) Ọgbọ́n àrékérekè mìíràn tí Sátánì ń lò ni láti sún àwọn Kristẹni tó ti ya ara wọn sí mímọ́ àtọmọdé àtàgbà sínú gbígbé ìgbésí ayé méjì kí wọ́n sì ‘kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run.’ (Éfésù 4:30) Àwọn kan ti kó sínú pańpẹ́ yìí nípasẹ̀ lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì nílòkulò.

13. Kí ni ìdẹkùn fífarasin tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ètekéte Èṣù, ìmọ̀ràn inú ìwé Òwe wo ló sì gbéṣẹ́ níhìn-ín?

13 Pańpẹ́ mìíràn tí Sátánì ń lò ni ẹgbẹ́ òkùnkùn tí ewu inú rẹ̀ fara sìn. Kò sí Kristẹni tòótọ́ kankan tó máa mọ̀ọ́mọ̀ kóra rẹ̀ sínú ìjọsìn Èṣù tàbí kó máa bá ẹ̀mí lò. Ṣùgbọ́n àwọn kan kì í kíyè sára nígbà tó bá di pé wọ́n ń wo fíìmù, tí wọ́n ń wo ètò tó ń lọ lórí tẹlifíṣọ̀n, àwọn eré àṣedárayá inú fídíò, kódà nígbà tí wọ́n bá ń ka ìwé àwọn ọmọ kéékèèké àti àwọn àwòrán tó ń fi ìwà ipá tàbí àwọn iṣẹ́ awo hàn. A gbọ́dọ̀ yẹra fún ohunkóhun tó bá ní í ṣe pẹ̀lú ẹgbẹ́ òkùnkùn. Òwe ọlọgbọ́n náà sọ pé: “Ẹ̀gún àti pańpẹ́ ń bẹ ní ọ̀nà oníwà wíwọ́; ẹni tí ń ṣọ́ ọkàn rẹ̀ yóò jìnnà réré sí wọn.” (Òwe 22:5) Níwọ̀n bí Sátánì ti jẹ́ “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí,” ohunkóhun tó bá lókìkí ló lè lò gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn pańpẹ́ rẹ̀.—2 Kọ́ríńtì 4:4; 1 Jòhánù 2:15, 16.

Jésù Kọ Ojú Ìjà sí Èṣù

14. Báwo ni Jésù ṣe borí àdánwò tí Èṣù kọ́kọ́ gbé dìde?

14 Jésù fi àpẹẹrẹ kíkọ ojú ìjà sí Èṣù lélẹ̀, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí ó sá. Lẹ́yìn tí Jésù ṣe ìrìbọmi tó sì gbààwẹ̀ fún ogójì ọjọ́, Sátánì dán an wò. (Mátíù 4:1-11) Ìdánwò àkọ́kọ́ ni pé ó gbìyànjú láti lo ebi tó mọ̀ pé á máa pa Jésù lẹ́yìn ààwẹ̀. Sátánì ní kí Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àkọ́kọ́ láti tẹ́ àìní fún ohun ti ara lọ́rùn. Jésù fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ìwé Diutarónómì 8:3, ó kọ̀ láti fi ìmọtara ẹni lo agbára tó ní, ó sì fi oúnjẹ tẹ̀mí ṣáájú oúnjẹ ti ara.

15. (a) Kí ni ohun téèyàn máa ń yán hànhàn fún tí Sátánì fi dán Jésù wò? (b) Kí ni ọ̀kan lára olórí ọgbọ́n àrékérekè tí Èṣù ń lò fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní, àmọ́ báwo la ṣe lè kọjú ìjà sí i?

15 Ohun tó jọni lójú jù nínú ìdánwò yìí ni pé Èṣù ò gbìyànjú láti mú kí Jésù dá ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè. Ebi tó máa ń mú kéèyàn yán hànhàn fún oúnjẹ dà bí ohun tó lágbára jù lọ láti fi dán Jésù wo lákòókò yìí. Kí ni Èṣù fi ń dán àwọn èèyàn Ọlọ́run wò lóde òní? Wọ́n pọ̀ bí ilẹ̀ bí ẹní, wọ́n sì yàtọ̀ síra wọn, àmọ́ ó ń lo ìṣekúṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára olórí ọgbọ́n àrékérekè tó fi ń sapá láti ba ìwà títọ́ àwọn èèyàn Jèhófà jẹ́. Nípa fífara wé Jésù, a lè kọjú ìjà sí Èṣù ká sì dènà ìdẹwò. Gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe ṣẹ́gun gbogbo ìdẹwò Sátánì nípa rírántí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó bá a mu wẹ́kú, nígbà tó bá fi ìṣekúṣe dán àwa náà wò, a lè rántí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi Jẹ́nẹ́sísì 39:9 àti 1 Kọ́ríńtì 6:18.

16. (a) Báwo ni Sátánì ṣe dán Jésù wò lẹ́ẹ̀kejì? (b) Àwọn ọ̀nà wo ni Sátánì lè gbìyànjú láti gbà mú ká dán Jèhófà wò?

16 Lẹ́yìn ìyẹn, Èṣù ní kí Jésù bẹ́ sílẹ̀ látorí ògiri tẹ́ńpìlì kó lè dán agbára tí Ọlọ́run ní láti fi àwọn áńgẹ́lì Rẹ̀ dáàbò bò ó wò. Jésù kọ̀ láti dán Baba rẹ̀ wò nípa fífa ọ̀rọ̀ yọ látinú ìwé Diutarónómì 6:16. Sátánì lè máà dán wa wò pé ká bẹ́ sílẹ̀ láti odi orí òrùlé tẹ́ńpìlì kan, àmọ́ ó lè sún wa láti dán Jèhófà wò. Ǹjẹ́ ó máa ń ṣe wá bí ẹni pé ká dọ́gbọ́n wá ọ̀nà tí a fi lè fara wé àṣà ìgbàlódé inú ayé ní ti àṣà ìwọṣọ àti ìmúra wa láìní gba ìbáwí? Ǹjẹ́ eré ìnàjú tí kò bójú mu ṣì máa ń wù wá? A lè máa tipa bẹ́ẹ̀ dán Jèhófà wò. Bí a bá ní irú ìtẹ̀sí ọkàn bẹ́ẹ̀, dípò tí Sátánì fi máa sá kúrò lọ́dọ̀ wa, ó lè dúró tì wá, kó máa fi gbogbo ìgbà gbìyànjú láti mú ká dara pọ̀ mọ́ òun.

17. (a) Báwo ni Èṣù ṣe dán Jésù wò nígbà kẹta? (b) Báwo ni ìwé Jákọ́bù 4:7 ṣe lè ṣe wá láǹfààní?

17 Nígbà tí Sátánì tún fi gbogbo ìjọba ayé lọ Jésù ní pàṣípààrọ̀ fún ìjọsìn kan ṣoṣo péré, Jésù tún ta kò ó nípa fífa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́, ó sì mú ìdúró rẹ̀ gbọn-in fún ìjọsìn tí a yà sọ́tọ̀ gédégbé fún Baba rẹ̀. (Diutarónómì 5:9; 6:13; 10:20) Sátánì lè má fi àwọn ìjọba ilẹ̀ ayé lọ̀ wá, àmọ́ gbogbo ìgbà ló máa ń fi ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì lọ̀ wá, kódà ó lè dán wa wò nípa mímú ká máa ronú àtidolówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀. Ǹjẹ́ a máa ń fèsì bíi ti Jésù, ká fún Jèhófà ní ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gédégbé? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, bí ọ̀rọ̀ Jésù ṣe rí náà ni tiwa ṣe máa rí. Àkọsílẹ̀ Mátíù sọ pé: “Nígbà náà ni Èṣù fi í sílẹ̀.” (Mátíù 4:11) Sátánì yóò fi wá sílẹ̀ bá a bá mú ìdúró wa lòdì sí i nípa rírántí àwọn ìlànà Bíbélì tó yẹ àti nípa fífi wọ́n sílò. Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn kọ̀wé pé: “Ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín.” (Jákọ́bù 4:7) Kristẹni kan kọ̀wé sí ẹ̀ka ilé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Faransé pé: “Alárèékérekè ni Sátánì ní tòótọ́. Bí mo ṣe ní èrò tó dára lọ́kàn tó, síbẹ̀ ó ṣòro fún mi gan-an láti darí ìmọ̀lára mi àti àwọn ohun tó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn mi. Síbẹ̀síbẹ̀, pẹ̀lú ìgboyà, sùúrù, àti lékè gbogbo rẹ̀, ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, mo tiraka láti pa ìwà títọ́ mi mọ́, mo sì fi ọwọ́ pàtàkì mú òtítọ́.”

Ẹ Gbára Dì Dáadáa Láti Kọ Ojú Ìjà sí Èṣù

18. Kí ni ìhámọ́ra tẹ̀mí tó mú wa gbára dì láti dojú ìjà kọ Èṣù?

18 Jèhófà ti fún wa ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun nípa tẹ̀mí ká lè “dúró gbọn-in gbọn-in lòdì sí àwọn ètekéte Èṣù.” (Éfésù 6:11-18) Ìfẹ́ tí a ní sí òtítọ́ yóò di abẹ́nú wa lámùrè, yóò múra wa sílẹ̀, fún ìgbòkègbodò Kristẹni. Bá a ṣe múra tán láti fi ọwọ́ pàtàkì mú àwọn ìlànà òdodo Jèhófà yóò dà bí àwo ìgbàyà kan tó ń dáàbò bo ọkàn wa. Bí a bá fi ìhìn rere wọ ẹsẹ̀ wa ní bàtà, a ó máa kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù náà déédéé, èyí yóò fún wa lókun, yóò sì dáàbò bò wá nípa tẹ̀mí. Ìgbàgbọ́ wa yóò dà bí apata ńlá ti ìgbàgbọ́, tó ń dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ “ohun ọṣẹ́ oníná ti ẹni burúkú náà,” ìyẹn àwọn ìkọlù alárèékérekè àti àwọn ìdẹwò rẹ̀. Ìrètí dídájú tá a ní nínú àwọn ìlérí Jèhófà yóò dà bí àṣíborí tó ń dáàbò bo agbára ìrònú wa, tó sì ń fi wá lọ́kàn balẹ̀. (Fílípì 4:7) Bí a bá di ògbógi nínú lílo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, yóò dà bí idà tá a lè lò láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè bọ́ nínú ìgbèkùn tẹ̀mí Sátánì. A sì tún lè lò ó láti gbèjà ara wa bí Jésù ti ṣe nígbà ìdẹwò.

19. Ní àfikún sí ‘kíkọ ojú ìjà sí Èṣù,’ kí ló tún ṣe pàtàkì?

19 Nípa gbígbé “ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run” yìí wọ̀, tá a sì ń gbàdúrà nígbà gbogbo, a lè ni ìdánilójú ààbò Jèhófà nígbà tí Sátánì bá gbéjà kò wá. (Jòhánù 17:15; 1 Kọ́ríńtì 10:13) Àmọ́ Jákọ́bù fi hàn pé ‘kíkọ ojú ìjà sí Èṣù’ nìkan kò tó. A tún gbọ́dọ̀ ‘fi ara wa sábẹ́ Ọlọ́run,’ tó bìkítà nípa wa. (Jákọ́bù 4:7, 8) Bí a ṣe lè ṣe èyí la óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Irú ìdẹkùn Sátánì wo làwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ní láti yẹra fún?

• Ìwà àrékérekè wo ni Sátánì ń lò láti dẹkùn mú àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lónìí?

• Báwo ni Jésù ṣe tako àwọn ìdẹwò Èṣù?

• Kí ni ìhámọ́ra ogun tẹ̀mí tó mú kó ṣeé se fún wa láti dojú ìjà kọ Èṣù?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

Jésù kọ ojú ìjà sí Èṣù

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ kọ eré ìnàjú tó kún fún ìwà ipá àti ìwà pálapàla

[Credit Line]

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Complete Encyclopedia of Illustration/J. G. Heck