Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Di Ọlọ́gbọ́n ní Ọjọ́ Ọ̀la Rẹ”

“Di Ọlọ́gbọ́n ní Ọjọ́ Ọ̀la Rẹ”

“Di Ọlọ́gbọ́n ní Ọjọ́ Ọ̀la Rẹ”

“Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú ẹ̀dá èèyàn ló máa ń fi ìgbà òwúrọ̀ wọn ba ìgbà alẹ́ wọn jẹ́.” Aláròkọ ọmọ ilẹ̀ Faransé nì, Jean de La Bruyère, tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún ló sọ̀rọ̀ yìí. Lóòótọ́, ọ̀dọ́ tí ò bá lè dá ṣèpinnu lè máa ṣiyèméjì lórí àwọn nǹkan tó wà níwájú rẹ̀, kò ní ní ìtẹ́lọ́rùn, gbogbo nǹkan sì lè tojú sú u. Àmọ́ ọ̀dọ́ tó jẹ́ olórí kunkun lè fàáké kọ́rí pé òun ò ní jáwọ́ nínú ohun tí kò dára tóun ń ṣe, èyí á sì kó ìbànújẹ́ bá a lọ́jọ́ alẹ́ rẹ̀. Èyí ó wù ó jẹ́, yálà èèyàn ò ṣe ohun tó tọ́ ni o tàbí èèyàn ń dá ẹ̀ṣẹ̀ ni o, méjèèjì ló lè kóni sí yọ́ọ́yọ́ọ́.

Báwo la ṣe lè yẹra fún irú àbájáde bẹ́ẹ̀? Gẹ́gẹ́ bí ìkìlọ̀ fáwọn èwe láti má ṣe jẹ́ aláìlèṣèpinnu, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wọ́n níyànjú pé: “Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá nísinsìnyí, ní àwọn ọjọ́ tí o wà ní ọ̀dọ́kùnrin, kí àwọn ọjọ́ oníyọnu àjálù tó bẹ̀rẹ̀ sí dé, tàbí tí àwọn ọdún náà yóò dé nígbà tí ìwọ yóò wí pé: ‘Èmi kò ní inú dídùn sí wọn.’” (Oníwàásù 12:1) Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, gbé àwọn ìgbésẹ̀ tó yẹ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa “Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá” nígbà tó o ṣì wà léwe.

Báwo wá ni Bíbélì ṣe ran àwọn èwe lọ́wọ́ láti yẹra fún àwọn ìwà tí ò bójú mu táwọn ọ̀dọ́ ń hù? Ohun tó sọ ni pé: “Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ìbáwí, kí o lè di ọlọ́gbọ́n ní ọjọ́ ọ̀la rẹ.” (Òwe 19:20) Bíbélì tún sọ ọ́ gbangba pé àbájáde kíkọ ọgbọ́n Ọlọ́run sílẹ̀ nípa ṣíṣàì kà á sí tàbí híhùwà ọ̀tẹ̀ léwe tàbí lágbà, máa ń korò bí ewúro. (Òwe 13:18) Àmọ́ títẹ̀lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run máa ń jẹ́ kéèyàn ní “ọjọ́ gígùn àti ọ̀pọ̀ ọdún ìwàláàyè àti àlàáfíà.” Èyí sì ń mú kéèyàn gbádùn ìgbésí ayé tẹ́rùntẹ́rùn.—Òwe 3:2.