Jèhófà Bìkítà Fún Yín
Jèhófà Bìkítà Fún Yín
“Ẹ . . . kó gbogbo àníyàn yín lé [Ọlọ́run], nítorí ó bìkítà fún yín.”—1 PÉTÉRÙ 5:7.
1. Inú ohun pàtàkì wo ni Jèhófà àti Sátánì ti yàtọ̀ síra pátápátá?
JÈHÓFÀ àti Sátánì yàtọ̀ síra pátápátá. Ńṣe ni Èṣù máa ń kórìíra ẹnikẹ́ni tó bá sún mọ́ Jèhófà. Ìyàtọ̀ yìí hàn kedere nínú ìwé kan tá a fa ọ̀rọ̀ yọ nínú rẹ̀. Ohun tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica (1970) sọ nípa ìgbòkègbodò Sátánì gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú ìwé Jóòbù inú Bíbélì ni pé: ‘Iṣẹ́ Sátánì ni kó máa rìn káàkiri ayé, kó máa wá ẹni tí òun máa fi ẹ̀sùn ìwà ibi kan; iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ sì tipa bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ pátápátá sí ti “ojú Olúwa,” tó ń lọ káàkiri ilẹ̀ ayé, tó sì ń fún gbogbo ẹni rere lókun (II Chron. xvi, 9). Sátánì jẹ́ alárìíwísí ìwà rere àwọn ẹ̀dá ènìyàn tó jẹ́ aláìmọtara-ẹni-nìkan, a sì fàyè gbà á láti dán an wò lábẹ́ ọlá àṣẹ àti ìdarí Ọlọ́run àti láàárín àkókò tí Ọlọ́run là sílẹ̀.’ Dájúdájú, wọ́n yàtọ̀ síra lóòótọ́!—Jóòbù 1:6-12; 2:1-7.
2, 3. (a) Báwo ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà “Èṣù” ṣe bá ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù mu wẹ́kú? (b) Báwo ni Bíbélì ṣe fi hàn pé Sátánì ò jáwọ́ nínú fífi ẹ̀sùn kan àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé?
2 Ọ̀rọ̀ tí Gíríìkì lò fún “Èṣù” túmọ̀ sí “afẹ̀sùn-èké-kanni,” “afọ̀rọ̀-èké-bani-jẹ́.” Ìwé Jóòbù fi hàn pé Sátánì fẹ̀sùn kan Jóòbù tó jẹ́ ìránṣẹ́ olóòótọ́ fún Jèhófà, pé tìtorí àǹfààní ara rẹ̀ ló ṣe ń sìn Ín, nípa sísọ pé: “Lásán ha ni Jóòbù ń bẹ̀rù Ọlọ́run bí?” (Jóòbù 1:9) Ìtàn inú ìwé Jóòbù fi hàn pé pẹ̀lú gbogbo àdánwò àti ìdẹwò tó bá a, ńṣe ni Jóòbù sún mọ́ Jèhófà pẹ́kípẹ́kí. (Jóòbù 10:9, 12; 12:9, 10; 19:25; 27:5; 28:28) Lẹ́yìn ìṣòro líle koko tó ní, ó sọ̀ fún Ọlọ́run pé: “Àgbọ́sọ ni mo gbọ́ nípa rẹ, ṣùgbọ́n nísinsìnyí, ojú mi ti rí ọ.”—Jóòbù 42:5.
3 Ṣé Sátánì ti jáwọ́ nínú fífẹ̀sùn kan àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run láti àkókò Jóòbù? Rárá o. Ìwé Ìṣípayá fi hàn pé Sátánì ń bá a lọ ní fífi ẹ̀sùn kan àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Jésù ní àkókò ìkẹyìn yìí, ó sì dájú pé ó ń ṣe bẹ́ẹ̀ sí àwọn olóòótọ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn pẹ̀lú. (2 Tímótì 3:12; Ìṣípayá 12:10, 17) Nítorí náà, ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ fún àwa Kristẹni tòótọ́ ni pé ká fi ara wa sábẹ́ Jèhófà Ọlọ́run wa tó bìkítà, kí ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tá a ní fún un máa mú wa sìn ín, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé èké ni ẹ̀sùn tí Sátánì fi ń kàn wá. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a óò mú ọkàn-àyà Jèhófà yọ̀.—Òwe 27:11.
Jèhófà Ń Wá Ọ̀nà Láti Ràn Wá Lọ́wọ́
4, 5. (a) Kí ni Jèhófà ń wá kiri orí ilẹ̀ ayé tó mú kó yàtọ̀ pátápátá sí Sátánì? (b) Bí a bá fẹ́ rí ojú rere Jèhófà, kí ni ohun tí àwa náà gbọ́dọ̀ ṣe?
4 Èṣù ń rìn káàkiri orí ilẹ̀ ayé, ó ń wá ẹni tó máa fẹ̀sùn kàn tó sì máa pa jẹ kiri. (Jóòbù 1:7, 9; 1 Pétérù 5:8) Àmọ́ Jèhófà yàtọ̀ pátápátá síyẹn o, ńṣe lòun ń wá ọ̀nà láti ran àwọn tó nílò okun rẹ̀ lọ́wọ́. Wòlíì Hánáánì sọ fún Ásà Ọba pé: “Ní ti Jèhófà, ojú rẹ̀ ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.” (2 Kíróníkà 16:9) Ẹ ò rí i pé ìyàtọ̀ ńlá ló wà láàárín kèéta Sátánì àti àbójútó onífẹ̀ẹ́ Jèhófà!
5 Jèhófà kì í ṣe amí wa, kó máa ka gbogbo àṣìṣe tá a bá ṣe sí wa lọ́rùn. Onísáàmù náà kọ̀wé pé: “Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ìṣìnà ni ìwọ ń ṣọ́, Jáà, Jèhófà, ta ni ì bá dúró?” (Sáàmù 130:3) Ìdáhùn rẹ̀ ni pé: kò sí ẹni tó lè dúró. (Oníwàásù 7:20) Bí a bá fi gbogbo ọkàn wa sún mọ́ Jèhófà, ojú rẹ̀ yóò wà lára wa, kì í ṣe láti dá wa lẹ́bi o, bí kò ṣe láti kíyè sí àwọn ìsapá wa kó sì dáhùn àwọn àdúrà tá à ń gbà pé kó ràn wá lọ́wọ́ kó sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Ojú Jèhófà ń bẹ lára àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn; ṣùgbọ́n ojú Jèhófà lòdì sí àwọn tí ń ṣe àwọn ohun búburú.”—1 Pétérù 3:12.
6. Báwo ni ọ̀ràn Dáfídì ṣe jẹ́ ìtùnú àti ìkìlọ̀ fún wa?
6 Dáfídì jẹ́ aláìpé, ó sì dá ẹ̀ṣẹ̀ tó wúwo gan-an. (2 Sámúẹ́lì 12:7-9) Àmọ́ ó tú ọkàn rẹ̀ jáde fún Jèhófà, ó sì sún mọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí nínú àdúrà àtọkànwá. (Sáàmù 51:1-12, àkọlé) Jèhófà gbọ́ àdúrà rẹ̀ ó sì dárí jì í, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ Dáfídì yìí mu ún lómi díẹ̀. (2 Sámúẹ́lì 12:10-14) Ó yẹ kí èyí jẹ́ ìtùnú àti ìkìlọ̀ fún wa. Ó tuni nínú gan-an láti mọ̀ pé Jèhófà múra tán láti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì bí a bá ronú pìwà dà ní ti tòótọ́, àmọ́ ó bani nínú jẹ́ láti mọ̀ pé ẹ̀ṣẹ̀ sábà máa ń ní àwọn àbájáde búburú. (Gálátíà 6:7-9) Bí a bá fẹ́ sún mọ́ Jèhófà pẹ́kípẹ́kí, a gbọ́dọ̀ fà sẹ́yìn pátápátá kúrò nínú ohunkóhun tínú Jèhófà ò dùn sí.— Sáàmù 97:10.
Jèhófà Ń Fa Àwọn Èèyàn Rẹ̀ Sọ́dọ̀ Ara Rẹ̀
7. Irú àwọn èèyàn wo ni Jèhófà ń wá, báwo ló sì ṣe ń fà wọ́n sọ́dọ̀ ara rẹ̀?
7 Dáfídì kọ ọ́ sínú ọ̀kan lára àwọn sáàmù rẹ̀ pé: “Jèhófà ga, síbẹ̀síbẹ̀, ó ń rí onírẹ̀lẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbé ara rẹ̀ ga fíofío ni òun mọ̀ kìkì láti òkèèrè.” (Sáàmù 138:6) Bákan náà ni sáàmù mìíràn tún sọ pé: “Ta ní dà bí Jèhófà Ọlọ́run wa, ẹni tí ó fi ibi gíga lókè ṣe ibùgbé rẹ̀? Ó ń rẹ ara rẹ̀ wálẹ̀ láti wo ọ̀run àti ilẹ̀ ayé, ó ń gbé ẹni rírẹlẹ̀ dìde àní láti inú ekuru.” (Sáàmù 113:5-7) Bẹ́ẹ̀ ni o, Olódùmarè Ẹlẹ́dàá Ọ̀run òun Ayé ń rẹ ara rẹ̀ wálẹ̀ láti wo ilẹ̀ ayé, ojú rẹ̀ sì ń rí “onírẹ̀lẹ̀,” “ẹni rírẹlẹ̀,” ìyẹn làwọn èèyàn tó “ń mí ìmí ẹ̀dùn, tí wọ́n sì ń kérora nítorí gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí tí a ń ṣe.” (Ìsíkíẹ́lì 9:4) Ó ń fa irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ sọ́dọ̀ ara rẹ̀ nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀. Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó sọ pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba, tí ó rán mi, fà á . . . Kò sí ẹni tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba yọ̀ǹda fún un.”—Jòhánù 6:44, 65.
8, 9. (a) Èé ṣe tó fi yẹ kí gbogbo wa wá sọ́dọ̀ Jésù? (b) Kí ló jẹ́ bàbàrà nípa ètò ìràpadà náà?
8 Gbogbo ènìyàn ní láti wá sọ́dọ̀ Jésù kí wọ́n sì lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà náà, nítorí pé a bí wọn ní ẹlẹ́ṣẹ̀ tí a sọ dàjèjì sí Ọlọ́run. (Jòhánù 3:36) Wọ́n ní láti padà bá Ọlọ́run rẹ́. (2 Kọ́ríńtì 5:20) Ọlọ́run kò dúró de àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ láti bẹ̀bẹ̀ pé kí ó ṣe àwọn ètò kan tí wọ́n fi lè rí àlàáfíà lọ́dọ̀ rẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ọlọ́run dámọ̀ràn ìfẹ́ tirẹ̀ fún wa ní ti pé, nígbà tí àwa ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa. . . . Nítorí bí ó bá jẹ́ pé, nígbà tí àwa jẹ́ ọ̀tá, a mú wa padà bá Ọlọ́run rẹ́ nípasẹ̀ ikú Ọmọ rẹ̀, mélòómélòó, nísinsìnyí tí a ti mú wa padà rẹ́, ni a ó gbà wá là nípasẹ̀ ìyè rẹ̀.”—Róòmù 5:8, 10.
9 Àpọ́sítélì Jòhánù fìdí òtítọ́ títayọ náà múlẹ̀ pé Ọlọ́run ń mú ènìyàn padà bá ara rẹ̀ rẹ́ nípa kíkọ̀wé pé: “Nípa èyí ni a fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn kedere nínú ọ̀ràn tiwa, nítorí Ọlọ́run rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo jáde sínú ayé kí a lè jèrè ìyè nípasẹ̀ rẹ̀. Ìfẹ́ náà jẹ́ lọ́nà yìí, kì í ṣe pé àwa ti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, bí kò ṣe pé òun nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì rán Ọmọ rẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìpẹ̀tù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.” (1 Jòhánù 4:9, 10) Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló lo ìdánúṣe, kì í ṣe ènìyàn. Ǹjẹ́ ó wù ọ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run tó fi irú ìfẹ́ tó ga báyẹn hàn sí “àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,” tí wọ́n jẹ́ “àwọn ọ̀tá” pàápàá?—Jòhánù 3:16.
Ìdí Tá A Fi Ní Láti Wá Jèhófà
10, 11. (a) Kí la gbọ́dọ̀ ṣe láti wá Jèhófà? (b) Irú ojú wo ló yẹ ká fi wo ètò àwọn nǹkan Sátánì?
10 Ká sọ tòótọ́, Jèhófà kò fagbára mú wa láti wá sọ́dọ̀ òun. Àmọ́ a gbọ́dọ̀ wá a, ká ‘táràrà fún un, ká sì rí i ní ti gidi, bó tilẹ̀ jẹ́ pé, ní ti tòótọ́, kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.’ (Ìṣe 17:27) A gbọ́dọ̀ mọyì ẹ̀tọ́ tí Jèhófà ní láti sọ pé ká fi ara wa sábẹ́ òun. Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn kọ̀wé pé: “Nítorí náà, ẹ fi ara yín sábẹ́ Ọlọ́run; ṣùgbọ́n ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín. Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín. Ẹ wẹ ọwọ́ yín mọ́, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀, kí ẹ sì wẹ ọkàn-àyà yín mọ́ gaara, ẹ̀yin aláìnípinnu.” (Jákọ́bù 4:7, 8) A ò gbọ́dọ̀ lọ́ tìkọ̀ rárá láti dúró gbọn-in lòdì sí Èṣù ká sì rọ̀ mọ́ Jèhófà.
11 Èyí túmọ̀ sí pé ká ya ara wa sọ́tọ̀ pátápátá kúrò nínú ètò nǹkan búburú ti Sátánì. Jákọ́bù tún kọ̀wé pé: “Ẹ kò ha mọ̀ pé ìṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú ayé jẹ́ ìṣọ̀tá pẹ̀lú Ọlọ́run? Nítorí náà, ẹnì yòówù tí ó bá fẹ́ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé ń sọ ara rẹ̀ di ọ̀tá Ọlọ́run.” (Jákọ́bù 4:4) Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, tá a bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ retí pé kí ayé Sátánì kórìíra wa.—Jòhánù 15:19; 1 Jòhánù 3:13.
12. (a) Àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú wo ni Dáfídì kọ? (b) Ìkìlọ̀ wo ni Jèhófà fúnni nípasẹ̀ wòlíì Asaráyà?
12 Nígbà tí ayé Sátánì bá gbógun tì wá láwọn ọ̀nà pàtàkì kan, a ní láti tọ Jèhófà lọ nínú àdúrà, kí a bẹ̀ ẹ́ pé kí ó ràn wá lọ́wọ́. Dáfídì tí Jèhófà kó yọ lọ́pọ̀ ìgbà kọ̀wé fún ìtùnú wa pé: “Jèhófà ń bẹ nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é, nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é ní òótọ́. Ìfẹ́-ọkàn àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ni òun yóò mú ṣẹ, igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́ ni òun yóò sì gbọ́, yóò sì gbà wọ́n là. Jèhófà ń ṣọ́ gbogbo àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n gbogbo ẹni burúkú ni òun yóò pa rẹ́ ráúráú.” (Sáàmù 145:18-20) Onísáàmù náà fi hàn pé Jèhófà lè dáàbò bò wá nígbà tá a bá dán wa wò lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti pé yóò gba àwọn èèyàn rẹ̀ lápapọ̀ là nígbà “ìpọ́njú ńlá.” (Ìṣípayá 7:14) Jèhófà yóò sún mọ́ wa tá a bá sún mọ́ ọn. Nípasẹ̀ “ẹ̀mí Ọlọ́run,” wòlíì Asaráyà sọ ohun tá a lè pè ní òtítọ́ ní gbogbo ọ̀nà, ó ní: “Jèhófà wà pẹ̀lú yín níwọ̀n ìgbà tí ẹ bá wà pẹ̀lú rẹ̀; bí ẹ bá sì wá a, òun yóò jẹ́ kí ẹ rí òun, ṣùgbọ́n bí ẹ bá fi í sílẹ̀, òun yóò fi yín sílẹ̀.”—2 Kíróníkà 15:1, 2.
Jèhófà Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Ẹni Gidi sí Wa
13. Báwo la ṣe lè fi hàn pé Jèhófà jẹ́ ẹni gidi sí wa?
13 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa Mósè pé: “Ó ń bá a lọ ní fífẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni tí a kò lè rí.” (Hébérù 11:27) Ká sọ tòótọ́, Mósè kò rí Ọlọ́run sójú rí. (Ẹ́kísódù 33:20) Àmọ́ Jèhófà jẹ́ ẹni gidi sí i débi pé ńṣe ló dà bíi pé ó rí I. Bákan náà, lẹ́yìn àdánwò Jóòbù, ó fojú ìgbàgbọ́ rí Jèhófà kedere pé ó jẹ́ Ọlọ́run tó fàyè gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láti fojú winá àdánwò àmọ́ tí kì í fi wọ́n sílẹ̀. (Jóòbù 42:5) A sọ nípa Énọ́kù àti Nóà pé wọ́n ‘bá Ọlọ́run rìn.’ Wọ́n ṣe èyí nípa gbígbìyànjú láti múnú Ọlọ́run dùn àti nípa ṣíṣègbọràn sí i. (Jẹ́nẹ́sísì 5:22-24; 6:9, 22; Hébérù 11:5, 7) Bí Jèhófà bá jẹ́ ẹni gidi sí wa bó ṣe jẹ́ sí Énọ́kù, Nóà, Jóòbù, àti Mósè, a óò máa “ṣàkíyèsí rẹ̀” ní gbogbo ọ̀nà wa, òun náà yóò “sì mú ipa ọ̀nà [wa] tọ́.”—Òwe 3:5, 6.
14. Kí ló túmọ̀ sí láti “rọ̀” mọ́ Jèhófà?
14 Nígbà tó kù díẹ̀ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, Mósè gbà wọ́n nímọ̀ràn pé: “Jèhófà Ọlọ́run yín ni kí ẹ máa rìn tọ̀ lẹ́yìn, òun sì ni kí ẹ máa bẹ̀rù, àwọn àṣẹ rẹ̀ sì ni kí ẹ máa pa mọ́, ohùn rẹ̀ sì ni kí ẹ máa fetí sí, òun sì ni kí ẹ máa sìn, òun sì ni kí ẹ rọ̀ mọ́.” (Diutarónómì 13:4) Wọ́n ní láti máa tẹ̀ lé Jèhófà, kí wọ́n máa bẹ̀rù rẹ̀, kí wọ́n ṣègbọràn sí i, kí wọ́n sì rọ̀ mọ́ ọn. Ohun tí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ kan sọ nípa ọ̀rọ̀ tá a tú sí “rọ̀” níhìn-ín ni pé “èdè náà tọ́ka sí àjọṣe tímọ́tímọ́.” Onísáàmù náà sọ pé: “Ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ ti àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.” (Sáàmù 25:14) Àjọṣe tímọ́tímọ́ yìí tó ṣeyebíye pẹ̀lú Jèhófà yóò jẹ́ tiwa bí òun bá jẹ́ ẹni gidi sí wa, tá a sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an débi tí a ò fi ní í fẹ́ láti bà á nínú jẹ́ lọ́nàkọnà.—Sáàmù 19:9-14.
Ǹjẹ́ O Mọ̀ Nípa Àbójútó Jèhófà?
15, 16. (a) Báwo ni Sáàmù kẹrìnlélọ́gbọ̀n ṣe fi hàn pé Jèhófà bìkítà fún wa? (b) Kí ló yẹ ká ṣe tó bá ṣòro fún wa láti rántí ohun rere tí Jèhófà ṣe fún wa?
15 Ọ̀kan nínú àwọn ìwà àrékérekè Sátánì ni pé kó gbìyànjú láti jẹ́ ká gbàgbé òkodoro òtítọ́ náà pé Jèhófà Ọlọ́run wa ń bójú tó àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní gbogbo ìgbà. Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì mọ̀ nípa ààbò Jèhófà dáadáa, kódà nígbà tí òde ò dẹrùn fún un. Nígbà tó di dandan fún un pé kó ṣe bí ayírí níwájú Ákíṣì Ọba Gátì, ó kọ orin kan, ìyẹn sáàmù kan tó dùn mọ̀ràn-ìn mọran-in, èyí tó ní àwọn gbólóhùn tó fi ìgbàgbọ́ hàn nínú pé: “Ẹ gbé Jèhófà ga lọ́lá pẹ̀lú mi, ẹ sì jẹ́ kí a jọ gbé orúkọ rẹ̀ ga. Mo wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, ó sì dá mi lóhùn, ó sì dá mi nídè nínú gbogbo jìnnìjìnnì mi. Áńgẹ́lì Jèhófà dó yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká, ó sì ń gbà wọ́n sílẹ̀. Ẹ tọ́ ọ wò, kí ẹ sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere; aláyọ̀ ni abarapá ọkùnrin tí ó sá di í. Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là. Ọ̀pọ̀ ni ìyọnu àjálù olódodo, ṣùgbọ́n Jèhófà ń dá a nídè nínú gbogbo wọn.”—Sáàmù 34:3, 4, 7, 8, 18, 19; 1 Sámúẹ́lì 21:10-15.
16 Ǹjẹ́ ó dá ọ lójú pé Jèhófà ní agbára láti gbani là? Ǹjẹ́ o mọ̀ pé àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ ń dáàbò boni? Ǹjẹ́ ìwọ fúnra rẹ ti tọ́ ọ wò tó o sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere? Ìgbà wo lo dìídì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere sí ọ? Gbìyànjú láti rántí. Ṣé nínú ilé tó o wọ̀ kẹ́yìn lóde ẹ̀rí yẹn ni, nígbà tó ti rẹ̀ ọ́ tẹnutẹnu? Bóyá ìgbà yẹn gan-an lo wá ní ìjíròrò alárinrin pẹ̀lú onílé náà. Ǹjẹ́ o rántí dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún okun tó fi kún okun rẹ àti bó ṣe bù kún ọ? (2 Kọ́ríńtì 4:7) Yàtọ̀ síyẹn, ó lè má rọrùn fún ọ láti rántí àwọn ohun rere kan tí Jèhófà ṣe fún ọ ní pàtó. Ó lè jẹ́ pé o ní láti ronú padà sí ọ̀sẹ̀ kan sẹ́yìn, ó tiẹ̀ lè jẹ́ oṣù kan, ọdún kan, tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ pàápàá. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ̀ràn rí, o ò ṣe sa gbogbo ipá rẹ láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, kó o sì gbìyànjú láti rí i bó ṣe máa tọ́ ẹ sọ́nà tó sì máa darí rẹ? Àpọ́sítélì Pétérù gba àwọn Kristẹni níyànjú pé: “Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára ńlá Ọlọ́run, . . . bí ẹ ti ń kó gbogbo àníyàn yín lé e, nítorí ó bìkítà fún yín.” (1 Pétérù 5:6, 7) Láìṣe àní-àní, bó ṣe ń bìkítà fún ọ tó yóò yà ọ́ lẹ́nu gan-an!—Sáàmù 73:28.
Má Ṣe Dẹ́kun Wíwá Jèhófà
17. Kí ló ṣe pàtàkì bá a bá fẹ́ máa wá Jèhófà lójú méjèèjì?
17 Níní àjọṣe pẹ̀lú Jèhófà gbọ́dọ̀ jẹ́ ohun tí a ó máa bá lọ bẹ́ẹ̀. Jésù sọ nínú àdúrà tó gbà sí Baba rẹ̀ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Gbígba ìmọ̀ Jèhófà àti ti Ọmọ rẹ̀ béèrè ìsapá wa ìgbà gbogbo. A nílò ìrànlọ́wọ́ àdúrà àti ẹ̀mí mímọ́ ká tó lè lóye “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 2:10; Lúùkù 11:13) A tún nílò ìtọ́sọ́nà “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” láti fi oúnjẹ tẹ̀mí tí wọ́n ń fúnni “ní àkókò tó bẹ́tọ̀ọ́ mu” bọ́ èrò inú wa. (Mátíù 24:45) Jèhófà ń tipasẹ̀ ìṣètò yẹn gbà wá nímọ̀ràn pé kí á ka Ọ̀rọ̀ òun lójoojúmọ́, ká lọ́ sí àwọn ìpàdé Kristẹni déédéé, ká sì fi tọkàntọkàn kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù “ìhìn rere ìjọba náà.” (Mátíù 24:14) Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a ó máa bá a lọ ní wíwá Jèhófà Ọlọ́run wa tó bìkítà.
18, 19. (a) Kí ló yẹ ká pinnu láti ṣe? (b) Bí a bá mú ìdúró wa gbọn-in lòdì sí Èṣù tá a sì ń wá Jèhófà lójú méjèèjì, báwo la ṣe máa bù kún wa?
18 Sátánì ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti mú inúnibíni, àtakò, àti wàhálà bá àwọn èèyàn Jèhófà ní gbogbo ọ̀nà. Ó ń gbìyànjú láti kó wa sí yọ́ọ́yọ́ọ́ kó sì ba ìdúró rere tá a ní lọ́dọ̀ Ọlọ́run jẹ́. Ó fẹ́ ká jáwọ́ nínú iṣẹ́ tá a ti ń wá àwọn ọlọ́kàntútù rí tá a sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti wá sí ìhà ọ̀dọ̀ Jèhófà lórí ọ̀ràn ipò ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run. Àmọ́ a gbọ́dọ̀ pinnu láti jẹ́ adúróṣinṣin ti Jèhófà, ká ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀ pé yóò gbà wá lọ́wọ́ ẹni burúkú náà. Nípa jíjẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣamọ̀nà wa àti nípa dídúró ṣánṣán ti ètò àjọ rẹ̀ tó ṣeé fojú rí, a lè ní ìdánilójú pé yóò máa tì wá lẹ́yìn ní gbogbo ìgbà.—Aísáyà 41:8-13.
19 Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká mú ìdúró wa gbọn-in lòdì sí Èṣù àti àwọn ìwà àrékérekè rẹ̀, ká máa fi gbogbo ìgbà wá Jèhófà Ọlọ́run wa ọ̀wọ́n, ẹni tí kò ní kùnà láti ‘fìdí wa múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in, tí yóò sì sọ wá di alágbára.’ (1 Pétérù 5:8-11) Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a ó ‘pa ara wa mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, bí a ti ń dúró de àánú Olúwa wa Jésù Kristi pẹ̀lú ìyè àìnípẹ̀kun níwájú.’—Júúdà 21.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí ni ọ̀rọ̀ náà “Èṣù” túmọ̀ sí, báwo sì ni Èṣù ṣe hùwà lọ́nà tó bá àpèlé yẹn mu?
• Báwo ni Jèhófà ṣe yàtọ̀ sí Èṣù nínú ọ̀nà tí Ó gbà ń wo àwọn olùgbé orí ilẹ̀ ayé?
• Èé ṣe tí ẹnì kan fi ní láti tẹ́wọ́ gba ìràpadà náà kí ó tó lè tọ Jèhófà lọ?
• Kí ló túmọ̀ sí láti “rọ̀” mọ́ Jèhófà, báwo la sì ṣe lè máa wá a lójú méjèèjì?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Pẹ̀lú onírúurú àdánwò tí Jóòbù ní, ó mọ̀ pé Jèhófà bìkítà fún òun
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Kíka Bíbélì lójoojúmọ́, lílọ sáwọn ìpàdé Kristẹni déédéé, àti fífi tìtaratìtara kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù ń rán wa létí pé Jèhófà bìkítà fún wa