Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí Kristẹni Máa Jowú?
Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí Kristẹni Máa Jowú?
OWÚ—ṣé ànímọ́ tó yẹ káwọn Kristẹni ní ni? Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, a gbà wá níyànjú láti “máa lépa ìfẹ́,” bẹ́ẹ̀ la sì sọ fún wa pé “ìfẹ́ kì í jowú.” (1 Kọ́ríńtì 13:4; 14:1) Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, a tún sọ fún wa pé ‘Ọlọ́run owú ni Jèhófà,’ a sì pa á láṣẹ fún wa láti “di aláfarawé Ọlọ́run.” (Ẹ́kísódù 34:14; Éfésù 5:1) Kí ló mú kó dà bí ẹni pé àwọn ọ̀rọ̀ yìí ta kora?
Ìdí ni pé ọ̀rọ̀ Hébérù àti ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “owú” nínú Bíbélì ní ìtumọ̀ tó gbòòrò gan-an. Wọ́n lè túmọ̀ sóhun tó dáa wọ́n sì lè túmọ̀ sí ohun tó burú, ó sinmi lórí bá a bá ṣe lò wọ́n. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ Hébérù tá a tú sí “owú” lè túmọ̀ sí “kéèyàn ranrí mọ́ ìfọkànsìn tá a yà sọ́tọ̀ gédégbé; kéèyàn má gba ìbáradíje kankan láàyè; ìtara; ẹ̀mí ìgbónára; owú [bóyá láti ṣe rere tàbí láti ṣe ibi]; ṣíṣe ìlara.” Ìtumọ̀ kan náà ni ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a lò fún un ní. Wọ́n lè lo ọ̀rọ̀ yìí fún èròkerò tí ẹnì kan ní sí ẹni tó fura sí pé ó ń bá òun dupò tàbí sí ẹnì kan tó dà bí ẹni pé ó ń gbádùn àwọn àǹfààní kan. (Òwe 14:30) Ọ̀rọ̀ kan náà yìí tún lè túmọ̀ sí ànímọ́ dáradára tí Ọlọ́run fúnni, ìyẹn ànímọ́ tó ń mú ká fẹ́ dáàbò bo èèyàn wa lọ́wọ́ ewu.—2 Kọ́ríńtì 11:2.
Àpẹẹrẹ Tó Ga Jù Lọ
Jèhófà fi àpẹẹrẹ tó ga jù lọ lélẹ̀ nípa jíjowú lọ́nà tó dáa. Kò ní ètekéte kankan lọ́kàn, nítorí pé kò fẹ́ kí àwọn èèyàn òun lọ́wọ́ nínú ìwà ìbàjẹ́ nípa tara àti nípa tẹ̀mí ló ṣe ń jowú. Ó sọ nípa àwọn èèyàn rẹ̀ àtijọ́, tó pè ní Síónì lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, pé: “Ṣe ni èmi yóò fi owú ńláǹlà jowú fún Síónì, ìhónú ńláǹlà sì ni èmi yóò fi jowú fún un.” (Sekaráyà 8:2) Bí bàbá tó nífẹ̀ẹ́ ṣe máa ń wà lójúfò ní gbogbo ìgbà láti dáàbò bo àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ ewu, náà ni Jèhófà ṣe ń wà lójúfò láti dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ ewu nípa tara àti nípa tẹ̀mí.
Kí Jèhófà lè dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ ló ṣe pèsè Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀ ìṣírí ló wà níbẹ̀ fún wọn láti rìn lọ́nà ọgbọ́n, àpẹẹrẹ àwọn tó ti ṣe bẹ́ẹ̀ sì kúnnú rẹ̀ fọ́fọ́. A kà á nínú Aísáyà 48:17, pé: “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn.” Ẹ ò rí bó ṣe ń tuni lára tó láti mọ̀ pé owú Jèhófà ló mú kó máa bójú tó wa kó sì máa dáàbò bò wá! Tí kì í bá ṣe pé ó ń jowú lọ́nà tó dáa ni, àìnírìírí wa ì bá ti kó wa sí yọ́ọ́yọ́ọ́. Ó dájú pé owú tí Jèhófà ń jẹ kì í ṣe ti onímọtara-ẹni-nìkan.
Níbi tá a wá dé yìí, ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín jíjowú lọ́nà tí Ọlọ́run fẹ́ àti jíjowú lọ́nà tí ò dáa? Ká tó lè mọ ìyàtọ̀ náà, ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ Míríámù àti Fíníhásì yẹ̀ wò. Kíyè sí ohun tó mú kí wọ́n hùwà lọ́nà tí wọ́n gbà hùwà.
Míríámù àti Fíníhásì
Míríámù ni ẹ̀gbọ́n Mósè àti Áárónì, tí wọ́n jẹ́ aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n jáde kúrò ní Íjíbítì. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà nínú aginjù, Míríámù bẹ̀rẹ̀ sí jowú Mósè àbúrò rẹ̀. Àkọsílẹ̀ inú Bíbélì kà pé: “Wàyí o, Míríámù àti Áárónì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ lòdì sí Mósè tìtorí aya tí ó jẹ́ ará Kúṣì tí ó fẹ́ . . . Wọ́n sì ń sọ ṣáá pé: Númérì 12:1-15.
‘Ṣé kìkì nípasẹ̀ Mósè nìkan ṣoṣo ni Jèhófà ti gbà sọ̀rọ̀ ni? Kò ha ti sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àwa pẹ̀lú bí?’” Ó hàn gbangba pé Míríámù ni abẹnugan nídìí ọ̀tẹ̀ tí wọ́n dì mọ́ Mósè, nítorí òun ni Jèhófà fìyà jẹ, kì í ṣe Áárónì. Àrùn ẹ̀tẹ̀ bò ó fún odidi ọ̀sẹ̀ kan gbáko nítorí ìwà ọ̀yájú tó hù.—Kí ló mú kí Míríámù dìtẹ̀ mọ́ Mósè? Ṣé ìjọsìn tòótọ́ ló ká a lára tó bẹ́ẹ̀ tó sì fẹ́ dáàbò bo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ ewu? Rárá o. Ńṣe ló dà bí ẹni pé Míríámù jẹ́ kí èròkerò láti di ẹni táwọn èèyàn ń wárí fún tí èèkù idà á sì tún wà lọ́wọ́ rẹ̀ gbilẹ̀ lọ́kàn òun. Wòlíì obìnrin ni ní Ísírẹ́lì, àwọn èèyàn ò sì kóyán rẹ̀ kéré, àgàgà àwọn obìnrin. Òun ló ń dárin fún àwọn èèyàn nígbà tá a fi iṣẹ́ ìyanu mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì la Òkun Pupa kọjá. Àmọ́ nígbà tó yá, ó ṣeé ṣe kí ìdààmú ti bá Míríámù níbi tó ti ń ronú pé ìyàwó Mósè á bẹ̀rẹ̀ sí bá òun ṣorogún, tóun ò sì ní gbayì bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Owú onímọtara-ẹni-nìkan yìí ló mú kó bẹ̀rẹ̀ sí dìtẹ̀ mọ́ Mósè, ẹni tí Jèhófà yàn.—Ẹ́kísódù 15:1, 20, 21.
Àmọ́ ọ̀tọ̀ lohun tó mú kí Fíníhásì ṣe ohun tó ṣe ní tirẹ̀. Nígbà tó kù díẹ̀ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, ìyẹn nígbà tí wọ́n pabùdó sí Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù, àwọn obìnrin Móábù àtàwọn obìnrin Mídíánì tan ọ̀pọ̀ ọkùnrin Ísírẹ́lì sínú ìwà ìṣekúṣe àti ìbọ̀rìṣà. Jèhófà pàṣẹ fún àwọn onídàájọ́ ní Ísírẹ́lì pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn ọkùnrin tó lọ́wọ́ nínú ìwà ìbàjẹ́ náà kí ibùdó náà lè di mímọ́ kí ìbínú Jèhófà sì rọlẹ̀. Símírì tó jẹ́ olóyè nínú ẹ̀yà Síméónì gbójú gbóyà débi pé ó mú Kọ́síbì, ọmọbìnrin Mídíánì wá sí ibùdó “lójú gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,” láti bá a ṣèṣekúṣe. Fíníhásì ò jáfara rárá. Owú tàbí ìtara fún ìjọsìn Jèhófà, àti ìfẹ́ láti mú kí ibùdó náà wà láìlẹ́gbin, mú kó pa àwọn alágbèrè náà nínú àgọ́ wọn. A gbóríyìn fún un nítorí “owú oníbìínú” rẹ̀, àti bí kò ṣe ‘fàyè gba bíbá Jèhófà díje rárá.’ Ìgbésẹ̀ ojú ẹsẹ̀ tí Fíníhásì gbé yìí ló dá àrùn tí Jèhófà fi jẹ wọ́n níyà dúró. Àrùn náà ti gbẹ̀mí ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún èèyàn. Jèhófà san èrè fún un nípa bíbá a dá májẹ̀mú pé ipò àlùfáà ò ní kúrò ní ìlà ìdílé rẹ̀ títí láé.—Númérì 25:4-13; The New English Bible.
Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín àwọn méjì tó jowú yìí? Owú onímọtara-ẹni-nìkan ló jẹ́ kí Míríámù gbógun ti àbúrò rẹ̀, àmọ́ Fíníhásì jowú tirẹ̀ lọ́nà tí Ọlọ́run fẹ́, èyí ló fi hùwà àìṣègbè. Bíi ti Fíníhásì, àwọn ìgbà mìíràn wà tó yẹ káwa náà la ọ̀rọ̀ mọ́lẹ̀ láìfi dúdú pe funfun, tàbí ká ṣe àwọn ohun kan láti fi gbèjà orúkọ Jèhófà, ìjọsìn rẹ̀ àtàwọn èèyàn rẹ̀.
Owúkówú
Àmọ́, ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kéèyàn máa jowúkówú? Ó ṣeé ṣe mọ̀nà. Bọ́ràn ṣe rí láàárín àwọn Júù ọ̀rúndún kìíní nìyẹn. Wọn kì í fi Òfin tí Ọlọ́run fún wọn àtàwọn àṣà ìbílẹ̀ wọn ṣeré rárá. Ibi tí wọ́n ti ń sapá láti dáàbò bo òfin yìí náà ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àìmọye àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ mìíràn àti ìkálọ́wọ́kò lónírúurú tó wá di ẹrù ìnira sáwọn èèyàn lọ́rùn. (Mátíù 23:4) Nítorí pé wọn ò fẹ́ gbà pé Ọlọ́run ti fi ohun náà gan-an tí Òfin Mósè ṣàpẹẹrẹ rọ́pò òfin náà ló mú kí wọn bẹ̀rẹ̀ sí í jowúkówú tí wọ́n fi ń han àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi léèmọ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tóun náà ti fìgbà kan ní ìtara tá a gbé gbòdì fún Òfin náà, sọ pé àwọn tí wọ́n ń gbèjà Òfin náà ní “ìtara [owú] fún Ọlọ́run; ṣùgbọ́n kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye.”—Róòmù 10:2; Gálátíà 1:14.
Kódà, kò rọrùn rárá fún ọ̀pọ̀ àwọn Júù tó di Kristẹni láti fi ìtara ànísódì tí wọ́n ní fún Òfin yìí sílẹ̀. Lẹ́yìn ìrìn àjò míṣọ́nnárì ẹlẹ́ẹ̀kẹta tí Pọ́ọ̀lù rìn, ó jábọ̀ fún ẹgbẹ́ olùṣàkóso nípa bí àwọn èèyàn ṣe yí padà. Nígbà yẹn, “gbogbo” ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Júù tí wọ́n jẹ́ Kristẹni ni “wọ́n . . . jẹ́ onítara fún Òfin.” (Ìṣe 21:20) Èyí kì í ṣe ọdún kan kì í sì í ṣe ọdún méjì lẹ́yìn tí ẹgbẹ́ olùṣàkóso ti sọ pé kò pọn dandan kí àwọn Kèfèrí tó di Kristẹni dá adọ̀dọ́. Àwọn ọ̀ràn tó jẹ mọ́ pípa Òfin mọ́ ti bẹ̀rẹ̀ sí fa gbọ́nmi-si omi-ò-to nínú ìjọ. (Ìṣe 15:1, 2, 28, 29; Gálátíà 4:9, 10; 5:7-12) Àwọn Kristẹni kan tí wọ́n jẹ́ Júù kò lóye ní kíkún nípa bí Jèhófà ṣe ń bá àwọn èèyàn rẹ̀ lò, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé èrò àwọn làwọn tó kù gbọ́dọ̀ gbà, wọ́n sì ń ṣe lámèyítọ́ wọn.—Kólósè 2:17; Hébérù 10:1.
Àwa náà gbọ́dọ̀ ṣọ́ra láti má ṣe jẹ́ kí owú mú wa gbìyànjú láti fi ọ̀ranyàn mú àwọn èèyàn ṣe ohun tó wà lọ́kàn wa tàbí ká mú wọn gba ọ̀nà tá a fẹ́ àmọ́ tí kò sí níbàámu pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Á dára ká fara mọ́ àwọn òye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ ń rí gbà nípasẹ̀ ipa ọ̀nà tí Jèhófà ń lò lónìí.
Jowú Nítorí Jèhófà
Owú jíjẹ lọ́nà tí Ọlọ́run fẹ́ ní àǹfààní tirẹ̀ nínú ìjọsìn tòótọ́. Tá ò bá ranrí mọ́ kìkì iyì ara wa tàbí ẹ̀tọ́ wa, owú jíjẹ lọ́nà tó tọ́ máa ń mú ká gbọ́ ti Jèhófà. Ó ń mú ká wá onírúurú ọ̀nà láti sọ òtítọ́ nípa rẹ̀ fáwọn èèyàn, ká gbèjà ọ̀nà rẹ̀ àtàwọn èèyàn rẹ̀.
Onílé kan tó ṣi ohun tí òfin Ọlọ́run sọ nípa ẹ̀jẹ̀ lóye sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sí Akiko, tó jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Akiko fọgbọ́n gbèjà Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó tiẹ̀ tún mẹ́nu kan àwọn ewu tó wà nínú gbígba ẹ̀jẹ̀ sára pàápàá. Ìtara mímúná tó ní láti sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà mú kó yí ìjíròrò náà sorí ohun tó wòye pé ó mú kí obìnrin náà máa ṣàtakò—ohun náà ni pé obìnrin yìí kò gbà gbọ́ pé Ẹlẹ́dàá wà. Akiko bá onílé náà fèrò wérò nípa bí ìṣẹ̀dá ṣe ti ìgbàgbọ́ pé Ẹlẹ́dàá kan wà lẹ́yìn. Kì í ṣe pé ìgbèjà tó ṣe láìṣojo yìí mú kí obìnrin náà pa ẹ̀tanú tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tó ní tẹ́lẹ̀ tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan nìkan, ó tún mu kó ṣeé ṣe fún arábìnrin yìí láti bẹ̀rẹ̀ sí bá obìnrin náà ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Onílé yìí tínú máa ń bí burúkú burúkú tẹ́lẹ̀ ti di olùyin Jèhófà báyìí.
Jíjowú lọ́nà tó tọ́ tàbí ìtara fún ìjọsìn tòótọ́ máa ń jẹ́ ká wà lójúfò, ó sì máa ń jẹ́ ká lo àǹfààní tá a bá ní láti sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn wa ká sì gbèjà rẹ̀ níbi iṣẹ́, nílé ìwé, níbi ìtajà tàbí nígbà tá a bá ń rìnrìn àjò. Bí àpẹẹrẹ, Midori pinnu pé òun á bá àwọn ẹlẹgbẹ́ òun níbi iṣẹ́ sọ̀rọ̀ nípa nǹkan tóun gbà gbọ́. Ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ tó ti lé lẹ́ni ogójì ọdún sọ pé òun ò fẹ́ a han obìnrin yìí, ó sì sọ pé òun lè bẹ̀rẹ̀ sí bá ọmọ obìnrin náà ṣèkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé náà. Ìkẹ́kọ̀ọ́ náà bẹ̀rẹ̀, àmọ́ obìnrin náà kì í sí níbi ìjíròrò náà. Midori jẹ́ kí obìnrin yìí wo fídíò Jehovah’s Witnesses—The Organization Behind the Name.* Èyí mú èrò òdì tó ti ní lọ́kàn tẹ́lẹ̀ kúrò. Ohun tó rí wú u lórí gan-an, ó sì sọ pé: “Mo fẹ́ dà bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Lòun náà bá bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bíi tọmọ rẹ̀.
gbọ́rọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà páàpáà. Nígbà tó ṣe, wọ́n jọ ní ìjíròrò mìíràn, àmọ́ obìnrin yìí bẹ̀rẹ̀ sí ṣàròyé nípa ìwà tí ò dára tí ọmọ rẹ̀ ń hù. Midori fi ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè-Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́,Jíjowú lọ́nà tó tọ́ láǹfààní tirẹ̀ nínú ìjọ Kristẹni. Ó ń mú kí ìfẹ́ gbilẹ̀ ó sì ń mú ká yẹra fún àwọn ohun tí kò dára tó lè pa àwọn ará wa nípa tẹ̀mí lára, bí òfófó ṣíṣe tàbí ríronú bíi tàwọn apẹ̀yìndà. Jíjowú lọ́nà tí Ọlọ́run fẹ́ á mú ká ti ìpinnu táwọn alàgbà bá ṣe lẹ́yìn, nítorí pé ìgbà míì wà tó máa ń pọn dandan fún wọn láti bá ẹni tó bá hùwà tí ò dáa wí. (1 Kọ́ríńtì 5:11-13; 1 Tímótì 5:20) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé nípa bó ṣe ń jowú nítorí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nínú ìjọ Kọ́ríńtì, ó sọ pé: “Èmi ń jowú lórí yín pẹ̀lú owú lọ́nà ti Ọlọ́run, nítorí èmi fúnra mi ti fẹ́ yín sọ́nà fún ọkọ kan, kí èmi lè mú yín wá fún Kristi gẹ́gẹ́ bí wúńdíá oníwà mímọ́.” (2 Kọ́ríńtì 11:2) Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni owú tá à ń jẹ ń mú ká sa gbogbo ipá wa láti mú kí gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ wà ní mímọ́ ní ti àwọn ẹ̀kọ́ wa, nípa tẹ̀mí àti ní ti ìwà rere.
Kò sírọ́ ńbẹ̀ o, jíjowú lọ́nà tó dáa—ìyẹn lọ́nà tí Ọlọ́run fẹ́—máa ń mú káwọn ẹlòmíràn ṣe ohun tó dára. Ó ń mú kéèyàn rójú rere Jèhófà, ó sì yẹ kó jẹ́ ọ̀kan lára ànímọ́ àwọn Kristẹni lónìí.—Jòhánù 2:17.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é jáde.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Jíjowú lọ́nà tí Ọlọ́run fẹ́ ló sún Fíníhásì ṣe àwọn ohun tó ṣe
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Ṣọ́ra fún owúkówú
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Jíjowú lọ́nà tí Ọlọ́run fẹ́ ló ń mú ká sọ ohun tá a gbà gbọ́ fáwọn ẹlòmíràn ká sì mọrírì ẹgbẹ́ àwọn ará