Sátánì—Ṣé Olubi Tó Wà Lóòótọ́ Ni àbí Ẹni Ìtàn Àròsọ Lásán?
Sátánì—Ṣé Olubi Tó Wà Lóòótọ́ Ni àbí Ẹni Ìtàn Àròsọ Lásán?
ÀTÌGBÀ ìwáṣẹ̀ làwọn tó mọnúúrò ti fẹ́ mọ ibi tí ohun búburú ti ń wá. Ìwé atúmọ̀ èdè A Dictionary of the Bible, látọwọ́ James Hastings sọ pé: “Àtìgbà tí ẹ̀dá èèyàn ti mọ ọ̀tún yàtọ̀ sí òsì làwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tágbára wọn ju tèèyàn lọ tí wọ́n sì ń ní ipa búburú lórí rẹ̀ ti ń kò ó lójú.” Ìwé tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ yìí tún sọ pé: “Nígbà ìwáṣẹ̀, ẹ̀dá èèyàn gbìyànjú láti mọ ohun tó ń mú káwọn nǹkan ṣẹlẹ̀, wọ́n sì parí èrò sí pé lóòótọ́ làwọn ẹ̀mí yìí àtàwọn ohun mìíràn tá à ń rí nínú ìṣẹ̀dá wà.”
Àwọn òpìtàn sọ pé látìgbà ìwáṣẹ̀ Mesopotámíà làwọn èèyàn ti gbà gbọ́ pé àwọn òrìṣà àtàwọn ẹ̀mí èṣù wà. Àwọn ará Bábílónì ìgbàanì gbà gbọ́ pé Nergal, ìyẹn ọlọ́run tó jẹ́ oníwà ipá “tó ń sunni nínú iná,” ló ń ṣàkóso ilẹ̀ àwọn òkú tàbí “ilẹ̀ àrèmábọ̀.” Wọ́n tún máa ń bẹ̀rù ẹ̀mí èṣù, wọ́n sì máa ń pe ògèdè lóríṣiríṣi láti tù wọ́n lójú. Nínú ìtàn ìwáṣẹ̀ Íjíbítì, Set lorúkọ ọlọ́run tó ń ṣe ibi, “wọ́n sì yàwòrán rẹ̀ bí ẹranko fàkìàfakia kan tí imú rẹ̀ rí sosoro, tó wá tẹ̀ kọdọrọ, etí rẹ̀ nà ó sì nígun mẹ́rin, ìrù rẹ̀ le ó sì pẹ̀ka.”—Larousse Encyclopedia of Mythology.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn Gíríìkì àtàwọn Hébérù ní ọlọ́run tó ń ṣe rere àtèyí tó ń ṣe ibi, wọn ò ní ọ̀kan sàn-án tó jẹ́ baba ìsàlẹ̀ àwọn tó ń ṣe ibi. Àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí wọn fi èrò méjì tó ta kora kọ́ àwọn èèyàn. Empedocles sọ pé Ìfẹ́ àti Rúdurùdu ni èrò méjì náà. Plato ní tiẹ̀ sọ pé ọ̀kan lára èrò méjì yìí jẹ́ akóredé nígbà tí èkejì sì ń fa ibi. Georges Minois sọ nínú ìwé rẹ̀ Le Diable (Èṣù), pé “ìsìn àwọn [Gíríìkì àti Róòmù] kèfèrí ayé ọjọ́un ò gbà pé Èṣù wà.”
Ní ìlú Iran, ohun tí ìsìn tí Wòlíì Zoroaster dá sílẹ̀ fi ń kọ́ni ni pé Ahura Mazda tàbí Ormazd, tó jẹ́ ọlọ́run tó ga ju àwọn tó kù lọ, ló ṣẹ̀dá Angra Mainyu, tàbí Ahriman, tó fẹ́ràn láti máa hùwà ibi, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ di Apanirun.
Nínú ìsìn àwọn Júù, wọ́n rọra ṣàlàyé Sátánì pé òun ni Elénìní Ọlọ́run, òun ló sì ń fa ẹ̀ṣẹ̀. Àmọ́ lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, wọ́n fi ẹ̀kọ́ àwọn kèfèrí yí ohun tí wọ́n sọ yìí padà. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Judaica, sọ pé: “Ìyípadà ńláǹlà ti wáyé . . . láwọn ọ̀rúndún tó kángun sí Sànmánì Tiwa. Àkókò yìí ni ẹ̀sìn [Júù] . . . bẹ̀rẹ̀ sí dáṣà tó jẹ́ ti ìgbàgbọ́ nínú èrò méjì tó ta kora pé àwọn ẹ̀mí búburú tó ń ṣebi tí wọ́n sì ń tanni jẹ ni ò jẹ́ kí Ọlọ́run àtàwọn ẹ̀mí tó ń ṣe rere àti òótọ́ rímú mí lọ́run àti lórí ilẹ̀ ayé. Ó dà bí ẹni pé ẹ̀sìn àwọn ará Páṣíà leku ẹdá tó dá èrò yìí sílẹ̀.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Concise Jewish Encyclopedia, sọ pé: “Títẹ̀lé
òfin àti síso ońdè mọ́ra ló ń dáàbò boni kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù.”Ẹ̀kọ́ Ìsìn Àwọn Kristẹni Apẹ̀yìndà
Bí àwọn ẹlẹ́sìn Júù ṣe gba ẹ̀kọ́ tó lòdì sí Bíbélì nípa Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù náà làwọn Kristẹni tó ti pẹ̀yìn dà ṣe ń fẹ àwọn ẹ̀kọ́ tí ò bá Ìwé Mímọ́ mu lójú. Ìwé The Anchor Bible Dictionary, sọ pé: “Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn tí ò bójú mú rárá táwọn ará ìgbàanì fi ń kọ́ni ni pé Ọlọ́run ra àwọn èèyàn rẹ̀ padà nípa sísanwó fún Sátánì láti tú wọn sílẹ̀.” Irenaeus (ní ọ̀rúndún kejì Sànmánì Tiwa) ló fi ẹ̀kọ́ yìí kọ́ àwọn èèyàn. Origen (ní ọ̀rúndún kẹta Sànmánì Tiwa) ló wá túbọ̀ fẹ ẹ̀kọ́ yìí lójú, ó sọ pé “èṣù ló jàre ẹjọ́ tó pe ẹdá èèyàn,” ó sì ka “ikú Kristi . . . sí owó ìràpadà tá a san fún èṣù.”—History of Dogma, látọwọ́ Adolf Harnack.
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Catholic Encyclopedia, sọ pé: “Fún nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún gbáko [ni ẹ̀kọ́ pé Èṣù la san owó ìràpadà fún] fi jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn,” àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ò sì tíì jáwọ́ nínú ìgbàgbọ́ yìí. Àwọn Bàbá Ìjọ kan, títí kan Augustine (ọ̀rúndún kẹrin sí ìkarùn-ún Sànmánì Tiwa) gbà gbọ́ nínú ẹ̀kọ́ náà pé Sátánì la sanwó ìràpadà fún. Ní paríparì rẹ̀, nígbà tó máa di ọ̀rúndún kejìlá Sànmánì Tiwa, Anselm àti Abelard, tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn wá fẹnu ọ̀rọ̀ ọ̀hún jóná síbì kan pé Ọlọ́run la rúbọ Kristi sí pé kì í ṣe Sátánì.
Ìgbàgbọ́ Nínú Ohun Asán Nígbà Ojú Dúdú
Dídákẹ́ táwọn àpérò Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì dákẹ́ lórí ọ̀ràn Sátánì yani lẹ́nu, àmọ́ ní 1215 Sànmánì Tiwa, Àpérò Lateran Kẹrin sọ ọ̀rọ̀ kan tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia pè ní “àsọjáde tó gbàrònú nípa ohun tí wọ́n gbà gbọ́.” Ìlànà àkọ́kọ́ níbi àpérò náà kà pé: “Àwọn ẹni ẹ̀mí tó dára ni Ọlọ́run fi èṣù àtàwọn ẹ̀mí èṣù yòókù dá níbẹ̀rẹ̀, àmọ́ àwọn fúnra wọn ló sọra wọn di ẹ̀mí búburú.” Ó fi kún un pé tọ̀sán-tòru ni wọ́n fi ń gbìyànjú láti da ẹ̀dá èèyàn sí àdánwò. Ọ̀rọ̀ yìí gba àfiyèsí ọ̀pọ̀ èèyàn gan-an ní Sànmánì Ojú Dúdú. Wọ́n gbà pé Sátánì ló wà lẹ́yìn ohunkóhun tí ò bá ti rí bó ṣe yẹ kó rí, bí àrùn tí wọn ò bá mojú rẹ̀, ikú òjijì tàbí kí irè oko má ṣe dáadáa. Ní 1233 Sànmánì Tiwa, Póòpù Gregory Kẹsàn-án ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ òfin tó de àwọn aládàámọ̀. Ara àwọn òfin ọ̀hún ni èyí tó fi de àwọn ọmọlẹ́yìn Lúsífà, ìyẹn àwọn tó sọ pé Èṣù làwọn ń jọ́sìn.
Kò pẹ́ tí ìgbàgbọ́ pé Èṣù tàbí àwọn ẹ̀mí búburú lè wọnú ẹ̀dá èèyàn fi bẹ̀rẹ̀ sí kó jìnnìjìnnì báwọn èèyàn, ìbẹ̀rùbojo sì ń mú wọn nítorí àwọn oṣó àti àjẹ́. Ọ̀rúndún kẹtàlá sí ọ̀rúndún kẹtàdínlógún ni ìbẹ̀rù àwọn àjẹ́ kárí gbogbo Yúróòpù títí dé Àríwá Amẹ́ríkà táwọn ọmọ ilẹ̀ Yúróòpù wà. Kódà, Martin Luther àti John Calvin tí wọ́n jẹ́ Pùròtẹ́sítáǹtì alátùn-únṣe ẹ̀sìn pàṣẹ pé káwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí ṣọdẹ àjẹ́ káàkiri. Ní Yúróòpù, tí wọ́n bá kàn gbọ́ hùnrùn-hùnrùn lásán pé ẹnì kan jẹ́ àjẹ́ tàbí kó tiẹ̀ jẹ́ pé abínú-ẹni kan ló parọ́ mọ́ ọn, ó di dandan kí onítọ̀hún déwájú ìgbìmọ̀ tó ń ṣe Ìwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀ kó sì tún fojú ba ilé ẹjọ́. Palaba ìyà ni wọ́n máa ń fi jẹ àwọn aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ kí wọ́n lè kà bòròbòrò pé àwọn ṣe ohun tí wọn ò ṣe.
Pípa ni wọ́n máa ń pa àwọn tó bá jẹ̀bi ẹ̀sùn yìí, wọ́n lè dáná sun wọ́n tàbí kí wọ́n gbé wọn kọ́gi bí wọ́n ṣe ń ṣe ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Scotland. Ní ti iye ẹ̀mí tó ti bá ọ̀ràn náà lọ, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The
World Book Encyclopedia sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí àwọn òpìtàn kan ṣe sọ, láti 1484 sí 1782, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún [300,000] ni iye obìnrin tí ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹni ti pa lórí ẹ̀sùn pé àjẹ́ ni wọ́n.” Tó bá jẹ́ pé Sátánì ló wà nídìí àjálù ayé ojú dúdú yìí, àwọn wo ló ń lò láti ṣe é, ṣé àwọn tá a pa ni àbí àwọn aláṣerégèé ẹlẹ́sìn tó ń ṣenúnibíni?Báwọn Kan Ṣe Gbà Làwọn Míì Ò Gbà
Èrò àwọn onílàákàyè tí wọ́n pè ní Ẹgbẹ́ Àwọn Amòye, gbilẹ̀ gan-an ní ọ̀rúndún kejìdínlógún. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica, sọ pé: “Ńṣe ni ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀kọ́ nípa ìsìn tí Ẹgbẹ́ Àwọn Amòye fi ń kọ́ni fẹ́ mú èrò èyíkéyìí nípa èṣù kúrò lọ́kàn àwọn Kristẹni pé ìtàn àròsọ Sànmánì Ojú Dúdú ló jẹ́.” Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì sọ pé òun ò gbà bẹ́ẹ̀ ó sì tún un sọ níbi Àpérò Kìíní Ìjọba Póòpù (1869 sí 1870), pé òun gbà pé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí Èṣù wà. Àmọ́ kò lè fi gbogbo ẹnu sọ̀rọ̀ lórí ìgbàgbọ́ rẹ̀ yìí mọ́ níbi Àpérò Kejì Ìjọba Póòpù (1962 sí 1965).
Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lákọọ́lẹ̀, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia, sọ pé “Ṣọ́ọ̀ṣì náà ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn áńgẹ́lì àtàwọn ẹ̀mí èṣù.” Àmọ́ o, ìwé atúmọ̀ èdè ẹ̀sìn Kátólíìkì lédè Faransé, tó ń jẹ́ Théo, sọ pé: “Ọ̀pọ̀ Kristẹni lóde òní ni kì í fẹ́ sọ pé èṣù ló ń fa láburú tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé.” Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, pẹ̀lú ìṣọ́ra làwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Kátólíìkì fi ń bójú tó ọ̀ràn yìí, wọ́n ń fọgbọọgbọ́n fara wọn si agbedeméjì ohun táwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì sọ pé wọ́n gbà gbọ́ àti báwọn èèyàn ṣe ń ronú lóde òní. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica, sọ pé: “Téèyàn bá kọ́kọ́ wò ó, ńṣe ló dà bíi pé àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn Kristẹni tó jẹ́ pé irú-wá-ògìrì-wá ni tiwọn ń sọ pé ‘ọ̀rọ̀ àpèjúwe lásánlàsàn’ ni ohun tí Bíbélì sọ nípa Sátánì jẹ́. Àmọ́ bẹ́ẹ̀ kọ́ lọ̀ràn rí, ńṣe ni wọ́n wò ó bí ìtàn àròsọ kan tí wọ́n fi ń gbìyànjú láti ṣàlàyé ohun tó wà ní tòótọ́ àti bí láburú ti ṣe pọ̀ tó láyé.” Ìwé tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ yìí tún sọ nípa àwọn ẹ̀sìn Pùròtẹ́sítáǹtì pé: “Ẹ̀sìn Pùròtẹ́sítáǹtì òde òní fẹ́ máa sọ pé kò yẹ kéèyàn gbà gbọ́ pé ẹni gidi kan ni èṣù.” Ṣùgbọ́n, ṣé ó yẹ káwọn Kristẹni tòótọ́ ka ohun tí Bíbélì sọ nípa Sátánì sí “ọ̀rọ̀ àpèjúwe lásánlàsàn”?
Ohun Tí Ìwé Mímọ́ Fi Kọ́ni
Ìmọ̀ ọgbọ́n orí ẹ̀dá èèyàn àti ẹ̀kọ́ ìsìn ò tíì lè ṣàlàyé tó ṣe gúnmọ́ nípa orírun àwọn ohun búburú gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe ṣàlàyé. Ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa Sátánì ṣe pàtàkì fún èèyàn láti lóye ohun tó ń fa àwọn nǹkan búburú tó ń ṣẹlẹ̀ àti ìjìyà ẹ̀dá èèyàn, àti ìdí tí ìwà ipá fi ń burú sí i lọ́dọọdún.
Àwọn kan lè béèrè pé: Bí Ọlọ́run bá jẹ́ Ẹlẹ́dàá Diutarónómì 30:19; 32:4; Jóṣúà 24:15; 1 Àwọn Ọba 18:21) Nítorí náà, ẹni ẹ̀mí tó di Sátánì ti ní láti jẹ́ ẹni tá a dá lọ́nà tó pé tó wá fúnra rẹ̀ kúrò lọ́nà òtítọ́ àti òdodo.—Jòhánù 8:44; Jákọ́bù 1:14, 15.
rere tó sì nífẹ̀ẹ́, kí ló dé tó fi dá Sátánì tó jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí búburú? Bíbélì fi yé wa pé kò sí àbùkù kankan nínú gbogbo iṣẹ́ tí Jèhófà Ọlọ́run ṣe, àti pé gbogbo ẹ̀dá onílàákàyè tó dá ló fún lómìnira láti yan ohun tó bá wù wọ́n. (Ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni ìgbésẹ̀ olóríkunkun tí Sátánì gbé fi bá ti “ọba Tírè,” mu, ẹni tá a fi èdè ewì ṣàpèjúwe rẹ̀ pé ó “pé ní ẹwà” ó sì ‘jẹ́ aláìní-àléébù ní àwọn ọ̀nà rẹ̀ láti ọjọ́ tí a ti dá a títí a fi rí àìṣòdodo nínú rẹ̀.’ (Ìsíkíẹ́lì 28:11-19) Jèhófà ni ẹni gíga jù lọ àti Adẹ́dàá, Sátánì kò sì sọ pé òun fẹ́ gbapò yìí. Báwo ló tiẹ̀ ṣe lè sọ bẹ́ẹ̀, nígbà tó jẹ́ pé Ọlọ́run ló ṣẹ̀dá rẹ̀? Àmọ́ ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń lo ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ni Sátánì pè níjà. Sátánì sọ ní ọgbà Édẹ́nì pé Ọlọ́run ń fi ohun kan tó jẹ́ ẹ̀tọ́ tọkọtaya àkọ́kọ́ dù wọ́n, àti pé ẹ̀tọ́ yìí ló lè mú kí nǹkan ṣẹnuure fún wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5) Ayò rẹ̀ kúkú jẹ, ó mú kí Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀ sí ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ òdodo, èyí sì fa ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú bá àwọn àti àtọmọdọ́mọ wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 3:6-19; Róòmù 5:12) Nítorí náà, Bíbélì fi hàn pé Sátánì ló ń fa ìjìyà ẹ̀dá èèyàn.
Ṣáájú Ìkún Omi, àwọn áńgẹ́lì kan dara pọ̀ mọ́ Sátánì nínú ọ̀tẹ̀ rẹ̀. Wọ́n gbé ara ẹ̀dá èèyàn wọ̀ láti wá tẹ́ ìfẹ́ ìbálòpọ̀ wọn lọ́rùn pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin èèyàn. (Jẹ́nẹ́sísì 6:1-4) Nígbà tí Ìkún Omi dé, àwọn áńgẹ́lì ọ̀dàlẹ̀ yìí padà sí ilẹ̀ ẹ̀mí àmọ́ kì í ṣe sí “ipò wọn ìpilẹ̀ṣẹ̀” lọ́dọ̀ Ọlọ́run ní ọ̀run. (Júúdà 6) A rẹ̀ wọ́n nípò wálẹ̀ sínú òkùnkùn biribiri nípa tẹ̀mí. (1 Pétérù 3:19, 20; 2 Pétérù 2:4) Àwọn ló wá di ẹ̀mí èṣù, wọn ò lè sìn lábẹ́ ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ mọ́, wọ́n wá di ọmọ abẹ́ Sátánì. Ó hàn gbangba pé àwọn ẹ̀mí èṣù yìí ò lè para dà mọ́, àmọ́ wọ́n lè sa agbára ńlá lórí èrò inú àti ìgbésí ayé ẹ̀dá èèyàn, àwọn sì ni eku ẹdá tó wà lẹ́yìn èyí tó pọ̀ jù nínú ìwà ipá tó ń ṣẹlẹ̀ lónìí.—Mátíù 12:43-45; Lúùkù 8:27-33.
Ìṣàkóso Sátánì Ò Ní Pẹ́ Kógbá Sílé
Ó hàn gbangba pé àwọn ẹ̀mí èṣù wà lẹ́nu iṣẹ́ lónìí. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.”—1 Jòhánù 5:19.
Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ti nímùúṣẹ fi hàn pé Èṣù ń mú kí ìṣòro ayé máa pọ̀ sí i nígbà tó kúkú ti mọ̀ pé “sáà àkókò kúkúrú ni òun ní” láti ṣe iṣẹ́ ibi ọwọ́ rẹ̀ ká tó dè é. (Ìṣípayá 12:7-12; 20:1-3) Tí ìṣàkóso Sátánì bá ti kógbá sílé, ayé titun òdodo á wá dé níbi tí ẹkún, ikú àti ìrora ‘kì yóò ti sí mọ́.’ Nígbà náà, ìfẹ́ Ọlọ́run á wá di ṣíṣe “gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.”—Ìṣípayá 21:1-4; Mátíù 6:10.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Àwọn ará Bábílónì nígbàgbọ́ nínú Nergal (apá òsì pátápátá), tó jẹ́ ọlọ́run oníwà ipá; Plato (apá òsì) gbà gbọ́ nínú “àwọn ọkàn” méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó ta kora
[Àwọn Credit Line]
Àgbá alámọ̀: Musée du Louvre, Paris; Plato: National Archaeological Museum, Athens, Gíríìsì
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Irenaeus, Origen, àti Augustine kọ́ni pé Èṣù la sanwó ìràpadà náà fún
[Àwọn Credit Line]
Origen: Àwọn Fọ́tò Culver; Augustine: Látinú ìwé Great Men and Famous Women
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Ìbẹ̀rù àjẹ́ mú kí wọ́n pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn èèyàn
[Credit Line]
Látinú ìwé Bildersaal deutscher Geschichte