Títọ́ Ọmọ Nílẹ̀ Òkèèrè Ìpèníjà àti Èrè Tó Wà Ńbẹ̀
Títọ́ Ọmọ Nílẹ̀ Òkèèrè Ìpèníjà àti Èrè Tó Wà Ńbẹ̀
Ọ̀KẸ́ àìmọye èèyàn ló ń ṣí láti ibì kan lọ síbòmíràn pẹ̀lú ìrètí àtilọ bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé lákọ̀tun lórílẹ̀-èdè tuntun. Àwọn aṣíwọ̀lú tó wà ní Yúróòpù báyìí lé ní ogún mílíọ̀nù, àwọn àjèjì tó wà ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà lé ní mílíọ̀nù mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n, nígbà tí ìpín mọ́kànlélógún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó ń gbé Ọsirélíà sì jẹ́ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè mìíràn. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ìdílé tó jẹ́ aṣíwọ̀lú wọ̀nyí gbọ́dọ̀ làkàkà láti kọ́ èdè tuntun kí wọ́n sì jẹ́ kí àṣà ìbílẹ̀ tuntun mọ́ àwọn lára.
Àwọn ọmọdé sábà máa ń yára kọ́ èdè àwọn orílẹ̀-èdè tuntun tí wọ́n wà, wọ́n á sì máa ronú ní èdè tuntun náà. Ó lè gba àwọn òbí wọn ní ọ̀pọ̀ àkókò kí wọ́n tó mọ èdè náà sọ. Nígbà táwọn ọmọdé bá dàgbà lórílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ń sọ èdè táwọn òbí wọn ò gbọ́, ìyẹn lè fa ìṣòro àìsí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀, èyí tí kì í tán nílẹ̀ bọ̀rọ̀.
Kì í ṣe pé èdè tuntun náà ń nípa lórí báwọn ọmọ ṣe ń ronú nìkan ni, àmọ́ àṣà ìbílẹ̀ orílẹ̀-èdè tuntun náà tún lè nípa lórí bí nǹkan ṣe ń rí lára wọn. Àwọn òbí lè rí i pé ó ṣòro fáwọn láti lóye ìwà àwọn ọmọ wọn. Nítorí náà, àwọn òbí tó jẹ́ aṣíwọ̀lú tí wọ́n ń gbìyànjú láti tọ́ àwọn ọmọ wọn nínú “ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà” ń dojú kọ àwọn ìpèníjà àrà ọ̀tọ̀.—Éfésù 6:4.
Ìpèníjà Mímọ Èrò Inú àti Ọkàn Wọn
Ìfẹ́ ọkàn àti ojúṣe àwọn Kristẹni òbí ni láti kọ́ àwọn ọmọ wọn ní “èdè mímọ́ gaara” ti òtítọ́ Bíbélì. (Sefanáyà 3:9) Àmọ́, tó bá jẹ́ pé ìwọ̀nba díẹ̀ làwọn ọmọ gbọ́ nínú èdè àwọn òbí wọn, táwọn òbí náà ò sì lè sọ èdè táwọn ọmọ wọn gbọ́ dáadáa, báwo làwọn òbí ṣe máa gbin òfin Jèhófà sínú ọkàn àwọn ọmọ wọn? (Diutarónómì 6:7) Àwọn ọmọ lè lóye ọ̀rọ̀ táwọn òbí wọn ń sọ, àmọ́ bí ohun tí wọ́n ń sọ kò bá dé inú ọkàn wọn, ìyẹn lè sọ wọ́n di àjèjì nínú ilé ara wọn.
Gúúsù Amẹ́ríkà ni Pedro àti Sandra ti ṣí lọ sí Ọsirélíà, wọ́n sì dojú kọ ìṣòro yìí nígbà tí wọ́n ń tọ́ àwọn ọmọkùnrin wọn méjì tó jẹ́ ọ̀dọ́langba. a Pedro sọ pé: “Nígbà téèyàn bá ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tẹ̀mí, àti ọkàn àti ìmọ̀lára ni ọ̀ràn náà kàn. O níláti sọ àwọn èrò tó jinlẹ̀ tó sì nítumọ̀ jáde, nítorí náà ó pọn dandan kó o lo àwọn àkànlò èdè.” Sandra fi kún un pé: “Bí àwọn ọmọ wa ò bá lóye èdè àbínibí wa dáadáa, ó lè ṣàkóbá fún ìgbésí ayé wọn nípa tẹ̀mí. Wọ́n lè máà ní ìmọrírì tó jinlẹ̀ fún òtítọ́, wọn ò sì ní lóye ìjẹ́pàtàkì ohun tí wọ́n ń kọ́. Wọ́n lè máà ní ìfòyemọ̀ nípa tẹ̀mí, kí àjọṣe àárín àwọn àti Jèhófà má sì dán mọ́rán.”
Gnanapirakasam àti Helen ṣí láti Sri Lanka lọ sí ilẹ̀ Jámánì, wọ́n sì ti ní àwọn ọmọ méjì báyìí. Wọ́n jọ fohùn ṣọ̀kan pé: “A ronú pé ó ṣe pàtàkì gan-an káwọn ọmọ wa máa sọ èdè ìbílẹ̀ wa nígbà tí wọ́n bá ń kọ́ èdè Jámánì lọ́wọ́. Ó ṣe pàtàkì fún wọn láti lè bá wa sọ̀rọ̀ nípa ìmọ̀lára wọn, kí wọ́n sì sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn jáde.”
Miguel àti Carmen, tí wọ́n ṣí láti Uruguay lọ sí Ọsirélíà sọ pé: “Àwọn òbí tó wà nípò tá a wà gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ àṣekára. Wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́ èdè tuntun náà dáadáa kí wọ́n lè lóye kí wọ́n sì lè ṣàlàyé àwọn ọ̀ràn tẹ̀mí ní èdè yẹn tàbí kí wọ́n kọ́ àwọn ọmọ wọn láti mọ èdè àwọn òbí wọn sọ dáadáa.”
Ìpinnu Ìdílé
Ohun tó ṣe pàtàkì fún ìlera tẹ̀mí ìdílé aṣíwọ̀lú èyíkéyìí ni pípinnu èdè tí ìdílé náà máa lò láti gba ẹ̀kọ́ “láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.” (Aísáyà 54:13) Bí ìjọ tó ń sọ èdè ìbílẹ̀ ìdílé náà bá wà nítòsí, ìdílé náà lè yàn láti máa dara pọ̀ mọ́ ìjọ yìí. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún lè yàn láti máa lọ sí ìjọ tó ń sọ èdè tí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ń sọ lórílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣí lọ. Àwọn kókó wo ló máa jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe máa ṣe ìpinnu yìí?
Demetrios àti Patroulla, tí wọ́n ṣí láti Kípírọ́sì lọ sí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n sì tọ́ àwọn ọmọ márùn-ún dàgbà níbẹ̀ ṣàlàyé ohun tó mú kí wọ́n ṣe ìpinnu tí wọ́n ṣe, wọ́n ní: “Ìjọ tó ń sọ èdè Gíríìkì ni ìdílé wa kọ́kọ́ ń lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí ran àwa òbí lọ́wọ́ gan-an, ìpalára ló jẹ́ fún ìdàgbàsókè tẹ̀mí àwọn ọmọ wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lóye èdè Gíríìkì dé ìwọ̀n kan, ó ṣòro fún wọn láti mọ àwọn apá pàtàkì nínú àwọn ọ̀ràn tẹ̀mí. Ohun tó fi èyí hàn ni bí wọn ò ṣe dàgbà nípa tẹ̀mí tó bó ṣe yẹ. Bí gbogbo ìdílé wa ṣe kó lọ sí ìjọ tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì nìyẹn, kò sì pẹ́ rárá tá a fi rí ìyọrísí rere tó ní lórí àwọn ọmọ wa. Ó ti fún wọn lókun nípa tẹ̀mí. Pípinnu láti fi ìjọ tá a wà tẹ́lẹ̀ sílẹ̀ kì í ṣe ohun tó rọrùn rárá, àmọ́ a ti wá rí i pé ohun tó bọ́gbọ́n mu ni.”
Ìdílé náà kò gbàgbé èdè àbínibí wọn, ìyẹn ṣì jẹ́ èrè ńlá fún wọn. Àwọn ọmọ wọn sọ pé: “Ohun iyebíye ni kí èdè téèyàn gbọ́ ju ẹyọ kan lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èdè Gẹ̀ẹ́sì ni èdè àbínibí wa, a ti rí i pé ìmọ̀ èdè Gíríìkì tá a ní ti mú kó ṣeé ṣe fún wa láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ láàárín ìdílé wa, àgàgà pẹ̀lú àwọn òbí wa àgbà. Ó tún ti jẹ́ ká túbọ̀ lẹ́mìí ìbánikẹ́dùn fún àwọn aṣíwọ̀lú, ó sì fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé a lè kọ́ èdè mìíràn. Nítorí náà, nígbà tá a dàgbà, ìdílé wa lọ ṣèrànwọ́ fún ìjọ tó ń sọ èdè Albanian.”
Christopher àti Margarita náà ṣí láti Kípírọ́sì lọ sí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, wọ́n sì tọ́ àwọn ọmọ wọn mẹ́ta dàgbà níbẹ̀. Wọ́n yàn láti dara pọ̀ mọ́ ìjọ tó ń sọ èdè Gíríìkì. Nikos, ọmọ wọn, tó ń sìn
gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ìjọ kan tó jẹ́ ti èdè Gíríìkì, rántí pé: “Wọ́n gbà wá níyànjú láti dara pọ̀ mọ́ ìjọ tuntun tó ń sọ èdè Gíríìkì. Ìdílé wa sì kà á sí iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn wá sí.”Margarita sọ pé: “Ìgbà tí ọ̀kan nínú àwọn ọmọkùnrin wa wà lọ́mọ ọdún méje tí ìkejì sì wà lọ́mọ ọdún mẹ́jọ ni wọ́n ti forúkọ sílẹ̀ nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́ bí òbí, bí wọn ò ṣe fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ èdè Gíríìkì yẹn máa ń ṣe wá bákan. Àmọ́ gbogbo àwa tá a wà nínú ìdílé ni iṣẹ́ tí wọ́n bá yan fún ẹnì kan nínú wọn máa ń já lé léjìká, ọ̀pọ̀ wákàtí la máa ń lò láti bá wọn múra iṣẹ́ wọn sílẹ̀.”
Joanna, ọmọbìnrin wọn sọ pé: “Mo lè rántí bí Dádì ṣe ń kọ́ wa ní èdè Gíríìkì nípa kíkọ álífábẹ́ẹ̀tì rẹ̀ sórí pátákó ìkọ̀wé tá a ní sílé, a sì gbọ́dọ̀ mọ̀ ọ́n dáadáa. Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń lo ọdún gbọọrọ láti kọ́ èdè kan, àmọ́ nítorí pé Dádì àti Mọ́mì ràn wá lọ́wọ́, àkókò tá a fi kọ́ èdè Gíríìkì ò pẹ́ rárá.”
Àwọn ìdílé kan máa ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè àbínibí wọn nítorí àwọn òbí ronú pé táwọn bá fẹ́ ní “ìfinúmòye ti ẹ̀mí” táwọn sì fẹ́ tẹ̀ síwájú, àwọn fúnra wọn gbọ́dọ̀ gba ẹ̀kọ́ ní èdè àbínibí àwọn. (Kólósè 1:9, 10; 1 Tímótì 4:13, 15) Tàbí kí ìdílé náà wo èdè tí wọ́n mọ̀ ọ́n sọ gẹ́gẹ́ bí ohun iyebíye láti ran àwọn mìíràn tó ṣí wá sílùú náà lọ́wọ́ kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.
Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ìdílé kan lè ronú pé yóò ṣe àwọn láǹfààní jù láti dara pọ̀ mọ́ ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè tí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ń sọ ní orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣí lọ. (Fílípì 2:4; 1 Tímótì 3:5) Lẹ́yìn tí ìdílé náà bá jíròrò ọ̀ràn náà pa pọ̀, ó kù sọ́wọ́ olórí ìdílé láti ṣe ìpinnu lẹ́yìn tó bá ti mú ọ̀ràn náà tọ Jèhófà lọ nínú àdúrà. (Róòmù 14:4; 1 Kọ́ríńtì 11:3; Fílípì 4:6, 7) Àwọn àbá wo ló lè ran àwọn ìdílé wọ̀nyí lọ́wọ́?
Àwọn Àbá Tó Gbéṣẹ́
Pedro àti Sandra tá a mẹ́nu kàn níṣàájú, sọ pé: “A gbé òfin kan kalẹ̀ láàárín ara wa pé èdè Spanish nìkan la gbọ́dọ̀ máa sọ nínú ilé ká má bàá gbàgbé èdè àbínibí wa. Òfin tá a ṣe yìí kò rọrùn rárá nítorí pé àwọn ọmọ wa mọ̀ pé a gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Àmọ́ tá ò bá pa òfin yìí mọ́, kò ní í pẹ́ tí wọn fi máa gbàgbé èdè Spanish pátápátá.”
Miguel àti Carmen tá a mẹ́nu kan níbẹ̀rẹ̀ dá a lábàá pé: “Bí àwọn òbí bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé déédéé tí wọ́n sì ń ka ẹsẹ ojoojúmọ́ ni èdè àbínibí wọn, ìyẹn yóò jẹ́ kí àwọn ọmọ mọ ìjìnlẹ̀ èdè náà—wọ́n á máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ tẹ̀mí ní èdè yẹn.”
Miguel tún dá a lábàá pé: “Jẹ́ kí iṣẹ́ ìjẹ́rìí gbádùn mọ́ni. Ìpínlẹ̀ wá ní apá tó pọ̀ jù lọ lára ìlú ńlá kan nínú, a sì máa ń lo ọ̀pọ̀ àkókò níbi tá a ti ń fi ọkọ̀ wá àwọn èèyàn tó gbọ́ èdè wa kiri. A máa ń fi àkókò náà ṣe àwọn eré tó ní í ṣe pẹ̀lú Bíbélì, a sì máa ń sọ̀rọ̀ lórí àwọn ọ̀ràn tó ṣe pàtàkì. Mo gbìyànjú láti ṣètò ìrìn àjò ìjẹ́rìí náà kó lè ṣeé ṣe fún wa láti ṣe àwọn ìpadàbẹ̀wò tó múná dóko. Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ náà bá fi máa ṣú, àwọn ọmọ á ti bá ẹnì kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ní ìjíròrò tó gbámúṣé.”
Kíkojú Àṣà Ìbílẹ̀ Tó Yàtọ̀ Síra
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gba àwọn ọ̀dọ́ nímọ̀ràn pé: “Fetí sílẹ̀, ọmọ mi, sí ìbáwí baba rẹ, má sì ṣá òfin ìyá rẹ tì.” (Òwe 1:8) Àmọ́, ìṣòro lè dìde nígbà tí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ tó yàtọ̀ sí ti ibi tí àwọn ọmọ ti dàgbà bá nípa lórí ìbáwí bàbá kan àti “òfin” ìyá kan.
Àmọ́ ṣá o, ọwọ́ olórí ìdílé kọ̀ọ̀kan ló kù sí láti pinnu bí òun ṣe máa ṣàbójútó agbo ilé òun, kò sì gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn ìdílé mìíràn nípa lórí òun láìnídìí. (Gálátíà 6:4, 5) Síbẹ̀, ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tó lárinrin láàárín àwọn òbí àtàwọn ọmọ lè ṣí ọ̀nà sílẹ̀ láti mú kó rọrùn fáwọn òbí láti fara mọ́ àwọn àṣà ìbílẹ̀ tuntun.
Ọ̀pọ̀ àwọn àṣà tó gbòde kan láwọn ilẹ̀ tó ti gòkè àgbà ló jẹ́ èyí tó lè ṣèpalára fún ìlera tẹ̀mí Róòmù 1:26-32) Àwọn Kristẹni òbí kò gbọ́dọ̀ fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú ojúṣe wọn láti darí orin àti eré ìnàjú táwọn ọmọ wọn yàn kìkì nítorí pé wọn ò gbọ́ èdè tí olórin náà ń sọ. Wọ́n gbọ́dọ̀ gbé ìlànà tó ṣe gúnmọ́ kalẹ̀. Síbẹ̀, èyí lè gbé ìpèníjà kan dìde.
àwọn Kristẹni. Ìwà pálapàla láàárín takọtabo, ìwọra, àti ẹ̀mí ọ̀tẹ̀ làwọn orin ìgbàlódé àti eré ìnàjú sábà máa ń gbé lárugẹ. (Carmen sọ pé: “A kì í sábà mọ àwọn ọ̀rọ̀ inú orin táwọn ọmọ wa ń gbọ́. Ohùn orin náà lè dún bí èyí tó dára, àmọ́ bí àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ bá ní ìtumọ̀ méjì tàbí tó ní àwọn ẹ̀dà ọ̀rọ̀ kan tó jẹ́ mọ́ ìṣekúṣe nínú a ò ní í mọ̀.” Báwo ni wọ́n ṣe bójú tó ipò yìí? Miguel sọ pé: “A lo ọ̀pọ̀ àkókò lórí kíkọ́ àwọn ọmọ wa nípa ewu tó wà nínú àwọn orinkórin, a sì gbìyànjú láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti yan orin tó ṣètẹ́wọ́gbà lójú Jèhófà.” Ó dájú pé wíwà lójúfò àti jíjẹ́ olóye ṣe pàtàkì láti kojú àṣà ìbílẹ̀ tó yàtọ̀ síra.—Diutarónómì 11:18, 19; Fílípì 4:5.
Rírí Àwọn Èrè Ibẹ̀
Títọ́ àwọn ọmọ nílẹ̀ òkèèrè ń béèrè ọ̀pọ̀ àkókò àti ìsapá. Òótọ́ ọ̀rọ̀ gan-an nìyẹn. Àmọ́ àwọn ọmọ àtàwọn òbí lè rí èrè púpọ̀ sí i nítorí ìsapá tí wọ́n ṣe.
Azzam àti Sara aya rẹ̀, ṣí láti Turkey lọ sí Jámánì, níbi tí wọ́n ti tọ́ àwọn ọmọ mẹ́ta dàgbà. Èyí tó dàgbà jù lọ nínú àwọn ọmọkùnrin wọn ti ń sìn ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Selters ilẹ̀ Jámánì báyìí. Azzam sọ pé: “Àǹfààní ńlá táwọn ọmọ wa ní ni pé wọ́n lè mú àwọn ànímọ́ tó dára nínú àwọn àṣà ìbílẹ̀ méjèèjì dàgbà.”
Antonio àti Lutonadio kó láti Àǹgólà lọ sí Jámánì wọ́n sì ń tọ́ ọmọ mẹ́sàn-án níbẹ̀. Ìdílé náà ń sọ èdè Lingala, wọ́n tún ń sọ èdè Faransé àti ti Jámánì. Antonio sọ pé: “Mímọ onírúurú èdè sọ ran ìdílé wa lọ́wọ́ láti jẹ́rìí fáwọn èèyàn tó ti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè wá. Èyí sì ń múnú wa dùn gan-an.”
Àwọn ọmọ méjì táwọn tọkọtaya tó ṣí lọ sí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì bí rí i pé gbígbọ́ èdè Japan àti ti Gẹ̀ẹ́sì ṣe àwọn láǹfààní gan-an. Àwọn ọmọ náà sọ pé: “Gbígbọ́ èdè méjì ràn wá lọ́wọ́ láti rí iṣẹ́. A ti jàǹfààní gan-an látinú àwọn àpéjọ ńlá tó jẹ́ ti èdè Gẹ̀ẹ́sì. Lákòókò kan náà, a ti láǹfààní sísìn nínú ìjọ tó ń sọ èdè Japan, níbi tí àìní gbé pọ̀.”
Ó Lè Ṣàṣeyọrí
Títọ́ àwọn ọmọ nígbà téèyàn bá ń gbé láàárín àwọn tí àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ sí tẹni jẹ́ ìpèníjà táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti ń dojú kọ láti àwọn àkókò tí wọ́n kọ Bíbélì. Àwọn òbí Mósè kẹ́sẹ járí bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilẹ̀ Íjíbítì ni wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà. (Ẹ́kísódù 2:9, 10) Àwọn bíi mélòó kan lára àwọn tá a kó nígbèkùn lọ sí Bábílónì ló tọ́ àwọn ọmọ tó múra tán láti padà sí Jerúsálẹ́mù kí wọ́n lè lọ fìdí ìjọsìn tòótọ́ múlẹ̀ níbẹ̀.—Ẹ́sírà 2:1, 2, 64-70.
Bákan náà làwọn Kristẹni òbí lè kẹ́sẹ járí lóde òní. Wọ́n lè rí èrè gbígbọ́ tí àwọn ọmọ wọn ń sọ ohun tí tọkọtaya kan gbọ́ látẹnu àwọn ọmọ wọn pé: “Ìdílé tó wà níṣọ̀kan gan-an ni ìdílé wa nítorí àbójútó onífẹ̀ẹ́ Dádì àti Mọ́mì, tá a máa ń bá ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ alárinrin ní gbogbo ìgbà. Inú wa dùn láti jẹ́ apá kan ìdílé tó ń sin Jèhófà jákèjádò ayé.”
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Sísọ kìkì èdè àbínibí rẹ nínú ilé ń jẹ́ káwọn ọmọ rẹ ní ìmọ̀ èdè yẹn dé ààyè kan
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Sísọ èdè kan náà ń jẹ́ kí ìṣọ̀kan wà láàárín àwọn òbí àgbà àtàwọn ọmọ ọmọ wọn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Kíkọ́ àwọn ọmọ rẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń jẹ́ kí wọ́n ní “ìfinúmòye ti ẹ̀mí”