Èé Ṣe Tí Títọrọ Àforíjì Fi Ṣòro Tó Bẹ́ẹ̀?
Èé Ṣe Tí Títọrọ Àforíjì Fi Ṣòro Tó Bẹ́ẹ̀?
NÍ JULY 2000, àwọn Ọmọ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ti Ìpínlẹ̀ California ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà gbé àbádòfin kan jáde, èyí tí wọ́n ṣe láti máa bá àwọn èèyàn gbófò bí wọ́n bá fi ẹ̀mí ìbánikẹ́dùn hàn sí àwọn tó fara pa nínú jàǹbá ọkọ̀ táwọn fúnra wọn wà lára àwọn tó ṣẹlẹ̀ sí. Kí nìdí tí wọ́n fi gbé àbádòfin náà jáde? Wọ́n kíyè sí i pé àwọn èèyàn sábà máa ń lọ́ tìkọ̀ láti bẹ̀bẹ̀ nígbà tí jàǹbá ọkọ̀ bá dá ọgbẹ́ síni lára tàbí tó bá sọni di aláàbọ̀ ara, nítorí ìbẹ̀rù pé ìyẹn á túmọ̀ sí gbígbà pé àwọn jẹ̀bi ọ̀ràn náà nígbà tó bá délé ẹjọ́. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn tó retí pé ó yẹ kí ẹni tó fa jàǹbá náà wá bẹ àwọn lè fa ìbínú yọ, kí jàǹbá tí kò tó nǹkan wá dá awuyewuye rẹpẹtẹ sílẹ̀.
Ká sọ tòótọ́, kò pọn dandan láti tọrọ àforíjì nítorí jàǹbá tí kì í ṣe ẹ̀bi rẹ. Àwọn ìgbà mìíràn sì wà tó jẹ́ pé ohun tó bọ́gbọ́n mu jù lọ ni pé kó o ṣọ́ra nípa ọ̀rọ̀ tó ń ti ẹnu rẹ jáde. Òwe àtijọ́ kan sọ pé: “Nínú ọ̀pọ̀ yanturu ọ̀rọ̀ kì í ṣàìsí ìrélànàkọjá, ṣùgbọ́n ẹni tí ń ṣàkóso ètè rẹ̀ ń hùwà tòyetòye.” (Òwe 10:19; 27:12) Síbẹ̀, o lè lo ìṣọ́ra kó o sì tún ṣèrànwọ́ lákòókò kan náà.
Àmọ́, ǹjẹ́ kì í ṣe òótọ́ ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni kì í tọrọ àforíjì mọ́, kódà nígbà tí ọ̀ràn náà kò bá kan ti ilé ẹjọ́? Nínú ilé, aya lè kédàárò pé, ‘Ọkọ mi ò sọ pé kí n jọ̀ọ́ máà bínú nítorí ohunkóhun rí.’ Níbi iṣẹ́, akóniṣiṣẹ́ kan lè ṣàròyé pé, ‘Àwọn tí mò ń kó ṣiṣẹ́ ò gba ẹ̀bi wọn lẹ́bi rí, agbára káká ni wọ́n sì fi lè sọ pé ẹ jọ̀wọ́, ẹ máà bínú.’ Olùkọ́ lè sọ nílé ìwé pé, ‘Àwọn òbí ò kọ́ àwọn ọmọ wọn mọ́ ní bí wọ́n ṣe máa ń tọrọ gáfárà.”
Ọ̀kan lára ìdí tẹ́nì kan fi lè máa lọ́ tìkọ̀ láti tọrọ àforíjì ni ìbẹ̀rù pé ìyẹn lè jẹ́ káwọn èèyàn fojú yẹpẹrẹ wo òun. Ìbẹ̀rù pé òun lè máà rẹ́ni ṣàánú òun tún lè mú ki onítọ̀hún máà fẹ́ fi bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára rẹ̀ hàn. Kódà, ẹni tá a ṣẹ̀ lè máà fẹ́ rí ẹni tó ṣẹ̀ ẹ́ sójú rárá, kíyẹn sì wá jẹ́ kó ṣòro gan-an láti yanjú ọ̀ràn náà.
Àìgba ti bí nǹkan ṣe rí lára àwọn ẹlòmíràn rò lè jẹ́ ìdí mìíràn táwọn kan fi ń lọ́ tìkọ̀ láti tọrọ àforíjì. Wọ́n lè ronú pé, ‘Títọrọ àforíjì kò lè yí àṣìṣe ńlá tí mo ṣe padà.’ Síbẹ̀, àwọn mìíràn máa ń lọ́ tìkọ̀ láti sọ pé ẹ jọ̀wọ́ ẹ máà bínú nítorí ohun tó ṣeé ṣe kó tẹ̀yìn rẹ̀ jáde. Ó lè máa ṣe wọ́n bíi pé, ‘Ǹjẹ́ wọn ò ní í sọ pé èmi ni mo jẹ̀bi pé kí n wá san owó gbà-máà-bínú?’ Àmọ́ o, ìgbéraga ni olórí ohun tí kì í jẹ́ káwọn èèyàn gbà pé àwọn ṣàṣìṣe. Ẹni tí ìgbéraga ò lè jẹ́ kó sọ pé “jọ̀wọ́ máà bínú” lè parí èrò sí pé, ‘Mi ò lè fi ara mi wọ́lẹ̀ nípa gbígbà pé mo ṣàṣìṣe. Ìyẹn á bu iyì mi kù láwùjọ.’
Ohun yòówù kó fà á, àwọn ọ̀rọ̀ tó jọ mọ́ títọrọ àforíjì máa ń ni ọ̀pọ̀ èèyàn lára láti sọ. Àmọ́ ṣé lóòótọ́ ni títọrọ àforíjì ṣe pàtàkì? Àwọn àǹfààní wo ló wà nínú kéèyàn tọrọ àforíjì?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
“Wọn ò kọ́ àwọn ọmọ ní bí wọ́n ṣe máa ń tọrọ gáfárà”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
“Àwọn tó ń bá mi ṣiṣẹ́ kì í gba ẹ̀bi wọn lẹ́bi”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
“Ọkọ mi ò tọrọ àforíjì rí”