Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ǹjẹ́ iyàn kíkọ́ lòdì bó tiẹ̀ jẹ́ pé owó tá a ó fi kọ́ ọ ò ju táṣẹ́rẹ́ lọ?

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí tẹ́tẹ́ títa, àmọ́ ó sọ ọ̀rọ̀ tó pọ̀ tó láti fi hàn pé gbogbo ohun tó bá jọ tẹ́tẹ́ títa ni kò bá ìlànà Bíbélì mu. a Bí àpẹẹrẹ, gbogbo èèyàn ló mọ̀ pé tẹ́tẹ́ títa máa ń jẹ́ kéèyàn ní ẹ̀mí ìwọra. Kókó yẹn nìkan tiẹ̀ ti tó ohun tó ṣe pàtàkì fáwọn Kristẹni láti gbé yẹ̀ wò, níwọ̀n bí Bíbélì ti sọ pé “àwọn oníwọra” kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run, tó sì jẹ́ pé ipò kan náà ni ojúkòkòrò àti ìbọ̀rìṣà wà.—1 Kọ́ríńtì 6:9, 10; Kólósè 3:5.

Tẹ́tẹ́ títa tún máa ń jẹ́ kéèyàn ní ẹ̀mí kò-sírú-mi àti ẹ̀mí ìdíje, ìyẹn ni fífẹ́ láti borí lọ́nàkọnà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò dára nígbà tó kọ̀wé pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a di olùgbéra-ẹni-lárugẹ, ní ríru ìdíje sókè pẹ̀lú ara wa lẹ́nì kìíní-kejì, ní ṣíṣe ìlara ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.” (Gálátíà 5:26) Síwájú sí i, tẹ́tẹ́ títa máa ń jẹ́ káwọn kan ní ìgbàgbọ́ nínú ohun asán tó ń mú kí wọ́n gbára lé oríire. Àwọn tó ń ta tẹ́tẹ́ máa ń gba gbogbo ohun asán gbọ́, pẹ̀lú ìrètí pé ìyẹn yóò jẹ́ kí oríire jẹ́ tiwọn. Wọ́n mú wa rántí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìṣòótọ́ tí wọ́n “ń tẹ́ tábìlì fún ọlọ́run Oríire, àti àwọn tí ń bu àdàlù wáìnì kún dẹ́nu fún ọlọ́run Ìpín.”—Aísáyà 65:11.

Àwọn kan lè ronú pé fífi owó kékeré kọ́ iyàn nígbà tí àwa àti àwọn ìbátan tàbí àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ bá ń ta káàdì tàbí tá a bá ń ta ayò wulẹ̀ jẹ́ eré ìdárayá lásán tí kò lè pani lára. Lóòótọ́, ẹni tó fi owó kékeré kọ́ iyàn lè máà wo ara rẹ̀ bí oníwọra, olùgbéra-ẹni-lárugẹ, olùdíje, tàbí ẹni tó nígbàgbọ́ nínú ohun asán. Síbẹ̀, ipa wo ni tẹ́tẹ́ tó ń ta náà máa ní lórí ẹni tí wọ́n jọ ń ta á? Ọ̀pọ̀ lára àwọn tí tẹ́tẹ́ títa ti di bárakú fún ló jẹ́ pé orí kíkọ́ iyàn kéékèèké ‘fún ìdárayá lásán’ ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀. (Lúùkù 16:10) Ohun tó dà bí eré aláìmọ̀kan lásánlàsàn á wá di ohun tó kó wọn sí yọ́ọ́yọ́ọ́.

Àgàgà tó bá jẹ́ pé àwọn ọmọdé ni ọ̀ràn náà kàn. Ọ̀pọ̀ ọmọdé ni jíjẹ tí wọ́n jẹ níbi tí wọ́n ti fi owó kékeré ta tẹ́tẹ́ ti sún dóríi fífi owó ńlá ta. (1 Tímótì 6:10) Ìwádìí ọlọ́jọ́ gbọọrọ tí Àjọ Tó Ń Rí sí Àwọn Tí Tẹ́tẹ́ Títa Ti Di Bárakú fún ní Arizona ń gbé jáde ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà fi hàn pé ọ̀pọ̀ lára àwọn tí tẹ́tẹ́ títa ti di bárakú fún ló jẹ́ pé láti kékeré ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ “nípa fífi owó kékeré kọ́ ìyàn lórí eré ìdárayá kan tàbí nípa títa káàdì pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn ẹbí.” Ìròyìn mìíràn sọ pé “ilé làwọn ọmọdé ti ń bẹ̀rẹ̀ tẹ́tẹ́ títa, wọ́n sábà máa ń bẹ̀rẹ̀ nípa títa káàdì pẹ̀lú àwọn ẹbí àtọ̀rẹ́ wọn.” Ìròyìn náà fi kún un pé “ìpín ọgbọ́n nínú ìpín ọgọ́rùn-ún lára àwọn ọmọdé tó ń ta tẹ́tẹ́ ló bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bẹ́ẹ̀ kí wọ́n tó pé ọmọ ọdún mọ́kànlá.” Ní ìbámu pẹ̀lú ìwádìí tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní Why Do People Gamble Too Much—Pathological and Problem Gambling, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló máa ń hu ìwà ọ̀daràn tàbí kí wọ́n ṣe ìṣekúṣe kí wọ́n lè rí owó ná sórí tẹ́tẹ́ tí wọ́n ń ta. Ẹ ò rí i pé nǹkan burúkú gbáà ló ń tẹ̀yìn ohun tó lè kọ́kọ́ dà bí èyí tí kò lè pani lára yìí jáde!

Nígbà tó jẹ pé inú ayé kan tó kún fún ọ̀pọ̀ ìdẹkùn àti ìdẹwò là ń gbé, èé ṣe tá a ó tún fi máa kóra wa sínú àwọn ìdẹkùn mìíràn? (Òwe 27:12) Tẹ́tẹ́ títa—yálà àwọn ọmọdé wà níbẹ̀ tàbí wọn ò sí níbẹ̀, yálà pẹ̀lú owó kékeré tàbí owó ńlá—jẹ́ ewu fún ipò tẹ̀mí, ó sì yẹ ká yẹra fún un. Ì bá dára káwọn Kristẹni tó máa ń fi eré ayò tàbí títa káàdì ṣe eré ìnàjú máa fi pẹ́ńsù kọ ọ́ sílẹ̀ bí wọ́n ṣe ń para wọn láyò tàbí kí wọ́n kúkú máa ṣe é fún ìnàjú lásán láìkọ iye ìgbà tí wọ́n para wọn láyò sílẹ̀. Àwọn Kristẹni tó jẹ́ ọlọgbọ́n, tí wọ́n bìkítà nípa ipò tẹ̀mí tiwọn àti ti àwọn ọ̀rẹ́ àti ìdílé wọn máa ń yẹra fún ohunkóhun tó jọ tẹ́tẹ́ títa—ì báà jẹ́ pẹ̀lú owó táṣẹ́rẹ́ pàápàá.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia túmọ̀ tẹ́tẹ́ títa sí “kíkọ́ iyàn lórí ohun tó máa jẹ́ àbájáde eré ìdárayá kan, ìṣẹ̀lẹ̀ kan, tàbí ohun tó ń wáyé láìròtẹ́lẹ̀.” Ó tún sọ síwájú sí i pé “àwọn tó ń ta tẹ́tẹ́ tàbí àwọn eléré ìdárayá sábà máa ń fi owó kọ́ iyàn lórí . . . àwọn eré ìdárayá bíi tẹ́tẹ́ oríire, káàdì títa, àti ayò.”