Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Ò Kúrò Nídìí Iṣẹ́ Tí Jèhófà Yàn fún Wa

A Ò Kúrò Nídìí Iṣẹ́ Tí Jèhófà Yàn fún Wa

Ìtàn Ìgbésí Ayé

A Ò Kúrò Nídìí Iṣẹ́ Tí Jèhófà Yàn fún Wa

GẸ́GẸ́ BÍ HERMANN BRUDER ṢE SỌ Ọ́

Wọ́n ní kí n sáà ti yan ọ̀kan nínú pé: kí n fi ọdún márùn-ún dara pọ̀ mọ́ Ẹgbẹ́ Ogun Ilẹ̀ Òkèèrè ti àwọn Faransé tàbí kí n fẹ̀wọ̀n jura nílẹ̀ Morocco. Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé ohun tó kó mi sínú ìṣòro yìí.

ÌLÚ Oppenau, ní Jámánì ni wọ́n ti bí mi ní 1911, ọdún mẹ́ta péré ṣáájú kí Ogun Àgbáyé Kìíní tó bẹ̀rẹ̀. Ọmọ mẹ́tàdínlógún làwọn òbí mi, Joseph àti Frida Bruder bí. Èmi ni wọ́n bí ṣìkẹtàlá.

Ohun tí mo kàn rántí pé ó ṣẹlẹ̀ nígbà kan tí mo ṣì wà lọ́mọdé ni pé mo rí àwọn ológun tí wọ́n ń kọrin tí wọ́n sì ń yan kiri ojú títì ìlú wa. Bí wọ́n ṣe ń yan kiri yìí wú mi lórí ni mo bá tẹ̀ lé wọn dé àgọ́ wọn, ìyẹn ni mo fi rí bàbá mi àtàwọn ọkùnrin mìíràn nínú aṣọ ológun tí wọ́n ń wọlé sínú ọkọ̀ ojú irin. Bí ọkọ̀ náà ṣe gbéra láti máa lọ báyìí, ńṣe làwọn obìnrin kan bú sẹ́kún. Kò pẹ́ sákòókò yìí ni àlùfáà ṣe ìwàásù gígùn ní ṣọ́ọ̀ṣì tó sì ka orúkọ àwọn ọkùnrin mẹ́rin tí wọ́n ti kú níbi tí wọ́n ti ń gbèjà ilẹ̀ baba wọn. Ó sọ pé: “Wọ́n ti wà lọ́run báyìí.” Ńṣe ni obìnrin kan tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi dákú gbọnrangandan.

Ibà jẹ̀funjẹ̀fun mú Bàbá níbi tó ti ń jagun ní ilẹ̀ Rọ́ṣíà. Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di ìdàkudà nígbà tó fi máa padà délé, kíá ló sì ti dèrò ilé ìwòsàn. Àlùfáà sọ fún mi pé: “Lọ sí ilé ìjọsìn kékeré tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ itẹ́ òkú kó o ka Bàbá Wa Tí Ń Bẹ Lọ́run nígbà àádọ́ta àti Ẹ Yin Màríà nígbà àádọ́ta. Tó o bá ti ṣe bẹ́ẹ̀, ara bàbá rẹ á yá.” Mo kúkú ṣe bó ṣe sọ, àmọ́ ọjọ́ kejì ni Bàbá gbẹ́mìí mì. Kódà, ọmọdé gan-an mọ̀ pé ohun burúkú gbáà ni ogun náà jẹ́.

Bí Mo Ṣe Rí Òtítọ́

Àtirí iṣẹ́ ní Jámánì kò rọrùn rárá ní gbogbo àkókò ogun náà. Àmọ́ nígbà tí mo kúrò nílé ìwé ní 1928, mo rí iṣẹ́ láti máa bojú tó ọgbà kan nílùú Basel, ní Switzerland.

Ojúlówó ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ni mí, Bàbá mi ni mo sì fi èyí jọ. Ohun tó wà lẹ́mìí mi ni láti di ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé ti Capuchin ní Íńdíà. Nígbà tí Richard àbúrò mi tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbọ́ ohun ti mò ń lépa yìí, kíá ló tẹkọ̀ létí wá sí Switzerland láti sọ fún mi pé kí n má ṣe bẹ́ẹ̀. Ó kìlọ̀ fún mi pé ó léwu púpọ̀ láti gbọ́kàn lé ọmọ èèyàn, àgàgà àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì, ó sì gbà mí níyànjú pé kí n ka Bíbélì dáadáa, pé òun nìkan sì ni kí n gbà gbọ́. Mi ò fi gbogbo ara gba ọ̀rọ̀ rẹ̀, àmọ́ mo wá Bíbélì kan tó jẹ́ kìkì Májẹ̀mú Tuntun mo sì bẹ̀rẹ̀ sí kà á. Díẹ̀díẹ̀ ojú mi bẹ̀rẹ̀ sí là, mo sì ń rí i pé ọ̀pọ̀ lára ohun tí mo gbà gbọ́ ni kò bá ẹ̀kọ́ Bíbélì mu.

Lọ́jọ́ Sunday kan ní 1933, nígbà tí mo wà nílé Richard ní Jámánì, ó mú mi mọ tọkọtaya kan tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tí wọ́n mọ̀ pé mo máa ń ka Bíbélì, wọ́n fún mi ní ẹ̀dà kan ìwé pẹlẹbẹ náà The Crisis. a Ààjìn òru ni mo tó fi ìwé náà sílẹ̀. Ó ti wá dá mi lójú báyìí pé mo ti rí òtítọ́!

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Basel fún mi ní ìdìpọ̀ méjì ìwé náà, Studies in the Scriptures* àti ìwé ìròyìn àtàwọn ìwé mìíràn. Àwọn nǹkan tí mo kà wú mi lórí gan-an, ni mo bá lọ bá àlùfáà ìjọ wa mo sì sọ fún un pé kó yọ orúkọ mi kúrò lára àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀. Ni àlùfáà bá tutọ́ sókè ló fojú gbà á tó bẹ̀rẹ̀ sí kìlọ̀ fún mi pé ìgbàgbọ́ mi ń kú lọ nìyẹn o. Àmọ́, kò rí bẹ́ẹ̀ rárá, ìgbàgbọ́ mi ò kú o. Kódà èyí nìgbà àkọ́kọ́ ti mo bẹ̀rẹ̀ sí ní ìgbàgbọ́ tòótọ́ ní ìgbésí ayé mi.

Àwọn ará ní Basel ń gbèrò láti sọdá sí ilẹ̀ Faransé lọ wàásù lópin ọ̀sẹ̀ náà. Ọ̀kan lára àwọn arákùnrin náà sì rọra ṣàlàyé fún mi pé mi ò ní lè bá wọn lọ nítorí pé mo ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí dara pọ̀ ni. Èyí ò kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi rárá, ńṣe ni mo sọ fún un pé ohun tó wà lórí ẹ̀mí mi ni pé kí n bẹ̀rẹ̀ sí wàásù. Lẹ́yìn tí arákùnrin yìí fọ̀rọ̀ náà tó alàgbà mìíràn létí, ó yan ìpínlẹ̀ kan fún mi ní Switzerland. Ilẹ̀ mọ́ tàìmọ́ lọ́jọ́ Sunday, mo ti gbé kẹ̀kẹ́ mi ó di abúlé kékeré kan nítòsí Basel. Mo kó ìwé ńlá mẹ́rin, ìwé ìròyìn méjìdínlọ́gbọ̀n àti ìwé pẹlẹbẹ ogún sínú àpò mi. Ṣọ́ọ̀ṣì ni ọ̀pọ̀ àwọn ará abúlé náà wà nígbà tí mo débẹ̀. Pẹ̀lú ìyẹn náà, gbogbo ìwé inú àpò mi ti tán nígbà tó fi máa di aago mọ́kànlá.

Nígbà tí mo sọ fáwọn arákùnrin náà pé mo fẹ́ ṣèrìbọmi, wọ́n bá mi sọ ojúlówó ọ̀rọ̀ wọ́n sì bi mí láwọn ìbéèrè tó gba àròjinlẹ̀ nípa òtítọ́. Ìtara àti ìdúróṣinṣin táwọn arákùnrin yìí ní sí Jèhófà àti ètò àjọ rẹ̀ wú mi lórí gan-an. Àkókò òtútù lákòókò náà, arákùnrin kan sì ṣèrìbọmi fún mi nínú ọpọ́n ìwẹ̀ tó wà nílé alàgbà kan. Mo rántí pé ayọ̀ mi ò ṣeé fẹnu sọ okun inú mi sì wá pọ̀ sí i. Gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ ní 1934.

Mo Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ ní Oko Society ní Switzerland

Ní 1936, mo gbọ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ra ilẹ̀ kan ní Switzerland. Mo yọ̀ǹda ara mi láti lọ ṣiṣẹ́ níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùtọ́jú ọgbà. Inú mi dùn gan-an pé wọ́n ké sí mi láti wá máa ṣiṣẹ́ ní Oko Society tó wà ní Steffisburg, nǹkan bí ọgbọ̀n kìlómítà sílùú Bern. Nígbà tó bá ṣeé ṣe, mo tún máa ń bá àwọn mìíràn ṣe iṣẹ́ wọn nínú oko yìí. Bẹ́tẹ́lì jẹ́ kí n mọ bó ti ṣe pàtàkì tó láti ní ẹ̀mí ìfọwọ́sowọ́pọ̀.

Àkókò tí mo gbádùn jù lọ nínú gbogbo ọdún tí mo lò ní Bẹ́tẹ́lì ni ìgbà tí Arákùnrin Rutherford wá bẹ̀ wá wò ní oko yìí lọ́dún 1936. Nígbà tó rí báwọn tòmátì wa ṣe tóbi kòǹgbà-kòǹgbà, ńṣe ló rẹ́rìn-ín músẹ́ tó sì kan sáárá sí wa. Káàsà, arákùnrin yìí mà ṣèèyàn o!

Bó ṣe lé díẹ̀ lọ́dún mẹ́ta tí mo ti ń sìn nínú oko yìí ni wọ́n ka lẹ́tà kan tó wá láti orílé-iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, oúnjẹ àárọ̀ là ń jẹ lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n kà á. Lẹ́tà náà sọ bí iṣẹ́ ìwàásù náà ṣe jẹ́ kánjúkánjú tó, ó sì rọ ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ láti sìn bí aṣáájú ọ̀nà ní ilẹ̀ òkèèrè láti ṣe bẹ́ẹ̀. Kíá ni mo yọ̀ǹda ara mi. Oṣù May 1939 ni wọ́n yan ibi tí màá ti sìn fún mi, ìyẹn ní orílẹ̀-èdè Brazil!

Nígbà tá a ń wí yìí, Ìjọ Thun ni mo wà, kò sì jìnnà sí Oko Society tí mo ti ń ṣiṣẹ́. Láwọn ọjọ́ Sunday, àwùjọ kan lára wa máa ń lọ wàásù láwọn òkè Alps tó ga fíofío, wákàtí méjì la máa fi gun kẹ̀kẹ́ débẹ̀ láti Thun. Margaritha Steiner wà lára àwùjọ yìí. Èrò kan kàn ṣàdédé sọ sí mi lọ́kàn ni pé: Ṣebí méjìméjì ni Jésù rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jáde? Mo fi tó Margaritha létí lọ́jọ́ kan pé wọ́n ti rán mi lọ sí Brazil, òun náà sì sọ pé ó wu òun láti lọ sìn níbi tí àìní bá gbé pọ̀. Bá a ṣe fẹ́ra wa nìyẹn ní July 31, 1939.

A Dúró Níbi Tá Ò Rò Tẹ́lẹ̀

A wọkọ̀ ojú omi láti Le Havre, ní ilẹ̀ Faransé lópin oṣù August 1939, a sì kọrí sọ́nà ìlú Santos, ní Brazil. Àwọn èèyàn ti wà ní gbogbo yàrá ẹlẹ́ni méjì tó wà nínú ọkọ̀ ojú omi náà, èyí ló mú ká wà ní yàrá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ọ̀nà ni ìròyìn ti kàn wá lára pé Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti ilẹ̀ Faransé ti bẹ̀rẹ̀ sí bá ilẹ̀ Jámánì jagun. Bí ọgbọ̀n lára àwọn èrò ọ̀kọ̀, tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Jámánì, kàn ṣe bẹ̀rẹ̀ sí kọ orin orílẹ̀-èdè Jámánì nìyẹn. Èyí múnú bí awakọ̀ òkun náà, ó sì yà bàrà ó forí lé Safi ní Morocco. Wọ́n fún gbogbo èrò inú ọkọ̀ náà tó jẹ́ pé ìwé ìrìnnà ilẹ̀ Jámánì ló wà lọ́wọ́ wọn ní ìṣẹ́jú márùn-ún péré láti jáde nínú ọkọ̀ náà. A wà lára àwọn wọ̀nyí.

A lo ọjọ́ kan gbáko ní àgọ́ ọlọ́pàá, lẹ́yìn náà ni wọ́n há gbogbo wa mọ́nú ọkọ̀ hẹ́gẹhẹ̀gẹ kan wọ́n sì kó wa lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Marrakech, nǹkan bí ogóje kìlómítà síbi tá a wà. A jẹ dẹndẹ ìyà fúngbà pípẹ́ lẹ́yìn náà. Èèyàn ti pọ̀ jù nínú yàrá tí wọ́n há wa mọ́ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ibẹ̀ sì dúdú kirikiri. Ihò tí wọ́n gbẹ́ sílẹ̀ ni ilé ìyàgbẹ́ tí gbogbo wa ń lò, àtìgbàdégbà ló sì máa ń dí. Wọ́n fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ní àpò ṣakaṣaka tó ti dọ̀tí láti tẹ́ sùn, àwọn èkúté sì máa ń jẹ ẹsẹ̀ wa lórú. Oúnjẹ ẹ̀ẹ̀mejì péré là ń jẹ lójúmọ́, agolo tó ti dípẹtà ni wọ́n sì ń bu oúnjẹ ọ̀hún sí fún wa.

Ọ̀gá sójà kan sọ fún mi pé wọ́n á dá mi sílẹ̀ bí mo bá gbà láti fi ọdún márùn-ún dara pọ̀ mọ́ Ẹgbẹ́ Ogun Ilẹ̀ Òkèèrè tàwọn Faransé. Mo kọ̀, àmọ́ kíkọ̀ mi fi ìyà odidi ọjọ́ kan gbáko jẹ mí nínú àjà ilẹ̀ tó ṣókùnkùn biribiri. Àdúrà ni mo fi èyí tó pọ̀ jù lọ lára àkókò yìí gbà.

Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́jọ, àwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà fún mi láyè láti rí Margaritha. Ó ti rù hangogo, bẹ́ẹ̀ ló ń sunkún pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀. Mo fún un ní gbogbo ìṣírí tí mo lè fún un. Wọ́n fọ̀rọ̀ wá wa lẹ́nu wò wọ́n sì fi ọkọ̀ ojú irin kó wa lọ sí Casablanca, ibẹ̀ ni wọ́n ti dá Margaritha sílẹ̀. Wọ́n lọ sọ èmi sí ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà ní Port Lyautey (tí wọ́n ń pè ní Kenitra báyìí), nǹkan bí ọgọ́sàn-án kìlómítà nibẹ̀. Aṣojú ìjọba ilẹ̀ Switzerland tó wà níbẹ̀ sọ fún Margaritha pé kó padà sí Switzerland, àmọ́ ó fàáké kọ́rí pé òun ò ní fi mí sílẹ̀ o. Ní gbogbo oṣù méjì tí mo lò ní Port Lyautey, ojoojúmọ́ ló ń ti Casablanca wá wò mí tó sì ń gbé oúnjẹ wá fún mi.

Ní ọdún kan ṣáájú àkókò yìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti tẹ ìwé kan jáde tá a pè ní Kreuzzug gegen das Christentum (Ogun Lòdì sí Ẹ̀sìn Kristẹni), láti mú kí gbogbo èèyàn mọ̀ pé kò sóhunkóhun tó pa àwa Ẹlẹ́rìí àti ìjọba Násì pọ̀. Nígbà tí mo wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Bern kọ̀wé sáwọn aláṣẹ ilẹ̀ Faransé, wọ́n sì fi ẹ̀dà kan ìwé náà ránṣẹ́ sí wọn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé kò sóhun tó kàn wá kan ìjọba Násì. Margaritha náà ṣe bẹbẹ. Bó ṣe ń lọ sọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ tibí ló ń lọ sí ti tọ̀hún láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ọwọ́ wa mọ́. Níparí ọdún 1939, wọ́n gbà ká kúrò ní Morocco.

A tún ti forí lé Brazil lẹ́ẹ̀kejì kí ìròyìn tó tún kàn wá lára pé àwọn ọkọ̀ abẹ́ omi ilẹ̀ Jámánì ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣọṣẹ́ fáwọn ọkọ̀ ojú omi ní òkun Àtìláńtíìkì, pé àwa gan-an ni wọ́n sì ń wá lójú méjèèjì. Ọkọ̀ òkun àwọn oníṣòwò tí ń jẹ́ Jamaique la wọ̀, síbẹ̀ ó ní ìbọn lóríṣiríṣi níwájú àti lẹ́yìn. Ńṣe ni awakọ̀ yìí ń pẹ́kọrọ lọ́tùn-ún lósì tó bá ń wakọ̀ lọ lọ́sàn-án, yóò sì máa yin àdó olóró lóòrèkóòrè. A kì í tan iná lóru kí àwọn ará Jámánì má bàa rí wa. Ọkàn wa balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn nígbà tá a gúnlẹ̀ sí Santos, ní Brazil ní February 6, 1940, lẹ́yìn odidi oṣù márùn-ún tá a ti kúrò nílẹ̀ Yúróòpù!

A Tún Dèrò Ọgbà Ẹ̀wọ̀n

Ìlú Montenegro tó wà ní ìpínlẹ̀ Rio Grande do Sul, ní gúúsù Brazil, ni wọ́n kọ́kọ́ yàn fún wa láti lọ wàásù. Ẹ̀rí fi hàn pé àwọn kan ti ta àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì lólobó pé a ti wọ̀lú. Èyí tá a fi wàásù ò tíì ju wákàtí méjì péré lọ, táwọn ọlọ́pàá fi rá wa mú tí wọ́n sì gba gbogbo rẹ́kọ́ọ̀dù ẹ̀rọ giramafóònù wa tí àsọyé Bíbélì wà nínú rẹ̀, wọ́n gba gbogbo ìwé wa títí kan àpò tí wọ́n fi awọ ràkúnmí ṣe tá a rà ní Morocco. Àlùfáà kan àti òjíṣẹ́ kan tó gbọ́ èdè Jámánì ti wà níkàlẹ̀ dè wá lágọ̀ọ́ ọlọ́pàá. Wọ́n tẹ́tí sílẹ̀ bí ọ̀gá ọlọ́pàá ṣe gbé ọ̀kan lára àwọn rẹ́kọ́ọ̀dù àsọyé Arákùnrin Rutherford sí i, lára èyí tó gbà lọ́wọ́ wa ni o. Arákùnrin Rutherford ní tiẹ̀ ò kúkú pẹ́ ọ̀rọ̀ sọ, ńṣe ló ń là á mọ́lẹ̀ bó ṣe rí! Bó ṣe sọ̀rọ̀ débi Ìjọba Póòpù báyìí, inú àlùfáà yìí ru ṣùṣù ó sì fìbínú jáde lọ.

Bíṣọ́ọ̀bù Santa Maria sọ pé káwọn ọlọ́pàá kó wa lọ sí olú ìlú ìpínlẹ̀ náà, Pôrto Alegre, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀. Kò pẹ́ lẹ́yìn èyí ni wọ́n fi Margaritha sílẹ̀, ó sì lọ bá àwọn aṣojú ìjọba Switzerland tó wà ní orílẹ̀-èdè náà láti ràn wá lọ́wọ́. Wọ́n sọ fún un pé ńṣe ni kó padà sí Switzerland. Àmọ́ ó tún sọ pé òun ò lè fi mí sílẹ̀. Alábàákẹ́gbẹ́ tó ní ẹ̀mí àrótì ni Margaritha jẹ́. Nígbà tó di oṣù kan lẹ́yìn èyí, wọ́n fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò wọ́n sì fi mí sílẹ̀. Àwọn ọlọ́pàá sọ ohun méjì fún wa pé ká yan ọ̀kan nínú rẹ̀: ẹ káńgárá yín kúrò lórílẹ̀-èdè yìí láàárín ọjọ́ mẹ́wàá péré tàbí kẹ́ ẹ “fara mọ́ ohun tójú yín bá rí.” Ni orílé-iṣẹ́ wa bá dámọ̀ràn pé ká kúkú máa lọ sílùú Rio de Janeiro, a sì lọ.

“Jọ̀wọ́ Ka Káàdì Yìí”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tá a kọ́kọ́ bá pàdé nílẹ̀ Brazil yìí ò bọ́ sí i, inú wa ṣì dùn! Ó ṣe kò ṣe, a ṣì wà láàyè, ìwé kúnnú àpò wa bámúbámú, a sì lè wàásù ní gbogbo ìlú Rio de Janeiro. Àmọ́ báwo la tiẹ̀ ṣe máa wàásù ọ̀hún nígbà tó jẹ́ pé tátàtá la gbọ́ nínú èdè Potogí? Káàdì ìjẹ́rìí là ń lò. Ọ̀rọ̀ tá a kọ́kọ́ kọ́ láti fi wàásù ní èdè Potogí ni “Por favor, leia este cartão” (“Jọ̀wọ́ ka káàdì yìí”). Àṣeyọrí ńláǹlà la fi káàdì yìí ṣe o! Láàárín oṣù kan péré, iye ìwé tá a fi sóde lé ní ẹgbẹ̀rún kan. Ọ̀pọ̀ àwọn tó gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ wa tẹ́wọ́ gba òtítọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Ká sòótọ́, àwọn ìwé wa jẹ́rìí lọ́nà tó gbéṣẹ́ ju bí àwa fúnra wa ò bá ti ṣe lọ. Èyí túbọ̀ tẹ ìjẹ́pàtàkì pé ká máa fún àwọn tó bá fìfẹ́ hàn láwọn ìtẹ̀jáde wa mọ́ mi lọ́kàn.

Ìlú Rio de Janeiro ni olú ìlú orílẹ̀-èdè Brazil nígbà tá à ń sọ yìí, wọ́n sì máa ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wa dáadáa láwọn ilé ìjọba. Mo láǹfààní láti wàásù fún mínísítà ètò ìnáwó àti tàwọn ológun pẹ̀lú. Mo rí ẹ̀rí tó dájú nípa bí ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ṣe ń ṣiṣẹ́ láwọn àkókò yìí.

Lọ́jọ́ kan, à ń wàásù láàárín ìgboro Rio, ni mo bá wọnú ilé Gbọ̀ngàn Ìdájọ́. Mo kàn ṣàdédé bá ara mi nínú yàrá kan tí mo ti já sáàárín àwọn èèyàn aláṣọ dúdú kan, tó dà bíi pé wọ́n ń bá ètò ìsìnkú lọ lọ́wọ́. Mo sún mọ́ ọ̀gbẹ́ni kan tó jókòó bí ọlọ́lá níbẹ̀ mo sì fún un ní káàdì ìjẹ́rìí. Òkú kọ́ làwọn aráabí yìí ń ṣe o. Àṣé kóòtù tí wọ́n ti ń dájọ́ lọ́wọ́ ni mo wọ̀ wẹ́rẹ́ yẹn, adájọ́ sì lẹni tí mo ń bá sọ̀rọ̀. Ńṣe ló bú sẹ́rìn-ín tó sì juwọ́ sáwọn ẹ̀ṣọ́ pé kí wọ́n má ṣèyọnu. Tayọ̀tayọ̀ ló fi gba ẹ̀dà kan ìwé Children b, ó sì ṣe ìtọrẹ. Bí mo ṣe ń jáde ni ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ṣọ́ náà fi ọ̀rọ̀ gàdàgbà gadagba tí wọ́n kọ sára ilẹ̀kùn hàn mí, ó kà pé: Proibida a entrada de pessoas estranhas, (Ẹni Tá Ò Bá fún Láṣẹ Ò Gbọ́dọ̀ Wọlé).

Ibòmíràn tó tún méso jáde ni èbúté tó wà ní ìlú náà. Nígbà kan, mo pàdé ọ̀gbẹ́ni kan tó ń wakọ̀ ojú omi, ó gba ìtẹ̀jáde kan lọ́wọ́ mi kó tó padà ṣíkọ̀ gba ojú òkun lọ. Nígbà tó yá, a pàdé ọ̀gbẹ́ni yìí ni àpéjọ kan. Gbogbo ìdílé rẹ̀ ti rí òtítọ́, òun fúnra rẹ̀ sì ń tẹ̀ síwájú dáadáa. Èyí mú kí inú wa dùn gan-an.

Àmọ́ o, kì í ṣe pé gbogbo nǹkan kàn ń lọ ní gbẹdẹmukẹ bẹ́ẹ̀ o. Ìwé àṣẹ ìwọ̀lú olóṣù mẹ́fà ni wọ́n fún wa, oṣù mẹ́fà ọ̀hún sì ti pé, ó di pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n lé wa padà sílé. Lẹ́yìn tá a kọ lẹ́tà nípa bọ́ràn ṣe rí sí orílé-iṣẹ́, èsì tó ń tuni lára la rí gbà látọ̀dọ̀ Arákùnrin Rutherford, ó sọ pé ká má rẹ̀wẹ̀sì ó sì ṣàlàyé ohun tó yẹ ní ṣíṣe fún wa. Ohun tá a fẹ́ ni pé ká wà ní ilẹ̀ Brazil, a sì rí lọ́yà kan tó ràn wá lọ́wọ́ tá a fi rí ìwé àṣẹ tá a lè fi máa gbébẹ̀ gbà ní 1945.

Iṣẹ́ Ọlọ́jọ́ Pípẹ́ Tá A Gbà

Àmọ́ ṣáájú àkókò yìí, a ti bí Jonathan, ọmọ wa ọkùnrin ní 1941, a bí Ruth ní 1943, a sì bí Esther ní 1945. Ó di dandan kí n bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ láti lè gbọ́ bùkátà ìdílé. Margaritha ní tiẹ̀ ń bá iṣẹ́ ìwàásù alákòókò kíkún lọ títí tó fi bi ọmọ wa kẹta.

Látìbẹ̀rẹ̀ ni gbogbo ìdílé wa ti máa ń wàásù pa pọ̀ láàárín ìlú, ní ibùdókọ̀ ọkọ̀ ojú irin, lójú pópó àti láwọn àgbègbè okòwò. Gbogbo ìdílé wa máa ń pín Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ní alaalẹ́ Sátidé, a sì máa ń gbádùn rẹ̀ gan-an.

Nínú ilé, ọmọ kọ̀ọ̀kan ní iṣẹ́ tó máa ṣe lójúmọ́. Jonathan ló máa ń nu sítóòfù tó sì máa ń tọ́jú ilé ìdáná. Àwọn ọmọbìnrin ní tiwọn máa ń nu fìríìjì, wọ́n á gbá gbogbo àgbàlá, wọ́n á sì nu bàtà wa. Èyí kọ́ wọ́n ní béèyàn ṣe ń wà létòlétò ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ béèyàn ṣe ń dánú ṣe nǹkan. Òṣìṣẹ́ alákíkanjú làwọn ọmọ wa lónìí, wọ́n ń bójú tó ilé wọn àtohun ìní wọn dáadáa, èyí sì ń múnú èmi àti Margaritha dùn.

A tún máa ń fẹ́ káwọn ọmọ náà ṣe dáadáa nínú ìpàdé. Kí ìpàdé bẹ̀rẹ̀, wọ́n á mu ife omi kan wọ́n á sì lọ tura nílé ìgbọ̀nsẹ̀. Tí ìpàdé bá bẹ̀rẹ̀, ọwọ́ òsì mi ni Jonathan máa ń jókòó, Ruth á jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún, Margaritha á jókòó tẹ̀ lé e, Esther á sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀. Èyí ń mú kí wọ́n lè pọkàn pọ̀ kí wọ́n sì gba oúnjẹ tẹ̀mí sínú látìgbà ọmọdé wọn.

Jèhófà ò ṣàì bù kún gbogbo ìsapá wa. Gbogbo àwọn ọmọ wa ló ń fi òótọ́ inú sin Jèhófà tí wọ́n sì ń fi tayọ̀tayọ̀ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù. Alàgbà ni Jonathan ní bá a ṣe ń wí yìí nínú Ìjọ Novo Méier, ní Rio de Janeiro.

Nígbà tó fi máa di 1970, gbogbo àwọn ọmọ wa ti ṣègbéyàwó wọ́n sì ti kúrò nílé, lèmi àti Margaritha bá pinnu láti ṣí lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀. Ìlú Poços de Caldas tó wà ní ìpínlẹ̀ Minas Gerais, la kọ́kọ́ lọ. Akéde Ìjọba mọ́kàndínlógún ló wà níbẹ̀ lákòókò náà. Inú mi bà jẹ́ nígbà tí mo kọ́kọ́ rí ibi tí wọ́n ti ń ṣèpàdé, ìyẹn iyàrá àjà ilẹ̀ kan báyìí tí ò ní fèrèsé tó sì nílò àtúnṣe púpọ̀. Kíá la bẹ̀rẹ̀ sí wá Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wuyì kiri, kò sì pẹ́ tá a fi rí ilé dáradára kan tó wà níbi tó dáa. Bí gbogbo nǹkan ṣe yí padà nìyẹn o! Ọdún mẹ́rin àbọ̀ lẹ́yìn náà, àwọn akéde ti pọ̀ sí i, iye wọ́n ti di márùndínlọ́gọ́jọ [155]. Ní 1989, a ṣí lọ sílùú Araruama ní ìpínlẹ̀ Rio de Janeiro, a sìn níbẹ̀ fún odidi ọdún mẹ́sàn-án. Ìjọ tuntun méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n dá sílẹ̀ níṣojú wa láàárín àkókò yìí.

A Jèrè Kíkúrò Tá Ò Kúrò Nídìí Iṣẹ́ Tá A Gbà

Ní 1998, ara tó ti ń di kẹ́gẹkẹ̀gẹ àti bó ṣe wù wá láti wà nítòsí àwọn ọmọ wa mú ká ṣí lọ sílùú São Gonçalo, ní Rio de Janeiro. Mo ṣì ń sìn bí alàgbà níbẹ̀. A ń sa gbogbo ipá wa láti máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù déédéé. Margaritha fẹ́ràn wíwàásù fáwọn èèyàn ní ilé ìtajà kan tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé wa, ìjọ wa sì ya àwọn ìpínlẹ̀ kan nítòsí ilé wa sọ́tọ̀ fún wa. Èyí jẹ́ kó rọrùn fún wa láti lè máa wàásù bí ìlera wa bá ṣe gbé e tó.

Ó ti lé ní ọgọ́ta ọdún báyìí tí èmi àti Margaritha ti di ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́. A ti fúnra wa rí i pé ‘kì í ṣe ìjọba tàbí àwọn ohun tí ó wà níhìn-ín nísinsìnyí tàbí àwọn ohun tí ń bọ̀ tàbí àwọn agbára tàbí ibi gíga tàbí ibi jíjìn tàbí ìṣẹ̀dá èyíkéyìí mìíràn ni yóò lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó wà nínú Kristi Jésù Olúwa wa.’ (Róòmù 8:38, 39) Ohun ayọ̀ gbáà ló sì jẹ́ láti rí bá a ṣe ń kó àwọn “àgùntàn mìíràn” jọ, ìyẹn àwọn tí wọ́n ní ìrètí àgbàyanu ti ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé pípé, tí wọn yóò máa gbé láàárín àwọn ohun rírẹwà tí Ọlọ́run dá! (Jòhánù 10:16) Ìjọ kan péré ló wà ní Rio de Janeiro nígbà tá a débẹ̀ ní 1940, akéde méjìdínlọ́gbọ̀n ló sì wà níbẹ̀. Àmọ́ lónìí, nǹkan bí igba ó lé àádọ́ta ìjọ ló wà níbẹ̀, àwọn akéde Ìjọba ibẹ̀ sì lé ní ọ̀kẹ́ kan.

Àwọn àkókò kan wà tá á dà bíi pé ká padà lọ bá àwọn èèyàn wa ní ilẹ̀ Yúróòpù. Àmọ́ Brazil níhìn-ín ni Jèhófà ti yanṣẹ́ fún wa. Inú wa sì dùn púpọ̀ pé a ò fiṣẹ́ náà sílẹ̀!

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ àmọ́ a ò tẹ̀ ẹ́ jáde mọ́.

b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́, àmọ́ a ò tẹ̀ ẹ́ jáde mọ́.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Ìgbà tí mo wà ní Oko Society nílùú Steffisburg, ní Switzerland, lópin àwọn ọdún 1930 (èmi ni mo kángun sápá òsì)

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Nígbà tó kù díẹ̀ ká ṣègbéyàwó ní 1939

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ìlú Casablanca láwọn ọdún 1940

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Gbogbo ìdílé wa ń wàásù

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

À ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ déédéé lónìí