Gbogbo Wa La Máa Ń Fẹ́ Ká Gbóríyìn fún Wa
Gbogbo Wa La Máa Ń Fẹ́ Ká Gbóríyìn fún Wa
ỌJỌ́ tó dáa gan-an ni ọjọ́ yẹn jẹ́ fún ọmọbìnrin kékeré náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń ṣe àwọn nǹkan tí wọ́n fi máa ń bá a wí láwọn ìgbà mìíràn, àmọ́ ó dìídì hùwà ọmọlúàbí lọ́jọ́ tá à ń wí yìí. Ṣùgbọ́n nígbà tó di alẹ́ ọjọ́ náà, lẹ́yìn tí wọ́n tẹ́ ọmọdébìnrin náà sórí ibùsùn, ìyá rẹ gbọ́ ẹkún rẹ̀. Nígbà tó béèrè ohun tó ń pa á nígbe, pẹ̀lú omijé lójú ló fi sọ pé: “Ṣé mi ò ṣe dáadáa lónìí ni?”
Ìbéèrè yẹn ba ìyá rẹ̀ nínú jẹ́ gan-an ni. Gbogbo ìgbà ló máa ń yára bá ọmọ rẹ̀ wí nígbà tó bá ṣe àṣìṣe. Àmọ́ lọ́jọ́ tá à ń wí yìí, pẹ̀lú gbogbo bí ìyá yìí ṣe kíyè sí i pé ọmọdébìnrin òun sá gbogbo ipá rẹ̀ láti hùwà ọmọlúàbí tó, kò tiẹ̀ sọ ọ̀rọ̀ kan láti fi hàn pé òun mọrírì ohun tí ọmọ náà ṣe.
Kì í ṣe àwọn ọmọdé nìkan ló fẹ́ ká gbóríyìn fáwọn ká sì fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀. Gbogbo wa la fẹ́ bẹ́ẹ̀—gẹ́gẹ́ bá a ṣe fẹ́ ìmọ̀ràn àti ìbáwí.
Báwo ló ṣe máa ń rí lára wa nígbà tí wọ́n bá gbóríyìn fún wa látọkànwá? Ǹjẹ́ kì í múnú wa dùn tí ara wa sì máa ń yá gágá? Ó ń jẹ́ ká mọ̀ pé ẹnì kan kíyè sí ohun tá a ṣe, ìyẹn ni pé ẹnì kan bìkítà nípa wa. Ó fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé ohun tó yẹ ká ṣe gan-an la ṣe, á sì jẹ́ ká túbọ̀ ṣe sí i lọ́jọ́ iwájú. Kò yani lẹ́nu pé gbígbóríyìn fúnni látọkànwá sábà máa ń múni sún mọ́ ẹni tó wá àkókò láti sọ ohun kan tó ń fúnni níṣìírí ọ̀hún.—Òwe 15:23.
Jésù Kristi mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì láti gbóríyìn fúnni. Nínú àkàwé tálẹ́ńtì, ọ̀gá náà (tó jẹ́ Jésù fúnra rẹ̀) fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà gbóríyìn fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹrú méjèèjì tó jẹ́ olóòótọ́, nípa sísọ pé: “O káre láé, ẹrú rere àti olùṣòtítọ́!” Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ yẹn múni lọ́kàn yọ̀ gan-an! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò lágbára bákan náà, èrè tí wọ́n jẹ sì yàtọ̀ síra, síbẹ̀ oríyìn kan náà ni wọ́n gbà.—Mátíù 25:19-23.
Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa rántí ìyá ọmọbìnrin kékeré yẹn. A ò ní láti dúró dìgbà táwọn èèyàn bá bú sẹ́kún ká tó gbóríyìn fún wọn. Dípò ìyẹn, a lè bẹ̀rẹ̀ sí fojú sílẹ̀ dáadáa ká máa wá àǹfààní tá a fi lè gbóríyìn fúnni. Láìṣe àní-àní, a nídìí gúnmọ́ láti gbóríyìn fúnni látọkànwá ní gbogbo ìgbà tí àyè rẹ̀ bá yọ.