Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Títọrọ Àforíjì Ọ̀nà Tó Gbéṣẹ́ Jù Lọ Láti Wá Àlàáfíà

Títọrọ Àforíjì Ọ̀nà Tó Gbéṣẹ́ Jù Lọ Láti Wá Àlàáfíà

Títọrọ Àforíjì Ọ̀nà Tó Gbéṣẹ́ Jù Lọ Láti Wá Àlàáfíà

“TÍTỌRỌ àforíjì lágbára púpọ̀. Ó lè yanjú ìforígbárí láìsí ìwà ipá, ó lè ṣàtúnṣe ìyapa láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, ó lè jẹ́ kí àwọn tó ń ṣèjọba mọ ìyà tó ń jẹ àwọn aráàlú wọn, ó sì lè fi àjọṣe tó dáa sáàárín àwọn èèyàn.” Ohun tí Deborah Tannen kọ nìyẹn, ẹni tó jẹ́ òǹkọ̀wé tí ìwé rẹ̀ tà jù lọ àti ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ èdè ní Yunifásítì Georgetown ní Washington, D.C.

Bíbélì jẹ́rìí sí i pé títọrọ àforíjì látọkànwá sábà máa ń jẹ́ ọ̀nà tó gbéṣẹ́ jù lọ láti tún àjọṣe tó ti bà jẹ́ ṣe. Bí àpẹẹrẹ, nínú òwe Jésù nípa ọmọ onínàákúnàá, nígbà tí ọmọ náà padà sílé tó wá tọrọ àforíjì, baba rẹ̀ ò lọ́ tìkọ̀ rárá láti gbà á padà sínú agbo ilé rẹ̀. (Lúùkù 15:17-24) Bẹ́ẹ̀ ni o, èèyàn ò gbọ́dọ̀ gbéra ga débi tí kò fi ní lè rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, kí ó bẹ̀bẹ̀, kó sì tọrọ àforíjì. Ká sòótọ́, títọrọ àforíjì kì í ṣe ohun tó ṣòro rárá fún àwọn onírẹ̀lẹ̀ ènìyàn.

Agbára Tí Títọrọ Àforíjì Ní

Ábígẹ́lì, obìnrin kan tó jẹ́ ọlọgbọ́n ní Ísírẹ́lì ìgbàanì hùwà lọ́nà tó jẹ́ ká rí bí títọrọ àforíjì ṣe lágbára tó, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkọ rẹ̀ ló dá ẹ̀ṣẹ̀ tó ń tìtorí rẹ̀ tọrọ àforíjì. Nígbà tí Dáfídì tó wá di ọba Ísírẹ́lì níkẹyìn àtàwọn ọkùnrin rẹ̀ ń gbé nínú aginjù, wọ́n dáàbò bo agbo ẹran Nábálì tó jẹ́ ọkọ Ábígẹ́lì. Àmọ́, nígbà táwọn ọkùnrin Dáfídì tọrọ búrẹ́dì àti omi lọ́dọ̀ Nábálì, ńṣe lo lé wọn dà nù tó sì sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sí wọn. Bí inú ṣe bí Dáfídì nìyẹn, ló bá kó irínwó ọkùnrin sòdí láti lọ bá Nábálì àti agbo ilé rẹ̀ jà. Bí Ábígẹ́lì ṣe gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ ló gbéra tó lọ pàdé Dáfídì. Nígbà tó rí i, ó dojú bolẹ̀ níwájú rẹ̀. Ó sì sọ pé: “Ìwọ olúwa mi, kí ìṣìnà náà wà lórí èmi gan-an; jọ̀wọ́, sì jẹ́ kí ẹrúbìnrin rẹ sọ̀rọ̀ ní etí rẹ, sì fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ ẹrúbìnrin rẹ.” Ábígẹ́lì wá ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí, ó sì fún Dáfídì ní ẹ̀bùn oúnjẹ àti ohun mímu. Nígbà náà ni Dáfídì wá sọ pé: “Gòkè lọ sí ilé rẹ ní àlàáfíà. Wò ó, mo ti fetí sí ohùn rẹ, kí n lè ní ìgbatẹnirò fún ìwọ fúnra rẹ.”—1 Sámúẹ́lì 25:2-35.

Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ Ábígẹ́lì àti àwọn ọ̀rọ̀ tó fi tọrọ ìdáríjì nítorí ìwà aláìlọ́wọ̀ tí ọkọ rẹ̀ hù ló gba agbo ilé rẹ̀ là. Kódà, Dáfídì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ pé kò jẹ́ kí òun wọnú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe Ábígẹ́lì ló ṣe ohun tí kò dára sí Dáfídì àtàwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀, síbẹ̀ ó gbà pé ìdílé òun ló jẹ̀bi ọ̀ràn náà, ó sì wá àlàáfíà pẹ̀lú Dáfídì.

Àpẹẹrẹ ẹlòmíràn tó mọ àkókò tó yẹ láti tọrọ àforíjì ni ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ìgbà kan wà tó ní láti gbèjà ara rẹ̀ níwájú Sànhẹ́dírìn, ìyẹn kóòtù gíga ti àwọn Júù. Nítorí pé òtítọ́ ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ bí Ananíà àlùfáà àgbà nínú, ó pàṣẹ pé kí àwọn tó wà nítòsí gbá Pọ́ọ̀lù lẹ́nu. Ìyẹn ló mú kí Pọ́ọ̀lù sọ fún un pé: “Ọlọ́run yóò gbá ọ, ìwọ ògiri tí a kùn lẹ́fun. Ìwọ ha jókòó láti ṣèdájọ́ mi ní ìbámu pẹ̀lú Òfin, ní àkókò kan náà, ní ríré Òfin kọjá, ìwọ sì pàṣẹ pé kí a gbá mi?” Nígbà táwọn tó ń wòran bá Pọ́ọ̀lù wí pé ó ń kẹ́gàn àlùfáà àgbà, ojú ẹsẹ̀ ni àpọ́sítélì náà gba ẹ̀bi rẹ̀ lẹ́bi, tó sọ pé: “Ẹ̀yin ará, èmi kò mọ̀ pé àlùfáà àgbà ni. Nítorí a kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ olùṣàkóso àwọn ènìyàn rẹ lọ́nà ìbàjẹ́.’”—Ìṣe 23:1-5.

Òótọ́ pọ́ńbélé ni ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ—pé ẹni tá a bá yàn gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́ kò gbọ́dọ̀ hùwà ipá. Síbẹ̀, ó tọrọ àforíjì fún sísọ̀rọ̀ sí àlùfáà àgbà lọ́nà tá a lè wò bí èyí tí kò fi ọ̀wọ̀ hàn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò mọ̀ọ́mọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀. a Ẹ̀bẹ̀ tí Pọ́ọ̀lù bẹ̀ ló jẹ́ kí Sànhẹ́dírìn fetí sí ohun tó fẹ́ sọ. Nítorí pé Pọ́ọ̀lù mọ̀ nípa àìfohùnṣọ̀kan àárín àwọn tó wà nínú kóòtù náà, ó sọ fún wọn pé tìtorí ìgbàgbọ́ tí òun ní nínú àjíǹde ni wọ́n ṣe ń dá òun lẹ́jọ́. Nítorí ìdí èyí, ọ̀pọ̀ ìyapa wá dìde láàárín wọn, àwọn Farisí sì fara mọ́ ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ.—Ìṣe 23:6-10.

Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú àwọn àpẹẹrẹ méjì tá a rí nínú Bíbélì yìí? Nínú àpẹẹrẹ méjèèjì, fífi òótọ́ inú sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó fi hàn pé wọ́n kábàámọ̀ ohun tí wọn ṣe ló ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ìfọ̀rọ̀wérọ̀ síwájú sí i. Nítorí náà, títọrọ àforíjì lè ràn wá lọ́wọ́ láti wá àlàáfíà. Bẹ́ẹ̀ ni o, gbígba àwọn ẹ̀bi wa lẹ́bi ká sì tọrọ àforíjì fún wàhálà tá a dá sílẹ̀ lè fún wa láǹfààní láti ní ìjíròrò tó gbámúṣé.

‘Àmọ́ Mi Ò Tíì Ṣe Ohun Búburú Kankan’

Nígbà tá a bá rí i pé ohun tá a sọ tàbí ohun tá a ṣe bí ẹnì kan nínú, a lè ronú pé ńṣe ni onítọ̀hún jẹ́ aláìlóye tàbí ẹni tó tètè máa ń ka nǹkan sí ju bó ṣe yẹ lọ. Síbẹ̀, Jésù Kristi gba àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nímọ̀ràn pé: “Nígbà náà, bí ìwọ bá ń mú ẹ̀bùn rẹ bọ̀ níbi pẹpẹ, tí o sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ ní ohun kan lòdì sí ọ, fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú pẹpẹ, kí o sì lọ; kọ́kọ́ wá àlàáfíà, ìwọ pẹ̀lú arákùnrin rẹ, àti lẹ́yìn náà, nígbà tí o bá ti padà wá, fi ẹ̀bùn rẹ rúbọ.”—Mátíù 5:23, 24.

Bí àpẹẹrẹ, arákùnrin kan lè rò pe o ti ṣẹ òun. Tọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, Jésù sọ pé o ní láti lọ kí o sì “wá àlàáfíà, ìwọ pẹ̀lú arákùnrin rẹ,” yálà o mọ̀ pé o ti ṣẹ̀ ẹ́ tàbí o kò mọ̀. Ní ìbámu pẹ̀lú èdè Gíríìkì, ọ̀rọ̀ tí Jésù lò níhìn-ín ‘túmọ̀ sí yíyanjú ọ̀ràn ní ìtùnbí ìnùbí lẹ́yìn gbúngbùngbún láàárín tọ̀túntòsì.’ (Ìwé atúmọ̀ èdè Vine’s Expository Dictionary of Old and New Testament Words) Láìṣe àní-àní, nígbà tí ẹni méjì bá ní aáwọ̀, àwọn méjèèjì ló máa ní ibi tí wọ́n ti jẹ̀bi, nítorí pé aláìpé láwọn méjèèjì wọ́n sì lè ṣe àṣìṣe. Èyí sábà máa ń gba pé kí àwọn méjèèjì jùmọ̀ yanjú ọ̀ràn náà.

Kókó tó wà níbẹ̀, kì í ṣe láti mọ ẹni tó jàre àti ẹni tó jẹ̀bi, bí kò ṣe ẹni tó máa gbé ìgbésẹ̀ láti wá àlàáfíà. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kíyè sí i pé àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì ń mú àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run lọ sílé ẹjọ́, lórí irú àwọn aáwọ̀ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ bí ọ̀rọ̀ lórí owó, ó bá wọn wí pé: “Èé ṣe tí ẹ kò kúkú jẹ́ kí a ṣe àìtọ́ sí ẹ̀yin fúnra yín? Èé ṣe tí ẹ kò kúkú jẹ́ kí a lu ẹ̀yin fúnra yín ní jìbìtì?” (1 Kọ́ríńtì 6:7) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù sọ èyí láti jẹ́ kí àwọn Kristẹni jáwọ́ nínú kíkó ọ̀ràn ara wọn lọ sílé ẹjọ́, síbẹ̀ ohun tó ní lọ́kàn ṣe kedere pé: Wíwá àlàáfíà láàárín àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ ṣe pàtàkì ju gbígbìyànjú láti mọ ẹni tó jàre àti ẹni tó jẹ̀bi. Tá a bá ní èyí lọ́kàn, yóò rọrùn fún wa láti tọrọ ìdáríjì fún ẹ̀ṣẹ̀ tẹ́nì kan rò pé a ṣẹ òun.

Òótọ́ Inú Ṣe Pàtàkì

Àmọ́ ṣá o, àwọn ènìyàn kan ti lo ọ̀rọ̀ tó yẹ kí wọ́n máa fi tọrọ àforíjì ju bó ṣe yẹ kí wọ́n lò ó lọ. Bí àpẹẹrẹ, ní Japan, ọ̀rọ̀ náà sumimasen, ìyẹn ọ̀rọ̀ tó yẹ kí wọ́n máa fi tọrọ àforíjì ti di èyí táwọn èèyàn máa ń sọ ní àìmọye ìgbà. Wọ́n tiẹ̀ lè lò ó láti dúpẹ́ oore, ó máa ń fi hàn pé ó ń ká onítọ̀hún lára pé òun ò lè san oore tẹ́nì kan ṣe fún òun padà. Nítorí pé ó ti di ohun táwọn èèyàn ń sọ ní gbogbo ìgbà, àwọn kan lé máa ṣe kàyéfì bóyá àwọn tó ń sọ ọ́ ń fi tinútinú sọ ọ́. Onírúurú ọ̀rọ̀ tá a fi ń tọrọ ìdáríjì bẹ́ẹ̀ lè wà táwọn èèyàn ti lò ju bó ṣe yẹ́ lọ láwọn àṣà ìbílẹ̀ mìíràn.

Nínú èdè èyíkéyìí, ó ṣe pàtàkì kéèyàn jẹ́ olóòótọ́ inú nígbà tó bá ń tọrọ àforíjì. Àwọn ọ̀rọ̀ tá a bá lò àti ohùn tá a bá fi sọ ọ́ gbọ́dọ̀ fi hàn pé ohun tá a ṣe dùn wá. Jésù Kristi kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nínú Ìwàásù Lórí Òkè pé: “Kí ọ̀rọ̀ yín Bẹ́ẹ̀ ni sáà túmọ̀ sí Bẹ́ẹ̀ ni, Bẹ́ẹ̀ kọ́ yín, Bẹ́ẹ̀ kọ́; nítorí ohun tí ó bá ju ìwọ̀nyí lọ wá láti ọ̀dọ̀ ẹni burúkú náà.” (Mátíù 5:37) Tó o bá ń tọrọ àforíjì, fi tọkàntọkàn ṣe é! Àpèjúwe kan rèé: Ọkùnrin kan tó tò sórí ìlà nídìí káńtà tí wọ́n ti ń pe àwọn èrò wọlé ní pápákọ̀ òfuurufú tọrọ àforíjì nígbà tó fi ẹrù rẹ̀ gbá obìnrin tó wà lẹ́yìn rẹ̀ lórí ìlà náà. Ìṣẹ́jú díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn, nígbà táwọn èèyàn sún síwájú, àpò tó kẹ́rù sí tún gbá obìnrin náà. Ọkùnrin náà tún sọ pé kó jọ̀wọ́ kó máà bínú. Nígbà tó tún fi gbá a lẹ́ẹ̀kẹta ni ọkùnrin tí òun àti obìnrin náà jọ ń rìnrìn àjò náà sọ fún ọkùnrin yìí pé tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni ohun tó ń sọ ti ọkàn rẹ̀ wá, kó rí i dájú pé àpò òun ò gbá obìnrin náà mọ́. Bẹ́ẹ̀ ni o, téèyàn bá fi tọkàntọkàn tọrọ àforíjì, ó gbọ́dọ̀ rí i dájú pé òun ò tún ṣe àṣìṣe náà mọ́.

Bí a bá jẹ́ olóòótọ́ ọkàn, títọrọ àforíjì wa yóò jẹ́ títẹ́wọ́ gba àṣìṣe èyíkéyìí, bíbẹ̀bẹ̀ fún ìdáríjì, àti sísapá láti ṣàtúnṣe ọ̀ràn náà débi tá a bá lè ṣe é dé. Bákan náà ni ẹni tá a ṣẹ̀ gbọ́dọ̀ múra tán láti dárí ji ẹni tó ronú pìwà dá náà. (Mátíù 18:21, 22; Máàkù 11:25; Éfésù 4:32; Kólósè 3:13) Níwọ̀n bí àwọn méjèèjì ti jẹ́ aláìpé, àtiwá àlàáfíà lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ téèyàn fi ń tọrọ àforíjì kó ipa tó lágbára gan-an nínú wíwá àlàáfíà.

Àkókò Tí Títọrọ Àforíjì Kò Bójú Mu

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀rọ̀ tó fi hàn pé èèyàn kábàámọ̀, ó sì kẹ́dùn fún ohun tó ṣe máa ń tuni lára ó sì máa ń jẹ́ kí àlàáfíà wà, síbẹ̀ ọlọgbọ́n èèyàn máa ń yẹra fún lílo irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ nígbà tí kò bá yẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àpẹẹrẹ kan ni nígbà tó bá jẹ́ pé ọ̀ràn náà kan ìwà títọ́ wa sí Ọlọ́run. Nígbà tí Kristi wà lórí ilẹ̀ ayé, “ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di onígbọràn títí dé ikú, bẹ́ẹ̀ ni, ikú lórí òpó igi oró.” (Fílípì 2:8) Síbẹ̀, kì í ṣe pé ó bẹ̀rẹ̀ sí tọrọ àforíjì nítorí ohun tó gbà gbọ́ kí wọ́n lè dín ìyà tí wọ́n fi ń jẹ ẹ́ kù. Jésù ò sì bẹ̀bẹ̀ nígbà tí àlùfáà àgbà sọ pé: “Mo fi Ọlọ́run alààyè mú kí o wá sábẹ́ ìbúra láti sọ fún wa yálà ìwọ ni Kristi Ọmọ Ọlọ́run!” Dípò kí Jésù máa bẹ̀bẹ̀, ńṣe ló fi tìgboyàtìgboyà fèsì pé: “Ìwọ fúnra rẹ wí i. Síbẹ̀ mo wí fún yín pé, Láti ìsinsìnyí lọ, ẹ óò rí Ọmọ ènìyàn tí yóò jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún agbára, tí yóò sì máa bọ̀ lórí àwọsánmà ọ̀run.” (Mátíù 26:63, 64) Èrò bíba ìwà títọ́ sí Baba rẹ̀, ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run, jẹ́ nítorí àtiwá àlàáfíà àlùfáà àgbà kò tiẹ̀ wá sọ́kàn Jésù rí.

Àwọn Kristẹni ń fi ọ̀wọ̀ àti ọlá hàn sí àwọn aláṣẹ. Síbẹ̀, wọ́n ò ní láti máa tọrọ àforíjì nítorí pé wọ́n ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run àti nítorí ìfẹ́ tí wọ́n ní sí àwọn arákùnrin wọn.—Mátíù 28:19, 20; Róòmù 13:5-7.

Kò Ní Sí Ohunkóhun Tó Máa Jẹ́ Ìdènà fún Àlàáfíà Mọ́

A ń ṣe àṣìṣe lóde òní nítorí pé a ti jogún àìpé àti ẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ Ádámù baba ńlá wa. (Róòmù 5:12; 1 Jòhánù 1:10) Ọ̀tẹ̀ tí Ádámù ṣe sí Ẹlẹ́dàá ló sún un sínú ipò ẹ̀ṣẹ̀ tó wà. Àmọ́ ṣá, ẹni pípé ni Ádámù àti Éfà níbẹ̀rẹ̀, wọ́n ò sì lẹ́ṣẹ̀, Ọlọ́run sì ti ṣèlérí àtimú ìran ènìyàn padà sínú ipò ìjẹ́pípé yìí. Yóò mú ẹ̀ṣẹ̀ àti gbogbo ipa tó ti ní kúrò.—1 Kọ́ríńtì 15:56, 57.

Ìwọ ronú lórí ohun tíyẹn máa túmọ̀ sí ná! Nígbà tí Jákọ́bù ọmọ ìyá Jésù ń gbani nímọ̀ràn lórí bó ṣe yẹ ká máa lo ahọ́n, ó sọ pé: “Bí ẹnì kan kò bá kọsẹ̀ nínú ọ̀rọ̀, ẹni yìí jẹ́ ènìyàn pípé, tí ó lè kó gbogbo ara rẹ̀ pẹ̀lú níjàánu.” (Jákọ́bù 3:2) Ẹni pípé lè darí ahọ́n rẹ̀ tí kò fi ní ní láti tọrọ àforíjì nítorí àṣìlò rẹ̀. Ó lè ‘kó gbogbo ara rẹ̀ níjàánu.’ Ẹ ò rí i bó ṣe máa dùn tó nígbà tá a bá di pípé! Kò ní sí ohunkóhun tó máa jẹ́ ìdènà fún àlàáfíà àárín àwọn èèyàn mọ́ nígbà yẹn. Àmọ́, ní báyìí ná, fífi tọkàntọkàn tọrọ àforíjì nítorí àṣìṣe ta a bá ṣe yóò ṣèrànwọ́ gan-an nínú wíwá àlàáfíà.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ó lè jẹ́ ojú Pọ́ọ̀lù tó ti ń di bàìbàì ni kò jẹ́ kó lè dá àlùfáà àgbà náà mọ̀.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Nígbà tí gbogbo ènìyàn bá di pípé, kò ní sí ohunkóhun tó máa jẹ́ ìdènà fún àlàáfíà mọ́