Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ṣé gbogbo ìgbà la gbọ́dọ̀ san ẹ̀jẹ́ tá a bá jẹ́ fún Ọlọ́run?

Ní ìbámu pẹ̀lú Ìwé Mímọ́, jíjẹ́jẹ̀ẹ́ túmọ̀ sí ṣíṣe ìlérí fún Ọlọ́run, lẹ́yìn tá a ti ronú dáadáa, pé a óò gbé ìgbésẹ̀ kan tàbí rú ẹbọ tàbí bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àkànṣe iṣẹ́ kan tàbí tẹ́wọ́ gba ipò kan tàbí pé a óò yàgò fún àwọn nǹkan láìjẹ́ pé àwọn nǹkan náà ò bófin mu. Bíbélì kún fún àwọn àkọsílẹ̀ nípa àwọn ẹ̀jẹ́ táwọn èèyàn jẹ́ pé àwọn á ṣe ohun pàtó kan tí Ọlọ́run bá kọ́kọ́ ṣe ohun kan fáwọn. Bí àpẹẹrẹ, Hánà, ìyá wòlíì Sámúẹ́lì, “bẹ̀rẹ̀ sí jẹ́ ẹ̀jẹ́, ó sì wí pé: ‘Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, . . . [bí ìwọ kò bá ní] gbàgbé ẹrúbìnrin rẹ, tí o sì fún ẹrúbìnrin rẹ ní ọmọ tí ó jẹ́ ọkùnrin ní ti tòótọ́, èmi yóò fi í fún Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, abẹ fẹ́lẹ́ kì yóò sì kan orí rẹ̀.’” (1 Sámúẹ́lì 1:11) Bíbélì tún ṣàpèjúwe àwọn ẹ̀jẹ́ bí òun tá a fínnúfíndọ̀ ṣe. Báwo ni sísan àwọn ẹ̀jẹ́ tá a jẹ́ fún Ọlọ́run ṣe pọn dandan tó?

Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì sọ pé: “Nígbàkigbà tí o bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Ọlọ́run, má ṣe lọ́ tìkọ̀ láti san án.” Ó fi kún un pé: “Ohun tí o jẹ́jẹ̀ẹ́, san án. Ó sàn kí o má ṣe jẹ́jẹ̀ẹ́ ju pé kí o jẹ́jẹ̀ẹ́, kí o má sì san án.” (Oníwàásù 5:4, 5) Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípasẹ̀ Mósè sọ pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ìwọ jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ, ìwọ kò gbọ́dọ̀ fi sísan án falẹ̀, nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò béèrè rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ láìkùnà, ní tòótọ́, yóò sì di ẹ̀ṣẹ̀ níhà ọ̀dọ̀ rẹ.” (Diutarónómì 23:21) Ó hàn kedere pé jíjẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Ọlọ́run kì í ṣe ohun tá à ń fọwọ́ yẹpẹrẹ mú rárá. A gbọ́dọ̀ ṣe é pẹ̀lú èrò rere lọ́kàn, ẹni tó sì ń ṣe é kò gbọ́dọ̀ ṣe iyèméjì rárá pé bóyá lòun ní agbára láti san nǹkan tóun ṣèlérí nínú ẹ̀jẹ́ náà. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó sàn kí onítọ̀hún máà wulẹ̀ jẹ́jẹ̀ẹ́ ọ̀hún. Àmọ́ téèyàn bá ti jẹ́jẹ̀ẹ́, ṣé gbogbo ẹ̀jẹ́ ló pọn dandan kéèyàn mú ṣẹ?

Bí ẹni kan bá jẹ́jẹ̀ẹ́ àtiṣe ohun kan àmọ́ tó wá rí i níkẹyìn pé ohun náà ò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu ńkọ́? Bí ẹ̀jẹ́ náà bá lọ jẹ́ èyí tó máa mú kéèyàn da ìwà pálapàla pọ̀ mọ́ ìjọsìn tòótọ́ ńkọ́? (Diutarónómì 23:18) Ó hàn gbangba pé kò pọn dandan kéèyàn mú irú ẹ̀jẹ́ bẹ́ẹ̀ ṣẹ. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, lábẹ́ Òfin Mósè, baba tàbí ọkọ obìnrin kan lè fagi lé ẹ̀jẹ́ tí obìnrin náà bá jẹ́.—Númérì 30:3-15.

Tún ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀ràn ẹnì kan tó ti jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Ọlọ́run pé òun máa wà lápọ̀n-ọ́n ní gbogbo ìgbésí ayé òun àmọ́ tó wá rí i pé ara òun kò gbà á mọ́. Ẹ̀jẹ́ tó ṣe ti jẹ́ kó bá ara rẹ̀ nínú ipò kan tó ti rí i pé mímú ẹ̀jẹ́ náà ṣẹ ti ń jẹ́ kí òun sún mọ́ bèbè rírú òfin Ọlọ́run nípa ìwà rere. Ṣé ó yẹ kó sọ pé òun gbọ́dọ̀ mú ẹ̀jẹ́ náà ṣẹ dandan? Ǹjẹ́ kò ní sàn fún un kí ó máà san ẹ̀jẹ́ rẹ̀ kó má bàa jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ìwà pálapàla, kó ha sàn kó bẹ̀bẹ̀ fún àánú Ọlọ́run kó sì tọrọ ìdáríjì? Òun nìkan ṣoṣo ló lè dá ìpinnu náà ṣe. Kò sí ẹnikẹ́ni mìíràn tó lè bá a ṣe ìpinnu náà.

Bí ẹnì kan bá jẹ́jẹ̀ẹ́ kan tó wá rí i níkẹyìn pé àìronújinlẹ̀ ló mú kí òun jẹ́ irú ẹ̀jẹ́ bẹ́ẹ̀ ńkọ́? Ṣé ó yẹ kó ṣì gbìyànjú láti mú ẹ̀jẹ́ náà ṣẹ? Kò rọrùn rárá fún Jẹ́fútà láti mú ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ fún Ọlọ́run ṣẹ, àmọ́ ó fi tọkàntọkàn ṣe bẹ́ẹ̀. (Àwọn Onídàájọ́ 11:30-40) Ìkùnà ẹnì kan láti mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ṣẹ lè mú kí Ọlọ́run ní “ìkannú” sí onítọ̀hún kí gbogbo ohun tó ti gbé ṣe sì di èyí tó fọ́ bà jẹ́. (Oníwàásù 5:6) Fífi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀ràn mímú ẹ̀jẹ́ ẹni ṣẹ lè yọrí sí pípàdánù ojú rere Ọlọ́run.

Jésù Kristi sọ pé: “Kí ọ̀rọ̀ yín Bẹ́ẹ̀ ni sáà túmọ̀ sí Bẹ́ẹ̀ ni, Bẹ́ẹ̀ kọ́ yín, Bẹ́ẹ̀ kọ́; nítorí ohun tí ó bá ju ìwọ̀nyí lọ wá láti ọ̀dọ̀ ẹni burúkú náà.” (Mátíù 5:37) Kì í ṣe ọ̀ràn sísan ẹ̀jẹ́ téèyàn jẹ́ fún Ọlọ́run nìkan ló yẹ kó ká Kristẹni kan lára, ó tún yẹ kí jíjẹ́ ẹni tó ṣeé gbíyè lé nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí Ọlọ́run àti sí ènìyàn ká a lára pẹ̀lú. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé ó kó ara rẹ̀ sínú wàhálà bíbá ẹnì kan ṣe àdéhùn kan tó dà bí èyí tó dára lákọ̀ọ́kọ́, àmọ́ tó wá rí i pé kò bọ́gbọ́n mu rárá nígbà tó gbé e yẹ̀ wò dáadáa ńkọ́? Kò gbọ́dọ̀ fọwọ́ yẹpẹrẹ mú irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ rárá. Àmọ́ tí wọ́n bá jọ jíròrò ọ̀rọ̀ náà dáadáa, ẹni kejì yẹn lè pinnu láti dá a nídè kúrò nínú ẹ̀jẹ́ náà.—Sáàmù 15:4; Òwe 6:2, 3.

Ní ti ọ̀ràn jíjẹ́jẹ̀ẹ́ àti gbogbo nǹkan mìíràn, kí ló yẹ kó jẹ́ olórí àníyàn wa? Ẹ jẹ́ ká máa là kàkà láti ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30, 31]

Hánà kò lọ́ tìkọ̀ láti san ẹ̀jẹ́ rẹ̀

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30, 31]

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn, síbẹ̀ Jẹ́fútà san ẹ̀jẹ́ rẹ̀