Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ẹ Máa Ṣe Olùṣọ́ Àgùntàn Agbo Ọlọ́run”

“Ẹ Máa Ṣe Olùṣọ́ Àgùntàn Agbo Ọlọ́run”

“Ẹ Wá Sọ́dọ̀ Mi, . . . Èmi Yóò Sì Tù Yín Lára”

“Ẹ Máa Ṣe Olùṣọ́ Àgùntàn Agbo Ọlọ́run”

“Gbogbo ìgbà lẹ máa ń tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí wa tẹ́ ẹ sì máa ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ afúnniníṣìírí fún wa látinú Bíbélì.”—Pamela.

“Ẹ ṣeun púpọ̀ fún gbogbo ohun tẹ́ ẹ̀ ń ṣe fún wa. Ipa tó ń ní lórí wa ò kéré.”—Robert.

ÌWÚRÍ ló mú kí Pamela àti Robert kọ àwọn ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ báwọ̀nyí sáwọn alàgbà Kristẹni nínú ìjọ wọn. Àwọn mìíràn láàárín àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kárí ayé pẹ̀lú ń dúpẹ́ fún ìtìlẹ́yìn àti ìtọ́jú tí wọ́n ń rí gbà látọ̀dọ̀ àwọn tó ń “ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run.” (1 Pétérù 5:2) Ní tòótọ́, àwọn èèyàn Jèhófà mọrírì onírúurú nǹkan táwọn alàgbà ń ṣe nítorí wọn lọ́pọ̀lọpọ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún mọrírì ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ṣe é.

“Ẹ Máa Ní Púpọ̀ Rẹpẹtẹ Láti Ṣe”

Ẹrù iṣẹ́ púpọ̀ rẹpẹtẹ làwọn Kristẹni alàgbà ń bojú tó. (Lúùkù 12:48) Wọ́n á múra àsọyé tí wọ́n á sọ nípàdé ìjọ, wọ́n á tún kópa nínú wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn. Ẹrù iṣẹ́ wọn kan ṣíṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn. Àwọn alàgbà tún máa ń wáyè gbọ́ tàwọn tó nílò àkànṣe àfiyèsí, irú bí àwọn àgbàlagbà àtàwọn mìíràn tó ṣe aláìní, síbẹ̀ wọn kì í fi ọ̀ràn tẹ̀mí àti tara ìdílé tiwọn fúnra wọn ṣeré. (Jóòbù 29:12-15; 1 Tímótì 3:4, 5; 5:8) Àwọn alàgbà mìíràn ń ṣèrànwọ́ láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àwọn mìíràn wà nínú Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn tàbí kí wọ́n jẹ́ ọ̀kan lára Ẹgbẹ́ Tó Ń Bẹ Àwọn Aláìsàn Wò. Ọ̀pọ̀ wọn ló sì ń yọ̀ǹda ara wọn láti ṣiṣẹ́ ní àpéjọ àyíká àti àpéjọ àgbègbè. Ká sòótọ́, àwọn alàgbà ní “púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe . . . nínú iṣẹ́ Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 15:58) Abájọ táwọn tó wà lábẹ́ àbójútó àwọn alàgbà tó ń ṣiṣẹ́ kára yìí fi máa ń mọrírì wọn gidigidi!—1 Tẹsalóníkà 5:12, 13.

Orísun ìṣírí ni alàgbà tó máa ń lọ bẹ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ wò nílé wọn tàbí níbòmíràn lóòrèkóòrè láti fún wọn lókun nípa tẹ̀mí jẹ́. Thomas tó jẹ́ pé ìyá rẹ̀ nìkan ló tọ́ ọ dàgbà sọ pé: “Tí kì í bá ṣe ìtìlẹ́yìn onífẹ̀ẹ́ àti ìṣírí àwọn alàgbà ni, mi ò rò pé ì bá ṣeé ṣe fún mi láti máa sin Jèhófà gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún lónìí.” Ọ̀pọ̀ àwọn èwe tá a tọ́ dàgbà nínú ìdílé olóbìí kan ni wọ́n sọ pé àfiyèsí táwọn alàgbà fún àwọn ló jẹ́ káwọn lè dẹni tó sún mọ́ Ọlọ́run.

Àwọn àgbàlagbà inú ìjọ pàápàá ò ṣàì mọrírì ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn. Àwọn alàgbà méjì lọ bẹ tọkọtaya tí wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì tó ti lé ní ẹni ọgọ́rin ọdún wò, lẹ́yìn ìbẹ̀wò náà tọkọtaya yìí kọ̀wé pé: “A fẹ́ láti dúpẹ́ fún bíbẹ̀ tẹ́ ẹ bẹ̀ wá wò. Nígbà tẹ́ ẹ lọ tán, a tún ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tẹ́ ẹ jíròrò pẹ̀lú wa kà. A ò jẹ́ gbàgbé àwọn ọ̀rọ̀ ìṣírí tẹ́ ẹ sọ fún wa.” Obìnrin opó kan ẹni àádọ́rin ọdún kọ̀wé sáwọn alàgbà pé: “Mo ti ń gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn mí lọ́wọ́, ó sì rán ẹ̀yin alàgbà méjèèjì sí mi. Ìbùkún látọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìbẹ̀wò yín jẹ́!” Ṣé bíbẹ̀ táwọn alàgbà ìjọ rẹ bẹ̀ ọ́ wò lẹ́nu àìpẹ́ yìí ti ṣe ìwọ náà láǹfààní? Dájúdájú, gbogbo wa la mọrírì ìsapá wọn láti bójú tó agbo tó wà níkàáwọ́ wọn!

Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn Tó Ń Fara Wé Ọlọ́run àti Kristi

Jèhófà jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn onífẹ̀ẹ́. (Sáàmù 23:1-4; Jeremáyà 31:10; 1 Pétérù 2:25) Jésù Kristi náà jẹ́ Olùṣọ́ Àgùntàn tó ń bójú tó àìní wa nípa tẹ̀mí lọ́nà tó tayọ. Kódà, a tiẹ̀ pè é ní “olùṣọ́ àgùntàn àtàtà,” “olùṣọ́ àgùntàn ńlá,” àti “olórí olùṣọ́ àgùntàn.” (Jòhánù 10:11; Hébérù 13:20; 1 Pétérù 5:4) Ọ̀nà wo ni Jésù gbà bá àwọn tó ń fẹ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lò? Ńṣe ló fi tìfẹ́tìfẹ́ ké sí wọn pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára.”—Mátíù 11:28.

Bákan náà làwọn alàgbà lóde òní ṣe ń sapá láti jẹ́ orísun ìtura àti ààbò fún agbo. Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí “dà bí ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù àti ibi ìlùmọ́ kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò, bí àwọn ìṣàn omi ní ilẹ̀ aláìlómi, bí òjìji àpáta gàǹgà ní ilẹ̀ gbígbẹ táútáú.” (Aísáyà 32:2) Irú àwọn èèyàn yìí, tó ń ṣe báyìí dáàbò bo àwọn ẹlòmíràn, máa ń mára tuni, agbo sì máa ń bọ̀wọ̀ fún wọn, wọ́n sì máa ń rí ojú rere Ọlọ́run.—Fílípì 2:29; 1 Tímótì 5:17.

Ìtìlẹ́yìn Pàtàkì Látọ̀dọ̀ Aya Wọn

Àwọn èèyàn Ọlọ́run mọrírì àwọn Kristẹni alàgbà púpọ̀, wọ́n sì tún mọrírì ìtìlẹ́yìn onífẹ̀ẹ́ táwọn ọkùnrin wọ̀nyí ń rí gbà látọ̀dọ̀ aya wọn. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn obìnrin yìí ní láti yááfì àwọn ohun kan kí wọ́n bàa lè ti àwọn ọkọ wọn lẹ́yìn. Nígbà mìíràn, wọ́n á wà nílé nígbà tí ọkọ wọn á wà níbi tó ti ń bójú tó àwọn ọ̀ràn ìjọ tàbí níbi tó ti ń ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn. Ìgbà mìíràn wà tí wọ́n ní láti yí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí wọ́n ti fara balẹ̀ ṣe padà nítorí àwọn ìṣòro àìròtẹ́lẹ̀ tó yọjú nínú ìjọ. Michelle sọ pé: “Pẹ̀lú ìyẹn náà, nígbà tí mo bá rí bí ọwọ́ ọkọ mi ṣe dí bó ṣe ń múra ìpàdé sílẹ̀ tàbí tó ń ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn, mo máa ń fi sọ́kàn pé iṣẹ́ Jèhófà ló ń ṣe mo sì ń gbìyànjú láti tì í lẹ́yìn ní gbogbo ọ̀nà tí mo bá mọ̀.”

Alàgbà lọkọ Cheryl náà, òun náà sì sọ pé: “Mo mọ̀ pé àwọn ará nínú ìjọ nílò àwọn alàgbà láti bá sọ̀rọ̀, mo sì fẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé wọ́n lè wá bá ọkọ mi nígbàkigbà tí wọ́n bá fẹ́ rí i.” Àwọn obìnrin bíi Michelle àti Cheryl, tó ń ti ọkọ wọn lẹ́yìn máa ń yááfì àwọn ohun kan kí ọkọ wọn bàa lè bójú tó àwọn àgùntàn Ọlọ́run. A mọrírì ìyàwó àwọn alàgbà nítorí ẹ̀mí ìtìlẹyìn wọn.

Àmọ́ o, alàgbà ò gbọ́dọ̀ torí pé ọwọ́ òun dí kó wá pa àwọn ohun tẹ̀mí àti àwọn ohun mìíràn tí ìyàwó rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀ nílò tì. Alàgbà tó bá ti láya gbọ́dọ̀ “wà láìní ẹ̀sùn lọ́rùn, ọkọ aya kan, tí ó ní àwọn ọmọ tí wọ́n gbà gbọ́, tí wọn kò sí lábẹ́ ẹ̀sùn ìwà wọ̀bìà tàbí ya ewèlè.” (Títù 1:6) Ó gbọ́dọ̀ máa bójú tó ìdílé rẹ̀ lọ́nà tí Ọlọ́run fẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ṣe ní káwọn Kristẹni alábòójútó máa ṣe.—1 Tímótì 3:1-7.

Kò sóhun tá a lè fi wé aya tó ń ṣètìlẹ́yìn fún ọkọ rẹ̀ alàgbà tọ́wọ́ rẹ̀ máa ń dí! Bó ṣe rí lára àwọn alàgbà tó mọnúúrò, tó ti láya nìyẹn. Ńṣe ló dà bí ohun tí Bíbélì sọ, pé: “Ẹnì kan ha ti rí aya rere bí? Ẹni náà ti rí ohun rere.” (Òwe 18:22) Nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe, àwọn alàgbà yìí ń jẹ́ káwọn aya wọn mọ̀ pé àwọn mọrírì wọn. Ní àfikún sí àdúrà tọkàntọkàn àti ìkẹ́kọ̀ọ́ tó ń gbádùn mọ́ni táwọn Kristẹni yìí tó ti gbéyàwó ń ṣe pa pọ̀, wọ́n tún máa ń ya àkókò sọ́tọ̀ láti ṣeré lọ sétí òkun, nasẹ̀ lọ sínú igbó tàbí kí wọ́n lọ najú ní ọgbà ìṣeré. Dájúdájú, ó máa ń dùn mọ́ àwọn alàgbà láti fi ìfẹ́ bójú tó ìyàwó wọn.—1 Pétérù 3:7.

Orísun ìtura nípa tẹ̀mí làwọn alàgbà tí wọ́n ń fi ẹ̀mí àìmọtara-ẹni-nìkan bójú tó agbo Ọlọ́run jẹ́ fáwọn èèyàn Jèhófà. “Ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” ni wọ́n lóòótọ́ o, wọ́n sì jẹ́ ìbùkún fún ìjọ!—Éfésù 4:8, 11-13.