Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kòṣeémáàní Làwa Kristẹni Jẹ́ Fún Ara Wa

Kòṣeémáàní Làwa Kristẹni Jẹ́ Fún Ara Wa

Kòṣeémáàní Làwa Kristẹni Jẹ́ Fún Ara Wa

“Ẹ̀yà ara tí ó jẹ́ ti ara wa lẹ́nì kìíní-kejì ni wá.”—ÉFÉSÙ 4:25.

1. Kí ni ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan sọ nípa ẹ̀yà ara èèyàn?

 ÀGBÀYANU iṣẹ́ ìṣẹ̀dá ni ara èèyàn jẹ́! Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé: “Nígbà mìíràn, àwọn èèyàn máa ń pe ẹ̀yà ara èèyàn ní oríṣi ẹ̀rọ kan—tí kò tíì sí oríṣi mìíràn tó dà bíi rẹ̀. Ká sọ tòótọ́, ara ènìyàn kì í ṣe ẹ̀rọ. Àmọ́ a lè fi wé ẹ̀rọ ní ọ̀pọ̀ ọ̀nà. Ọ̀pọ̀ ẹ̀yà ló para pọ̀ jẹ́ ara èèyàn bíi ti ẹ̀rọ. Ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan nínú ara ló ní iṣẹ́ àrà ọ̀tọ̀ tó ń ṣe, bíi ti ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan lára ẹ̀rọ kan. Àmọ́ gbogbo ẹ̀yà ara náà ló ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ kí ara tàbí ẹ̀rọ náà lè ṣiṣẹ́ lọ́nà tó já geere.”

2. Ọ̀nà wo ni ara èèyàn àti ìjọ Kristẹni gbà bára mu?

2 Bẹ́ẹ̀ ni o, ara èèyàn ní ẹ̀yà tó pọ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló sì máa ń ṣe ohun kan tó wúlò fún ara. Kò sí iṣan kan, iṣu ẹran ara tàbí ẹ̀yà ara kan tí kò níṣẹ́ tó ń ṣe. Bákan náà ni ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìjọ Kristẹni lè ṣe ohun kan láti fi kún ìlera àti ẹwà tẹ̀mí ìjọ náà. (1 Kọ́ríńtì 12:14-26) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnì kankan kò gbọ́dọ̀ rò pé òun lọ́lá ju àwọn mìíràn lọ nínú ìjọ, síbẹ̀ kò sẹ́ni tó gbọ́dọ̀ ka ara rẹ̀ sẹ́ni tí ò já mọ́ nǹkankan.—Róòmù 12:3.

3. Báwo ni Éfésù 4:25 ṣe fi hàn pé kòṣeémáàní làwọn Kristẹni jẹ́ fún ara wọn?

3 Bí ẹ̀yà ara èèyàn ṣe gbára léra wọn náà làwọn Kristẹni ṣe jẹ́ kòṣeémáàní fún ara wọn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn onígbàgbọ́ tá a fẹ̀mí yàn bíi tirẹ̀ pé: “Nísinsìnyí tí ẹ ti fi èké ṣíṣe sílẹ̀, kí olúkúlùkù yín máa bá aládùúgbò rẹ̀ sọ òtítọ́, nítorí ẹ̀yà ara tí ó jẹ́ ti ara wa lẹ́nì kìíní-kejì ni wá.” (Éfésù 4:25) Níwọ̀n bí wọ́n ti ‘jẹ́ ti ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì,’ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tòótọ́ àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wà láàárín àwọn Ísírẹ́lì tẹ̀mí—“ara Kristi.” Dájúdájú, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọ́n gbára lé àwọn tó kù. (Éfésù 4:11-13) Àwọn tó sì fi tayọ̀tayọ̀ wà níṣọ̀kan pẹ̀lú wọn ni àwọn Kristẹni tòótọ́, tí wọ́n ní ìrètí gbígbé lórí ilẹ̀ ayé.

4. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà ran àwọn ẹni tuntun lọ́wọ́?

4 Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tó ń retí àtigbé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé ló ń ṣèrìbọmi lọ́dọọdún. Àwọn ará yòókù nínú ìjọ ń fi tayọ̀tayọ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti “tẹ̀ síwájú sí ìdàgbàdénú.” (Hébérù 6:1-3) Ìrànlọ́wọ́ yìí lè ní dídáhùn àwọn ìbéèrè tó jẹ mọ́ Ìwé Mímọ́ nínú tàbí ríràn wọ́n lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. A lè ran àwọn ẹni tuntun lọ́wọ́ nípa fífi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nípa dídáhùn déédéé láwọn ìpàdé Kristẹni. Tó bá sì di àkókò ìṣòro, a tún lè fún wọn níṣìírí tàbí ká tù wọ́n nínú. (1 Tẹsalóníkà 5:14, 15) A gbọ́dọ̀ wá àwọn ọ̀nà tá a lè gbà ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa “bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.” (3 Jòhánù 4) Yálà a jẹ́ ọ̀dọ́ tàbí àgbàlagbà, yálà a ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí rìn nínú òtítọ́ ni tàbí a ti ń rìn nínú rẹ̀ tipẹ́, a lè ṣe kún ire tẹ̀mí àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́—wọ́n sì nílò wa gan-an ni.

Wọ́n Pèsè Ìrànlọ́wọ́ Tí Wọ́n Nílò

5. Báwo ni Ákúílà àti Pírísílà ṣe ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́?

5 Àwọn Kristẹni tó jẹ́ tọkọtaya wà lára àwọn tinú wọn máa ń dùn láti ṣèrànwọ́ fáwọn onígbàgbọ́ bíi tiwọn. Bí àpẹẹrẹ, Ákúílà àti Pírísílà (Pírísíkà) aya rẹ̀ ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́. Wọ́n gbà á sínú ilé wọn, wọ́n bá a ṣiṣẹ́ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí olùpàgọ́, wọ́n sì ràn án lọ́wọ́ láti gbé ìjọ tuntun tó wà ní Kọ́ríńtì ró. (Ìṣe 18:1-4) Wọ́n tiẹ̀ fi ẹ̀mí ara wọn sínú ewu nítorí Pọ́ọ̀lù láwọn ọ̀nà kan tí a kò mọ̀ pàápàá. Róòmù ni wọ́n ń gbé nígbà tí Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn Kristẹni tó wà níbẹ̀ pé: “Ẹ bá mi kí Pírísíkà àti Ákúílà àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ mi nínú Kristi Jésù, tí wọ́n fi ọrùn ara wọn wewu nítorí ọkàn mi, àwọn ẹni tí kì í ṣe èmi nìkan ṣùgbọ́n tí gbogbo ìjọ àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú ń fi ọpẹ́ fún.” (Róòmù 16:3, 4) Bíi ti Ákúílà àti Pírísílà, àwọn Kristẹni kan lóde òní ti gbé ìjọ ró, wọ́n sì ti ran àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ olùjọsìn lọ́wọ́ lónírúurú ọ̀nà, wọ́n tiẹ̀ ti fi ẹ̀mí ara wọn sínú ewu láwọn ìgbà mìíràn kí wọ́n má bàa kó àwọn mìíràn tó jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run sínú ewu ìwà òkú òǹrorò tàbí ikú pàápàá látọwọ́ àwọn onínúnibíni.

6. Irú ìrànlọ́wọ́ wo ni Ápólò rí gbà?

6 Ákúílà àti Pírísílà tún ran Ápólò lọ́wọ́, ìyẹn Kristẹni tó jẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ nì, ẹni tó ń kọ́ àwọn olùgbé Éfésù nípa Jésù Kristi. Ní àkókò yẹn, Ápólò ò mọ̀ ju ìbatisí tí Jòhánù ṣe gẹ́gẹ́ bí àmì ìrònúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ lòdì sí májẹ̀mú Òfin. Nígbà tí Ákúílà àti Pírísílà rí i pé Ápólò nílò ìrànlọ́wọ́, wọ́n “làdí ọ̀nà Ọlọ́run fún un lọ́nà tí ó túbọ̀ pé rẹ́gí.” Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ṣàlàyé fún un pé ìbatisí Kristẹni ní ríri èèyàn bọnú omi àti gbígba ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́ nínú. Ápólò fi ohun tí wọ́n kọ́ ọ sílò. Lẹ́yìn ìyẹn, ní Ákáyà, “ó ṣe ìrànlọ́wọ́ ńláǹlà fún àwọn tí wọ́n ti gbà gbọ́ ní tìtorí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí [Ọlọ́run]; nítorí pé pẹ̀lú ìgbónájanjan, ó fi hàn délẹ̀délẹ̀ ní gbangba pé àwọn Júù kò tọ̀nà, bí ó ti fi hàn nípasẹ̀ Ìwé Mímọ́ pé Jésù ni Kristi náà.” (Ìṣe 18:24-28) Àwọn ọ̀rọ̀ tó ń tẹnu àwọn tá a jọ jẹ́ olùjọsìn jáde lè ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nínú èyí pẹ̀lú, kòṣeémáàní la jẹ́ fún ara wa.

Fífi Ohun Ìní Ṣèrànwọ́

7. Kí làwọn ará Fílípì ṣe nígbà táwọn Kristẹni bíi tiwọn nílò ìrànlọ́wọ́ nípa tara?

7 Àwọn ará tó wà nínú ìjọ Kristẹni ní Fílípì nífẹ̀ẹ́ Pọ́ọ̀lù gan-an, wọ́n sì fi àwọn ohun ìní ránṣẹ́ sí i nígbà tó wà ní Tẹsalóníkà. (Fílípì 4:15, 16) Nígbà táwọn ará ní Jerúsálẹ́mù nílò ìrànlọ́wọ́ nípa tara, àwọn ará Fílípì fi hàn pé àwọn múra tán láti ṣètọrẹ, kódà wọ́n ṣe é kọjá agbára wọn gan-an. Pọ́ọ̀lù mọyì ẹ̀mí rere táwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ̀ tó wà ní Fílípì ní débi pé ó fi wọ́n ṣe àpẹẹrẹ fún àwọn onígbàgbọ́ yòókù.—2 Kọ́ríńtì 8:1-6.

8. Irú ẹ̀mí wo ni Ẹpafíródítù fi hàn?

8 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n, kì í ṣe pé àwọn ará Fílípì fi àwọn ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí i nìkan ni, àmọ́ wọ́n tún rán ẹnì kan sí i gẹ́gẹ́ bí aṣojú wọn, ìyẹn ni Ẹpafíródítù. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Tìtorí iṣẹ́ Olúwa ni [Ẹpafíródítù] fi sún mọ́ bèbè ikú, ó fi ọkàn rẹ̀ wewu, kí òun ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ lè dí àlàfo àìsí níhìn-ín yín láti ṣe iṣẹ́ ìsìn ti ara ẹni fún mi.” (Fílípì 2:25-30; 4:18) Wọ́n ò sọ fún wa bóyá alàgbà ni Ẹpafíródítù tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Síbẹ̀, Kristẹni tó ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ tó sì wúlò ni, Pọ́ọ̀lù sì nílò rẹ̀ gan-an. Ǹjẹ́ a rẹ́ni tó dà bí Ẹpafíródítù nínú ìjọ rẹ?

“Àrànṣe Afúnnilókun” Ni Wọ́n

9. Àpẹẹrẹ wo la rí kọ́ lára Àrísítákọ́sì?

9 A mọrírì àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa onífẹ̀ẹ́, bí Ákúílà, Pírísílà, àti Ẹpafíródítù gan-an nínú ìjọ èyíkéyìí tí wọ́n bá wà. Àwọn kan lára àwọn tá a jọ jẹ́ olùjọsìn lè da bíi Kristẹni Àrísítákọ́sì ti ọ̀rúndún kìíní. Òun àtàwọn mìíràn jẹ́ “àrànṣe afúnnilókun,” ó ṣeé ṣe kí wọ́n jẹ́ orísun ìtùnú tàbí kí wọ́n máa ṣèrànwọ́ nínú àwọn ọ̀ràn ti ara. (Kólósè 4:10, 11) Nípa ríran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́, Àrísítákọ́sì fi hàn pé òun jẹ́ ojúlówó ọ̀rẹ́ láwọn àkókò ìṣòro. Ó jẹ́ irú ẹni tá a mẹ́nu kàn nínú Òwe 17:17 pé: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.” Ǹjẹ́ kò yẹ kí gbogbo wa gbìyànjú láti jẹ́ “àrànṣe afúnnilókun” fún àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa? Ní pàtàkì jù lọ, a gbọ́dọ̀ ṣèrànlọ́wọ́ fáwọn tó wà nínú ìpọ́njú.

10. Àpẹẹrẹ wo ni Pétérù fi lélẹ̀ fáwọn Kristẹni alàgbà?

10 Àwọn Kristẹni alàgbà ní pàtàkì gbọ́dọ̀ jẹ́ àrànṣe afúnnilókun fáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wọn nípa tẹ̀mí. Kristi sọ fún àpọ́sítélì Pétérù pé: “Fún àwọn arákùnrin rẹ lókun.” (Lúùkù 22:32) Èyí ṣeé ṣe fún Pétérù nítorí pé ó ní àwọn ànímọ́ kan tó lágbára àgàgà lẹ́yìn àjíǹde Jésù. Ẹ̀yin alàgbà, ẹ rí i dájú pé ẹ tiraka láti ṣe bákan náà nítorí pé àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ onígbàgbọ́ nílò ìrànlọ́wọ́ yín.—Ìṣe 20:28-30; 1 Pétérù 5:2, 3.

11. Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú gbígbé irú ẹ̀mí tí Tímótì ní yẹ̀ wò?

11 Tímótì tí òun àti Pọ́ọ̀lù jọ ń rìnrìn àjò jẹ́ alàgbà tó ń ṣàníyàn gan-an nípa àwọn Kristẹni mìíràn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní àwọn àìlera pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tó ń yọ ọ́ lẹ́nu, síbẹ̀ Tímótì fi ìgbàgbọ́ tó lágbára hàn, ó sì ‘sìnrú pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù fún ìtẹ̀síwájú ìhìn rere.’ Òun ni àpọ́sítélì náà fi lè sọ fún àwọn ará Fílípì pé: “Èmi kò ní ẹlòmíràn tí ó ní ìtẹ̀sí-ọkàn bí tirẹ̀ tí yóò fi òótọ́ inú bójú tó àwọn ohun tí ó jẹmọ́ yín.” (Fílípì 2:20, 22; 1 Tímótì 5:23; 2 Tímótì 1:5) A lè jẹ́ ìbùkún fún àwọn tá a jọ jẹ́ olùjọsìn Jèhófà nípa fífi irú ẹ̀mí tí Tímótì ní hàn. Lóòótọ́, a gbọ́dọ̀ fara da àwọn ìkùdíẹ̀-káàtó tiwa fúnra wa àti onírúurú àdánwò, àmọ́ àwa náà lè fi ìgbàgbọ́ tó lágbára àti àníyàn onífẹ̀ẹ́ hàn fáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa nípa tẹ̀mí, a sì gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀. A gbọ́dọ̀ máa rántí ní gbogbo ìgbà pé kòṣeémáàní la jẹ́ fún wọn.

Àwọn Obìnrin Tó Bìkítà Nípa Àwọn Ẹlòmíràn

12. Kí la lè rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Dọ́káàsì?

12 Dọ́káàsì wà lára àwọn obìnrin tó bìkítà nípa àwọn ẹlòmíràn. Nígbà tó kú, àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá Pétérù rí, wọ́n sì mú un lọ sí ìyẹ̀wù òkè. Níbẹ̀ “gbogbo àwọn opó sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń sunkún, wọ́n sì ń fi ọ̀pọ̀ ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ àti ẹ̀wù àwọ̀lékè tí Dọ́káàsì ti máa ń ṣe nígbà tí ó wà pẹ̀lú wọn hàn.” A jí Dọ́káàsì dìde, ó sì dájú pé ó tún ń bá a lọ ní ‘pípọ̀ gidigidi nínú àwọn iṣẹ́ rere àti àwọn ẹ̀bùn àánú.’ Àwọn obìnrin bíi Dọ́káàsì tí wọ́n lè ṣe àwọn ẹ̀wù tàbí àwọn nǹkan mìíràn tó fìfẹ́ hàn fún àwọn aláìní wà nínú ìjọ Kristẹni òde òní. Àmọ́, mímú kí ire Ìjọba náà tẹ̀ síwájú àti kíkópa nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn ni olórí iṣẹ́ rere tí wọ́n ń ṣe.—Ìṣe 9:36-42; Mátíù 6:33; 28:19, 20.

13. Báwo ni Lìdíà ṣe fi àníyàn tó ní fún àwọn Kristẹni bíi tirẹ̀ hàn?

13 Obìnrin kan tó bẹ̀rù Ọlọ́run gan-an, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Lìdíà bìkítà nípa àwọn ẹlòmíràn. Ọmọ ìlú Tíátírà ni, ìlú Fílípì ló ń gbé nígbà tí Pọ́ọ̀lù wàásù níbẹ̀ ní nǹkan bí ọdún 50 Sànmánì Tiwa. Ó ṣeé ṣe kí Lìdíà jẹ́ aláwọ̀ṣe Júù, àmọ́ kí iye àwọn Júù tó wà ní Fílípì máà tó nǹkan kí wọ́n má sì ní sínágọ́gù. Òun àtàwọn obìnrin mìíràn tó jẹ́ olùfọkànsìn ni wọ́n kóra jọ láti jọ́sìn lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò kan nígbà tí àpọ́sítélì náà wá kéde ìhìn rere fún wọn. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Jèhófà sì ṣí ọkàn-àyà [Lìdíà] sílẹ̀ láti fiyè sí àwọn ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ. Wàyí o, nígbà tí a batisí òun àti agbo ilé rẹ̀, ó sọ pẹ̀lú ìpàrọwà pé: ‘Bí ẹ bá kà mí sí olùṣòtítọ́ sí Jèhófà, ẹ wọ ilé mi, kí ẹ sì dúró níbẹ̀.’ Ó sáà mú kí a wá.” (Ìṣe 16:12-15) Nítorí pé Lìdíà fẹ́ ṣe ohun tó dáa fáwọn ẹlòmíràn ló fi rọ Pọ́ọ̀lù àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ títí tí wọ́n fi dúró sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ẹ ò rí i bá a ṣe máa ń mọyì rẹ̀ tó nígbà táwọn Kristẹni onínúure àti onífẹ̀ẹ́ bá fi irú aájò àlejò bẹ́ẹ̀ hàn sí wa lóde òní!— Róòmù 12:13; 1 Pétérù 4:9.

A Nílò Ẹ̀yin Ọ̀dọ́ Pẹ̀lú

14. Báwo ni Jésù Kristi ṣe ṣe sí àwọn ọmọdé?

14 Àtọ̀dọ̀ Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run, tó jẹ́ onínúure àti ọlọ́yàyà ni ìjọ Kristẹni ti bẹ̀rẹ̀. Ọkàn àwọn èèyàn máa ń balẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀ nítorí pé ó jẹ́ onífẹ̀ẹ́ àti oníyọ̀ọ́nú. Nígbà tí àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí mú àwọn ọmọ wọn wá sọ́dọ̀ Jésù ní àkókò kan, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gbìyànjú láti lé wọn sẹ́yìn. Àmọ́ Jésù sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi; ẹ má gbìyànjú láti dá wọn lẹ́kun, nítorí ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ti irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹnì yòówù tí kò bá gba ìjọba Ọlọ́run bí ọmọ kékeré kì yóò wọ inú rẹ̀ lọ́nàkọnà.” (Máàkù 10:13-15) Ká tó lè rí ìbùkún ìjọba gbà, a gbọ́dọ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni tó ṣeé kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ bíi ti àwọn ọmọ kéékèèké. Jésù fi ìfẹ́ tó ní fáwọn ọmọdé hàn nípa gbígbé wọn sí apá rẹ̀ tó sì súre fún wọn. (Máàkù 10:16) Ẹ̀yin ọ̀dọ́ òde òní ńkọ́? Ẹ mọ̀ dájú pé a nífẹ̀ẹ́ yín a sì nílò yín nínú ìjọ.

15. Kókó pàtàkì wo ló wà nínú ìwé Lúùkù 2:40-52 nípa ìgbésí ayé Jésù, àpẹẹrẹ wo ló sì fi lélẹ̀ fáwọn ọ̀dọ́?

15 Nígbà tí Jésù ṣì wà lọ́dọ̀ọ́, ó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti Ìwé Mímọ́. Nígbà tó wà lọ́mọ ọdún méjìlá, òun àtàwọn òbí rẹ̀, Jósẹ́fù àti Màríà, rìnrìn àjò láti ìlú wọn ni Násárétì lọ sí Jerúsálẹ́mù láti lọ ṣayẹyẹ Ìrékọjá. Nígbà tí wọ́n ń padà bọ̀ wálé, àwọn òbí Jésù rí i pé Jésù ò sí láàárín àwọn tí wọ́n jọ ń rin ìrìn àjò náà. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, wọ́n rí i tó jókòó sínú ọ̀kan lára àwọn gbọ̀ngàn tẹ́ńpìlì náà, tó ń fetí sílẹ̀ sí àwọn olùkọ́ Júù tó sì ń bi wọ́n láwọn ìbéèrè. Nítorí pé ó ya Jésù lẹ́nu pé Jósẹ́fù àti Màríà ò mọ ibi tó yẹ kí wọ́n wá òun wá, ó béèrè pé: “Ṣé ẹ kò mọ̀ pé èmi gbọ́dọ̀ wà nínú ilé Baba mi ni?” Ó bá àwọn òbí rẹ̀ padà sílé, ó ń tẹrí ba fún wọn, ó sì ń bá a lọ ní títẹ̀síwájú ní ọgbọ́n àti ní ìdàgbàsókè. (Lúùkù 2:40-52) Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà ni Jésù fi lélẹ̀ fáwọn ọ̀dọ́! Ó dájú pé àwọn náà gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sáwọn òbí wọn kí inú wọn sì máa dùn láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan tẹ̀mí.—Diutarónómì 5:16; Éfésù 6:1-3.

16. (a) Igbe wo làwọn ọmọdékùnrin kan ń ké nígbà tí Jésù ń jẹ́rìí nínú tẹ́ńpìlì? (b) Àǹfààní wo làwọn ọ̀dọ́ Kristẹni ní lónìí?

16 Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́, o lè máa jẹ́rìí nípa Jèhófà nílé ìwé, kó o si máa tẹ̀ lé àwọn òbí rẹ jáde láti wàásù láti ilé dé ilé. (Aísáyà 43:10-12; Ìṣe 20:20, 21) Nígbà tí Jésù ń jẹ́rìí tó sì ń mú àwọn èèyàn lára dá nínú tẹ́ńpìlì kété ṣáájú ikú rẹ̀, àwọn ọmọkùnrin bíi mélòó kan ń kígbe pé: “Gba Ọmọkùnrin Dáfídì là, ni àwa bẹ̀bẹ̀!” Ọ̀rọ̀ yìí bí àwọn olórí àlùfáà àtàwọn akọ̀wé nínú tí wọ́n fi sọ fún un pé: “Ìwọ ha gbọ́ ohun tí àwọn wọ̀nyí ń sọ?” Jésù fèsì pé: “Bẹ́ẹ̀ ni. Ṣé ẹ kò tíì ka èyí rí pé, ‘Láti ẹnu àwọn ìkókó àti àwọn ọmọ ẹnu ọmú ni o ti mú ìyìn jáde’?” (Mátíù 21:15-17) Bíi tàwọn ọmọ wọ̀nyẹn, ẹ̀yin ọ̀dọ́ nínú ìjọ ní àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ láti yin Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ lógo. A fẹ́ kẹ́ ẹ máa wà lọ́dọ̀ wa kẹ́ ẹ sì máa bá wa ṣiṣẹ́ pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí olùpòkìkí Ìjọba náà.

Nígbà Tí Ìpọ́njú Bá Dé

17, 18. (a) Èé ṣe tí Pọ́ọ̀lù fi ṣètò ìkówójọ fáwọn Kristẹni tó wà ní Jùdíà? (b) Ipa wo ni ọrẹ àtinúwá tí wọ́n ṣe fáwọn onígbàgbọ́ ará Jùdíà ní lórí àwọn Júù àtàwọn Kèfèrí tó jẹ́ Kristẹni?

17 Ipòkípò tá a lè wà, ìfẹ́ ń sún wa láti ran àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa tó jẹ́ aláìní lọ́wọ́. (Jòhánù 13:34, 35; Jákọ́bù 2:14-17) Ìfẹ́ tí Pọ́ọ̀lù ní sí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin rẹ̀ tó wà ní Jùdíà ló sún un láti ṣètò fún ṣíṣe ìtọrẹ fún wọn láàárín àwọn ìjọ tó wà ní Ákáyà, Gálátíà, Makedóníà, àti ní àwọn àgbègbè Éṣíà. Ó lè jẹ́ inúnibíni, rìgbòrìyẹ̀ àti ìyà táwọn ọmọ ẹ̀yìn dojú kọ ní Jerúsálẹ́mù ló yọrí sí ohun tí Pọ́ọ̀lù pè ní “àwọn ìjìyà,” “ìpọ́njú,” àti “pípiyẹ́ àwọn nǹkan ìní [wọn].” (Hébérù 10:32-34; Ìṣe 11:27–12:1) Ó wá bójú tó owó tí wọ́n dá fún àwọn Kristẹni tó jẹ́ aláìní ní Jùdíà.—1 Kọ́ríńtì 16:1-3; 2 Kọ́ríńtì 8:1-4, 13-15; 9:1, 2, 7.

18 Ọrẹ àtinúwá tí wọ́n ṣe fún àwọn ẹni mímọ́ ní Jùdíà fi hàn pé ẹ̀mí ará wà láàárín àwọn Júù àtàwọn Kèfèrí tí wọ́n jẹ́ olùjọsìn Jèhófà. Kíkó tí wọ́n kó ọrẹ náà lọ fún wọn mú kó ṣeé ṣe fáwọn Kèfèrí tó jẹ́ Kristẹni láti fi ìmọrírì wọn hàn fún ìlàlóye tẹ̀mí tí wọ́n rí gbà látọ̀dọ̀ àwọn ará Jùdíà tó jẹ́ olùjọsìn bíi tiwọn. Ìyẹn wá túmọ̀ sí pé wọ́n jùmọ̀ ṣàjọpín ohun ti ara àti ohun tẹ̀mí. (Róòmù 15:26, 27) Ṣíṣe ìtọrẹ fún àwọn aláìní tó jẹ́ onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa lóde òní jẹ́ ohun tá à ń ṣe látọkànwá, ìfẹ́ ló sì ń sún wa ṣe é. (Máàkù 12:28-31) Kòṣeémáàní la tún jẹ fún ara wa nínú èyí pẹ̀lú kí ìmúdọ́gba lè wà ‘kí ẹni tó ní díẹ̀ má bàa ní kíkéré jù.’—2 Kọ́ríńtì 8:15.

19, 20. Fúnni ní àpẹẹrẹ kan tó fi báwọn èèyàn Jèhófà ṣe ń pèsè ìrànlọ́wọ́ nígbà tí jàǹbá bá ṣẹlẹ̀ hàn.

19 Mímọ̀ tá a mọ̀ pé kòṣeémáàní làwa Kristẹni jẹ́ fún ara wa la ṣe máa ń yára láti ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa nínú ìgbàgbọ́ lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, ronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí ìsẹ̀lẹ̀ runlé-rùnnà àti ilẹ̀ ríri wáyé ní El Salvador níbẹ̀rẹ̀ ọdún 2001. Ìròyìn kan sọ pé: “Àwọn ará ṣètò ìrànlọ́wọ́ láti dín ìṣòro kù ní gbogbo àgbègbè El Salvador. Àwọn ẹgbẹ́ ará láti Guatemala, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà àti Kánádà wá ràn wá lọ́wọ́. . . . Àwọn ilé tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] àtàwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́ta tó fani mọ́ra ni wọ́n kọ́ lójú ẹsẹ̀. Iṣẹ́ àṣekára àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn ará tó ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ wọ̀nyí ti jẹ́rìí ńlá.”

20 Ìròyìn kan láti Gúúsù Áfíríkà sọ pé: “Ìkún omi bíburú jáì kan tó pa apá tó pọ̀ ní ilẹ̀ Mòsáńbíìkì rẹ́ tún ṣèpalára fún ọ̀pọ̀ lára àwọn Kristẹni arákùnrin wa. Ẹ̀ka ilé iṣẹ́ tó wà ní Mòsáńbíìkì ṣètò láti bójú tó èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àìní wọn. Àmọ́ wọ́n sọ pé ká fi àwọn àlòkù aṣọ tó dáa ránṣẹ́ sí àwọn arákùnrin wa tó jẹ́ aláìní. Aṣọ tá a kó jọ pọ̀ gan-an tá a fi fi àpótí ìkẹ́rùránṣẹ́ onímítà méjìlá tó kún fún aṣọ ránṣẹ́ sí àwọn arákùnrin wa tó wà ní Mòsáńbíìkì.” Bẹ́ẹ̀ ni o, ní ọ̀nà yìí pẹ̀lú, kòṣeémáàní la jẹ́ fún ara wa.

21. Kí la óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó máa tẹ̀ lé èyí?

21 Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ níṣàájú, gbogbo ẹ̀yà ara èèyàn ló ṣe pàtàkì. Bákan náà gẹ́ẹ́ ló ṣe rí pẹ̀lú ìjọ Kristẹni. Gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ ló jẹ́ kòṣeémáàní fún ara wọn. Wọ́n sí tún ní láti máa bá iṣẹ́ ìsìn wọn lọ níṣọ̀kan. Àwọn kókó bíi mélòó kan tó mú kí èyí ṣeé ṣe la óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Kí ni ohun tí ẹ̀yà ara èèyàn àti ìjọ Kristẹni fi jọra?

• Kí làwọn Kristẹni ìjímìjí ṣe nígbà táwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ nílò ìrànlọ́wọ́?

• Àwọn àpẹẹrẹ wo ló wà nínú Ìwé Mímọ́ tó fi hàn pé kòṣeémáàní làwọn Kristẹni jẹ́ fún ara wọn?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ákúílà àti Pírísílà bìkítà nípa àwọn ẹlòmíràn

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Àwọn èèyàn Jèhófà ń ran ara wọn àtàwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ nígbà tí jàǹbá bá ṣẹlẹ̀