Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ a Nílò—Àwọn Ibi Ìjọsìn?

Ǹjẹ́ a Nílò—Àwọn Ibi Ìjọsìn?

Ǹjẹ́ a Nílò—Àwọn Ibi Ìjọsìn?

‘Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn arìnrìn-àjò ìsìn tí wọ́n wọṣọ aláwọ̀ mèremère, wá láti apá ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní orílẹ̀-èdè náà. Àwọn ará Íńdíà ń jó han aráyé bí ìlù ṣe ń dún, wọ́n ń jó irú ijó tí wọ́n láwọn ń jó ṣáájú kí àwọn ará Sípéènì tó wá jọba lé wọn lórí. Bẹ́ẹ̀ làwọn ọmọ ìjọ tí ń fi eékún wọn wọ́ gba àárín ogunlọ́gọ̀ èèyàn kọjá lọ sí ibùjọsìn kún àyíká ilé ìjọsìn ńlá náà àtàwọn òpópónà tó yí i ká.’

BÁYÌÍ ni ìwé ìròyìn El Economista ṣe ṣàpèjúwe àwọn èrò kan tó pọ̀ bí eṣú ní December 2001. Lákòókò náà, nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́ta èèyàn ló lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ńlá tó wà ní Ìlú Mẹ́síkò láti fi hàn pé àwọn nígbàgbọ́ nínú Wúńdíá Guadalupe. Bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú làwọn èrò ṣe ń rọ́ lọ sáwọn ilé ìjọsìn ńláńlá mìíràn, bíi Ṣọ́ọ̀ṣì Ńlá ti Pétérù Mímọ́ ní Róòmù.

Ipò ọ̀wọ̀ ni ọ̀pọ̀ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ ìjọsìn Ọlọ́run máa ń fi ilé ìjọsìn sí. Maria tó jẹ́ ọmọ Brazil sọ pé: “Ní tèmi o, ibi tí mo ti lè sún mọ́ Ọlọ́run ni ṣọ́ọ̀ṣì jẹ́. Ibi mímọ́ ni. Mo gbà gbọ́ pé lílọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ń sọ ọkàn di mímọ́, àti pé ẹ̀ṣẹ̀ ni téèyàn ò bá lọ ṣe Ìsìn kó sì lọ ṣe ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ní ṣọ́ọ̀ṣì lọ́jọọjọ́ Sunday.” Consuelo ọmọ ilẹ̀ Mẹ́síkò sọ pé: “Ṣọ́ọ̀ṣì máa ń dùn mọ́ mi ó sì máa ń mórí mi wú; n kì í fọ̀rọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì ṣeré rárá. Bí mo bá wà níbẹ̀ báyìí, ńṣe lá dà bí ẹni pé mo ti wà lọ́run.”

Lóòótọ́ làwọn kan kì í kóyán ṣọ́ọ̀ṣì kéré rárá, àmọ́ àwọn mìíràn ń ṣiyèméjì pé bóyá la tiẹ̀ nílò ṣọ́ọ̀ṣì fún ìjọsìn. Nígbà tí Peter Sibert, tó jẹ́ àlùfáà Kátólíìkì nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ń sọ̀rọ̀ nípa báwọn èèyàn ò ṣe ń wá sí ṣọ́ọ̀ṣì dáadáa, ó sọ pé: “Apá ibi tó wu àwọn [èèyàn] nínú ọ̀ràn ẹ̀sìn ni wọ́n ń ṣe. Ọ̀pọ̀ àwọn àgbàlagbà ló jẹ́ Kátólíìkì wọ́n sì ń gbé ìgbésí ayé wọn níbàámu pẹ̀lú ohun tí wọ́n gbà gbọ́—àmọ́ àwọn èwe ìwòyí ò fọwọ́ pàtàkì bẹ́ẹ̀ mú ẹ̀sìn mọ́.” Ìwé ìròyìn ìlú London kan, ìyẹn Daily Telegraph ti November 20, 1998, sọ pé: “Láti 1979, nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500 ] ṣọ́ọ̀ṣì ni wọ́n ti tì pa ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tá a bá fi wéra pẹ̀lú ṣọ́ọ̀ṣì márùndínlẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [495] tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lò àti àádọ́jọ [150] tí wọ́n tún kọ́.”

Ní 1997, ìwé ìròyìn Süddeutsche Zeitung ti Munich ní ilẹ̀ Jámánì ròyìn pé: “Wọ́n ti ń sọ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì di ilé sinimá àti ilé gbígbé: Àwọn ọmọ ìjọ ò lọ jọ́sìn ní ṣọ́ọ̀ṣì mọ́, wọ́n ti ń lo ilé ìjọsìn fún ohun mìíràn. . . . Wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tó ti dàṣà àwọn èèyàn nílẹ̀ Netherlands tàbí nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ní ilẹ̀ Jámánì pẹ̀lú.” Ó fi kún un pé: “Èèyàn lè rí ọgbọ̀n tàbí ogójì ṣọ́ọ̀ṣì pàápàá tí wọ́n ti tà láàárín ọdún mélòó kan sẹ́yìn.”

Ṣé ọ̀ranyàn ni ká nílé ìjọsìn ká tó lè sin Ọlọ́run ni? Ǹjẹ́ àwọn ilé ìjọsìn ràgàjìràgàjì àtàwọn tí wọ́n kọ́ lọ́nà àràbarà ní àfijọ nínú Bíbélì? Irú ilé wo la mọ̀ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run tòótọ́ àti alààyè? Kí la lè rí kọ́ látinú irú àwọn ilé bẹ́ẹ̀ nípa bá a ṣe nílò àwọn ibi ìjọsìn àti nípa ohun tó yẹ ká máa ṣe níbẹ̀?