Àkókò Tó Dára Jù Lọ Là Ń Gbé Yìí
Àkókò Tó Dára Jù Lọ Là Ń Gbé Yìí
NÍGBÀ tó o bá wà nínú ìṣòro, ǹjẹ́ ó máa ń ṣe ọ́ bí i pé “káyé tún padà dáa bíi tàtijọ́”? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, gbé ọ̀rọ̀ Sólómọ́nì Ọba yẹ̀ wò, èyí tó sọ pé: “Má sọ pé: ‘Èé ṣe tí ó fi jẹ́ pé àwọn ọjọ́ àtijọ́ sàn ju ìwọ̀nyí lọ?’ nítorí pé ọgbọ́n kọ́ ni ìwọ fi béèrè nípa èyí.”—Oníwàásù 7:10.
Kí nìdí tí Sólómọ́nì fi fúnni nímọ̀ràn yìí? Ó ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí ó mọ̀ pé níní èrò tí ó tọ́ nípa ìgbà àtijọ́ jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì gan-an fún wa láti fara da bí ipò nǹkan ò ṣe bára dé nísinsìnyí. Àwọn tó máa ń fẹ́ “káyé tún padà dáa bíi tàtijọ́” ti lè gbàgbé pé ìṣòro àti wàhálà wà láyé ìgbà yẹn náà àti pé ayé ò tíì fìgbà kan dáa lọ títí. Àwọn nǹkan kan lè dára látijọ́ ju ti ìsinsìnyí lọ o, àmọ́ àwọn nǹkan mìíràn náà á wà tí kò dára nígbà yẹn. Gẹ́gẹ́ bí Sólómọ́nì ti kíyè sí i, kò sí ọgbọ́n nínú kéèyàn máa ní èrò tí kò tọ́ nípa ìgbà àtijọ́, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ohun tó ti kọjá ti kọjá.
Ǹjẹ́ ìpalára kankan lè wà nínú kéèyàn máa retí lójú méjèèjì pé kí nǹkan tún rí bíi tàtijọ́? Bẹ́ẹ̀ ni o, tó bá lọ sọ wá dẹni tí ò lè mú nǹkan mọ́ra, tá ò wá lè fara da bí nǹkan ṣe rí lóde òní mọ́ tàbí tí kò jẹ́ ká mọrírì àkókò tí à ń gbé àti ìrètí tó lè jẹ́ tiwa.
Láìsí àní-àní, bí a kò bá fi bí àwọn ìṣòro ṣe ń pọ̀ sí i nínú ayé pè, àkókò tá à ń gbé yìí gan-an ni àkókò tó dára jù lọ. Kí nìdí? Ìdí ni pé a ti ń sún mọ́ ìmúṣẹ ète Ọlọ́run fún ilẹ̀ ayé wa àti ìbùkún ìṣàkóso alálàáfíà ti Ìjọba rẹ̀. Bíbélì ṣèlérí pé: “Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” (Ìṣípayá 21:4) Ní àkókò yẹn, pẹ̀lú bí ipò nǹkan ṣe máa sunwọ̀n sí i, kò sẹ́ni tó tún máa nídìí kankan láti máa yán hànhàn pé “káyé tún padà dáa bíi tàtijọ́.”