Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ǹjẹ́ ó yẹ kí Ìṣípayá 20:8 mú wa parí èrò sí pé àwọn tó pọ̀ rẹpẹtẹ ni Sátánì máa ṣì lọ́nà nígbà ìdánwò ìkẹyìn?

Ìṣípayá 20:8 ṣàpèjúwe ìgbà ìkẹyìn tí Sátánì yóò kọ lu àwọn èèyàn tó ń gbé lórí ilẹ̀ ayé ní òpin ẹgbẹ̀rún ọdún ìṣàkóso Ìjọba Mèsáyà. Ẹsẹ náà sọ nípa Sátánì pé: “Yóò sì jáde lọ láti ṣi orílẹ̀-èdè wọnnì ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé lọ́nà, Gọ́ọ̀gù àti Mágọ́gù, láti kó wọn jọpọ̀ fún ogun. Iye àwọn wọ̀nyí rí bí iyanrìn òkun.”

Pẹ̀lú gbogbo ìtẹ̀síwájú nínú ìlànà sáyẹ́ǹsì àti ìmọ̀ ẹ̀rọ, kò tíì sẹ́ni tó mọ bí “iyanrìn òkun” ṣe pọ̀ tó. Ìdí nìyẹn tá a fi lè sọ pé gbólóhùn yẹn dúró fún iye tí a kò mọ̀, tá ò sì lè sọ ní pàtó. Àmọ́, ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí iye kíkàmàmà kan, tó pọ̀ bí eéṣú, kódà tó pọ̀ lọ́nà tí kò ṣeé finú wòye, tàbí ńṣe ló wulẹ̀ jẹ́ èyí tí a kò mọ iye tó jẹ́ ní pàtó àmọ́ tí kò pọ̀ jù?

A lo gbólóhùn náà “bí iyanrìn òkun” láwọn ọ̀nà bíi mélòó kan nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, nínú Jẹ́nẹ́sísì 41:49, a kà á pé: “Jósẹ́fù sì ń bá a lọ láti to ọkà jọ pelemọ ní ìwọ̀n púpọ̀ rẹpẹtẹ, bí iyanrìn òkun, tí ó fi jẹ́ pé, níkẹyìn, wọ́n jáwọ́ nínú kíkà á, nítorí pé kò níye.” Ohun tá à ń sọ níhìn-ín ni pé kò lóǹkà. Bákan náà, Jèhófà sọ pé: “Gan-an bí a kò ti lè ka ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run, tí a kò sì lè díwọ̀n iyanrìn òkun, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sọ irú-ọmọ Dáfídì ìránṣẹ́ mi . . . di púpọ̀.” Bó ṣe dájú pé kò sí ẹni tó lè kaye ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti iyanrìn òkun bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe dájú pé Jèhófà yóò mú ìlérí tó ṣe fún Dáfídì ṣẹ.—Jeremáyà 33:22.

Ọ̀pọ̀ ìgbà ni gbólóhùn náà “iyanrìn òkun” máa ń tọ́ka sí ohun kan tó pọ̀ níye tàbí tó tóbi. Ṣìbáṣìbo bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Gílígálì nítorí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Filísínì tó kóra jọ sí Míkímáṣì, tí wọ́n dà “bí àwọn egunrín iyanrìn tí ó wà ní etíkun nítorí jíjẹ́ ògìdìgbó.” (1 Sámúẹ́lì 13:5, 6; Àwọn Onídàájọ́ 7:12) “Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti fún Sólómọ́nì ní ọgbọ́n àti òye ní ìwọ̀n púpọ̀ gidigidi àti fífẹ̀ ọkàn-àyà, bí iyanrìn tí ó wà ní etíkun.” (1 Àwọn Ọba 4:29) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tá à ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú ọ̀ràn kọ̀ọ̀kan pọ̀ gan-an, síbẹ̀ ó níbi tó mọ.

“Iyanrìn òkun” tún lè dúró fún iye tá ò mọ̀, kó má sì túmọ̀ sí ohun tó pọ̀ lọ́nà kíkàmàmà. Jèhófà sọ fún Ábúráhámù pé: “Èmi yóò bù kún ọ dájúdájú, èmi yóò sì sọ irú-ọmọ rẹ di púpọ̀ dájúdájú bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti bí àwọn egunrín iyanrìn tí ó wà ní etíkun.” (Jẹ́nẹ́sísì 22:17) Nígbà tí Jèhófà ń tún ọ̀rọ̀ yìí sọ fún Jékọ́bù tó jẹ́ ọmọ ọmọ Ábúráhámù, ó lo gbólóhùn náà “àwọn egunrín ekuru ilẹ̀,” èyí tí Jékọ́bù wá pè ní “àwọn egunrín iyanrìn òkun.” (Jẹ́nẹ́sísì 28:14; 32:12) Àbárèbábọ̀ ọ̀rọ̀ náà sì ni pé, yàtọ̀ sí Jésù Kristi “irú ọmọ” Ábúráhámù wá jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì, tí Jésù pè ní “agbo kékeré.”—Lúùkù 12:32; Gálátíà 3:16, 29; Ìṣípayá 7:4; 14:1, 3.

Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ wọ̀nyí? Ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ ni pé gbólóhùn náà “bí iyanrìn etíkun” kì í sábà túmọ̀ sí iye tí kò lóǹkà, tó pọ̀ lọ́nà tí kò ṣeé finú wòye; bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe gbogbo ìgbà la máa ń lò ó láti ṣàpèjúwe ohun kíkàmàmà tàbí ohun tó tóbi kọjá sísọ. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń dúró fún iye tí a kò mọ̀ àmọ́ tó mọ níwọ̀nba. Látàrí èyí, ó bọ́gbọ́n mu láti gbà gbọ́ pé àwọn ọlọ̀tẹ̀ èèyàn tó máa ti Sátánì lẹ́yìn nígbà ìkẹyìn tó máa kọ lu àwọn èèyàn Ọlọ́run kò ní í jẹ́ àwọn tó pọ̀ lọ́nà tí kò ṣeé finú wòye, àmọ́ iye wọn á pọ̀ díẹ̀ á sì jọjú tó láti dáyà foni. Àmọ́ kò tíì sẹ́ni tó mọ iye náà báyìí.