Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìdákẹ́kọ̀ọ́ Tó Ń mú Ká Di Olùkọ́ Tó Pegedé

Ìdákẹ́kọ̀ọ́ Tó Ń mú Ká Di Olùkọ́ Tó Pegedé

Ìdákẹ́kọ̀ọ́ Tó Ń mú Ká Di Olùkọ́ Tó Pegedé

“Máa fẹ̀sọ̀ ronú lórí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá, kí ìlọsíwájú rẹ lè fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn. Máa fiyè sí ara rẹ nígbà gbogbo àti sí ẹ̀kọ́ rẹ.” —1 TÍMÓTÌ 4:15, 16.

1. Kí ló sábà máa ń ṣẹlẹ̀ nípa àkókò àti ìdákẹ́kọ̀ọ́?

 BÍBÉLÌ sọ nínú Oníwàásù 3:1, pé: “Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún.” Bọ́rọ̀ ìdákẹ́kọ̀ọ́ ṣe rí gẹ́lẹ́ sì nìyẹn. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kì í lè ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ohun tẹ̀mí tí àkókò tí wọ́n fẹ́ ṣe é tàbí ibi tí wọ́n ti fẹ́ ṣe é kò bá dára. Bí àpẹẹrẹ, ká ló o ti ṣiṣẹ́ àṣekára lóòjọ́, tó o wá jẹun yó dáadáa tán lálẹ́, tó o sì rọra jókòó tó o fẹ̀yìn tì sínú àga tìmùtìmù rẹ tó ò ń wo tẹlifíṣọ̀n, ṣé wà á fẹ́ ṣèkẹ́kọ̀ọ́? Kò dájú. Nígbà náà, kí lojútùú ọ̀rọ̀ náà? Ó ṣe kedere pé a ní láti wá àkókò àti ibi tá a ti máa dá kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú ète pé á fẹ́ jàǹfààní kíkún látinú ìsapá tá a ṣe.

2. Àkókò wo ló sábàá máa ń dára jù fún ìdákẹ́kọ̀ọ́?

2 Ọ̀pọ̀ ló rí i pé àkókò tó dára jù lọ fáwọn láti kẹ́kọ̀ọ́ ni òwúrọ̀ kùtù, ìgbà yẹn ni wọn máa ń pọkàn pọ̀ jù lọ. Àwọn mìíràn máa ń lo àkókò ìjẹun ọ̀sán láti ṣèkẹ́kọ̀ọ́ díẹ̀. Kíyè sí bá a ṣe sọ̀rọ̀ nípa àkókò láti ṣe àwọn nǹkan tẹ̀mí tó ṣe pàtàkì nínú àwọn àpẹẹrẹ tó wà nísàlẹ̀ yìí. Dáfídì ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì kọ̀wé pé: “Mú kí n gbọ́ inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ ní òwúrọ̀, nítorí tí èmi gbẹ́kẹ̀ lé ọ. Mú mi mọ ọ̀nà tí ó yẹ kí n máa rìn, nítorí pé ọ̀dọ̀ rẹ ni mo gbé ọkàn mi sókè sí.” (Sáàmù 143:8) Wòlíì Aísáyà fi irú ìmọrírì kan náà hàn fún ìdákẹ́kọ̀ọ́ nígbà tó sọ pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ tìkára rẹ̀ ti fún mi ní ahọ́n àwọn tí a kọ́, kí n lè mọ bí a ti ń fi ọ̀rọ̀ dá ẹni tí ó ti rẹ̀ lóhùn. Ó ń jí mi ní òròòwúrọ̀; ó ń jí etí mi láti gbọ́, bí àwọn tí a kọ́.” Kókó ibẹ̀ ni pé ó yẹ ká máa kẹ́kọ̀ọ́ ká sì bá Jèhófà sọ̀rọ̀ nígbà tí ọpọlọ wa bá ṣì jí pépé, ì báà jẹ́ láàárọ̀, lọ́sàn-án tàbí lálẹ́.—Aísáyà 50:4, 5; Sáàmù 5:3; 88:13.

3. Ipò wo ló yẹ kéèyàn wà tó bá fẹ́ ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ tó múná dóko?

3 Kókó mìíràn láti mú kí ìdákẹ́kọ̀ọ́ wa gbéṣẹ́ ni pé ká má máa jókòó lórí àga ìgbafàájì tàbí àga ìrọ̀gbọ̀kú. Èyí ò ní jẹ́ ká káràmáásìkí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́, a gbọ́dọ̀ ṣe é tọkàntara ni, bẹ́ẹ̀ kẹ̀, jíjókòó síbi tó tura jù ò ní jẹ́ kí èyí ṣeé ṣe. Ohun mìíràn tó tún dára téèyàn bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ kó sì ṣàṣàrò lé e lórí ni pé kó máà sí ariwo tàbí ohun tó lè pín ọkàn níyà níbi téèyàn wà. Èèyàn ò lè kẹ́kọ̀ọ́ bó ṣe yẹ níbi tí rédíò àti tẹlifíṣọ̀n ti ń dún, táwọn ọmọ sì ń da olúwarẹ̀ láàmú. Nígbà tí Jésù fẹ́ ṣàṣàrò, ńṣe ló lọ síbi tó pa lọ́lọ́. Ó tiẹ̀ tún sọ̀rọ̀ nípa bó ti ṣe pàtàkì tó láti lọ síbi tó pa lọ́lọ́ téèyàn bá fẹ́ gbàdúrà.—Mátíù 6:6; 14:13; Máàkù 6:30-32.

Ìdákẹ́kọ̀ọ́ Tó Ń Jẹ́ Ká Lè Dáhùn Ìbéèrè

4, 5. Àwọn ọ̀nà wo ni ìwé pẹlẹbẹ Béèrè gbà jẹ́ ojúlówó ìrànlọ́wọ́?

4 Èèyàn máa ń gbádùn ìdákẹ́kọ̀ọ́ tó bá lo àwọn ohun èèlò tó ń mú kéèyàn lóye Bíbélì láti fi ṣèwádìí jinlẹ̀ lórí àwọn kókó kan, àgàgà téèyàn bá fẹ́ wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tẹ́nì kan fòtítọ́ inú béèrè. (1 Tímótì 1:4; 2 Tímótì 2:23) Ọ̀pọ̀ àwọn ẹni tuntun ló ń fi ìwé pẹlẹbẹ Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn. a Ìwé yìí ti wà ní ọ̀tàlénígba-ó-lé-kan èdè [261] báyìí. Ìtẹ̀jáde náà rọrùn dáadáa ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ sì ṣe ṣàkó, Bíbélì la gbé e kà látòkèdélẹ̀. Ó ń jẹ́ káwọn tó ń kà á tètè lóye ohun tí Ọlọ́run ń béèrè fún ìjọsìn tòótọ́. Àmọ́, torí pé ó jẹ́ ìwé pẹlẹbẹ, kò ṣeé ṣe láti tú iṣu désàlẹ̀ ìkòkò lórí kókó kọ̀ọ̀kan. Bí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ bá wá béèrè àwọn ìbéèrè nípa àwọn kókó kan tẹ́ ẹ̀ ń jíròrò látinú Bíbélì ńkọ́, báwo lo ṣe lè rí àfikún ìsọfúnni látinú Bíbélì tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti dáhùn àwọn ìbéèrè náà?

5 Ó rọrùn fáwọn tí wọ́n bá ní Watchtower Library on CD-ROM [Àkójọ Ìtẹ̀jáde Society Tá A Ṣe Sórí Ike Pẹlẹbẹ Tá À Ń Fi Kọ̀ǹpútà Lò] lédè wọn láti fi ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà wá omilẹgbẹ ìsọfúnni láìlàágùn. Àmọ́ àwọn tí wọn ò ní àwọn ohun èèlò yìí ńkọ́? Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò kókó méjì tá a gbé yẹ̀ wò nínú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè ká lè rí ọ̀nà tá a lè gbà mú kí òye wa pọ̀ sí i ká sì tún lè dáhùn àwọn ìbéèrè ní kíkún pàápàá nígbà tí ẹnì kan bá béèrè ìbéèrè bíi, Ta ni Ọlọ́run, àti irú èèyàn wo ni Jésù?—Ẹ́kísódù 5:2; Lúùkù 9:18-20; 1 Pétérù 3:15.

Ta Ni Ọlọ́run?

6, 7. (a) Ìbéèrè wo ló jẹ yọ nípa Ọlọ́run? (b) Ohun pàtàkì wo ni àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì kan kùnà láti sọ nínú àsọyé rẹ̀?

6 Ẹ̀kọ́ 2 nínú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè dáhùn ìbéèrè pàtàkì náà, Ta ni Ọlọ́run? Ọ̀ràn pàtàkì tó kan ìjọsìn lèyí o nítorí pé béèyàn ò bá mọ Ọlọ́run tòótọ́ náà tàbí tó ń ṣiyèméjì nípa bóyá Ó wà tàbí kò sí, kò lè ṣeé ṣe fún irú ẹni bẹ́ẹ̀ láti jọ́sìn rẹ̀. (Róòmù 1:19, 20; Hébérù 11:6) Síbẹ̀, onírúurú èrò ló wà lọ́kàn àwọn èèyàn kárí ayé nípa irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́. (1 Kọ́ríńtì 8:4-6) Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sì ni ìdáhùn tí ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn kọ̀ọ̀kan ń fúnni nípa irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́. Ní ti àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, ọ̀pọ̀ ìsìn ló gbà pé Ọlọ́run jẹ́ Mẹ́talọ́kan. Ìlúmọ̀ọ́ká àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì kan ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ àsọyé kan tó pe àkọlé rẹ̀ ní “Ǹjẹ́ O Mọ Ọlọ́run?” àmọ́ kò tiẹ̀ dárúkọ Ọlọ́run lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo nínú gbogbo ọ̀rọ̀ tó sọ, àìmọye ìgbà ló sì fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù. Kò yani lẹ́nu ṣáá, nítorí “Olúwa” èyí tó lè nítumọ̀ méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí kò sì fi orúkọ Ọlọ́run hàn ló wà nínú Bíbélì tí ọkùnrin yìí kà dípò Jèhófà tàbí Yahweh.

7 Àlùfáà yìí sọ kókó pàtàkì kan nù nígbà tó ṣàyọlò Jeremáyà 31:33, 34 tó kà pé: “Nwọn kì yio si kọni mọ ẹnikini ẹnikeji rẹ̀, ati ẹ̀gbọn, aburo rẹ̀ wipe, Mọ̀ Oluwa [lédè Hébérù “Mọ Jèhófà”]: nitoripe gbogbo nwọn ni yio mọ̀ mi, lati ẹni-kekere wọn de ẹni-nla wọn, li Oluwa [lédè Hébérù, Jèhófà] wi.” (Bibeli Mimọ) Kò sí Jèhófà nínú ìtumọ̀ Bíbélì tó lò, ìyẹn orúkọ tó fi Ọlọ́run hàn yàtọ̀.—Sáàmù 103:1, 2.

8. Kí ló sọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì láti máa lo orúkọ Ọlọ́run?

8 Sáàmù 8:9 sọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì láti lo orúkọ Jèhófà, ó ní: “Ìwọ Jèhófà Olúwa wa, orúkọ rẹ mà kún fún ọlá ńlá ní gbogbo ilẹ̀ ayé o!” Fi èyí wéra pẹ̀lú: “Oluwa, Oluwa wa, orukọ rẹ ti ní iyìn to ni gbogbo aiye! (Bibeli Mimọ; tún wo The New American Bible, The Holy Bible—New International Version, Tanakh—The Holy Scriptures) Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, a lè “rí ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an” tá a bá jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa là wá lóye. Ohun èèlò tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wo ló máa lè dáhùn àwọn ìbéèrè wa tẹ́rùntẹ́rùn nípa bí orúkọ Ọlọ́run ṣe ṣe pàtàkì tó?—Òwe 2:1-6.

9. (a) Ìtẹ̀jáde wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàlàyé ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká lo orúkọ Ọlọ́run? (b) Báwo ni ọ̀pọ̀ àwọn olùtumọ̀ Bíbélì ò ṣe bọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run?

9 A lè lọ ṣàyẹ̀wò ìwé pẹlẹbẹ Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, tá a ti tú sí èdè mọ́kàndínláàádọ́rin báyìí. b Apá náà tá a pe àkọlé rẹ̀ ní “Orukọ Ọlọrun—Itumọ ati Pípè Rẹ̀” (ojú ìwé 6 sí 11) fi hàn kedere pé lẹ́tà Hébérù mẹ́rin tó dúró fórúkọ Ọlọ́run fara hàn ní nǹkan bí ìgbà ẹgbẹ̀rún méje nínú Bíbélì Hébérù ìgbàanì. Àmọ́ àwùjọ àlùfáà àtàwọn atúmọ̀ èdè fún ìsìn àwọn Júù àti tàwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti mọ̀ọ́mọ̀ yọ ọ́ kúrò nínú èyí tó pọ̀ jù lọ lára ìtumọ̀ Bíbélì wọn. c Ẹnu wo ni wọ́n á wá fi sọ ọ́ pé àwọn mọ Ọlọ́run àti pé àjọṣe àwọn pẹ̀lú rẹ̀ dán mọ́rán nígbà tí wọn ò fi orúkọ rẹ̀ pè é? Orúkọ rẹ̀ gangan ló ń jẹ́ kéèyàn lóye àwọn ète rẹ̀ àti irú ẹni tó jẹ́. Láfikún sí i, tá ò bá lo orúkọ Ọlọ́run, kí wá làǹfààní apá kan àdúrà àwòkọ́ṣe Jésù tó sọ pé “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́?”—Mátíù 6:9; Jòhánù 5:43; 17:6.

Ta Ni Jésù Kristi?

10. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà mọ̀ nípa ìgbésí ayé Jésù àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́?

10 Àkòrí ẹ̀kọ́ 3 nínú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè ni “Ta Ni Jesu Kristi?” Nínú ìpínrọ̀ mẹ́fà péré tó wà níbẹ̀, ó ṣàlàyé ṣókí nípa Jésù, ibi tó ti wá àti ìdí tó fi wá sáyé. Àmọ́ tó o bá fẹ́ mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀, tá a bá ti mú àwọn ìwé Ìhìn Rere kúrò, kò tún síbòmíràn tó dáa tó tinú ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Ìwé yìí ti wà lédè mọ́kànléláàádọ́fà [111] báyìí. d Ìwé yìí ṣàlàyé ìgbésí ayé Jésù àtàwọn ohun tó kọ́ni lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ àti bí wọ́n ṣe ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra, látinú ohun tí ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sọ. Orí mẹ́tàléláàádóje [133] tó wà níbẹ̀ ṣàlàyé nípa ìgbésí ayé Jésù àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Tó o bá fẹ́ kanlẹ̀ gbé ọ̀ràn Jésù yẹ̀ wò, tó o fẹ́ mọ tìfun-tẹ̀dọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ kan, o lè lọ wo ìwé Insight, Apá Kejì labẹ́ àkọlé náà “Jesus Christ” [Jésù Kristi].

11. (a) Kí ló mú káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yàtọ̀ gédégbé ní ti ohun tí wọ́n gbà gbọ́ nípa Jésù? (b) Kí ni díẹ̀ lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó fi hàn pé irọ́ ni ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan, ìtẹ̀jáde wo ló sì lè ṣèrànwọ́ nípa èyí?

11 Àríyànjiyàn tó wà láàárín àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ni pé bóyá Jésù ni “Ọmọ Ọlọ́run” tàbí “Ọlọ́run Ọmọ.” Tàbí lédè mìíràn, ẹnu wọn ò kò lórí ohun tí ìwé Catechism of the Catholic Church pè ní “olórí àdììtú inú ẹ̀sìn Kristẹni,” ìyẹn ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yàtọ̀ gédégbé sáwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, nítorí a gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ló dá Jésù, pé Jésù kì í ṣe Ọlọ́run. Ìjíròrò kúnná-kúnná nípa kókó yìí wà nínú ìwé pẹlẹbẹ Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, tá a ti tú sí èdè márùndínlọ́gọ́rùn-ún báyìí. e Lára ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó fi hàn pé irọ́ ni ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan rèé: Máàkù 13:32; 1 Kọ́ríńtì 15:24, 28.

12. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká tún gbé yẹ̀ wò?

12 Ìjíròrò tó wà lókè yìí nípa Ọlọ́run àti Jésù Kristi ń jẹ́ ká mọ ọ̀nà tá a lè gbà ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú ète pé a fẹ́ ran àwọn tí ò mọ òtítọ́ inú Bíbélì lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní ìmọ̀ tó péye. (Jòhánù 17:3) Ó dára, ní tàwọn tó ti wá wà nínú ìjọ Kristẹni látọjọ́ pípẹ́ ńkọ́? Pẹ̀lú adúrú ìmọ̀ Bíbélì tí wọ́n ti ní, ṣé ó tún pọn dandan fún wọn láti fiyè sí ọ̀ràn ìdákẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Jèhófà ni?

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká ‘Máa Fiyè sí Ẹ̀kọ́ Wa Nígbà Gbogbo’?

13. Èrò òdì wo làwọn kan lè ní nípa ìdákẹ́kọ̀ọ́?

13 Àwọn kan tí wọ́n ti wà nínú ètò fúngbà pípẹ́ lè dẹni tó bẹ̀rẹ̀ sí gbára lé kìkì ìmọ̀ Bíbélì tí wọ́n ní láwọn ọdún mélòó kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó rọrùn kéèyàn bẹ̀rẹ̀ sí ronú pé: “Kò pọn dandan kí ń máa fi gbogbo ara kẹ́kọ̀ọ́ bíi tàwọn ẹni tuntun o jàre. Ó ṣe tán, láti àwọn ọdún yìí wá kì í ṣe ẹ̀ẹ̀kan kì í ṣe ẹ̀ẹ̀mejì ni mo ti ka Bíbélì jálẹ̀ àtàwọn ìtẹ̀jáde mìíràn tá a gbé karí Bíbélì.” Èyí ò yàtọ̀ sígbà téèyàn bá sọ pé: “Pẹ̀lú adúrú oúnjẹ tí mo ti jẹ sẹ́yìn kò pọn dandan kí n tún máa jẹ oúnjẹ gidi kan mọ́ jàre.” A mọ̀ pé oúnjẹ lọ̀rẹ́ àwọ̀. Kí ará lè mókun kó sì máa ta kébékébé, oúnjẹ déédéé, tó ń ṣara lóore, tí wọ́n sè dáadáa ṣe pàtàkì. Bákan náà ló mà ṣe rí pẹ̀lú ìlera àti okun wa nípa tẹ̀mí o!—Hébérù 5:12-14.

14. Kí nìdí tá a fi ní láti máa fiyè sí ara wa nígbà gbogbo?

14 Nítorí náà, yálà ọjọ́ ti pẹ́ tá a ti jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, gbogbo wa gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún Tímótì, tó ti di alábòójútó tó dàgbà dénú lákòókò yẹn, pé: “Máa fiyè sí ara rẹ nígbà gbogbo àti sí ẹ̀kọ́ rẹ. Dúró nínú nǹkan wọ̀nyí, nítorí nípa ṣíṣe èyí, ìwọ yóò gba ara rẹ àti àwọn tí ń fetí sí ọ là.” (1 Tímótì 4:15, 16) Kí nìdí tó fi yẹ ká fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sọ́kàn? Rántí pé Pọ́ọ̀lù tún sọ pé a ní ìjà kan lòdì sí “àwọn ètekéte [“àrékérekè”] Èṣù” àti “lòdì sí àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú ní àwọn ibi ọ̀run.” Àpọ́sítélì Pétérù sì kìlọ̀ fún wa pé Èṣù ń “wá ọ̀nà láti pani jẹ,” bẹ́ẹ̀ sì rèé ‘ẹni’ tó sọ pé ó wá láti pa jẹ níhìn-ín lè jẹ́ ẹnikẹ́ni nínú wa. Tá a bá lọ jáfara pẹ́nrẹ́n, èyí lè jẹ́ irú àyè tó ń wá láti nawọ́ gán wa.—Éfésù 6:11, 12; 1 Pétérù 5:8.

15. Ohun èèlò ìdáàbòbò tẹ̀mí wo la ní, báwo la sì ṣe lè máa tọ́jú rẹ̀?

15 Níbi tọ́ràn dé yìí, ohun èèlò wo la ní láti fi dáàbò bo ara wa? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rán wa létí pé: “Ẹ gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, kí ẹ bàa lè dúró tiiri ní ọjọ́ burúkú náà, lẹ́yìn tí ẹ bá ti ṣe ohun gbogbo kínníkínní, kí ẹ sì lè dúró gbọn-in gbọn-in.” (Éfésù 6:13) Yàtọ̀ sí pé bí ìhámọ́ra ogun yìí á ṣe gbéṣẹ́ tó sinmi lórí bó bá ṣe jẹ́ ojúlówó tó, ó tún kan bá a ṣe ń tọ́jú rẹ̀ déédéé tó. Nítorí náà, ìhámọ́ra ogun yìí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ ní ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó bá àsìkò mu nínú. Èyí fi hàn pé ká má ṣe jẹ́ kí òye òtítọ́ tí Jèhófà ń fún wa nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti nípasẹ̀ ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye yà wá lẹ́sẹ̀ kan. Dídákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde tá a gbé karí Bíbélì nígbà gbogbo jẹ́ nǹkan pàtàkì tá a nílò láti fi máa tọ́jú ìhámọ́ra ogun wa nípa tẹ̀mí.—Mátíù 24:45-47; Éfésù 6:14, 15.

16. Kí la lè ṣe láti rí i dájú pé “apata ńlá ti ìgbàgbọ́” tá a ní wà nípò tó dáa?

16 Pọ́ọ̀lù sọ ohun kan tó ṣe kókó lára ìhámọ́ra tá a lè fi dáàbò bo ara wa, ìyẹn ni “apata ńlá ti ìgbàgbọ́,” èyí tá a lè fi gbá àwọn ohun ọṣẹ́ oníná Sátánì bí ẹ̀sùn èké àti ẹ̀kọ́ àwọn apẹ̀yìndà dà nù ká sì paná wọn. (Éfésù 6:16) Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì ká ṣàyẹ̀wò bí apata ìgbàgbọ́ wa ṣe lágbára sí ká sì wo àwọn ohun tá à ń ṣe láti tọ́jú rẹ̀ láti fún un lókun sí i. Bí àpẹẹrẹ, o lè bi ara rẹ: ‘Ọ̀nà wo ni mo gbà ń fi Ilé Ìṣọ́ múra ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ sílẹ̀? Ǹjẹ́ mo ti kẹ́kọ̀ọ́ dáadáa dé àyè tí màá fi lè ‘ru àwọn ara sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà’ nípa àwọn ìdáhùn tá a ti ronú sí dáadáa tó ń jáde lẹ́nu mi nípàdé? Ṣé mo máa ń ṣí Bíbélì mi láti ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a kọ láìfa ọ̀rọ̀ inú wọn yọ? Ṣé mo máa ń fún àwọn ẹlòmíràn níṣìírí nípa fífi tìtaratìtara kópa nínú ìpàdé?’ Oúnjẹ líle loúnjẹ wa nípa tẹ̀mí, a ní láti jẹ́ kó dà dáadáa kó lè ṣe wá láǹfààní kíkún.—Hébérù 5:14; 10:24.

17. (a) Májèlé wo ni Sátánì ń lò láti fi ba ipò tẹ̀mí wa jẹ́? (b) Kí la lè fi pa oró májèlé Sátánì?

17 Sátánì mọ àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ ẹ̀dá èèyàn aláìpé, ńṣe ló sì máa ń yọ́ kẹ́lẹ́ ṣọṣẹ́. Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tó gbà ń ṣe iṣẹ́ ibi rẹ̀ ni bó ṣe túbọ̀ ń mú kí àwọn ohun arùfẹ́ ìṣekúṣe sókè di èyí tó wọ́pọ̀ gan-an lórí tẹlifíṣọ̀n, nídìí Íńtánẹ́ẹ̀tì, nínú fídíò àti nínú àwọn ìwé lóríṣiríṣi. Àwọn Kristẹni kan ti jẹ́ kí májèlé yìí ríbi wọlé sáwọn lára, ó sì ti mú kí wọ́n pàdánù àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n ní nínú ìjọ tàbí kó tiẹ̀ yọrí sí ohun tó burú jù bẹ́ẹ̀ lọ pàápàá. (Éfésù 4:17-19) Kí la máa fi pa oró májèlé tẹ̀mí látẹnu Sátánì yìí? A ò gbọ́dọ̀ pa ìdákẹ́kọ̀ọ́ tì, àtàwọn ìpàdé Kristẹni wa àti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Àpapọ̀ èyí ń fún wa lókun láti mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́ ká sì kórìíra ohun tí Ọlọ́run kórìíra.—Sáàmù 97:10; Róòmù 12:9.

18. Báwo ni “idà ẹ̀mí” ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ nínú ìjà tẹ̀mí tá à ń jà?

18 Tá a bá sọ ọ́ dàṣà láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, ìmọ̀ pípéye ti Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run á fún wa lókun dáadáa láti dáàbò bo ara wa, àá tún lè fi “idà ẹ̀mí, èyíinì ni, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,” gbéjà ko Èṣù. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí lọ, ó sì ń gúnni àní títí dé pípín ọkàn àti ẹ̀mí níyà, àti àwọn oríkèé àti mùdùnmúdùn wọn, ó sì lè fi òye mọ ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà.” (Éfésù 6:17; Hébérù 4:12) Tá a bá já fáfá nínú lílo “idà” yìí, tí àdánwò wá dé, kedere la ó máa wo ọ̀fìn tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀ràn tó dà bíi pé ó ń dán gbinrin, tàbí tó tiẹ̀ fani mọ́ra pàápàá. A ó lè tú u fó pé pàkúté panipani tí ẹni ibi náà dẹ sílẹ̀ ni. Ìmọ̀ Bíbélì àti òye tá a ti ní á ràn wá lọ́wọ́ láti kọ ohun búburú sílẹ̀ ká sì ṣe ohun tó dára. Nítorí náà, ó yẹ kí gbogbo wa bi ara wa pé: ‘Ṣé idà mi mú bérébéré ni tàbí ó ti ku bọ̀nnàbọnna? Ṣé ó máa ń ṣòro fún mi láti rántí ẹsẹ Bíbélì tó lè mú kí ọwọ́ ìjà mi túbọ̀ le sí i?’ Ẹ jẹ́ kí ṣíṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ́ wa lára dáadáa ká bàa lè dènà Èṣù.—Éfésù 4:22-24.

19. Àǹfààní wo la lè rí tá ò bá fọ̀rọ̀ ìdákẹ́kọ̀ọ́ ṣeré?

19 Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo, kí ènìyàn Ọlọ́run lè pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.” Tá a bá fi ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì yìí sọ́kàn, àá lè mú kí ipò tẹ̀mí wa lókun sí i, iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa á sì túbọ̀ múná dóko. Àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí wọ́n jẹ́ ẹni tẹ̀mí á ṣe ìjọ láǹfààní gan-an, gbogbo wa á sì lè dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́.—2 Tímótì 3:16, 17; Mátíù 7:24-27.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bó ti sábàá máa ń rí ni pé tí olùfìfẹ́hàn kan bá ti kẹ́kọ̀ọ́ ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tán, ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun ló kàn tó máa fi kẹ́kọ̀ọ́, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ méjèèjì jáde. Àwọn ìsọfúnni tó wà níbẹ̀ á yanjú àwọn ohun tó lè ṣèdíwọ́ fún ìtẹ̀síwájú rẹ̀ nípa tẹ̀mí.

b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde. Àwọn tí ìwé Insight on the Scriptures wà lédè wọn lè wo Apá Kejì, lábẹ́ àkòrí náà “Jehovah.” Fún ìsọfúnni síwájú sí i, wo orí 3 ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun.

c Ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ táwọn ará Sípéènì àtàwọn ará Catalonia ṣe kò dà bíi tiwọn nítorí pé “Yavé,” “Yahveh,” “Jahvè,” àti “Jehová” ni wọ́n fi túmọ̀ lẹ́tà Hébérù mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run.

d Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.

e Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Àwọn ipò wo ló máa ń mú kí ìdákẹ́kọ̀ọ́ ẹni kẹ́sẹ járí?

• Àṣìṣe wo ni ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì ṣe nípa orúkọ Ọlọ́run?

• Àwọn ẹsẹ Bíbélì wo lo máa lò láti fi hàn pé irọ́ ni ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan?

• Kí la gbọ́dọ̀ ṣe láti dáàbò bo ara wa lọ́wọ́ àwọn ètekéte Sátánì, à báà ti jẹ́ Kristẹni tòótọ́ látọjọ́ pípẹ́?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Kí ìdákẹ́kọ̀ọ́ rẹ bàa lè kẹ́sẹ járí, ó yẹ kó o ṣe é níbi tí ohunkóhun ò ti ní pín ọkàn rẹ níyà

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ṣé “idà” rẹ mú bérébéré tàbí ó ti ku bọ̀nnàbọnna?