Dídáwó Títí Àpò Á Fi Gbẹ
Dídáwó Títí Àpò Á Fi Gbẹ
“Ẹ LÈ pè mí ní alágbe o; àgunlá àguntẹ̀tẹ̀. Jésù ni mò ń tọrọ báárà tèmi fún.” Ọ̀rọ̀ tí àlùfáà Pùròtẹ́sítáǹtì kan sọ yẹn jẹ́ ká rí àríyànjiyàn tó ń jà ràn-ìn lórí ọ̀ràn ọ̀nà tówó gbà ń wọlé fún ìsìn. Kìkì ìgbà tí owó tó tówó bá ń wọlé fún àwọn ẹlẹ́sìn làwọn ètò wọn tó máa ń lọ bó ṣe yẹ. Ó di dandan kí wọ́n sanwó oṣù fáwọn òṣìṣẹ́, kí wọ́n kọ́ ilé ìjọsìn kí wọ́n sì máa bójú tó o, wọ́n á sì tún sọ pé àwọn máa náwó lórí iṣẹ́ ìhìn rere tí wọ́n ń ṣe. Báwo ni wọ́n á ṣe wá rí gbogbo owó tí wọ́n nílò yìí?
Ọ̀nà tí ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì gbà ń rí owó tiwọn jẹ́ nípa gbígba ìdá mẹ́wàá. a Ajíhìnrere Norman Robertson sọ pé: “Gbígba ìdá mẹ́wàá ni ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń bójú tó ìjọba Rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Òun ni ọ̀nà tó gbà ń ṣètò ìṣúnná owó Rẹ̀ kí wíwàásù Ìhìn Rere bàa lè ṣeé ṣe.” Kò pẹ́ ọ̀rọ̀ sọ rárá nígbà tó ń rán àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ létí ojúṣe wọn láti máa ṣètọrẹ, ó là á mọ́lẹ̀ pé: ‘Ìdá mẹ́wàá kì í ṣe ohun tó o máa ṣe nítorí pé o lágbára láti ṣe é. Dandan ni. Tó ò bá san ìdá mẹ́wàá, a jẹ́ pé ò ń tàpá sí àṣẹ Ọlọ́run nìyẹn, aláìgbọràn ni ọ́. Owó olówó lo sì ń kó jẹ yẹn.’—Tithing—God’s Financial Plan.
Ó ṣeé ṣe kó o gbà pé ṣíṣe ìtọrẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ ara ìjọsìn Kristẹni. Àmọ́, ǹjẹ́ kì í dá ọ lágara tàbí kó tiẹ̀ máa run ọ́ nínú pàápàá tó bá di tọ́ràn dídáwó títí àpò á fi gbẹ? Ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ọmọ ilẹ̀ Brazil nì, Inácio Strieder dá àwọn ṣọ́ọ̀ṣì lẹ́bi nípa bí wọ́n ṣe ń gba ìdá mẹ́wàá láti “yanjú àwọn ìṣòro ẹ̀sìn wọn” ó sì pe irú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀ ní “èyí tí kò bófin mu, tó jẹ́ àṣìlóye, tó sì yàtọ̀ pátápátá sí ẹ̀kọ́ ìsìn.” Ohun tó kíyè sí ni pé “àwọn aláìníṣẹ́, àwọn opó, àwọn tó ń gbé nínú àwọn ilé hẹ́gẹhẹ̀gẹ àti àwọn tí kò ní làákàyè tó ń rò pé Ọlọ́run ti pa àwọn tì àti pé à ń fagbára mú àwọn láti fún ‘oníwàásù’ lówó tó pọ̀ gan-an débi tí ebi fi wá ń pa ìdílé àwọn.”
O lè ṣe kàyéfì pé: ‘Ǹjẹ́ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó ń fagbára múni san ìdá mẹ́wàá yìí ń fi ohun tí Ìwé Mímọ́ wí sílò? Tàbí ẹ̀rù làwọn ẹ̀sìn kàn ń dá ba àwọn ọmọ ìjọ wọn pé Ọlọ́run á fìyà jẹ wọ́n kí wọ́n lè fọgbọ́n gba gbogbo owó ọwọ́ wọn? Ṣe lóòótọ́ ni Ọlọ́run ní ká dáwó títí àpò wa á fi gbẹ gẹ́gẹ́ bí èrò àwọn kan?’
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìdá mẹ́wàá túmọ̀ sí ìpín mẹ́wàá nínú ìpín ọgọ́rùn-ún gbogbo owó tó ń wọlé fún èèyàn.