Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Fún Ọwọ́ Rẹ Lókun

Fún Ọwọ́ Rẹ Lókun

Fún Ọwọ́ Rẹ Lókun

ÀÌMỌYE ìgbà la sọ̀rọ̀ nípa ọwọ́ nínú Bíbélì. Onírúurú ọ̀nà la sì gbà lo àwọn àkànlò èdè tó ní í ṣe pẹ̀lú ọwọ́. Bí àpẹẹrẹ, ọwọ́ mímọ́ tónítóní túmọ̀ sí àìmọwọ́mẹsẹ̀. (2 Sámúẹ́lì 22:21; Sáàmù 24:3, 4) Líla ọwọ́ túmọ̀ sí fífi ìwà ọ̀làwọ́ hàn sáwọn ẹlòmíràn. (Diutarónómì 15:11; Sáàmù 145:16) Ẹni tó bá fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu la máa ń sọ pé ó fi ọkàn rẹ̀ sí ọwọ́ rẹ̀. (1 Sámúẹ́lì 19:5) Jíjẹ́ kí ọwọ́ ẹni rọ̀ jọwọrọ túmọ̀ sí dídi ẹni tó rẹ̀wẹ̀sì. (2 Kíróníkà 15:7) Fífún ọwọ́ ẹni lókun sì túmọ̀ sí níní okun àti agbára láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ kan.—1 Sámúẹ́lì 23:16.

Ó ti di ọ̀ràn kánjúkánjú fún wa láti fún ọwọ́ wa lókun lóde òní. “Àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” là ń gbé. (2 Tímótì 3:1) Nígbà tí ohun kan bá sì mú wa rẹ̀wẹ̀sì, ohun tó sábà máa ń jẹ́ èrò ẹ̀dá ni pé ká juwọ́ sílẹ̀ bí ẹni pé ọwọ́ wa rọ̀ jọwọrọ nítorí àìsí okun. A sábà máa ń rí àwọn ọ̀dọ́langba tó ń fi ilé ìwé sílẹ̀, àwọn ọkọ máa ń fi ìdílé wọn sílẹ̀, àwọn ìyá náà sì máa ń já àwọn ọmọ wọn sílẹ̀. Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, a ní láti fún ọwọ́ wa lókùn ká lè fara da àwọn àdánwò tá à ń dojú kọ nínú iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run. (Mátíù 24:13) Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò mú ọkàn Jèhófà yọ̀.—Òwe 27:11.

Bí A Ṣe Ń Fún Ọwọ́ Lókun

Àwọn Júù ìgbà ayé Ẹ́sírà ní láti fún ọwọ́ wọn lókun kí wọ́n lè parí tẹ́ńpìlì Jèhófà tí wọ́n ń tún kọ́ ní Jerúsálẹ́mù. Báwo ni wọ́n ṣe fún ọwọ́ wọn lókun? Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Wọ́n sì ń bá a lọ ní fífi ayọ̀ yíyọ̀ ṣe àjọyọ̀ àwọn àkàrà aláìwú fún ọjọ́ méje; nítorí pé Jèhófà mú kí wọ́n máa yọ̀, ó sì yí ọkàn-àyà ọba Ásíríà padà síhà ọ̀dọ̀ wọn láti fún ọwọ́ wọn lókun nínú iṣẹ́ ilé Ọlọ́run tòótọ́, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.” (Ẹ́sírà 6:22) Ó hàn gbangba pé ipá ìṣiṣẹ́ Jèhófà ló mú kí “ọba Ásíríà” fún àwọn èèyàn Ọlọ́run láyè láti padà, Ó sì ru ẹ̀mí àwọn èèyàn náà sókè, tí wọ́n fi parí iṣẹ́ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀.

Nígbà tó yá, tí wọ́n ní láti tún odi Jerúsálẹ́mù kọ́, Nehemáyà fún ọwọ́ àwọn arákùnrin rẹ̀ lókun nítorí iṣẹ́ náà. A kà á pé: “Mo sì ń bá a lọ láti sọ fún wọn nípa ọwọ́ Ọlọ́run mi, bí ó ti dára lára mi, àti nípa ọ̀rọ̀ ọba tí ó sọ fún mi. Látàrí èyí, wọ́n wí pé: ‘Ẹ jẹ́ kí a dìde, kí a sì mọlé.’ Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fún ọwọ́ wọn lókun fún iṣẹ́ rere náà.” Nítorí ọwọ́ wọn tí wọ́n fún lókun yìí, ó ṣeé ṣe fún Nehemáyà àtàwọn Júù ẹlẹgbẹ́ rẹ láti tún àwọn odi Jerúsálẹ́mù kọ́ láàárín ọjọ́ méjìléláàádọ́ta péré!— Nehemáyà 2:18; 6:9, 15.

Bákan náà ni Jèhófà ṣe ń fún ọwọ́ wa lókun láti wàásù ìhìn rere Ìjọba náà. (Mátíù 24:14) Ó ń ṣe bẹ́ẹ̀ nípa ‘fífún wa ní ohun rere gbogbo láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀.’ (Hébérù 13:21) Ó ti fún wa láwọn ohun èlò tó jẹ́ ojúlówó jù lọ. A ní Bíbélì àtàwọn ìwé tá a gbé ka Bíbélì, àwọn ìwé ìròyìn, ìwé pẹlẹbẹ, ìwé àṣàrò kúkúrú, àti ohùn tá a gbà sílẹ̀ àtàwọn fídíò tá à ń lò láti dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn káàkiri ayé. Àní sẹ́, àwọn ìtẹ̀jáde wa ti wà lárọ̀ọ́wọ́tó níye èdè tó lé ní irínwó ó dín ogún [380] báyìí. Láfikún sí i, Jèhófà tún ń lo àwọn ìpàdé ìjọ àtàwọn àpéjọ láti fún wa ní ìlàlóye àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àtọ̀runwá lórí bí a ṣe ń lo àwọn ohun èlò àtàtà wọ̀nyí láti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa láṣeparí.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ń fún ọwọ́ wa lókun láwọn ọ̀nà tó pọ̀ gan-an, ó tún retí pé kí àwa náà sa gbogbo ipá wa. Rántí ohun tí wòlíì Èlíṣà sọ fún Jèhóáṣì Ọba, tó wá sọ́dọ̀ Èlíṣà fún ìrànlọ́wọ́ láti bá àwọn ará Síríà tó wá gbógun tì wọ́n jà. Èlíṣà sọ fún ọba náà pé kó mú àwọn ọfà bíi mélòó kan kó si ta wọ́n sórí ilẹ̀. Ìtàn inú Bíbélì náà sọ fún wa pé: “Ó ta á ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta, ó sì dáwọ́ dúró. Ìkannú ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ sì ru sí i; nítorí náà, ó wí pé: ‘Ẹ̀ẹ̀márùn-ún tàbí mẹ́fà ni ìwọ ì bá ta á! Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, dájúdájú, ìwọ ì bá máa ṣá Síríà balẹ̀ títí yóò fi pa rẹ́, ṣùgbọ́n, nísinsìnyí, ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ni ìwọ yóò ṣá Síríà balẹ̀.’” (2 Àwọn Ọba 13:18, 19) Ìwọ̀nba àṣeyọrí díẹ̀ ni Jèhóáṣì ní nínú ìjà tó bá àwọn Síríà jà nítorí pé kò fi ìtara ṣe é.

Ìlànà kan náà làwa náà ní láti tẹ̀ lé bá a bá fẹ́ ṣe iṣẹ́ tí Jèhófà gbé lé wa lọ́wọ́ láṣeparí. Dípò ká máa ṣàníyàn nípa àwọn ohun tó jẹ́ ìdènà fún wa tàbí nípa bí iṣẹ́ náà ṣe lágbára tó, a gbọ́dọ̀ fi ìtara ṣe é tọkàntọkàn. A gbọ́dọ̀ fún ọwọ́ wa lókun, ká sì máa wo Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́.—Aísáyà 35:3, 4.

Jèhófà Yóò fún Ọwọ́ Wa Lókun

Jèhófà kò ní kùnà láti ràn wá lọ́wọ́ àti láti fún ọwọ́ wa lókun láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Àmọ́ ṣá o, Ọlọ́run kò ní ṣe iṣẹ́ ìyanu, bẹ́ẹ̀ ni kò ní bá wa ṣe gbogbo ohun tó yẹ ká ṣe. Ohun tó retí ni pé ká ṣe ipa tiwa—nípa kíka Bíbélì lójoojúmọ́, mímúra àwọn ìpàdé sílẹ̀ àti wíwá sípàdé déédéé, kíkópa nínú iṣẹ́ ìwàásù ní gbogbo ìgbà tó bá ṣeé ṣe fún wa, àti gbígbàdúrà sí Ọlọ́run nígbà gbogbo. Bá a bá fi tòótọ́tòótọ́ àti taápọntaápọn ṣe ipa tiwa nígbà tá a bá láǹfààní láti ṣe é, Jèhófà yóò fún wa lókun láti ṣe ohun tó retí látọ̀dọ̀ wa.—Fílípì 4:13.

Ronú nípa ọ̀ràn Kristẹni kan tí ìyàwó rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ kú láàárín ọdún kan ṣoṣo. Orí ìbànújẹ́ yẹn ló ṣì wà nígbà tí aya ọmọ rẹ̀ tún fi ọmọ rẹ̀ sílẹ̀ tó sì yà kúrò lọ́nà ìgbésí ayé Kristẹni. Arákùnrin yìí sọ pé: “Mo wá mọ̀ pé a ò lè yan àwọn àdánwò tó máa dé bá wa, bẹ́ẹ̀ náà la ò lè yan àkókò tá a fẹ́ káwọn àdánwò náà dé tàbí bá a ṣe fẹ́ kí wọ́n jìnnà síra tó.” Báwo ló ṣe wáá rí okun tó gbé e ró? Ó ní: “Àdúrà àti ìdákẹ́kọ̀ọ́ ni ohun agbẹ́mìíró tí kò jẹ́ kí n kú. Ìtìlẹ́yìn àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin mi nípa tẹ̀mí sì ti fún mi ní ìtùnú tó pọ̀. Lékè gbogbo rẹ̀, mo ti wá rí bó ti ṣe pàtàkì tó láti ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà kí àwọn ipò lílekoko tó dé.”

Ohun yòówù tó lè ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé rẹ, pinnu láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Jèhófà kó o sì máa lo gbogbo ìpèsè tó ṣe láti fún ọwọ́ rẹ lókun. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò mú kó ṣeé ṣe fún ọ láti ṣe ojúlówó iṣẹ́ ìsìn fún Jèhófà, wàá sì tipa bẹ́ẹ̀ mú ìyìn àti ọlá bá orúkọ rẹ̀ ṣíṣeyebíye.—Hébérù 13:15.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Ìwọ̀nba àṣeyọrí díẹ̀ ni Jèhóáṣì lè ní nínú ìjà tó bá àwọn ará Síríà jà nítorí pé kó fi ìtara ṣe é