Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Gbádùn Ìdákẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Gbádùn Ìdákẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Gbádùn Ìdákẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

“Dájúdájú, èmi yóò máa ṣe àṣàrò lórí gbogbo ìgbòkègbodò rẹ, ṣe ni èmi yóò sì máa dàníyàn nípa ìbálò rẹ.”—SÁÀMÙ 77:12.

1, 2. (a) Èé ṣe tá a fi gbọ́dọ̀ ya àkókò sọ́tọ̀ fún ṣíṣàṣàrò? (b) Kí ló túmọ̀ sí láti ṣàṣàrò?

 GẸ́GẸ́ bí ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi, àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run àti ìdí tá a fi ń jọ́sìn Rẹ̀ lohun tó yẹ kó jẹ wá lógún jù lọ. Àmọ́ lóde òní, ọwọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn dí débi pé wọn kì í ráyè láti ṣàṣàrò. Kòókòó jàn-ánjàn-án nítorí ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, ká máa ra tibí ra tọ̀hún àti ìgbésí ayé jayéjayé ti gbà wọ́n lọ́kàn. Báwo la ṣe lè yẹra fún àwọn nǹkan asán bí èyí? Bá a ṣe ń ya àkókò sọ́tọ̀ lójoojúmọ́ láti ṣe àwọn nǹkan pàtàkì, bí oúnjẹ jíjẹ àti oorun sísùn, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ ká máa wáyè lójoojúmọ́ láti ronú lórí àwọn ìgbòkègbodò Jèhófà àti ìbálò rẹ̀.—Diutarónómì 8:3; Mátíù 4:4.

2 Ǹjẹ́ o tiẹ̀ máa ń ráyè ṣàṣàrò? Kí ló túmọ̀ sí láti ṣàṣàrò? Ìwé atúmọ̀ èdè kan túmọ̀ ọ̀rọ̀ náà sí pé ká pe èrò kan wá sí ọkàn ẹni: kéèyàn ronú jinlẹ̀ nípa nǹkan kan pàápàá ní ìdákọ́ńkọ́, kó fara balẹ̀ dà á rò jinlẹ̀jinlẹ̀. Kí ni èyí túmọ̀ sí fún wa?

3. Kí ni ìtẹ̀síwájú ẹni nípa tẹ̀mí so pọ̀ mọ́?

3 Lákọ̀ọ́kọ́, ó yẹ kó mú wa rántí ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ Tímótì pé: “Láàárín àkókò tí mo ń bọ̀wá, máa bá a lọ ní fífi ara rẹ fún ìwé kíkà ní gbangba, fún ìgbani-níyànjú, fún kíkọ́ni. . . . Máa fẹ̀sọ̀ ronú lórí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá, kí ìlọsíwájú rẹ lè fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn.” Bó ṣe rí gan-an nìyẹn, ó yẹ kéèyàn máa tẹ̀ síwájú, àwọn ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù sì fi hàn pé fífẹ̀sọ̀ ronú lórí nǹkan tẹ̀mí àti ìtẹ̀síwájú ẹni so pọ̀ mọ́ra. Bákan náà lọ̀ràn rí lónìí. Tá a bá fẹ́ gbádùn ìtẹ́lọ́rùn tó so mọ́ ìtẹ̀síwájú nípa tẹ̀mí, a gbọ́dọ̀ máa “fẹ̀sọ̀ ronú” ká sì ‘fi ara wa fún’ àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “pátápátá.”—1 Tímótì 4:13-15.

4. Àwọn ohun wo lo lè lò láti fi máa fẹ̀sọ̀ ronú lórí Ọ̀rọ̀ Jèhófà déédéé?

4 Ìwọ fúnra rẹ àti irú ìgbòkègbodò tí ìdílé rẹ ń ṣe ló máa pinnu àkókò tó dára jù lọ fún ọ láti ṣàṣàrò. Àárọ̀ kùtù làwọn kan máa ń fẹ̀sọ̀ ronú lórí ẹsẹ Bíbélì kan lẹ́yìn tí wọ́n bá ka ìwé pẹlẹbẹ Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́. Kódà, ohun tí nǹkan bí ọ̀kẹ́ kan [20,000] àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni láwọn ilé Bẹ́tẹ́lì kárí ayé kọ́kọ́ ń ṣe láàárọ̀ ni pé wọ́n máa ń fi ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ṣàyẹ̀wò ẹsẹ Bíbélì ti ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Lóòótọ́, nǹkan bí èèyàn mẹ́rin péré nínú ìdílé Bẹ́tẹ́lì ló máa ń sọ̀rọ̀ láràárọ̀, àwọn tó kù máa ń ronú lórí ohun táwọn yẹn sọ àtèyí tí wọ́n kà. Àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn máa ń ronú lórí Ọ̀rọ̀ Jèhófà nígbà tí wọ́n bá ń lọ síbi iṣẹ́. Wọ́n máa ń gbọ́ àwọn kásẹ́ẹ̀tì tá a ka Bíbélì sínú rẹ̀ àtèyí tá a ka ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! sínú rẹ̀, tó wà láwọn èdè kan. Àwọn ìyàwó ilé mìíràn máa ń ṣe tiwọn nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ ilé. Ńṣe ni wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ ṣe bíi ti onísáàmù náà Ásáfù, ẹni tó kọ̀wé pé: “Èmi yóò rántí àwọn iṣẹ́ Jáà; nítorí ó dájú pé èmi yóò rántí ìṣe ìyanu rẹ ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn. Dájúdájú, èmi yóò máa ṣe àṣàrò lórí gbogbo ìgbòkègbodò rẹ, ṣe ni èmi yóò sì máa dàníyàn nípa ìbálò rẹ.”—Sáàmù 77:11, 12.

Níní Ẹ̀mí Tó Tọ́ Ń Ṣàǹfààní

5. Èé ṣe tó fi yẹ kí ìdákẹ́kọ̀ọ́ jẹ wá lógún?

5 Láyé tí tẹlifíṣọ̀n, fídíò àti kọ̀ǹpútà gbòde yìí, àwọn èèyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ kàwé mọ́. Àmọ́ èyí ò gbọ́dọ̀ rí bẹ́ẹ̀ láàárín àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nítorí pé ńṣe ni Bíbélì kíkà dà bí ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń fúnra rẹ̀ bá wa sọ̀rọ̀ tààràtà. Ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn, Jóṣúà di aṣáájú Ísírẹ́lì lẹ́yìn Mósè. Kó tó lè rí ìbùkún Jèhófà gbà, ó ní láti máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fúnra rẹ̀. (Jóṣúà 1:8; Sáàmù 1:1, 2) A ṣì ń béèrè pé kí àwa náà ṣe bẹ́ẹ̀ lónìí. Àmọ́ ìwé kíkà ò rọrùn fáwọn kan, iṣẹ́ ńlá ló sì jẹ́ fún wọn nítorí pé ẹ̀kọ́ wọn nípa ìwé kíkà ò tó nǹkan. Nígbà náà, kí ló lè mú kó máa wù wá láti ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ká sì máa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀? Ìdáhùn ìbéèrè yìí wà nínú ọ̀rọ̀ Sólómọ́nì Ọba tó wà nínú Òwe 2:1-6. Jọ̀wọ́, ṣí Bíbélì rẹ kó o sì ka ẹsẹ wọ̀nyí. A óò wá jíròrò rẹ̀ pa pọ̀.

6. Irú ẹ̀mí wo ló yẹ ká ní sí ìmọ̀ Ọlọ́run?

6 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, a rí ọ̀rọ̀ ìyànjú yìí níbẹ̀ pé: “Ọmọ mi, bí ìwọ yóò bá gba àwọn àsọjáde mi, tí ìwọ yóò sì fi àwọn àṣẹ tèmi ṣúra sọ́dọ̀ rẹ, láti lè dẹ etí rẹ sí ọgbọ́n, kí o lè fi ọkàn-àyà rẹ sí ìfòyemọ̀; . . . ” (Òwe 2:1, 2) Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí? Ẹ̀kọ́ náà ni pé ojúṣe olúkúlùkù wa ni láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kíyè sí orí ọ̀rọ̀ tó gbé e kà. Ó ní “bí ìwọ yóò bá gba àwọn àsọjáde mi.” Ọ̀rọ̀ ńlá ni “bí” tó wà ńbẹ̀ o nítorí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni kì í fẹ́ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní àfiyèsí. Bá a bá fẹ́ gbádùn kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ máa múra tán láti gba ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá sọ ká sì wò wọ́n bí ìṣúra oníyebíye tá ò fẹ́ pàdánù. A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìgbòkègbodò wa ojoojúmọ́ mú kí ọwọ́ wa dí jù tàbí kó gbà wá lọ́kàn jù débi tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ò fi ní wú wa lórí mọ́ tàbí tá a ó fi wá máa ṣiyèméjì nípa rẹ̀.—Róòmù 3:3, 4.

7. Èé ṣe tó fi yẹ ká máa wà láwọn ìpàdé Kristẹni ká sì máa fetí sílẹ̀ bó bá ti lè ṣeé ṣe tó?

7 Ǹjẹ́ a máa ń “dẹ etí” wa tá a sì ń fiyè sílẹ̀ dáadáa nígbà tí wọ́n bá ń ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láwọn ìpàdé Kristẹni wa? (Éfésù 4:20, 21) Ṣé a máa ń ‘fi ọkàn àyà wa’ sí ọ̀nà tí a ó fi ní ìfòyemọ̀? Olùbánisọ̀rọ̀ tó wà lórí pèpéle lè máà jẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dáńtọ́ o, síbẹ̀ ó yẹ ká tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ń sọ. Ní tòdodo, láti lè fiyè sí ọgbọ́n Jèhófà, a gbọ́dọ̀ máa wà láwọn ìpàdé Kristẹni bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. (Òwe 18:1) Ronú nípa ohun ṣíṣeyebíye tí ẹni tí kò wá sípàdé tí wọ́n ṣe ní yàrá òkè ní Jerúsálẹ́mù lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa pàdánù! Òótọ́ ni pé irú ohun àrà tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn kì í ṣẹlẹ̀ láwọn ìpàdé wa lọ́jọ́ òní, àmọ́ Bíbélì tó jẹ́ ọba ìwé wa là ń jíròrò. Nítorí náà, gbogbo ìpàdé ló lè ṣe wá láǹfààní nípa tẹ̀mí tá a bá fetí sílẹ̀ tá a sì ń fojú bá a lọ nínú Bíbélì tiwa náà.—Ìṣe 2:1-4; Hébérù 10:24, 25.

8, 9. (a) Kí ni ìdákẹ́kọ̀ọ́ ń béèrè pé ká ṣe? (b) Báwo lo ṣe lè fi bí wúrà ṣe níye lórí tó wéra pẹ̀lú lílóye ìmọ̀ Ọlọ́run?

8 Ọlọ́gbọ́n ọba náà sọ síwájú sí i pé: “Jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí o bá ké pe òye, tí o sì fọ ohùn rẹ jáde sí ìfòyemọ̀, . . . ” (Òwe 2:3) Irú ẹ̀mí wo làwọn ọ̀rọ̀ yìí ń fi hàn pó yẹ ká ní? Ìtara ọkàn láti lóye Ọ̀rọ̀ Jèhófà ni! Ó túmọ̀ sí pé ká múra tán láti kẹ́kọ̀ọ́ ká bàa lè ní ìfòyemọ̀, èyí táá jẹ́ ká lè mọ ohun tí Jèhófà ń fẹ́. Àmọ́ ṣá o, ṣíṣe èyí ń béèrè ìsapá, èyí ló gbé wa débi àwọn ọ̀rọ̀ àti àkàwé Sólómọ́nì tó kàn.—Éfésù 5:15-17.

9 Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ nìṣó pé: “Bí o bá ń bá a nìṣó ní wíwá a [ìyẹn òye] bí fàdákà, tí o sì ń bá a nìṣó ní wíwá a kiri bí àwọn ìṣúra fífarasin, . . . ” (Òwe 2:4) Èyí jẹ́ ká ronú nípa èrè àwọn awakùsà látayébáyé tí wọ́n ti ń wá fàdákà àti wúrà táráyé kà sí ìṣúra iyebíye . Àwọn èèyàn ti gbẹ̀mí ara wọn nítorí wúrà. Àwọn mìíràn ti fi gbogbo ìgbésí ayé wọn wá a. Àmọ́, báwo ni wúrà tiẹ̀ ṣe níye lórí tó lóòótọ́? Ká ló o sọ nù sínú aṣálẹ̀ kan tí òùngbẹ sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ gbẹ ọ́ pa, èwo lo máa yàn nínú: ègé wúrà ńlá kan àti ife omi kan? Síbẹ̀, ẹ wo báwọn èèyàn ṣe ń fi ìtara wá wúrà tó, tó sì jẹ́ pé ojú táwọn èèyàn fi ń wo ìníyelórí rẹ̀ kò dúró sójú kan! a Nígbà náà, ẹ ò rí i pé ó yẹ ká fi ìtara tó ju èyí lọ wá ọgbọ́n, ìfòyemọ̀, òye Ọlọ́run àti ìfẹ́ rẹ̀! Àwọn àǹfààní wo la sì máa rí nínú wíwá àwọn nǹkan wọ̀nyí?—Sáàmù 19:7-10; Òwe 3:13-18.

10. Kí la lè rí tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

10 Sólómọ́nì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò lóye ìbẹ̀rù Jèhófà, ìwọ yóò sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an.” (Òwe 2:5) Ẹ̀n-ẹ́n, pé àwa ẹ̀dá èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ lè rí “ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an,” ìyẹn Jèhófà Ọba Aláṣẹ Àgbáyé, èyí mà kàmàmà o! (Sáàmù 73:28; Ìṣe 4:24) Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún làwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí àtàwọn ọ̀mọ̀ràn ti ń sapá láti lóye àwọn ohun ìjìnlẹ̀ nípa ìwàláàyè àti ayé òun ìsálú ọ̀run. Àmọ́ ọwọ́ wọn ò tíì tẹ “ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an.” Èé ṣe? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún, wọn ò kà á sí, wọ́n ló ti rọrùn jù, wọn ò sì gbà á, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò sì lóye rẹ̀.—1 Kọ́ríńtì 1:18-21.

11. Kí ni díẹ̀ lára àwọn àǹfààní tó wà nínú dídákẹ́kọ̀ọ́?

11 Ohun amóríyá mìíràn tí Sólómọ́nì tún mẹ́nu bà rèé: “Jèhófà fúnra rẹ̀ ní ń fúnni ní ọgbọ́n; láti ẹnu rẹ̀ ni ìmọ̀ àti ìfòyemọ̀ ti ń wá.” (Òwe 2:6) Jèhófà fúnra rẹ̀ ló ń fi ọgbọ́n, ìmọ̀ àti ìfòyemọ̀ ta ẹnikẹ́ni tó bá wá a lọ́rẹ fàlàlà. Dájúdájú, ó yẹ ká mọrírì ìdákẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gidi gan-an, kódà bó tiẹ̀ gba ìsapá, tó gba ká kára wa lọ́wọ́ kò, kí á sì fàwọn ohun kan rúbọ. Ó ṣe tán, àwọn ẹ̀dà Bíbélì tá a ti tẹ̀ jáde ń bẹ, a ò tún ní ṣẹ̀ṣẹ̀ máa fọwọ́ dà á kọ báwọn kan ṣe ń ṣe láyé ọjọ́un!—Diutarónómì 17:18, 19.

Ká Lè Máa Rìn Lọ́nà Tó Yẹ Jèhófà

12. Kí ló yẹ kó jẹ́ ète tá a fi ń wá ìmọ̀ Ọlọ́run?

12 Kí ló yẹ kó jẹ́ ète tá a fi ń dá kẹ́kọ̀ọ́? Ṣé torí ká lè máa fi hàn pé a sàn ju àwọn mìíràn lọ ni? Ṣé torí káwọn èèyàn lè máa ṣe sàdáńkátà wa ni? Àbí kẹ̀, ṣé ká lè di àká ìmọ̀ Bíbélì ni? Rárá o. Ìdí tá a fi ń dá kẹ́kọ̀ọ́ ni pé ká lè jẹ́ Kristẹni tìrìn-tìrìn, tọ̀rọ̀tọ̀rọ̀, àti nínú ìṣe wa. Ká máa jẹ́ ẹni tó ṣe tán nígbà gbogbo láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ lọ́nà tó ń tuni lára bíi ti Kristi. (Mátíù 11:28-30) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé: “Ìmọ̀ a máa wú fùkẹ̀, ṣùgbọ́n ìfẹ́ a máa gbéni ró.” (1 Kọ́ríńtì 8:1) Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ ní irú ìwà ìrẹ̀lẹ̀ tí Mósè ní nígbà tó sọ fún Jèhófà pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n mọ àwọn ọ̀nà rẹ, kí n lè mọ̀ ọ́, kí n lè rí ojú rere lójú rẹ.” (Ẹ́kísódù 33:13) Bó ṣe rí gan-an nìyẹn o, torí àtilè ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ló ṣe yẹ ká ní ìmọ̀ kì í ṣe láti lè máa fi ṣe fọ́rífọ́rí. A fẹ́ jẹ́ ìránṣẹ́ tó ń rìn lọ́nà tó yẹ Ọlọ́run, tó sì níwà ìrẹ̀lẹ̀. Báwo lọwọ́ wá ṣe lè tẹ àwọn nǹkan wọ̀nyí?

13. Kí ló ṣe kókó téèyàn bá fẹ́ di ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó tóótun?

13 Pọ́ọ̀lù fún Tímótì nímọ̀ràn nípa bó ṣe lè ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, ó sọ pé: “Sa gbogbo ipá rẹ láti fi ara rẹ hàn fún Ọlọ́run ní ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà, aṣiṣẹ́ tí kò ní ohun kankan láti tì í lójú, tí ń fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.” (2 Tímótì 2:15) Gbólóhùn náà “fi ọwọ́ títọ̀nà mú” wá látinú ọ̀rọ̀ ìṣe àkànmórúkọ kan lédè Gíríìkì tó túmọ̀ sí “gígé nǹkan ní ọ̀gbanrangandan,” tàbí ‘láti gé nǹkan tọ́.’ (Kingdom Interlinear) Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀mọ̀wé kan ṣe sọ, èyí ń sọ nípa aránṣọ kan tó ń gé aṣọ sí bátànì kan, tàbí àgbẹ̀ kan tó ń túlẹ̀ tó fẹ́ fi dáko àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Èyí ó wù ó jẹ́, ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ohun tí wọ́n bá ṣe gbọ́dọ̀ gún. Kókó tá a fẹ́ fà yọ ni pé kí Tímótì tó lè di ìránṣẹ́ tó tóótun tí Ọlọ́run sì fọwọ́ sí, ó gbọ́dọ̀ ‘sa gbogbo ipá rẹ̀’ láti rí i dájú pé ohun tó ń kọ́ àwọn èèyàn àti ìwà rẹ̀ wà níbàámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ òtítọ́.—1 Tímótì 4:16.

14. Báwo ló ṣe yẹ kí ìdákẹ́kọ̀ọ́ nípa lórí ìṣe wa àti ọ̀rọ̀ ẹnu wa?

14 Pọ́ọ̀lù tún sọ kókó kan náà yìí nígbà tó rọ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní Kólósè pé kí wọ́n “máa rìn lọ́nà tí ó yẹ Jèhófà fún ète wíwù ú ní kíkún” nípa “síso èso nínú iṣẹ́ rere gbogbo” kí wọ́n sì máa “pọ̀ sí i nínú ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run.” (Kólósè 1:10) Níbí yìí, Pọ́ọ̀lù sọ bí rírìn lọ́nà tó yẹ Jèhófà ṣe tan mọ́ “síso èso nínú iṣẹ́ rere gbogbo” àti ‘pípọ̀ sí i nínú ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run.’ Ká sọ ọ́ lédè mìíràn, kì í ṣe kìkì bá a ṣe mọyì ìmọ̀ ni ohun tí Jèhófà kà sí pàtàkì bí kò ṣe bá a ṣe ń rọ̀ mọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tímọ́tímọ́ nínú ìṣe wa àti ọ̀rọ̀ ẹnu wa. (Róòmù 2:21, 22) Èyí túmọ̀ sí pé ìdákẹ́kọ̀ọ́ wa gbọ́dọ̀ nípa lórí bá a ṣe ń ronú àti bá a ṣe ń hùwà tá a bá fẹ́ kínú Ọlọ́run dùn sí wa.

15. Báwo la ṣe lè dáàbò bo ọkàn wa ká sì máa darí rẹ̀ bó ṣe yẹ?

15 Lónìí, Sátánì ń sapá láti ba ipò tẹ̀mí wa jẹ́ pẹ̀lú bó ṣe ń gbógun ti èrò ọkàn wa. (Róòmù 7:14-25) Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ dáàbò bo ọkàn wà àti èrò inú wa ká sì máa darí rẹ̀ bó ṣe yẹ tá a bá fẹ́ máa rìn lọ́nà tó yẹ Jèhófà Ọlọ́run wa. “Ìmọ̀ nípa Ọlọ́run” ni ohun ìjà tá a ní, ó sì lágbára láti “mú gbogbo ìrònú wá sí oko òǹdè láti mú un ṣègbọràn sí Kristi.” Ìdí rèé tó fi ṣe pàtàkì pé ká túbọ̀ mú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ojoojúmọ́ lọ́kùn-ún-kúndùn bá a ṣe ń fẹ́ láti mú èrò ìmọtara-ẹni-nìkan àti èrò tara kúrò lọ́kàn wa.—2 Kọ́ríńtì 10:5.

Àwọn Ohun Tó Lè Là Wá Lóye

16. Báwo la ṣe lè ṣe ara wa láǹfààní bí Jèhófà ṣe ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́?

16 Ìbùkún nípa tara àti nípa tẹ̀mí ní ń bẹ nínú ẹ̀kọ́ tí Jèhófà ń kọ́ wa. Kì í ṣe ẹ̀kọ́ ìsìn tó máa ń súni, tí kò sì ṣe é mú lò. Ìdí rèé tá a fi kà á pé: “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn.” (Aísáyà 48:17) Báwo ni Jèhófà ṣe ń mú ká rìn ní ọ̀nà rẹ̀ tó ń ṣeni láǹfààní? Lákọ̀ọ́kọ́, a ní Ọ̀rọ̀ rẹ̀ onímìísí, ìyẹn Bíbélì Mímọ́. Òun ni olórí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa, inú rẹ̀ la sì ti máa ń gba ìsọfúnni látìgbàdégbà. Ìdí rèé tó fi dára ká máa ṣí Bíbélì wa láti máa fọkàn bá ohun tí wọ́n bá ń sọ nípàdé lọ. A lè rí àǹfààní ṣíṣe bẹ́ẹ̀ látinú ìtàn ìwẹ̀fà ará Etiópíà tá a kọ sínú Ìṣe, orí 8.

17. Kí ló ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀ràn ìwẹ̀fà ará Etiópíà, kí lèyí sì fi ń yé wa?

17 Ńṣe ni ìwẹ̀fà ará Etiópíà yí padà dẹni tó ń ṣe ẹ̀sìn àwọn Júù. Tọkàntọkàn ló fi gba Ọlọ́run gbọ́, ó sì kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ gan-an. Ó ń ka ìwé Aísáyà lọ́wọ́ nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin tó fi ń rìnrìn àjò lọ ni Fílípì sáré bá a tó sì bi í pé: “Ní ti gidi, ìwọ ha mọ ohun tí o ń kà bí?” Báwo ni ìwẹ̀fà yìí ṣe fèsì? “‘Ní ti tòótọ́, báwo ni mo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀, láìjẹ́ pé ẹnì kan fi mí mọ̀nà?’ Ó sì pàrọwà fún Fílípì pé kí ó gòkè wá, kí ó sì jókòó pẹ̀lú òun.” Ẹ̀mí mímọ́ wá mú kí Fílípì ran ìwẹ̀fà yìí lọ́wọ́ láti lóye àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà. (Ìṣe 8:27-35) Kí lèyí ń fi yé wa? Ó jẹ́ ká mọ̀ pé dídá ka Bíbélì fúnra wa nìkan kò tó tá a bá fẹ́ lóye. Jèhófà ń tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ lo ẹrú olóòótọ́ àti olóye láti mú ká lè lóye Ọ̀rọ̀ rẹ̀ lákòókò tó yẹ. Báwo ló ṣe ń ṣe èyí?—Mátíù 24:45-47; Lúùkù 12:42.

18. Báwo ni ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye ṣe ń ràn wá lọ́wọ́?

18 Òótọ́ ni Bíbélì pe ẹgbẹ́ ẹrú náà ní “olóòótọ́ àti olóye,” àmọ́ Jésù ò sọ pé kò lè ṣàṣìṣe. Àwọn Kristẹni tó jẹ́ èèyàn aláìpé ló wà nínú àwùjọ àwọn ará tó jẹ́ ẹni àmì òróró olóòótọ́ yìí. Bí wọ́n ṣe ní ète tó dáa lọ́kàn tó, wọ́n ṣì lè ṣàṣìṣe, gẹ́gẹ́ bí àwọn èèyàn tó wà nípò wọn ní ọ̀rúndún kìíní náà ti ṣe pẹ̀lú. (Ìṣe 10:9-15; Gálátíà 2:8, 11-14) Síbẹ̀, kò sí kọ̀lọ̀kọ́lọ́ kankan lọ́kàn wọn, Jèhófà sì ń lò wọ́n láti fún wa láwọn ohun èèlò tá a lè fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí ìgbàgbọ́ wa nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn ìlérí rẹ̀ lè dúró sán-ún. Olórí ohun èèlò tí ẹrú náà ti pèsè fún wa láti máa lò fún ìdákẹ́kọ̀ọ́ ni Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Ní bá a ṣe ń wí yìí, ó ti wà lódindi tàbí lápá kan ní èdè méjìlélógójì, a sì ti tẹ mílíọ̀nù ọgọ́rùn-ún ó lé mẹ́rìnlá ẹ̀dà jáde. Báwo la ṣe lè lò ó lọ́nà tó gbéṣẹ́ fún ìdákẹ́kọ̀ọ́ wa?—2 Tímótì 3:14-17.

19. Àwọn ẹ̀ka wo ló wà nínú Bíbélì New World Translation—With References tó lè ranni lọ́wọ́ nígbà ìdákẹ́kọ̀ọ́?

19 Àpẹẹrẹ kan ni ti Bíbélì New World Translation of the Holy Scriptures—With References. Atọ́ka etí ìwé wà nínú rẹ̀, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, atọ́ka kékeré tá a pè ní “Atọ́ka Àṣàyàn Ọ̀rọ̀ Bíbélì” àti “Atọ́ka Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé,” àti Àsomọ́ tó jíròrò kókó ọ̀rọ̀ mẹ́tàlélógójì, ó ní àwòrán ilẹ̀ àti àwòrán atọ́ka nínú. “Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú” tún wà nínú rẹ̀ tó ṣàlàyé ibi tá a ti rí àwọn ìsọfúnni tá a lò fún ìtumọ̀ Bíbélì tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí. Tí Bíbélì yìí bá wà ní èdè tó lè yé ọ, gbìyànjú láti mọ apá kọ̀ọ̀kan rẹ̀ kó o sì máa lò ó. Bó ti wù kó rí, látorí Bíbélì ni ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ wa ti ń bẹ̀rẹ̀. Ìtumọ̀ Ayé Tuntun sì jẹ́ Bíbélì tó gbé orúkọ Jèhófà yọ bó ṣe tọ́ tó sì tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run.—Sáàmù 149:1-9; Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:9, 10.

20. Àwọn ìbéèrè wo nípa ìdákẹ́kọ̀ọ́ ló ń fẹ́ ìdáhùn?

20 Níbi tá a dé yìí, a lè béèrè pé: ‘Ìrànlọ́wọ́ wo la tún nílò láti lóye Bíbélì? Báwo la ṣe lè ṣètò àkókò fún ìdákẹ́kọ̀ọ́? Báwo la ṣe lè mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ wa túbọ̀ múná dóko? Báwo ló ṣe yẹ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ wa kan àwọn ẹlòmíràn?’ Àpilẹ̀kọ tó kàn á jíròrò apá pàtàkì yìí nínú ìtẹ̀síwájú wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Látọdún 1979 ni iye owó wúrà ò ti dúró sójú kan. Àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀rin [$850] dọ́là ni wọ́n ń ta wúrà gíráàmù mọ́kànlélọ́gbọ̀n lọ́dún 1980. Nígbà tó fi máa di 1999, ó ti wálẹ̀ sórí iye tó lé ní àádọ́ta-lé-rúgba dọ́là ó lé méjì [$252].

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Kí ló túmọ̀ sí láti “ṣàṣàrò”?

• Irú ẹ̀mí wo ló yẹ ká ní sí kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

• Kí ni a gbọ́dọ̀ máa lépa tá a bá ń ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́?

• Ohun èèlò wo la ní tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti lóye Bíbélì?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ìdílé Bẹ́tẹ́lì rí i pé fífi ìjíròrò ẹsẹ Bíbélì ṣe ohun àkọ́kọ́ láàárọ̀ ń fúnni lókun nípa tẹ̀mí

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

A lè lo àkókò wa ṣíṣeyebíye lọ́nà tó dára nípa gbígbọ́ àwọn kásẹ́ẹ̀tì tá a ka Bíbélì sínú wọn tá a bá ń rìnrìn àjò

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Àwọn èèyàn ń ṣiṣẹ́ kára fún ọ̀pọ̀ àkókò láti lè rí wúrà. Báwo lo ṣe ń ṣakitiyan tó láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

[Credit Line]

Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda California State Parks, 2002

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Bíbélì jẹ́ ìṣúra tó lè mú wa ní ìyè àìnípẹ̀kun