Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ibi Tá A Ti Ń Ṣiṣẹ́ Míṣọ́nnárì Di Ilé Wa

Ibi Tá A Ti Ń Ṣiṣẹ́ Míṣọ́nnárì Di Ilé Wa

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Ibi Tá A Ti Ń Ṣiṣẹ́ Míṣọ́nnárì Di Ilé Wa

GẸ́GẸ́ BÍ DICK WALDRON ṢE SỌ Ọ́

Ọ̀sán ọjọ́ Sunday kan ni ní September 1953. Àlejò ṣì ni wá ní Gúúsù Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà (tó di Nàmíbíà báyìí). Kò tíì tó ọ̀sẹ̀ kan tá a dé orílẹ̀-èdè náà, a sì ń múra àtiṣe ìpàdé fún gbogbo èèyàn ní ìlú Windhoek tí í ṣe olú ìlú ibẹ̀. Kí ló mú wa ti iyànníyàn Ọsirélíà wá sí ilẹ̀ Áfíríkà yìí? Iṣẹ́ míṣọ́nnárì tó ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ló gbé èmi, ìyàwó mi àti ọ̀dọ́bìnrin mẹ́ta débẹ̀.—Mátíù 24:14.

ILẸ̀ Ọsirélíà lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún ni ìgbésí ayé mi ti bẹ̀rẹ̀, lọ́dún mánigbàgbé nì, ìyẹn ọdún 1914. Ìgbà ọ̀dọ́langba mi bọ́ sí àkókò Ìlọsílẹ̀ Gígadabú Nínú Ọrọ̀ Ajé tó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1929, ló bá di pé kí èmi náà máa ṣe ipa tèmi nínú ìpèsè jíjẹ mímu fún ìdílé wa. Kò síṣẹ́, àmọ́ ọgbọ́n tí mo ta ni pé mo máa ń ṣọdẹ ehoro kiri, ṣé wọ́n kúkú pọ̀ ní Ọsirélíà. Bẹ́ẹ̀ ló di pé ọ̀kan lára oúnjẹ tí mò ń pèsè fún ìdílé wa látìgbàdégbà ni ẹran ehoro.

Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì fi máa bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1939, mo ti ríṣẹ́ sí iléeṣẹ́ ọkọ̀ akérò láàárín ìlú Melbourne. Nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [700] ọkùnrin ló máa ń gbaṣẹ́ lọ́wọ́ ara wọn nídìí àwọn ọkọ̀ yìí. Oríṣiríṣi àwọn awakọ̀ àtàwọn kọ̀ǹdọ́ ni mo máa ń bá pàdé lásìkò iṣẹ́. Mo sábà máa ń bi ẹnì kọ̀ọ̀kan pé “Ẹ̀sìn wo lò ń ṣe?” tí màá sì ní kí wọ́n ṣàlàyé ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fún mi. Ẹnì kan ṣoṣo tó dáhùn àwọn ìbéèrè mi lọ́nà tó tẹ́ mi lọ́rùn jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó ṣàlàyé nípa Párádísè ilẹ̀ ayé kan tí Bíbélì wí fún mi, ìyẹn ibi táwọn ẹ̀dá èèyàn tó bẹ̀rù Ọlọ́run á máa gbé títí láé.—Sáàmù 37:29.

Láàárín àkókò yìí náà ni màmá mi pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọ̀pọ̀ ìgbà tí mo bá tibi iṣẹ́ alẹ́ dé, oúnjẹ mi á ti wà nílẹ̀, pẹ̀lú ẹ̀dà kan ìwé ìròyìn Consolation (tá à ń pè ní Jí! báyìí). Ohun tí mò ń kà wù mí gan-an. Bí àkókò ti ń lọ, mo sọ lọ́kàn ara mi pé ìsìn tòótọ́ rèé, mo bẹ̀rẹ̀ sí dara pọ̀ mọ́ àwọn ará nínú ìjọ, mo sì ṣèrìbọmi ní May 1940.

Ní Melbourne, ilé kan wà fáwọn aṣáájú ọ̀nà, nǹkan bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ló sì ń gbébẹ̀. Mo lọ ń gbébẹ̀ pẹ̀lú wọn. Ojoojúmọ́ ni mo máa ń tẹ́tí sáwọn ìrírí alárinrin tí wọ́n ní nínú iṣẹ́ ìwàásù, ó sì wu èmi náà pé kí n di aṣáájú ọ̀nà. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, mo kọ̀wé béèrè pé mo fẹ́ wọ iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà. Wọ́n fọwọ́ sí ìbéèrè mi wọ́n sì pè mí láti wá sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ọsirélíà. Bi mo ṣe di ọ̀kan lára ìdílé Bẹ́tẹ́lì nìyẹn.

Ẹ̀wọ̀n àti Ìfòfindè

Ọ̀kan lára iṣẹ́ tí mo ṣe ní Bẹ́tẹ́lì ni iṣẹ́ pákó lílà. A máa ń la igi gẹdú tá a fi ń ṣe èédú tí ọkọ̀ wa ń lò. Èyí làwọn ọkọ̀ tó wà ní ọ́fíìsì ẹ̀ka wa ń lò nítorí pé ogun tó ń lọ lọ́wọ́ mú kí epo bẹntiróòlù wọ́n lóde. Àwa méjìlá là ń ṣiṣẹ́ níbi tá a ti ń la pákó yìí, gbogbo wa pátá ló sì jẹ́ ẹni tí ìjọba pàṣẹ pé kó wọṣẹ́ ológun. Láìpẹ́, wọ́n ní ká lọ fẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà mẹ́fà jura fún kíkọ̀ tá a kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun nítorí ohun tí Bíbélì sọ. (Aísáyà 2:4) Wọ́n kó wa lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ láti ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó. Ẹ ò béèrè pé irú iṣẹ́ wo ni wọ́n fún wa níbẹ̀? Pákó ni wọ́n sọ pé ká máa là o, iṣẹ́ tá a ti dọ̀gá nínú rẹ̀ ní Bẹ́tẹ́lì!

A ṣe dáadáa nídìí pákó lílà yìí débi pé alákòóso ọgbà ẹ̀wọ̀n náà fún wa ní Bíbélì kan àtàwọn ìtẹ̀jáde Bíbélì wa, bẹ́ẹ̀ wọ́n ti ṣòfin pé wọn ò gbọ́dọ̀ fún wa lóhun tó jọ bẹ́ẹ̀. Àkókò yìí ni mo kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì kan nípa àjọṣe ẹ̀dá. Nígbà tí mo ń ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì, arákùnrin kan wà tọ́rọ̀ èmi rẹ̀ ò wọ̀ rárá. Ìwà àwa méjèèjì ò bára mu páàpáà. Àmọ́, ǹjẹ́ ẹ mọ ẹni tí wọ́n fi èmi rẹ̀ sínú yàrá kan náà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n? Arákùnrin yẹn gan-an ni. A wá ní àkókò báyìí láti mọ̀wà ara wa dáadáa, ọ̀rẹ́ àwa méjèèjì wá wọ̀ gan-an.

Kò pẹ́ sígbà yìí ni wọ́n fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ọsirélíà. Gbogbo owó wa ni wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé, owó tó wà lọ́wọ́ àwọn ará tó wà ní Bẹ́tẹ́lì ò sì tó nǹkan mọ́. Lọ́jọ́ kan, ọ̀kan nínú wọn wá bá mi ó sì sọ pé: “Dick, mo fẹ́ lọ wàásù nígboro àmọ́ mi ò ní bàtà, bàtà iṣẹ́ nìkan ni mo ní.” Inú mi dùn láti ràn án lọ́wọ́, ó sì wọ bàtà mi lọ sígboro.

Nígbà tó yá, ìròyìn kàn wá pé àwọn ọlọ́pàá ti mú un wọ́n sì ti sọ ọ́ sẹ́wọ̀n nítorí pé ó ń wàásù. Mo bá kọ ìwé kékeré kan sí i pé: “Pẹ̀lẹ́ o, mo bá ọ kẹ́dùn. Inú mi dùn pé kì í ṣe èmi ló ṣẹlẹ̀ sí.” Àmọ́ kò pẹ́ tọ́wọ́ fi ba èmi náà tí wọ́n sì jù mí sẹ́wọ̀n lẹ́ẹ̀kejì nítorí àìdásí tọ̀túntòsì mi. Lẹ́yìn tí mo tẹ̀wọ̀n dé, wọ́n ní kí n máa bójú tó oko tá a ti ń pèsè nǹkan jíjẹ fún ìdílé Bẹ́tẹ́lì. Lákòókò yìí, a ti jàre ẹjọ́ ní kóòtù, wọ́n sì ti gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Mo Gbé Ajíhìnrere Onítara Níyàwó

Lákòókò tí mo fi ń ṣiṣẹ́ ní oko, mo bẹ̀rẹ̀ sí ronú nípa ìgbéyàwó, ọmọbìnrin aṣáájú ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Coralie Clogan sì wù mí láti fẹ́. Ìyá ìyá Coralie lẹni àkọ́kọ́ tó nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn Bíbélì nínú ìdílé wọn. Nígbà tó fẹ́ kú, ó sọ fún ìyá Coralie tó ń jẹ́ Vera, pé: “Tọ́ àwọn ọmọ rẹ láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run kí wọ́n sì sìn ín o, ìyẹn á jẹ́ ká pàdé nínú Párádísè ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ kan.” Nígbà tó yá, tí aṣáájú ọ̀nà kan wá sílé Vera tó sì fún un ni ìtẹ̀jáde Millions Now Living Will Never Die, [Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Tó Ń Bẹ Láàyè Báyìí Kì Yóò Kú Láéláé] ó bẹ̀rẹ̀ sí lóye àwọn ọ̀rọ̀ yẹn. Ìwé pẹlẹbẹ náà jẹ́ kó yé Vera pé ète Ọlọ́run ni pé kí ẹ̀dá èèyàn gbádùn ìgbésí ayé nínú Párádísè ilẹ̀ ayé. (Ìṣípayá 21:4) Ó ṣèrìbọmi láàárín ọdún 1930 sí 1934, ó sì ran àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, ìyẹn Lucy, Jean àti Coralie, lọ́wọ́ láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí màmá rẹ̀ ṣe sọ fún un. Àmọ́ bàbá Coralie ta ko ẹ̀sìn tí ìdílé rẹ̀ ń ṣe yìí gan-an, gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ pé ó lè ṣẹlẹ̀ láàárín ìdílé.—Mátíù 10:34-36.

Ilé olórin ni ìdílé Clogan, ọmọ kọ̀ọ̀kan ló ní ohun èèlò orin tó mọ̀ ọ́n lò. Coralie ní tiẹ̀ máa ń ta gòjé. Ó gba ìwé ẹ̀rí dípúlọ́mà nínú orin lọ́dún 1939 nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Ogun Àgbáyé Kejì tó bẹ́ silẹ̀ mú kí Coralie wá bẹ̀rẹ̀ sí ronú jinlẹ̀jinlẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la rẹ̀. Ó ti tó àkókò fún un láti pinnu bó ṣe fẹ́ lo ìgbésí ayé rẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́, ó ṣeé ṣe fún un láti di oníṣẹ́ orin. Kódà, Ẹgbẹ́ Akọrin Ìlú Melbourne ti ní kó máa bọ̀ nínú ẹgbẹ́ àwọn. Bẹ́ẹ̀ tún rèé, ó lè ṣeé ṣe fún un láti lo àkókò rẹ̀ fún iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ ti wíwàásù ìhìn Ìjọba Ọlọ́run. Lẹ́yìn tó ro ọ̀rọ̀ yìí sọ́tùn-ún sósì, Coralie àtàwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ méjì tó kù ṣèrìbọmi lọ́dún 1940 wọ́n sì gbára dì láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere alákòókò kíkún.

Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Coralie pinnu pé òun á ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ni arákùnrin kan tó ní ẹrù iṣẹ́ pàtàkì, ìyẹn Lloyd Barry láti ẹ̀ka Ọsirélíà wá bá a. Arákùnrin yìí di ọ̀kan lára Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà tó yá. Bó ṣe sọ àsọyé kan tán nílùú Melbourne ló bá sọ fún Coralie pé: “Mò ń padà sí Bẹ́tẹ́lì nìyẹn o. O ò ṣe kúkú bá mi wọ ọkọ̀ ojú irin padà kí ìwọ náà sì di ọ̀kan lára ìdílé Bẹ́tẹ́lì?” Ó sì fínnúfíndọ̀ tẹ́wọ́ gba ìkésíni yìí.

Coralie àtàwọn arábìnrin mìíràn nínú ìdílé Bẹ́tẹ́lì ṣe gudugudu méje nídìí rírí i pé àwọn ará ní Ọsirélíà rí àwọn ìtẹ̀jáde Bíbélì gbà lákòókò tí wọ́n fòfin de iṣẹ́ wa lásìkò tí ogun fi ń jà. Kódà, àwọn ló ń tẹ èyí tó pọ̀ jù lọ nínú ìwé tá à ń tẹ̀, lábẹ́ àbójútó arákùnrin Malcolm Vale. Wọ́n tẹ ìwé The New World àti ìwé Children, wọ́n sì di ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn pọ̀, ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ kò ṣàì jáde ní gbogbo ohun tó lé ní ọdún méjì tí wọ́n fi fòfin de iṣẹ́ wa.

Odidi nǹkan bí ìgbà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún la ṣí kúrò níbi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tá a ti ń tẹ̀wé láti sá fún àwọn ọlọ́pàá. Lákòókò kan, àjàalẹ̀ ilé kan la ti ń tẹ àwọn ìtẹ̀jáde tó dá lórí Bíbélì, tí a sì ń tẹ oríṣi ìwé mìíràn níwájú ilé yìí láti fi ṣe arúmọjẹ. Arábìnrin tó wà ní yàrá ìgbàlejò wa lè tẹ bọ́tìnnì kan níbẹ̀ tó máa lu aago kan ní àjàalẹ̀ lọ́hùn-ún láti ta wọ́n lólobó pé ewu ń bọ̀, káwọn arábìnrin tó wà níbẹ̀ lè tọ́jú àwọn ìtẹ̀jáde wa kí ẹnikẹ́ni tó débẹ̀ láti yẹ ibẹ̀ wò.

Ní àkókò kan tí wọ́n wá yẹ ibẹ̀ wò, jìnnìjìnnì bo díẹ̀ lára àwọn arábìnrin yìí nígbà tí wọ́n rí i pé ẹ̀dà kan Ilé Ìṣọ́ wà ní gbangba lórí tábìlì. Ọlọ́pàá kan wọlé, orí Ilé Ìṣọ́ yìí gan-an ló sì gbé àpò rẹ̀ sí tó fi bẹ̀rẹ̀ sí wá gbogbo ilé náà. Nígbà tí kò rí nǹkan kan, ó gbé àpò rẹ̀ ó sì jáde!

Lẹ́yìn tí wọ́n gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí iṣẹ́ wa tí wọ́n sì dá ọ́fíìsì ẹ̀ka wa padà fún àwọn ará wa, ọ̀pọ̀ wọn ló láǹfààní láti lọ ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà àkànṣe. Ìgbà yẹn ni Coralie yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti lọ sí Glen Innes. Mo lọ bá a níbẹ̀ lẹ́yìn ìgbéyàwó wa ní January 1, 1948. Nígbà tá a máa fibẹ̀ sílẹ̀, ìjọ kan tó ń ṣe dáadáa ti wà níbẹ̀.

Ìlú Rockhampton la tún yàn fún wa, àmọ́ a ò rí ilé tá a máa gbé níbẹ̀. La bá pàgọ́ síbì kan tó tẹ́jú nínú oko olùfìfẹ́hàn kan. Oṣù mẹ́sàn-án gbáko la fi gbénú àgọ́ náà. Ì bá kúkú jù bẹ́ẹ̀ lọ, àmọ́ nígbà tó di àkókò òjò, ìjì ńlá kan jà ó sì gbọn àgọ́ náà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, ọ̀wààrà òjò sì wá wọ́ gbogbo rẹ̀ lọ.

A Yanṣẹ́ fún Wa Nílẹ̀ Òkèèrè

Nígbà tá a wà nílùú Rockhampton, a rí ìkésíni kan gbà láti wá sí kíláàsì kọkàndínlógún ti ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead, láti wá gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Báyìí ni wọ́n rán wa lọ sí ibi tí wọ́n ń pè ní Gúúsù Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà nígbà yẹn, lẹ́yìn tá a kẹ́kọ̀ọ́ yege lọ́dún 1952.

Àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì ò jáfara rárá, láti jẹ́ ká mọ bí iṣẹ́ míṣọ́nnárì wa ṣe rí lára àwọn. Fún odidi ọ̀sẹ̀ mẹ́fà gbáko, gbogbo ọjọ́ Sunday ni wọ́n máa ń wàásù fáwọn ọmọ ìjọ nínú ṣọ́ọ̀ṣì wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ gbà wá láyè. Wọ́n sọ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ ká wọlé wọn kí wọ́n má sì gbà wá láyè láti ka Bíbélì fún wọn nítorí èyí lè ṣì wọ́n lọ́nà. A fi ìtẹ̀jáde púpọ̀ sóde ní àdúgbò kan, àmọ́ ńṣe ni aṣáájú ìjọ níbẹ̀ ń tẹ̀ lé wa láti ojúlé dé ojúlé tó sì ń gba àwọn ìtẹ̀jáde náà lọ́wọ́ àwọn èèyàn. Lọ́jọ́ kan, à ń bá òjíṣẹ́ yìí jíròrò nínú yàrá ìkàwé rẹ̀, ibẹ̀ la ti rí i pé iye ìwé wa tó wà lọ́wọ́ rẹ̀ kúrò ní díẹ̀.

Kò pẹ́ rárá táwọn aláṣẹ ìlú náà fi bẹ̀rẹ̀ sí fi hàn pé inú àwọn ò dùn sí iṣẹ́ tá à ń ṣe. Ó dájú pé àwọn àlùfáà ló kó sí wọn lórí tí wọ́n fi ń fura pé a ní àjọṣe kan pẹ̀lú ìjọba Kọ́múníìsì. Ni wọ́n bá sọ pé ká wá tẹ̀ka, wọ́n sì fọ̀rọ̀ wá díẹ̀ lára àwọn tá a wàásù fún lẹ́nu wò. Pẹ̀lú gbogbo àtakò yìí, ńṣe ni iye èèyàn tó ń wá sípàdé wa ń lọ sókè.

Látìgbà tá a ti dé àgbègbè yìí ló ti ń wù wá gan-an pé ká tan ìhìn Bíbélì kálẹ̀ láàárín àwọn ọmọ ìbílẹ̀ ibẹ̀, ìyẹn ẹ̀yà Ovambo, Herero àti Nama. Àmọ́, èyí kò rọrùn rárá. Lákòókò tá à ń sọ yìí, Gúúsù Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà wà lábẹ́ àkóso ìjọba kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ti Gúúsù Áfíríkà. Aláwọ̀ funfun ni wá, wọn ò sì gbà wá láyè láti lọ wàásù lágbègbè àwọn aláwọ̀ dúdú láìjẹ́ pé a gbàwé àṣẹ ìjọba. Gbogbo ìgbà là ń béèrè fún ìwé àṣẹ yìí, àmọ́ àwọn aláṣẹ kọ̀ wọn ò fún wa.

Lẹ́yìn tá a lo ọdún méjì gbáko níbi iṣẹ́ wa nílẹ̀ òkèèrè, ohun tá ò retí ṣẹlẹ̀. Coralie fẹ́ra kù. A wá bí Charlotte, ọmọ wa obìnrin ní October 1955. Lóòótọ́ a ò lè máa bá iṣẹ́ míṣọ́nnárì wa lọ mọ́, mo bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ àbọ̀ọ̀ṣẹ́ mo sì ń bá iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà lọ fúngbà díẹ̀.

Àdúrà Wa Gbà

Ìpèníjà mìíràn dé lọ́dún 1960. Coralie gba lẹ́tà kan láti ilé pé màmá rẹ̀ ṣàìsàn tó le gan-an pé tí kò bá sì wálé, ó lè máà rí màmá rẹ̀ mọ́ o. La bá ń múra láti kúrò ní Gúúsù Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà ká sì padà sí Ọsirélíà. Àmọ́ ohun kan ṣẹlẹ̀, lọ́sẹ̀ tá a fẹ́ kúrò gan-an ni mo rí ìwé àṣẹ gbà látọ̀dọ̀ ìjọba pé a lè wọ ìlú Katutura tó jẹ́ tàwọn aláwọ̀ dúdú. Kí wá ni ṣíṣe báyìí? Ṣé ká dá ìwé àṣẹ yìí padà ni lẹ́yìn tá a ti ṣe wàhálà nítorí rẹ̀ fún odidi ọdún méje? Ó rọrùn láti ronú pé àwọn ẹlòmíràn á bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà níbi tá a bá a dé. Àmọ́, ṣé ẹ̀bùn kọ́ lèyí jẹ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà, ìyẹn ìdáhùn sí àdúrà tá a ti ń gbà?

Mi ò jáfara rárá láti pinnu ohun tí màá ṣe. Mo pinnu pé èmi ò ní kúrò ní orílẹ̀-èdè náà, nítorí tí gbogbo wa bá lọ sí Ọsirélíà, gbogbo wàhálà tá a ti ṣe láti gba ìwé àṣẹ ìgbélùú á já sásán. Nígbà tó di ọjọ́ kejì, mo wọ́gi lé ìrìn àjò tèmi mo sì fi Coralie àti Charlotte lé ọkọ̀ òkun pé kí wọ́n máa lọ sí Ọsirélíà fún ìsinmi ọlọ́jọ́ gbọọrọ.

Lẹ́yìn tí wọ́n lọ, mo bẹ̀rẹ̀ sí wàásù fáwọn èèyàn tó wà nílùú aláwọ̀ dúdú. Wọ́n fìfẹ́ hàn gan-an ni. Nígbà tí Coralie àti Charlotte fi máa padà dé, ọ̀pọ̀ èèyàn láti ìlú àwọn aláwọ̀ dúdú ti ń wá sípàdé.

Mo ti wá ní ọkọ̀ ògbólógbòó kan lákòókò tí mò ń wí yìí, òun sì ni mo fi ń gbé àwọn olùfìfẹ́hàn wá sípàdé. Mó máa ń pààrà bí ẹ̀ẹ̀mẹrin tàbí ẹ̀ẹ̀marùn-ún láti gbé àwọn èèyàn wá sípàdé, mo sì máa ń kó èèyàn méje sí mẹ́sàn-án lẹ́ẹ̀kan. Bí ẹni tó gbẹ̀yìn bá ti bọ́ọ́lẹ̀ nínú ọkọ̀, Coralie á bẹ̀rẹ̀ sí dápàárá pé: “Èèyàn mélòó ló ṣì kù lábẹ́ ìjókòó ọkọ̀?”

Kí iṣẹ́ ìwàásù wa lè gbéṣẹ́ sí i, a nílò àwọn ìwé lédè ìbílẹ̀ àwọn èèyàn yìí. Èyí fún mi láǹfààní àkànṣe láti ṣètò bá a ṣe máa tú ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Igbesi-aye ninu Aye Titun alalaafia kan, sí èdè mẹ́rin tí wọ́n ń sọ níbẹ̀, ìyẹn: Herero, Nama, Ndonga àti Kwanyama. Àwọn ọ̀mọ̀wé tá à ń bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì làwọn olùtumọ̀ wọ̀nyí, àmọ́ ńṣe ni mo jókòó tì wọ́n tá a jọ ń ṣiṣẹ́ náà pa pọ̀ kí n lè rí sí i pé wọ́n tú gbólóhùn kọ̀ọ̀kan bó ṣe yẹ. Ọ̀wọ́ ọ̀rọ̀ tó wà nínú èdè Nama kò tó nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, mo fẹ́ kí wọ́n túmọ̀ kókó náà pé: “Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, Ádámù jẹ́ èèyàn pípé.” Olùtumọ̀ náà fọwọ́ họrí títí ó sì sọ pé òun ò rántí ọ̀rọ̀ tí èdè Nama ń lò fún ọ̀rọ̀ náà “pípé.” Ẹ̀ẹ̀kan náà ló sọ pé: “Ẹ̀n-hẹ́n-ẹ̀n, mo ti mọ ohun tá a máa pè é. Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, Ádámù dà bí èso peach tó ti pọ́n.”

Ibi Tá A Ti Ń Sìn Tẹ́ Wa Lọ́rùn

Ọdún mọ́kàndínláàádọ́ta ti kọjá tá a ti dé orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń pè ní Nàmíbíà báyìí. A ò nílò àtigbàwé àṣẹ láti wọ̀lùú àwọn aláwọ̀ dúdú mọ́. Ìjọba tuntun tí kò lo òfin kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà mọ́ ló ń ṣàkóso ilẹ̀ Nàmíbíà báyìí. Lónìí, ìjọ mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló wà ní Windhoek, inú Gbọ̀ngàn Ìjọba tó tuni lára ni wọ́n sì ti ń ṣèpàdé.

Gbogbo ìgbà la máa ń rántí ọ̀rọ̀ tá a gbọ́ ní Gílíádì pé: “Ẹ fi ibi tá a yanṣẹ́ sí fún yín nílẹ̀ òkèèrè ṣelé.” Pẹ̀lú ọ̀nà tí Jèhófà gbé àwọn ọ̀ràn wa gbà, ó dá wa lójú pé ìfẹ́ rẹ̀ ni pé ká fi ilẹ̀ òkèèrè yìí ṣelé. A nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa, pẹ̀lú àṣà ìbílẹ̀ olúkúlùkù wọn tó fani mọ́ra. A ti bá wọn yọ̀ lọ́jọ́ ayọ̀, a sì tún bá wọn kédàárò lọ́jọ́ ìṣòro. Lára àwọn ẹni tuntun ìgbà yẹn tá a máa ń fún mọ́nú ọkọ̀ wa láti gbé wọn wá sípàdé ti di òpómúléró nínú ìjọ wọn báyìí. Nígbà tá a dé sí ilẹ̀ tó pọ̀ lọ rabidun yìí lọ́dún 1953, àwọn akéde tó ń wàásù ìhìn rere náà níbẹ̀ ò tó mẹ́wàá. Látorí ìbẹ̀rẹ̀ kékeré yẹn, iye wa ti lọ sókè ó sì ti lé ní ẹgbẹ̀fà [1,200]. Jèhófà ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ o, ó ti mú kí ìdàgbàsókè bá ibi tí àwa àtàwọn mìíràn ti ‘gbìn tá a sì bomi rin.’—1 Kọ́ríńtì 3:6.

Tí èmi àti Coralie bá bojú wẹ̀yìn wo ọ̀pọ̀ ọdún tá a ti fi sìn ní Ọsirélíà lákọ̀ọ́kọ́ àti ní Nàmíbíà báyìí, inú wa máa ń dùn, ọkàn wa sì máa ń balẹ̀ gan-an. Ìrètí àti àdúrà wa ni pé kí Jèhófà túbọ̀ máa fún wa ní àlékún okun láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ nísinsìnyí àti títí láé.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26, 27]

Ìgbà tá à ń ṣí lọ síbi iṣẹ́ àyànfúnni wa nílùú Rockhampton, ní Ọsirélíà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

A wà nínú ọkọ̀ òkun nígbà tá à ń lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Wíwàásù ní Nàmíbíà fún wa láyọ̀ gan-an