Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Lórí Tábìlì Ọ̀gákọ̀

Lórí Tábìlì Ọ̀gákọ̀

Lórí Tábìlì Ọ̀gákọ̀

ÀWỌN èèyàn tó gbayì tó gbáfẹ́, oúnjẹ aládùn, àti ìjíròrò tó lárinrin máa ń mú kí oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan lórí tábìlì ọ̀gákọ̀ nínú ọkọ̀ òkun gbádùn mọ́ni gan-an. Àmọ́ ìjíròrò kan lórí tábìlì Ọ̀gákọ̀ Robert G. Smith, tó ń bá ilé iṣẹ́ ọkọ̀ ojú omi White Star Line ṣiṣẹ́, tànmọ́lẹ̀ sórí àsè tẹ̀mí kan.—Aísáyà 25:6.

Ní 1894, nígbà tí Robert wà lẹ́ni ọdún mẹ́rìnlélógún, ó wa ọkọ òkun Kinclune of Dundee láti rin ìrìn àjò ojú òkun tó kọ́kọ́ rìn káàkiri ayé. Ẹ̀yìn ìyẹn ló wá ń darí àwọn ọkọ̀ òkun ti White Star, bíi Cedric, Cevic, àti Runic. a Nígbà tí Robert wà nínú ọ̀kan lára àwọn ọkọ̀ òkun wọ̀nyí, tó ń gba Àtìláńtíìkì ní New York kọjá lọ sí Liverpool, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ó gba Charles Taze Russell lálejò lórí tábìlì tí ọ̀gákọ̀ tí máa ń jẹun. Ìjíròrò tí Robert ní pẹ̀lú Russell ló tanná ran ìfẹ́ tí Robert ní nínú ìhìn Bíbélì, kó lè túbọ̀ mọ̀ sí i, ó fi tayọ̀tayọ̀ gba àwọn ẹ̀dà bíi mélòó kan ìwé Studies in the Scriptures lọ́wọ́ Russell.

Russell wá bẹ̀rẹ̀ sí kọ lẹ́tà sí Robert, bí ìfẹ́ tí Robert ní sí ìhìn Bíbélì ṣe pọ̀ sí i nìyẹn. Robert sọ nípa ìmọ̀ tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ní fún ìyàwó rẹ̀. Kò pẹ́ rárá tí àwọn méjèèjì fi di ògbóṣáṣá Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn orúkọ tí wọ́n máa ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Nígbà tó yá, Robert láǹfààní láti máa sọ àsọyé Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ̀rọ̀ lórí “Ìkunra Gílíádì” ní Brisbane, Ọsirélíà, ó sì fi bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ní ìhìn kan tó jẹ́ “ẹ̀rọ̀ fún gbogbo wàhálà ayé” hàn. Ìyàwó rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀ ràn án lọ́wọ́ láti fi “Photo-Drama of Creation” [Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá] han àwọn èèyàn ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, wọ́n sì máa ń fi rẹ́kọ́ọ̀dù ọ̀rọ̀ tí Russell fi ṣàlàyé àwọn àwòrán náà sínú ẹ̀rọ agbóhùnjáde káwọn èèyàn lè máa gbọ́ ọ bí àwòrán ti ń jáde.

Robert fi ogún òtítọ́ Ìjọba náà tó rí gbà lé àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́. Lónìí, tó ti ní ìrandíran karùn-ún lẹ́yìn ìgbà yẹn, àwọn méjìdínlógún tó jẹ́ ara ìdílé rẹ̀ ló ń kópa nínú sísọ ìhìn rere náà fáwọn ẹlòmíràn, wọ́n sì ń dúpẹ́ fún oúnjẹ tẹ̀mí tí wọ́n fún un jẹ lórí tábìlì ọ̀gákọ̀.

Àwọn ìwé táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ jáde àti iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ń ṣe ni wọ́n fi ń ran àwọn èèyàn jákèjádò ayé lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ ìhìn Bíbélì tó ru Ọ̀gákọ̀ Smith lọ́kàn sókè gan-an. Ìwọ náà lè wádìí ohun tó dùn mọ́ni tó bẹ́ẹ̀ lórí tábìlì ọ̀gákọ̀.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ọkọ̀ òkun kan tó fara jọ ìyẹn, tó ń jẹ́ Titanic, ni Ọ̀gákọ̀ E. J. Smith (wọn kì í ṣe mọ̀lẹ́bí o) ń wà nígbà tó rin ìrìn àjò oníjàábá tó kọ́kọ́ rìn lórí òkun.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Robert G. Smith

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Charles T. Russell