Ohun Tí Jóṣúà Rántí
Ohun Tí Jóṣúà Rántí
JÈHÓFÀ sọ pé: “Mósè ìránṣẹ́ mi ti kú; dìde nísinsìnyí, kí o sì sọdá Jọ́dánì yìí, ìwọ àti gbogbo ènìyàn yìí, sórí ilẹ̀ tí èmi yóò fi fún wọn.” (Jóṣúà 1:2) Iṣẹ́ ńlá ló mà já lé Jóṣúà léjìká yìí! Ó ti jẹ́ ẹmẹ̀wà Mósè fún nǹkan bí ogójì ọdún. A wá sọ fún un báyìí pé kó bọ́ sí ipò ọ̀gá rẹ̀ kó sì kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n sábà máa ń ṣòro láti bá da nǹkan pọ̀ wọ Ilẹ̀ Ìlérí.
Bí Jóṣúà ṣe ń ronú nípa iṣẹ́ tó fẹ́ dáwọ́ lé, ó ṣeé ṣe kí àwọn àdánwò tó ti rí tẹ́lẹ̀ tó sì ti borí wá sọ́kàn rẹ̀. Kò sí iyèméjì pé àwọn ohun tí Jóṣúà rántí jẹ́ àrànṣe aláìlẹ́gbẹ́ fún un nígbà yẹn lọ́hùn-ún, wọ́n sì lè jẹ́ ohun kan náà fáwọn Kristẹni òde òní.
Ẹrú Ni Kó Tó Di Aláṣẹ
Lára àwọn ohun tí Jóṣúà rántí ni bó ṣe jẹ́ ẹrú fún ọ̀pọ̀ ọdún. (Ẹ́kísódù 1:13, 14; 2:23) Ojú inú la lè fi wo ohun tójú Jóṣúà rí lákòókò yẹn, níwọ̀n bí Bíbélì ò ti sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún wa. Ó lè jẹ́ pé ìgbà tí Jóṣúà ń ṣiṣẹ́ nílẹ̀ Íjíbítì ló ti kọ́ béèyàn ṣe ń mọ ètò ṣe dáadáa, ó sì ti lè ṣèrànwọ́ nínú kíkó àwọn Hébérù àti “àwùjọ onírúurú ènìyàn púpọ̀ jaburata” kúrò ní ilẹ̀ náà.—Ẹ́kísódù 12:38.
Jóṣúà jẹ́ ara ìdílé kan nínú ẹ̀yà Éfúráímù. Eliṣámà, baba rẹ̀ àgbà sí jẹ́ ìjòyè látinú ẹ̀yà náà, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun ló darí àwọn ẹgbàá mẹ́rìnléláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún [108,100] ọkùnrin tó dìhámọ́ra tí wọ́n jẹ́ agbo kan lára ẹ̀yà mẹ́ta tá a pín Ísírẹ́lì sí. (Númérì 1:4, 10, 16; 2:18-24; 1 Kíróníkà 7:20, 26, 27) Síbẹ̀, nígbà tí àwọn ará Ámálékì gbógun dìde sí Ísírẹ́lì kété lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì, Jóṣúà ni Mósè sọ fún pé kó ṣètò àwọn tí yóò lọ gbèjà wọn. (Ẹ́kísódù 17:8, 9a) Ó ṣe wá jẹ́ pé Jóṣúà ló pè, tí ò pe baba rẹ̀ àgbà tàbí baba rẹ̀ pàápàá? Èrò kan nípa ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé: “[Jóṣúà] ni Mósè yíjú sí gẹ́gẹ́ bí aṣáájú tó tóótun jù lọ láti yan àwọn jagunjagun náà kó sì ṣètò wọn, nítorí pé ó jẹ́ ìjòyè kan látinú ẹ̀yà pàtàkì ti Éfúráímù, gbogbo wọ́n sì ti mọ̀ ọ́n mọ́ ọgbọ́n ìṣètò tó ní, àwọn èèyàn náà sì fọkàn tán an gan-an.”
Ohun yòówù kó jẹ́, nígbà tí wọ́n yan Jóṣúà, ohun tí Mósè pa láṣẹ fún un gẹ́ẹ́ ló ṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò fi bẹ́ẹ̀ mọ ogun-ún jà, síbẹ̀ ó dá Jóṣúà lójú pé Ọlọ́run yóò ràn wọ́n lọ́wọ́. Ìdí nìyẹn tí kìkì ọ̀rọ̀ tí Mósè sọ fún un pé, “ní ọ̀la, èmi fúnra mi yóò dúró sí orí òkè kékeré, pẹ̀lú ọ̀pá Ọlọ́run tòótọ́ ní ọwọ́ mi,” fi tó ẹ̀rí ìdánilójú fún un. Jóṣúà ti ní láti rántí pé Jèhófà ṣẹ̀ṣẹ̀ pa àwọn tó mọ ogun-ún jà jù lọ lákòókò yẹn run ni. Ní ọjọ́ kejì, nígbà tí Mósè gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè títí tí oòrùn fi wọ̀, kò sí ọ̀tá kankan tó lè ko Ísírẹ́lì lójú, àwọn Ámálékì sì pa run tán pátápátá. Jèhófà wá pàṣẹ fún Mósè pé kó kọ ohun tí òun pinnu láti ṣe sínú ìwé kan kó sì ‘sọ ọ́ ní etí Jóṣúà’ pé: “Èmi yóò nu ìrántí Ámálékì kúrò pátápátá lábẹ́ ọ̀run.” (Ẹ́kísódù 17:9b-14) Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà yóò mú ohun tó sọ yẹn ṣẹ dandan.
Ó Ṣe Ẹmẹ̀wà Mósè
Ọ̀ràn àwọn Ámálékì ti ní láti jẹ́ kí àjọṣe àárín Jóṣúà àti Mósè túbọ̀ lágbára sí i. Jóṣúà láǹfààní láti jẹ́ ẹmẹ̀wà tàbí “ìránṣẹ́,” Mósè “láti ìgbà ọ̀dọ́kùnrin rẹ̀” títí fi di ìgbà ikú Mósè, ìyẹn jẹ́ nǹkan bí ogójì ọdún.—Númérì 11:28.
Ipò yẹn túmọ̀ sí àǹfààní ńlá àti ẹrù iṣẹ́ fún un. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Mósè, Áárónì, àwọn ọmọ Áárónì, àtàwọn àádọ́rin àgbà ọkùnrin mìíràn ní Ísírẹ́lì gun Òkè Sínáì, tí wọ́n sì rí ìran ògo Jèhófà, ó ṣeé ṣe kí Jóṣúà wà láàárín wọn. Nígbà tó wà lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹmẹ̀wà, ó tẹ̀ lé Mósè lọ sí ibi gíga jù ní òkè náà, ó sì han gbangba pé ńṣe ló dúró sọ́ọ̀ọ́kán nígbà tí Mósè wọnú àwọsánmà tó dúró fún ibi tí Jèhófà wà. Ohun tó yani lẹ́nu ni bó ṣe dà bíi pé Jóṣúà ti wà lórí òkè náà fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru. Tó ń dúró de ìpadàbọ̀ ọ̀gá rẹ̀, nítorí pé nígbà tí Mósè bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀ kalẹ̀ pẹ̀lú àwọn wàláà Gbólóhùn Ẹ̀rí lọ́wọ́ rẹ̀, Jóṣúà wà níbẹ̀ láti pàdé rẹ̀.—Ẹ́kísódù 24:1, 2, 9-18; 32:15-17.
Lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bọ òrìṣà ère ọmọ màlúù, Jóṣúà ṣì ń ṣe ẹmẹ̀wà Mósè ní àgọ́ ìpàdé ní òde ibùdó náà. Ibẹ̀ ni Jèhófà ti bá Mósè sọ̀rọ̀ lójúkojú. Àmọ́, nígbà tí Mósè padà sí ibùdó, Jóṣúà “kì yóò kúrò nínú àgọ́ náà.” Ẹ́kísódù 33:7, 11.
Bóyá wọ́n fẹ́ kó wà níbẹ̀ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì má bàá wọnú àgọ́ náà nínú ipò àìmọ́ wọn. Jóṣúà ò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ẹrù iṣẹ́ yìí rárá!—Àjọṣe tó wà láàárín òun àti Mósè, ẹni tí òpìtàn nì, Josephus, sọ pé ó fi nǹkan bí ọdún márùndínlógójì dàgbà ju Jóṣúà, ti ní láti fún ìgbàgbọ́ Jóṣúà ní okun tó ga. Ohun táwọn èèyàn pe àjọṣe àárín wọn ni “àjọṣe láàárín ẹni tó dàgbà dénú àti ọ̀dọ́, láàárín ọ̀gá àti ọmọ ilé ìwé,” àbájáde rẹ̀ sì ni pé Jóṣúà di “akíkanjú ọkùnrin tó ṣeé fọkàn tán.” A ò láwọn wòlíì bíi Mósè láàárín wa lónìí, àmọ́ àwọn àgbàlagbà wà lára àwọn èèyàn Jèhófà, ìyẹn àwọn àgbà tí ìrírí tí wọ́n ti ní àti ipò tẹ̀mí wọn jẹ́ orísun okun àti ìṣírí. Ǹjẹ́ o mọyì wọn? Ṣé ò ń jàǹfààní nínú bíbá wọn rìn?
Amí ní Kénáánì
Ohun pàtàkì kan ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé Jóṣúà kété lẹ́yìn tí Ísírẹ́lì gba Òfin. Wọ́n yàn án pé kí ó ṣojú fún ẹ̀yà tirẹ̀ láti lọ ṣe amí Ilẹ̀ Ìlérí. Gbogbo wa la mọ ìtàn náà bí ẹní mowó. Gbogbo àwọn amí méjìlá náà ló gbà pé lóòótọ́ ni ilẹ̀ náà “ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin,” gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti ṣèlérí rẹ̀. Àmọ́ àwọn mẹ́wàá tí kò nígbàgbọ́ bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀rù pé Ísírẹ́lì ò tó bẹ́ẹ̀ láti lé àwọn olùgbé ilẹ̀ náà kúrò. Jóṣúà àti Kálébù nìkan ló rọ àwọn èèyàn náà pé kí wọ́n má ṣe ṣọ̀tẹ̀ nítorí ìbẹ̀rù, nítorí ó dájú pé Jèhófà yóò wà pẹ̀lú wọn. Látàrí èyí, gbogbo àwùjọ náà yarí, wọ́n sì sọ pé ńṣe làwọn máa sọ àwọn méjèèjì lókùúta. Bóyá wọn ì bá ṣe bẹ́ẹ̀ tí kì í bá ṣe pé Jèhófà tètè dá sí ọ̀ràn náà nípa fífi ògo rẹ̀ hàn. Nítorí àìní ìgbàgbọ́ wọn, Ọlọ́run wá sọ pé kò sí èyíkéyìí nínú àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ ní Ísírẹ́lì láti ẹni ogún ọdún sókè tí yóò wà láàyè láti wọ Kénáánì. Nínú gbogbo àwọn wọ̀nyí, kìkì Jóṣúà, Kálébù àti àwọn ọmọ Léfì nìkan ló là á já.—Númérì 13:1-16, 25-29; 14:6-10, 26-30.
Ṣé kì í ṣe gbogbo àwọn èèyàn náà ló rí agbára ńlá Jèhófà ní Íjíbítì ni? Báwo wá ni Jóṣúà ṣe nígbàgbọ́ pé Ọlọ́run yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà tí àwọn tó pọ̀ jù lọ ń ṣiyèméjì? Jóṣúà ti ní láti rántí gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣèlérí rẹ̀ tó sì ti mú ṣẹ, kó sì ti ronú lórí ìwọ̀nyí. Ìdí nìyẹn tó fi lè sọ ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà pé ‘kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rere tí Jèhófà ti sọ fún Ísírẹ́lì. Gbogbo wọn pátá ló ti ṣẹ.’ (Jóṣúà 23:14) Jóṣúà wá tipa bẹ́ẹ̀ gbà gbọ́ pé gbogbo ìlérí tí Jèhófà ṣe nípa ọjọ́ iwájú ni yóò nímùúṣẹ láìkùnà. (Hébérù 11:6) Èyí ní láti mú kéèyàn béèrè lọ́wọ́ ara rẹ̀ pé: ‘Èmi náà ńkọ́? Ǹjẹ́ ipá tí mo ti sà láti kẹ́kọ̀ọ́ àti láti fara balẹ̀ ronú lórí àwọn ìlérí Jèhófà ti mú un dá mi lójú pé wọ́n ṣe é gbẹ́kẹ̀ lé? Ǹjẹ́ mo gbà gbọ́ pé Ọlọ́run lè dáàbò bò mí pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀ nínú ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀?
Kì í ṣe pé Jóṣúà lo ìgbàgbọ́ nìkan, ó tún ní ìgboyà láti ṣe ohun tí ó tọ́ pẹ̀lú. Òun àti Kálébù nìkan ló mú ìdúró wọn, gbogbo àwùjọ náà sì ń sọ̀rọ̀ nípa sísọ wọ́n lókùúta. Ká ní ìwọ ni, kí lò bá ṣe? Wàá máa gbọ̀n jìnnìjìnnì àbí? Jóṣúà ò ṣe bẹ́ẹ̀ rárá. Òun àti Kálébù fi tìgboyàtìgboyà sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ jáde. Ìdúróṣinṣin wa sí Jèhófà lè béèrè pé ká ṣe bákan náà lọ́jọ́ kan.
Ìtàn àwọn amí náà tún sọ fún wa pé a yí orúkọ Jóṣúà padà. Mósè wá fi sílébù tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run kún orúkọ rẹ̀, ìyẹn Hóṣéà, tó túmọ̀ sí “Ìgbàlà,” ó wá pè é ní Jèhóṣúà, tàbí Jóṣúà—ìyẹn “Jèhófà Ni Ìgbàlà.” Ìtumọ̀ Septuagint pe orúkọ rẹ̀ ní “Jésù.” (Númérì 13:8, 16) Gẹ́gẹ́ bí ohun tí orúkọ ńlá yẹn túmọ̀ sí gan-an ni Jóṣúà ṣe fi àìṣojo polongo pé Jèhófà ni ìgbàlà. Orúkọ Jóṣúà tí wọ́n yí padà yìí kò jẹ́ àìròtẹ́lẹ̀. Ó fi hàn bí Mósè ṣe fi ojú tó dáa wo ìwà Jóṣúà, ìyẹn sì wá so mọ́ ipa pàtàkì tí Jóṣúà yóò kó nínú kíkó ìran tuntun náà wọ Ilẹ̀ Ìlérí.
Bí àwọn baba wọn ṣe ń kú níkọ̀ọ̀kan náà ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń rìn gbéregbère nínú aginjù fún ogójì ọdún tí ń tánni lókun. A ò mọ ohunkóhun nípa Jóṣúà ní àkókò yẹn. Àmọ́, ó ti ní láti kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ tó pọ̀. Ó ṣeé ṣe kó rí ìdájọ́ tí Ọlọ́run ṣe fún Kórà, Dátánì, àti Ábírámù tí Númérì 16:1-50; 20:9-13; 25:1-9.
wọ́n dìtẹ̀ àti àwọn ẹmẹ̀wà wọn àtàwọn tó lọ́wọ́ nínú ìjọsìn ẹlẹ́gbin ti Báálì Péórù. Ó dájú pé ìbànújẹ́ á dorí Jóṣúà kodò nígbà tó gbọ́ pé Mósè kò ní bá wọn wọ Ilẹ̀ Ìlérí nítorí pé ó kùnà láti sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́ nínú ọ̀ràn omi Mẹ́ríbà.—A Yàn Án Láti Gbapò Mósè
Nígbà tó kù díẹ̀ kí Mósè kú, ó ní kí Ọlọ́run yan ẹni tí yóò gba ipò òun kí Ísírẹ́lì má bàá dà “bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.” Kí ni ìdáhùn Jèhófà? Ó ní Jóṣúà, “ọkùnrin kan tí ẹ̀mí wà nínú rẹ̀,” ni kí ó fàṣẹ yàn níwájú gbogbo àpéjọ náà. Wọ́n ní láti máa gbọ́ràn sí i lẹ́nu. Ẹ ò rí i pé ìdámọ̀ràn tó ga lèyí! Jèhófà ti rí ìgbàgbọ́ Jóṣúà àti ibi tágbára rẹ̀ mọ. Kò tún sí ẹni tó tóótun jù ìyẹn lọ láti gbapò aṣáájú ní Ísírẹ́lì. (Númérì 27:15-20) Síbẹ̀, Mósè mọ̀ pé iṣẹ́ ńlá ló já lé Jóṣúà léjìká. Nítorí náà, Mósè rọ ẹni tó fẹ́ gbapò rẹ̀ yìí pé kó “jẹ́ onígboyà àti alágbára,” nítorí pé Jèhófà yóò máa wà pẹ̀lú rẹ̀.—Diutarónómì 31:7, 8.
Ọlọ́run fúnra rẹ̀ tún fún Jóṣúà ní ìṣírí kan náà, ó sì fi kún un pé: “Máa kíyè sára láti máa ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo òfin tí Mósè ìránṣẹ́ mi pa láṣẹ fún ọ. Má yà kúrò nínú rẹ̀ sí ọ̀tún tàbí sí òsì, kí o lè máa hùwà ọgbọ́n níbi gbogbo tí o bá lọ. Ìwé òfin yìí kò gbọ́dọ̀ kúrò ní ẹnu rẹ, kí o sì máa fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ kà láti inú rẹ̀ ní ọ̀sán àti ní òru, kí o lè kíyè sára láti máa ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí a kọ sínú rẹ̀; nítorí nígbà náà ni ìwọ yóò mú kí ọ̀nà rẹ yọrí sí rere, nígbà náà ni ìwọ yóò sì hùwà ọgbọ́n. Èmi kò ha ti pàṣẹ fún ọ bí? Jẹ́ onígboyà àti alágbára. Má gbọ̀n rìrì tàbí kí o jáyà, nítorí Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ ní ibikíbi tí o bá lọ.”—Jóṣúà 1:7-9.
Pẹ̀lú bí ọ̀rọ̀ Jèhófà yìí ṣe ń dún gbọnmọgbọnmọ létí rẹ̀ àti àwọn ìrírí tó ti ní tẹ́lẹ̀, báwo ni Jóṣúà tún ṣe fẹ́ ṣiyèméjì? Ó dájú pé wọ́n máa ṣẹ́gun ilẹ̀ náà. Lóòótọ́, ìṣòro á wà o, ọ̀kan nínú wọn ni ìṣòro tó kọ́kọ́ yọjú pàá, ìyẹn fífẹsẹ̀ wọ́ Odò Jọ́dánì tó kún àkúnya sọdá. Àmọ́, Jèhófà fúnra rẹ̀ ti pa á láṣẹ pé: “Dìde, . . . kí o sì sọdá Jọ́dánì yìí.” Nígbà náà, ìṣòro wo ló wá lè yọjú tí wọn ò ní lè borí?—Jóṣúà 1:2.
Àwọn nǹkan mìíràn tó tún ṣẹlẹ̀ ní tẹ̀lé-n-tẹ̀lé nínú ìgbésí ayé Jóṣúà—bí ìṣẹ́gun Jẹ́ríkò, títẹ àwọn ọ̀tá wọn lórí bá léraléra, àti pínpín ilẹ̀ náà—fi hàn pé kò fìgbà kan gbàgbé àwọn ìlérí Ọlọ́run. Nígbà tí Jóṣúà ń sún mọ́ òpin ìgbésí ayé rẹ̀, ìyẹn nígbà tí Jèhófà ti fún Ísírẹ́lì nísinmi kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn, ó kó àwọn èèyàn náà jọ láti sọ gbogbo bí Ọlọ́run ṣe bá wọn lò fún wọn àti láti rọ̀ wọn pé kí wọ́n sìn Ín tọkàntọkàn. Nítorí ìdí èyí, Ísírẹ́lì fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ tún májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà ṣe, ó sì dájú pé àpẹẹrẹ aṣáájú wọn ló mú kí ‘Ísírẹ́lì máa bá a lọ láti sin Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé Jóṣúà.’—Jóṣúà 24:16, 31.
Jóṣúà fi àpẹẹrẹ títayọ lélẹ̀ fún wa. Onírúurú àdánwò ìgbàgbọ́ ló dojú kọ àwa Kristẹni lónìí. Ó ṣe pàtàkì fún wa láti borí wọn ká lè rí ojú rere Jèhófà ká sì jogún àwọn ìlérí rẹ̀ níkẹyìn. Ìgbàgbọ́ lílágbára tí Jóṣúà ní ló mú kó kẹ́sẹ járí. Lóòótọ́, àwa ó tíì rí àwọn iṣẹ́ àrà Ọlọ́run bí Jóṣúà ṣe rí wọn, àmọ́ bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ṣiyèméjì, ìwé Bíbélì tá a fi orúkọ Jóṣúà pè pèsè ẹ̀rí látọ̀dọ̀ ẹni tí ọ̀rọ̀ ṣojú rẹ̀ tó jẹ́ ká mọ bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ ti ṣeé gbára lé tó. Bíi ti Jóṣúà la ṣe mú un dá àwa náà lójú pé ọgbọ́n á jẹ́ tiwa a ó sì kẹ́sẹ járí bí a bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ tá a sì ń kíyè sára láti fi ohun tó wà níbẹ̀ sílò nínú ìgbésí ayé wa.
Ṣe ìwà àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ máa ń bà ọ́ nínú jẹ́ nígbà mìíràn. Ronú nípa ìfaradà tí Jóṣúà ní, kò bá wọn dá ẹ̀ṣẹ̀ síbẹ̀ ó bá àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ tí kò nígbàgbọ́ rìn gbéregbère nínú aginjù fún odidi ogójì ọdún. Ṣé ó máa ń ṣòro fún ọ láti gbèjà ohun tó o gbà gbọ́? Rántí ohun tí Jóṣúà àti Kálébù ṣe. Wọ́n gba èrè ńlá nítorí ìgbàgbọ́ àti ìgbọràn wọn. Bẹ́ẹ̀ ni o, ó dá Jóṣúà lójú hán-únhán-ún pé Jèhófà yóò mú gbogbo ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Ǹjẹ́ kí àwa náà lè ṣe bákan náà.—Jóṣúà 23:14.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Bíbá tí Jóṣúà bá Mósè rìn ló fún ìgbàgbọ́ Jóṣúà lókun
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Jóṣúà àti Kálébù ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú agbára Jèhófà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ọ̀nà tí Jóṣúà gbà lo ipò aṣáájú sún àwọn èèyàn náà láti rọ̀ mọ́ Jèhófà típẹ́típẹ́