Ọ̀nà Tí A Gbà Bí Jésù àti Ìdí Tí A Fi Bí I
Ọ̀nà Tí A Gbà Bí Jésù àti Ìdí Tí A Fi Bí I
“KÒ LÈ jẹ́ bẹ́ẹ̀!” Ohun tí ọ̀pọ̀ àwọn tí kì í ṣe Kristẹni máa sọ nìyẹn nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ìtàn ìbí Jésù. Èrò wọn ni pé ó lòdì pátápátá sí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì láti gbà gbọ́ pé wúńdíá kan lè lóyún kó sì bímọ láìjẹ́ pé ọkùnrin kan bá a dàpọ̀. Kí lèrò tìrẹ nípa rẹ̀?
Lọ́dún 1984, ìwé ìròyìn The Times ti London gbé lẹ́tà kan jáde tó dá lórí ọ̀ràn yìí. Ó sọ pé: “Kò bọ́gbọ́n mu rárá láti máa fi ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì jiyàn pé kò sóhun tó ń jẹ́ iṣẹ́ ìyanu nítorí pé yálà èèyàn gbà pé iṣẹ́ ìyanu ń ṣẹlẹ̀ tàbí pé kì í ṣẹlẹ̀, orí ohun téèyàn gbà gbọ́ ni gbogbo rẹ̀ dá lé.” Àwọn mẹ́rìnlá tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ láwọn yunifásítì ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ló fọwọ́ si lẹ́tà náà. Wọ́n sọ pé: “A fi tayọ̀tayọ̀ tẹ́wọ́ gba ìbímọ wúńdíá, àwọn iṣẹ́ ìyanu inú ìwé Ìhìn Rere àti àjíǹde Jésù gẹ́gẹ́ bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú ìtàn.”
Lóòótọ́, kò sídìí tí kò fi ní ṣeni ní kàyéfì nígbà téèyàn bá kọ́kọ́ gbọ́ pé wúńdíá ló bí Jésù. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún wúńdíá ìyá Jésù alára nígbà tí áńgẹ́lì Ọlọ́run sọ pé: “Sì wò ó! ìwọ yóò lóyún nínú ilé ọlẹ̀ rẹ, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù.” Màríà béèrè pé: “Báwo ni èyí yóò ṣe rí bẹ́ẹ̀, níwọ̀n bí èmi kò ti ń ní ìbádàpọ̀ kankan pẹ̀lú ọkùnrin?” Ìgbà yẹn ni áńgẹ́lì náà wá ṣàlàyé pé ńṣe ni Ọlọ́run máa fi ẹ̀mí mímọ́ Rẹ̀ ṣe èyí, ó tún sọ pé: “Lọ́dọ̀ Ọlọ́run kò sí ìpolongo kankan tí yóò jẹ́ aláìṣeéṣe.” (Lúùkù 1:31, 34-37) Ó dájú pé ẹni tó ṣètò ìbímọ ẹ̀dá èèyàn lọ́nà àgbàyanu lè mú kí wúńdíá tó jẹ́ oníwà mímọ́ lóyún kó sì bí Jésù. Ọlọ́run tó lè dá ayé òun ìsálú ọ̀run pẹ̀lú àwọn òfin gígún régé tó ń gbé e ró, lè fi ẹyin kékeré kan látinú ẹ̀yà ìbímọ Màríà ṣẹ̀dá Ọmọkùnrin pípé.
Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì
Jósẹ́fù tó jẹ́ èèyàn Ọlọ́run ló ń fẹ́ Màríà sọ́nà nígbà tí Màríà lóyún. Inú àlá ni áńgẹ́lì Ọlọ́run ti ṣàlàyé fún Jósẹ́fù ìdí pàtàkì tí àfẹ́sọ́nà rẹ̀ tó jẹ́ wúńdíá fi lóyún. Áńgẹ́lì náà sọ pé: “Má fòyà láti mú Màríà aya rẹ sí ilé, nítorí èyíinì tí ó lóyún rẹ̀ jẹ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́. Yóò bí ọmọkùnrin kan, kí ìwọ sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù, nítorí òun yóò gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” (Mátíù 1:20, 21) Lédè Hébérù, orúkọ náà Jésù túmọ̀ sí “Jèhófà Ni Ìgbàlà.” Èyí rán wa létí ìdí tá a fi nílò ìgbàlà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú àti ètò tí Jèhófà Ọlọ́run tí ṣe fún ìgbàlà yìí nípasẹ̀ Jésù.
Níwọ̀n bí ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́, ìyẹn Ádámù ti dẹ́ṣẹ̀, gbogbo àtọmọdọ́mọ rẹ̀ ló jẹ́ aláìpé, wọ́n sì lè rú òfin Ọlọ́run. (Róòmù 5:12) Báwo la ṣe lè gba àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ kí wọ́n sì di pípé? Ìwàláàyè ẹ̀dá èèyàn pípé mìíràn, tó ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ti Ádámù, la gbọ́dọ̀ fi rúbọ láti mú ohun tí ìdájọ́ òdodo béèrè ṣẹ. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi mú ká bí ẹ̀dá èèyàn pípé kan, ìyẹn Jésù, èyí ló sì fà á tí Jésù fi jẹ́ káwọn ọ̀tá pa òun. (Jòhánù 10:17, 18; 1 Tímótì 2:5, 6) Lẹ́yìn tí Jésù jí dìde tó sì lọ sọ́run, pẹ̀lú ìfọwọ́sọ̀yà ló fi là á mọ́lẹ̀ pé: “Mo sì ti di òkú tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n, wò ó! mo wà láàyè títí láé àti láéláé, mo sì ní kọ́kọ́rọ́ ikú àti ti Hédíìsì [sàréè gbogbo aráyé] lọ́wọ́.”—Ìṣípayá 1:18.
Jésù fi kọ́kọ́rọ́ ìṣàpẹẹrẹ ikú àti Hédíìsì tó wà lọ́wọ́ rẹ̀ yìí ṣí ọ̀nà fún ẹ̀dá èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ láti rí ohun tí Ádámù gbé sọ nù gbà padà. Jésù ṣàlàyé pé: “Èmi ni àjíǹde àti ìyè. Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè; àti olúkúlùkù ẹni tí ń bẹ láàyè, tí ó sì ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, kì yóò kú láé.” (Jòhánù 11:25, 26) Ìlérí àgbàyanu mà lèyí o! Àmọ́, ìdí kan tó tún ṣe pàtàkì ju èyí lọ wà tá a fi bí Jésù.
Ìdí Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ
Kì í ṣe oyún Jésù nínú ilé ọlẹ̀ Màríà ni ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé Jésù. Ó sọ ọ́ kedere pé “èmi sọ kalẹ̀ wá láti ọ̀run.” (Jòhánù 6:38) Látìgbà ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá ni Jésù ti wà ní ibùgbé àwọn ẹ̀mí pẹ̀lú Bàbá rẹ̀ ọ̀run. Kódà, Bíbélì pè é ní “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá láti ọwọ́ Ọlọ́run.” (Ìṣípayá 3:14) Láti ọ̀run ni Jésù ti rí ọ̀tẹ̀ áńgẹ́lì búburú tó mú kí ẹ̀dá èèyàn tí Ọlọ́run kọ́kọ́ dá kẹ̀yìn sí ìṣàkóso Ọlọ́run. Èyí ni ìdí pàtàkì jù lọ tí Jésù fi fẹ́ ká bí òun gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn pípé tó jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run. Kí nìdí náà?
Ó jẹ́ láti fi hàn gbangba pé Bàbá rẹ̀ ọ̀run lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé òun ọ̀run. Jíjẹ́ tí Jésù jẹ́ olóòótọ́ látìgbà ìbí rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé títí dìgbà ikú rẹ̀ fi hàn pé ó múra tán láti fi ara rẹ̀ sábẹ́ ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń ṣàkóso àwọn ẹ̀dá Rẹ̀. Kí àwọn ọ̀tá Ọlọ́run tó pa Jésù, ó sọ ní kedere ìdí tóun fi múra tán láti fi ìwàláàyè òun rúbọ. Ó ní ìdí èyí ni pé kí ayé lè mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ Baba. (Jòhánù 14:31) Ká sọ pé ẹ̀dá èèyàn méjì àkọ́kọ́, ìyẹn Ádámù àti Éfà ní irú ìfẹ́ yẹn ni, wọn ò bá di ìṣòtítọ́ wọn mú nígbà ìdánwò kékeré tó bá wọn.—Jẹ́nẹ́sísì 2:15-17.
Ìṣòtítọ́ Jésù tún fi áńgẹ́lì burúkú náà, Sátánì hàn bí òpùrọ́. Sátánì purọ́ mọ́ Ọlọ́run àti èèyàn nígbà tó sọ níwájú àwọn áńgẹ́lì ní ọ̀run pé: “Ohun gbogbo tí ènìyàn bá sì ní ni yóò fi fúnni nítorí ẹ̀mí rẹ̀.” (Jóòbù 2:1, 4, Tanakh—The Holy Scriptures) Sátánì fẹ̀sùn èké kan gbogbo ẹ̀dá èèyàn pé tí ìwàláàyè wọn bá wà nínú ewu pẹ́nrẹ́n, wọn ò ní gbọ́ ti Ọlọ́run mọ́.
Ńṣe làwọn ọ̀ràn yìí pe ẹ̀tọ́ tí Ọlọ́run ní láti máa ṣàkóso níjà. Láti yanjú ọ̀ràn yìí ni Jésù fi fẹ́ ká bí òun bí ẹ̀dá èèyàn kóun sì ṣòótọ́ títí dójú ikú.
Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí Jésù fúnra rẹ̀ ṣe sọ, ìdí pàtàkì tá a fi bí i sórí ilẹ̀ ayé ni pé kí ó “lè jẹ́rìí sí òtítọ́.” (Jòhánù 18:37) Ó ṣe bẹ́ẹ̀ nípa fífi hàn nínú ọ̀rọ̀ àti nínú ìṣe pé òdodo ni ìṣàkóso Ọlọ́run látòkèdélẹ̀ àti pé fífi ara ẹni sábẹ́ ìṣàkóso yìí ń yọrí sí àlàáfíà tó wà pẹ́ títí. Jésù tún ṣàlàyé pé òun wá sáyé láti fi ìwàláàyè ẹ̀dá èèyàn òun ṣe “ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn,” ó wá tipa bẹ́ẹ̀ ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ẹ̀dá èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ láti dé ìjẹ́pípé kí wọ́n sì ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Máàkù 10:45) Àkọsílẹ̀ nípa ìbí Jésù ṣe pàtàkì gan-an kí ẹ̀dá èèyàn bàa mọ̀ nípa àwọn ọ̀ràn pàtàkì yìí. Síwájú sí i, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wé mọ́ ìbí Jésù tún ní àwọn ẹ̀kọ́ mìíràn nínú, àpilẹ̀kọ tó kàn á jẹ́ ká mọ èyí.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Báwo la ṣe lè gba àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀?