Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Máa Fi Ìfẹ́ Hàn Nínú Agbo Ìdílé

Ẹ Máa Fi Ìfẹ́ Hàn Nínú Agbo Ìdílé

Ẹ Máa Fi Ìfẹ́ Hàn Nínú Agbo Ìdílé

“JÓ O tó o bá tó bẹ́ẹ̀! Àní kó o jó o!” Ohun tí Tohru sọ fún Yoko, aya rẹ̀ nìyẹn. a Òun náà dáhùn pé “mà á dẹ̀ jó o,” bó ṣe ṣá igi ìṣáná kan nìyẹn tó fẹ́ jó fọ́tò táwọn méjèèjì jọ yà. Ẹ̀yìn ìyẹn ló tún fìbínú sọ pé: “Máa jo ilé yìí kanlẹ̀!” Ni Tohru bá di ìgbájú òun ìgbátí ru ìyàwó rẹ̀, lọ̀ràn bá di rannto.

Ọdún mẹ́ta ṣáájú àkókò yẹn ni Tohru àti Yoko bẹ̀rẹ̀ sí gbé ìgbésí ayé wọn pà pọ̀ gẹ́gẹ́ bíi tọkọtaya aláyọ̀. Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ènìyàn jẹ́jẹ́ ni Tohru, síbẹ̀ ìyàwó rẹ̀ ní kò fẹ́ràn òun àti pé kì í sábà bìkítà nípa bọ́ràn ṣe ń rí lára òun. Gbogbo bí ìyàwó yìí ṣe ń fìfẹ́ hàn sí ọkọ rẹ̀ tó, ńṣe ló dà bíi pé ọkọ rẹ̀ kò fìfẹ́ hàn padà. Nítorí pé Yoko kò lè fara da èyí mọ́, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí kanra, ó sì ń bínú. Ó ní àwọn ìṣòro bí àìróorunsùntó, àníyàn, àìlèjẹun, títètè bínú, àti ìsoríkọ́, kódà ó tiẹ̀ ń ní ìpayà ọkàn pàápàá. Síbẹ̀, Tohru kò tiẹ̀ ka gbogbo nǹkan tó ń lọ nínú ilé sí rárá. Ó dá bíi pé bó ṣe yẹ kó rí náà ló rí lójú rẹ̀.

“Àwọn Àkókò Tí Ó Nira Láti Bá Lò”

Irú àwọn ìṣòro yẹn gbòde kan lónìí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé àkókò wa yóò kún fún àwọn èèyàn tí wọn kò ní “ìfẹ́ni àdánidá.” (2 Tímótì 3:1-5) Èdè Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ tá a tú sí ‘àìní ìfẹ́ni àdánidá’ níhìn-ín bá ọ̀rọ̀ tá a lò fún ìfẹ́ àdánidá tó wà nínú agbo ìdílé mu gan-an ni. Ìgbà tiwa yìí gan-an ni àkókò tí kò sí irú ìfẹ́ni bẹ́ẹ̀. Kódà bí ìfẹ́ni tiẹ̀ wà, àwọn tó wà nínú ìdílé lè máà fẹ́ fi hàn sí ara wọn.

Ọ̀pọ̀ òbí lóde òní ni ò mọ bí wọ́n ṣe lè fi ìfẹ́ àti ìfẹ́ni hàn sí àwọn ọmọ tiwọn fúnra wọn. Àwọn kan ti dàgbà nínú ìdílé tí kò ti sí ìfẹ́ni, wọ́n sì lè má mọ̀ pé kìkì ìgbà tí ìfẹ́ni bá wà táwọn èèyàn sì ń fi hàn sí ara wọn ni ìgbésí ayé tó lè túbọ̀ láyọ̀ kó sì gbádùn mọ́ni. Ó dá bíi pé ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀ràn Tohru nìyẹn. Nígbà tó wà lọ́mọdé, gbogbo ìgbà ni ọwọ́ baba rẹ̀ máa ń dí lẹ́nu iṣẹ́, òru ló sì máa ń wọlé. Agbára káká ló fi máa ń bá Tohru sọ̀rọ̀, ìgbà tó bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, tèébútèébú ni. Iṣẹ́ àtàárọ̀ dalẹ́ ni ìyá Tohru náà ń ṣe, kò sì lo àkókò tó pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Tẹlifíṣọ̀n ló bá wọn tọ́ ọ dàgbà. Kò sóhun tó jọ oríyìn tàbí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ nínú ìdílé náà.

Àṣà ìbílẹ̀ tún lè jẹ́ kókó kan. Ní àwọn apá ibì kan ní Látìn Amẹ́ríkà, ọkùnrin kan ní láti ṣe ohun tó lòdì sí àṣà ìbílẹ̀ ibẹ̀ kó tó lè fìfẹ́ hàn sí aya rẹ̀. Ó lòdì sí àṣà ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè Ìlà Oòrùn àti ti Áfíríkà pé kí ẹnì kan fi ìfẹ́ hàn nínú ọ̀rọ̀ tàbí nínú ìṣe. Ó lè ṣòro fún ọkọ láti sọ fún aya tàbí àwọn ọmọ rẹ̀ pé “Mo nífẹ̀ẹ́ rẹ.” Síbẹ̀síbẹ̀, a lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú àjọṣe ìdílé kan tó jẹ́ òléwájú, tó sì ti wà fún àkókò tó gùn gan-an.

Àjọṣe Ìdílé Tó Jẹ́ Àwòfiṣàpẹẹrẹ

Ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ tó wà láàárín Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo náà ni àpẹẹrẹ tó dára jù lọ fún ìdílé. Wọ́n fìfẹ́ hàn sí ara wọn lọ́nà pípé. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ni ẹ̀dá ẹ̀mí tó wá di Jésù Kristi fi gbádùn àjọṣe aláyọ̀ pẹ̀lú Baba rẹ̀. Bó ṣe ṣàpèjúwe ìdè tó wà láàárín wọn rèé, ó ní: “Mo . . . wá jẹ́ ẹni tí ó ní ìfẹ́ni sí lọ́nà àkànṣe lójoojúmọ́, tí mo ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ níwájú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà.” (Òwe 8:30) Ìfẹ́ Baba rẹ̀ dá Ọmọ lójú gan-an débi tó fi lè polongo fún àwọn ẹlòmíràn pé Jèhófà ní ìfẹ́ni sí òun lọ́nà àkànṣe lójoojúmọ́. Gbogbo ìgbà ni inú rẹ̀ máa ń dùn lọ́dọ̀ Baba rẹ̀.

Kódà nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ènìyàn, a tún mú ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí Baba rẹ̀ ní sí i dá Ọmọ Ọlọ́run lójú. Lẹ́yìn tí Jésù ṣe ìrìbọmi, ó gbọ́ ohùn Baba rẹ̀ tó sọ pé: “Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.” (Mátíù 3:17) Ẹ ò rí i pé fífi ìfẹ́ hàn lọ́nà tó wúni lórí gan-an nìyí, ní ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tá a rán Jésù wá ṣe lórí ilẹ̀ ayé! Gbígbọ́ tí Jésù gbọ́ bí Baba rẹ̀ ṣe tẹ́wọ́ gbà á nígbà tó ń rántí gbogbo àkókò tó fi gbé ní ọ̀run ti ní láti mú orí rẹ̀ wú gan-an ni.

Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà fi àpẹẹrẹ tó dára jù lọ lélẹ̀ nínú fífi ìfẹ́ hàn fún ìdílé rẹ̀ kárí ayé lọ́nà tó kún rẹ́rẹ́ jù lọ. Bí a bá tẹ́wọ́ gba Jésù Kristi, àwa náà lè gbádùn ìfẹ́ni Jèhófà. (Jòhánù 16:27) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò ní í gbọ́ ọ̀rọ̀ kankan láti ọ̀run, a óò rí i bí Jèhófà ṣe fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn nínú ìṣẹ̀dá, nínú ìpèsè ẹbọ ìràpadà Jésù, àti láwọn ọ̀nà mìíràn. (1 Jòhánù 4:9, 10) Kódà Jèhófà máa ń gbọ́ àwọn àdúrà wa ó sì máa ń dáhùn wọn lọ́nà tó máa ṣe wá láǹfààní jù lọ. (Sáàmù 145:18; Aísáyà 48:17) Bá a ṣe ń ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà ni à ń jẹ́ kí ìmọrírì tá a ní fún àbójútó onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ túbọ̀ jinlẹ̀ sí i.

Ọ̀dọ̀ Baba Jésù ni Jésù ti kọ́ béèyàn ṣe ń ní ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò, ìgbatẹnirò, inú rere, àti àníyàn jíjinlẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn. Ó ṣàlàyé pé: “Ohun yòówù tí [Baba] ń ṣe, nǹkan wọ̀nyí ni Ọmọ ń ṣe pẹ̀lú lọ́nà kan náà. Nítorí pé Baba ní ìfẹ́ni fún Ọmọ, ó sì fi gbogbo ohun tí òun fúnra rẹ̀ ń ṣe hàn án.” (Jòhánù 5:19, 20) Àwa náà lè kọ́ bí a ṣe ń fi ìfẹ́ni hàn nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀ nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé.—Fílípì 1:8.

Ìfẹ́ni Nínú Ìdílé—Lọ́nà Wo?

Nítorí pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́” tá a sì dá wa “ní àwòrán rẹ̀,” a ní agbára láti nífẹ̀ẹ́ àti láti fìfẹ́ hàn. (1 Jòhánù 4:8; Jẹ́nẹ́sísì 1:26, 27) Síbẹ̀, agbára tá a ní láti fìfẹ́ hàn yẹn kì í ṣàdédé wáyé. Ká tó lè fìfẹ́ hàn, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ rí i pé a nífẹ̀ẹ́ ọkọ tàbí aya wa àtàwọn ọmọ wa. Fojú sílẹ̀, kó o sì kíyè sí àwọn ànímọ́ rere tí wọ́n ní, bó ti wù kí àwọn ànímọ́ wọ̀nyẹn kéré tó níbẹ̀rẹ̀, kó o sì wá máa ronú lórí irú àwọn ànímọ́ bẹ́ẹ̀. Ó lè sọ pé, ‘Kò sí ohun tó ń wúni lórí lára ọkọ [aya tàbí ọmọ] mi.’ Àwọn tó jẹ́ pé òbí tàbí alágbàtọ́ ló yan ọkọ tàbí aya fún wọn lè máà fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Àwọn kan lè máà ní i lọ́kàn tẹ́lẹ̀ láti bímọ. Síbẹ̀, ronú nípa ojú tí Jèhófà fi wo aya ìṣàpẹẹrẹ rẹ̀, ìyẹn orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, ní ọ̀rúndún kẹwàá ṣááju Sànmánì Tiwa. Nígbà tí Èlíjà wòlíì rẹ̀ rò pé kò sí ẹlòmíràn tó jẹ́ olùjọsìn Jèhófà mọ́ láàárín ẹ̀yà mẹ́wàá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, Jèhófà fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò wọn, ó sì rí àwọn èèyàn tó pọ̀—ẹgbẹ̀rún méje [7,000] lápapọ̀—tí wọ́n ní àwọn ànímọ́ tínú rẹ̀ dùn sí. Ǹjẹ́ o lè fara wé Jèhófà nípa wíwá ànímọ́ rere táwọn tó wà nínú ìdílé rẹ ní?—1 Àwọn Ọba 19:14-18.

Àmọ́, tó o bá fẹ́ kí àwọn yòókù nínú ìdílé rẹ mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn, o gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá rẹ láti fìfẹ́ náà hàn. Ìgbàkigbà tó o bá ti kíyè sí ohun kan tí wọ́n ṣe tó yẹ fún oríyìn ni kó o sọ ìmọrírì rẹ jáde. Nígbà tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń ṣàpèjúwe aya tó dáńgájíá, ó kíyè sí ànímọ́ kan tó fani mọ́ra lára ìdílé rẹ̀, ó ní: “Àwọn ọmọ rẹ̀ dìde, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pè é ní aláyọ̀; olúwa rẹ̀ dìde, ó sì yìn ín.” (Òwe 31:28) Kíyè sí bí àwọn tó wà nínú ìdílé náà ṣe ń sọ ọ́ jáde bí wọ́n ṣe mọrírì ara wọn tó. Nígbà tí baba kan bá ń gbóríyìn fún aya rẹ̀, ńṣe ló ń fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, tó ń fún un níṣìírí láti máa gbóríyìn fún aya rẹ̀ dáadáa nígbà tó bá gbéyàwó.

Bákan náà ló ṣe yẹ káwọn òbí máa gbóríyìn fáwọn ọmọ wọn. Ìyẹn lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti gbin iyì ara ẹni sọ́kàn àwọn ọmọ náà. Àbí, báwo ni ẹnì kan ṣe lè ‘nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ̀ bí ara rẹ̀’ tí ẹni bẹ́ẹ̀ kò bá ní ọ̀wọ̀ fún ara rẹ̀? (Mátíù 22:39) Yàtọ̀ síyẹn, bí àwọn òbí bá ń fi gbogbo ìgbà bá àwọn ọmọ wọn wí, tí wọn kì í gbóríyìn fún wọn rárá, àwọn ọmọ náà lè di ẹni tí kò ní iyì ara ẹni mọ́, ó sì lè ṣòro fún wọn láti fìfẹ́ hàn sáwọn ẹlòmíràn.—Éfésù 4:31, 32.

O Lè Rí Ìrànlọ́wọ́

Bí wọn ò bá tọ́ ẹ dàgbà nínú agboolé tí ìfẹ́ wà ńkọ́? O ṣì lè kọ́ bá a ṣe ń fìfẹ́ hàn. Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ ni kó o gbà pé ìṣòro ni, kó o sì gbà pé ó yẹ kó o ṣàtúnṣe. Bíbélì, tí í ṣe Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, jẹ́ ojúlówó ìrànlọ́wọ́ nínú ọ̀ràn yìí. A lè fi wé dígí kan. Nígbà tá a bá fi ẹ̀kọ́ Bíbélì tó dà bíi dígí yẹ ara wa wò, gbogbo ìkùdíẹ̀-káàtó tàbí àbùkù tó wà nínú èrò wa la óò rí kedere. (Jákọ́bù 1:23) Ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ Bíbélì, a lè ṣàtúnṣe àwọn èrò èyíkéyìí tí kò bá bójú mu. (Éfésù 4:20-24; Fílípì 4:8, 9) A ní láti máa ṣe bẹ́ẹ̀ déédéé, kí a ‘má ṣe juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára’ láé.—Gálátíà 6:9.

Ó lè ṣòro fáwọn kan láti fìfẹ́ hàn nítorí bá a ṣe tọ́ wọn dàgbà tàbí àṣà ìbílẹ̀ wọn. Àmọ́, àwọn ìwádìí ẹnu àìpẹ́ yìí fi hàn pé a lè borí irú àwọn ìdènà bẹ́ẹ̀. Dókítà Goleman, tó jẹ́ ògbóǹtagí nínú ìlera ọpọlọ, ṣàlàyé pé ‘kódà ìwà tó ti jingíri síni lọ́kàn láti kékeré ṣeé yí padà.’ Ní ohun tó lé ní ọ̀rúndún mọ́kàndínlógún sẹ́yìn, Bíbélì fi hàn pé pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí Ọlọ́run, kódà èrò tó ti fìdí múlẹ̀ ṣinṣin nínú ọkàn pàápàá lè yí padà. Ó gbà wá níyànjú pé: “Ẹ bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn àṣà rẹ̀, ẹ sì fi àkópọ̀ ìwà tuntun wọ ara yín láṣọ.”—Kólósè 3:9, 10.

Gbàrà tí wọ́n bá ti mọ ìṣòro wọn, ìdílé náà lè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí wọ́n sì fi ohun tó jẹ́ àìní wọn sọ́kàn. Bí àpẹẹrẹ, o ò ṣe wádìí ohun tí Bíbélì wí nípa “ìfẹ́ni”? O lè rí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bí irú èyí tó sọ pé: “Ẹ ti gbọ́ nípa ìfaradà Jóòbù, ẹ sì ti rí ìyọrísí tí Jèhófà mú wá, pé Jèhófà jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi nínú ìfẹ́ni, ó sì jẹ́ aláàánú.” (Jákọ́bù 5:11) Lẹ́yìn náà, kó o gbé ìtàn Bíbélì nípa Jóòbù yẹ̀ wò, darí àfiyèsí sórí bí Jèhófà ṣe jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gan-an, tó sì jẹ́ aláàánú sí Jóòbù. Ó dájú pé wà á fẹ́ fara wé Jèhófà nípa jíjẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gan-an àti jíjẹ́ aláàánú sí ìdílé rẹ.

Àmọ́, nítorí pé a jẹ́ aláìpé, “gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà” nínú bí a ṣe ń lo ahọ́n wa. (Jákọ́bù 3:2) A lè kùnà láti lo ahọ́n wa lọ́nà tí ń fúnni níṣìírí nínú agbo ìdílé wa. Ibí yìí ni àdúrà àti gbígbára lé Jèhófà ti pọn dandan. Ẹ má ṣe juwọ́ sílẹ̀. “Ẹ máa gbàdúrà láìdabọ̀.” (1 Tẹsalóníkà 5:17) Jèhófà yóò ran àwọn tó ń wá ìfẹ́ nínú ìdílé lọ́wọ́ àtàwọn tó fẹ́ fi ìfẹ́ hàn àmọ́ tí ohun kan tàbí òmíràn ò jẹ́ kí wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀.

Láfikún sí i, Jèhófà ti fi inú rere pèsè ìrànlọ́wọ́ nínú ìjọ Kristẹni. Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Ẹnikẹ́ni ha wà tí ń ṣàìsàn [nípa tẹ̀mí] láàárín yín bí? Kí ó pe àwọn àgbà ọkùnrin ìjọ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, kí wọ́n sì gbàdúrà lé e lórí, ní fífi òróró pa á ní orúkọ Jèhófà.” (Jákọ́bù 5:14) Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn alàgbà nínú ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè ṣe ìrànwọ́ tó ga fún àwọn ìdílé tó ní ìṣòro fífi ìfẹ́ hàn sí ara wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe onímọ̀ nípa ìrònú òun ìhùwà, síbẹ̀ àwọn alàgbà lè fi sùúrù ran àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn lọ́wọ́, wọn ò ní sọ ohun tí wọ́n máa ṣe fún wọn o, àmọ́ wọ́n lè rán wọn létí ojú tí Jèhófà fi ń wo ọ̀ràn náà kí wọ́n sì gbàdúrà pẹ̀lú wọn àti fún wọn.—Sáàmù 119:105; Gálátíà 6:1.

Nínú ọ̀ràn Tohru àti Yoko, gbogbo ìgbà làwọn Kristẹni alàgbà máa ń fetí si àwọn ìṣòro wọn tí wọ́n sì máa ń tù wọ́n nínú. (1 Pétérù 5:2, 3) Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, alàgbà kan àti ìyàwó rẹ̀ máa ń ṣèbẹ̀wò sílé wọn, kí Yoko lè jàǹfààní lára àgbà obìnrin Kristẹni tó lè ‘pe orí’ Yoko ‘wálé láti nífẹ̀ẹ́ ọkọ rẹ̀.’ (Títù 2:3, 4) Nípa fífi òye àti ẹ̀mí ìbánikẹ́dùn hàn sí àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn nítorí ìyà àti ìrora ọkàn wọn, àwọn alàgbà lè di “ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù àti ibi ìlùmọ́ kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò.”—Aísáyà 32:1, 2.

Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn alàgbà tó jẹ́ onínúure, Tohru wá mọ̀ pé ìṣòro tóun ní ni pé òun kì í sọ bí nǹkan ṣe ń rí lára òun jáde àti pé Sátánì ń gbógun tí ètò ìdílé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (2 Tímótì 3:1) Tohru pinnu láti kojú ìṣòro rẹ̀. Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí rí i pé ohun tó fà á tóun fi kùnà láti fìfẹ́ hàn ni pé wọn ò fìfẹ́ hàn sóun láti kékeré. Nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní àkọ́jinlẹ̀ àti àdúrà gbígbà, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ Tohru bẹ̀rẹ̀ sí kọbi ara sí bí ọ̀ràn ṣe ń rí lára Yoko.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Yoko ti máa ń bínú sí Tohru tẹ́lẹ̀, àmọ́ nígbà tó wá lóye bí ìdílé tí wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà ṣe rí, tóun náà tún mọ ẹ̀bi tiẹ̀ lẹ́bi, ó sa gbogbo ipá rẹ̀ láti rí àwọn ànímọ́ rere tí ọkọ rẹ̀ ní. (Mátíù 7:1-3; Róòmù 5:12; Kólósè 3:12-14) Ó wá bẹ Jèhófà pé kó fún òun ní okun kí òun lè máa nífẹ̀ẹ́ ọkọ òun. (Fílípì 4:6, 7) Bí àkókò ti ń lọ, Tohru bẹ̀rẹ̀ sí fìfẹ́ hàn, èyí sì múnú ìyàwó rẹ̀ dùn gan-an ni.

Bẹ́ẹ̀ ni o, kódà bó tiẹ̀ ṣòro fún ọ láti nífẹ̀ẹ́ àti láti fìfẹ́ hàn nínú ìdílé, síbẹ̀ o lè borí ìṣòro yẹn. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wa ní ìtọ́sọ́nà tó gbámúṣé. (Sáàmù 19:7) Nípa mímọ bí ọ̀ràn náà ti ṣe pàtàkì tó, nípa gbígbìyànjú láti rí àwọn ànímọ́ rere táwọn tó wà nínú ìdílé rẹ ní, nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ àti fífi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò, nípa gbígbára lé Jèhófà nípasẹ̀ àdúrà àtọkànwá, àti nípa wíwá ìrànlọ́wọ́ àwọn Kristẹni alàgbà tó dàgbà dénú, o lè borí ohun tó lè dà bí ìdènà lílágbára láàárín ìwọ àti ìdílé rẹ. (1 Pétérù 5:7) Ìwọ náà lè láyọ̀ bíi ti ọkọ kan ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Wọ́n gbà á níyànjú láti jẹ́ kí aya rẹ̀ mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Nígbà tó wá lo ìgboyà láti sọ pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ rẹ,” bí aya rẹ̀ ṣe fèsì yà á lẹ́nu gan-an ni. Pẹ̀lú omijé ayọ̀ lójú obìnrin náà, ó sọ pé: “Èmi náà nífẹ̀ẹ́ rẹ, àmọ́ ìgbà àkọ́kọ́ tó o máa sọ bẹ́ẹ̀ nìyí láti ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tá a ti fẹ́ra.” Má ṣe dúró de àkókò tó gùn tóyẹn kó o tó fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ ọkọ tàbí aya rẹ àtàwọn ọmọ rẹ o!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Jèhófà ń pèsè ìrànlọ́wọ́ látinú Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ rẹ̀