Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ta Ni “Àwọn Amòye Mẹ́ta” Náà?

Ta Ni “Àwọn Amòye Mẹ́ta” Náà?

Ta Ni “Àwọn Amòye Mẹ́ta” Náà?

Àwọn àwòrán nípa ìbí Jésù sábà máa ń ní àwọn ọkùnrin mẹ́ta àti ràkúnmí wọn, tí wọ́n dé sí ibùjẹ àwọn ẹran ọ̀sìn kan tá a tẹ́ ìkókó náà Jésù sí. Wọ́n sábà máa ń pe àwọn àlejò wọ̀nyí tí wọ́n múra lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ní àwọn amòye mẹ́ta. Kí ni Bíbélì sọ nípa wọn?

Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, àwọn ọkùnrin táwọn èèyàn sábà máa ń pè ní amòye yìí wá “láti àwọn apá ìlà-oòrùn,” ibẹ̀ ni wọ́n sì ti gbọ́ nípa ìbí Jésù. (Mátíù 2:1, 2, 9) Kì í ṣe ìrìn àjò ọlọ́jọ́ díẹ̀ làwọn ọkùnrin wọ̀nyí rìn wá sí Jùdíà o. Nígbà tí wọ́n fi máa dé ọ̀dọ̀ Jésù, ó ti kúrò ní ìkókó tó wà ní ibùjẹ ẹran. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe làwọn ọkùnrin yìí bá Màríà àti “ọmọ kékeré náà” nínú ilé tí wọ́n ń gbé.—Mátíù 2:11.

Bíbélì pe àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ní afìràwọ̀mòye tàbí “àwọn awòràwọ̀,” kò sì sọ iye tí wọ́n jẹ́. Ìwé The Oxford Companion to the Bible ṣàlàyé pé: “Báwọn àlejò náà ò ṣe kóyán ìràwọ̀ tí wọ́n tọpa rẹ̀ wá dé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù kéré fi bí iṣẹ́ òkùnkùn àti ìràwọ̀ wíwò ṣe so pọ̀ mọ́ra hàn.” Ó hàn gbangba pé Bíbélì ka gbogbo iṣẹ́ òkùnkùn àti báwọn ará Bábílónì ṣe ń wo ìràwọ̀ láti gba àwọn ìsọfúnni kan léèwọ̀.—Diutarónómì 18:10-12; Aísáyà 47:13.

Ìsọfúnni táwọn ọkùnrin wọ̀nyí rí gbà kò bímọ re. Ńṣe ló mú kí inú Hẹ́rọ́dù Ọba burúkú yẹn ru fùfù. Èyí ló mú kí Jósẹ́fù, Màríà àti Jésù sá lọ sí Íjíbítì, òun náà ló mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí pa àwọn ọmọdékùnrin “láti ọmọ ọdún méjì sí ìsàlẹ̀” ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Hẹ́rọ́dù ti fara balẹ̀ ṣírò ìgbà tá a bí Jésù látinú ohun tó gbọ́ lẹ́nu àwọn awòràwọ̀ náà. (Mátíù 2:16) Pẹ̀lú onírúurú ìṣòro tí ìbẹ̀wò wọn fà, ó bọ́gbọ́n mu láti sọ pé ọ̀dọ̀ ọ̀tá Ọlọ́run, ìyẹn Sátánì Èṣù tó fẹ́ pa Jésù, ni ìràwọ̀ tí wọ́n rí àti ìròyìn tí wọ́n gbọ́ nípa “ẹni tí a bí ní ọba àwọn Júù” ti wá.—Mátíù 2:1, 2.