Ìwé Pélébé Tó Yí Ìgbésí Ayé Mi Padà
Ìtàn Ìgbésí Ayé
Ìwé Pélébé Tó Yí Ìgbésí Ayé Mi Padà
GẸ́GẸ́ BÍ IRENE HOCHSTENBACH ṢE SỌ Ọ́
Ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Tuesday kan lọ̀rọ̀ ọ̀hún ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1972. Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún ni mí nígbà náà, mo sì tẹ̀ lé àwọn òbí mi lọ sí ìpàdé ìsìn kan nílùú Eindhoven, tó wà ní ẹkùn Brabant, ní orílẹ̀-èdè Netherlands. Ara mi ò balẹ̀ níbẹ̀ rárá ó sì dà bíi pé kí n wá ibòmíràn gbà lọ. Làwọn ọ̀dọ́bìnrin méjì kan bá fún mi níwèé pélébé kan, ohun tí wọ́n kọ síbẹ̀ rèé: “Irene wa ọ̀wọ́n, àá fẹ́ láti ràn ọ́ lọ́wọ́.” Mi ò mọ̀ pé ìwé pélébé yẹn máa wá yí ìgbésí ayé mi padà. Àmọ́ kí n tó sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà fún yín, ẹ jẹ́ kí n kọ́kọ́ sọ bí ìgbésí ayé mi ṣe bẹ̀rẹ̀.
ERÉKÙṢÙ Belitung, ní orílẹ̀-èdè Indonesia, ni wọ́n ti bí mi. Mo ṣì rántí àwọn ìró téèyàn máa ń gbọ́ ní erékùṣù ilẹ̀ olóoru yìí—bí àwọn imọ̀ ọ̀pẹ ṣe ń dún tí afẹ́fẹ́ bá ń fẹ́, ìró odò tó rọra ń ṣàn wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́, ẹ̀rín kèékèé àwọn ọmọdé tó ń ṣeré lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé àti orin tó máa ń dún nínú ilé wa. Ìdílé wa ti orílẹ̀-èdè Indonesia ṣí lọ sí orílẹ̀-èdè Netherlands lọ́dún 1960, ọmọ ọdún mẹ́rin ni mí nígbà náà. Ọkọ̀ ojú omi la wọ̀ nígbà ìrìn àjò gígùn ọ̀hún, ìró kan tí mi ò sì lè gbàgbé ni bí ohun ìṣeré tí mo fẹ́ràn jù lọ tí mo mú dání nígbà ìrìn àjò náà ṣe máa ń dún. Bèbí kékeré, apanilẹ́rìn-ín kan tó máa ń lu ìlù ni o. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méje ni àìsàn kan kọ lù mí tó sì di mí létí, àtìgbà náà ni mi ò ti gbọ́ ìró kankan mọ́. Àwọn ohun tí mo ti gbọ́ tẹ́lẹ̀ nìkan ló kù tí mo máa ń rántí.
Bí Mo Ṣe Ya Adití Dàgbà
Tìfẹ́tìfẹ́ làwọn òbí mi fi ń tọ́jú mi, èyí ò sì jẹ́ kí n kọ́kọ́ mọ̀ pé jíjẹ́ adití kì í ṣe ọ̀ràn
kékeré. Gẹ́gẹ́ bí ìṣe ọmọdé, nǹkan ìṣeré ni mo ka ẹ̀rọ ńlá tí mo fi ń gbọ́ràn sí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò fi bẹ́ẹ̀ wúlò fún mi pàápàá. Ńṣe làwọn ọmọ àdúgbò máa ń kọ gbogbo ohun tí wọ́n bá fẹ́ bá mi sọ sára ògiri ẹ̀bá ọ̀nà, màá sì dá wọn lóhùn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi fúnra mi ò gbọ́ ohun tí mò ń sọ.Bí mo ṣe ń dàgbà sí i ni mo wá ń mọ̀ pé mo yàtọ̀ sáwọn èèyàn tó kù. Mo tún kíyè sí i pé àwọn kan máa ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí pé adití ni mí, àwọn mìíràn kì í tiẹ̀ fẹ́ kí n wà láàárín wọn. Mo wá dẹni táwọn èèyàn kì í dá sí, tó ń dá wà. Ìgbà náà ni mo bẹ̀rẹ̀ sí mọ ohun tí ojú adití ń rí, bí mo ṣe ń dàgbà sí i ni ẹ̀rù àwọn èèyàn tí kì í ṣe adití túbọ̀ ń bà mí sí i.
Ìdílé wa torí kí n lè lọ sílé ẹ̀kọ́ àwọn adití, wọ́n ṣí kúrò ní abúlé tó wà ní ẹkùn-ìpínlẹ̀ Limburg, lọ sí ìlú Eindhoven. Bàbá mi bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ níbẹ̀, àbúrò mi ọkùnrin àtàwọn ẹ̀gbọ́n mi obìnrin náà bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé níbẹ̀. Mo mọrírì àyípadà tí wọ́n ṣe nítorí tèmi. Nílé ìwé, wọ́n kọ́ mi ní bi mo ṣe lè máa mọ ìgbà tí màá gbóhùn sókè sọ̀rọ̀ tàbí tí máa rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀ àti bí mo ṣe lè túbọ̀ máa sọ̀rọ̀ lọ́nà tó já gaara. Àwọn olùkọ́ náà kì í lo èdè àwọn adití, àmọ́ àwọn ọmọ kíláàsì kọ́ mi ní èdè yìí.
Mo Di Anìkanjẹ̀
Àwọn òbí mi ń sapá gan-an láti ṣàlàyé àwọn nǹkan fún mi bí mo ṣe ń dàgbà, àmọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan ni mi ò lóye. Bí àpẹẹrẹ, mi ò mọ̀ pé àwọn òbí mi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́ mo rántí pé lọ́jọ́ kan, ìdílé wa lọ síbì kan níbi tí omilẹgbẹ èèyàn ti jókòó sórí àga. Gbogbo wọn ń wo iwájú, wọ́n á pàtẹ́wọ́ nígbà míì. Tó bá ṣe sàà wọ́n á dìde, wọ́n á tún jókòó—àmọ́ mi ò mọ ìdí tí wọ́n fi ń ṣe gbogbo èyí. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà ni mo tó mọ̀ pé àpéjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mo lọ yẹn. Àwọn òbí mi tún máa ń mú mi lọ sí gbọ̀ngàn kékeré kan tó wà nílùú Eindhoven. Ara mi máa ń balẹ̀ níbẹ̀ nítorí pé onínúure ni gbogbo àwọn èèyàn náà, ó sì jọ pé inú ìdílé mi máa ń dùn níbẹ̀. Àmọ́ ohun tá à ń lọ ṣe níbẹ̀ gan-an ò yé mi. Ìsinsìnyí ni mo wá mọ̀ pé Gbọ̀ngàn Ìjọba àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni gbọ̀ngàn kékeré tá a máa ń lọ yẹn.
Ká sọ pé mo tún rẹ́ni ṣàlàyé ohun tí wọ́n ń sọ láwọn ìpàdé yìí fún mi ì bá dáa, ṣùgbọ́n kò sí. Ìsinyìí ni mo wá mọ̀ pé àwọn ará tó wà níbẹ̀ fẹ́ ràn mí lọ́wọ́ àmọ́ wọn ò mọ bí wọ́n ṣe lè ṣe é nítorí pé adití ni mí. Ńṣe ló máa ń dà bí ẹni pé mo dá nìkan wà láwọn ìpàdé yìí mo wá ń ronú pé: ‘Ká ní ilé ìwé ni mo wà ni, ì bá pé mi ju ibí yìí lọ o.’ Èrò yìí ló wà lọ́kàn mi nígbà tí àwọn ọ̀dọ́bìnrin méjì kan sáré kọ ọ̀rọ̀ ṣókí sí bébà pélébé tí wọ́n sì fún mi. Ìwé pélébé yìí ni mò ń sọ nípa rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ yìí. Mi ò mọ̀ rárá pé ìwé pélébé yìí ni á mú mi dẹni tó láwọn ọ̀rẹ́ àtàtà tó máa yọ mí nínú ìnìkanwà.
Mo Di Ọlọ́rẹ̀ẹ́ Àtàtà
Colette àti Hermine tó fún mi níwèé pélébé yìí ṣẹ̀ṣẹ̀ lé lọ́mọ ogún ọdún ni. Ìgbà tó yá ni mo wá mọ̀ pé ńṣe ni wọ́n wá sìn bí aṣáájú ọ̀nà déédéé tàbí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí mo lọ. Colette àti Hermine ò mọ èdè adití, àmọ́ mo máa ń wo ẹnu wọn tí wọ́n bá ń bá mi sọ̀rọ̀, ìyẹn ni mo fi ń mọ ohun tí wọ́n ń sọ, bá a sì ṣe dẹni tó jọ ń bára wa sọ̀rọ̀ dáadáa nìyẹn.
Inú àwọn òbí mi dùn gan-an nígbà tí Colette àti Hermine sọ pé àwọn fẹ́ kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ ohun táwọn ọ̀dọ́bìnrin yìí ṣe jùyẹn lọ. Wọ́n ń sapá gan-an láti ṣàlàyé àwọn ìpàdé tá à ń lọ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba fún mi, wọ́n
sì tún ń mú kí n bá àwọn ará inú ìjọ kẹ́gbẹ́ pọ̀. Wọ́n ń kọ́ mi láwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ inú Bíbélì láti lò nínú iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n sì tún máa ń bá mi múra iṣẹ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run sílẹ̀. Àbí ẹ ò rí nǹkan, èmi náà ni mo wá dẹni tó lè sọ̀rọ̀ níwájú àwọn èèyàn tí kì í ṣe adití!Ọ̀rọ̀ ò tán síbẹ̀ o, Colette àti Hermine jẹ́ kí n mọ̀ pé mo lè gbọ́kàn lé wọn. Wọ́n ní sùúrù púpọ̀ wọ́n sì máa ń tẹ́tí sí mi. Lóòótọ́ la máa ń rẹ́rìn-ín tí mo bá ṣe àṣìṣe o, àmọ́ wọn ò jẹ́ fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ láé; wíwà tí mo wà láàárín wọn kì í sì í kó ìtìjú bá wọn. Wọ́n sapá láti mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára mi, bíi pé a jọ jẹ́ ẹgbẹ́ kan náà la sì jọ máa ń ṣe síra. Àwọn ọ̀dọ́bìnrin onínúure yìí fún mi lẹ́bùn àtàtà kan—wọ́n fẹ́ràn mi wọ́n sì sọ mí dọ̀rẹ́.
Pabanbarì rẹ̀ ni pé Colette àti Hermine kọ́ mi pé mo gbọ́dọ̀ mọ Jèhófà Ọlọ́run wa, kí n sì mú un bí ọ̀rẹ́ tí mo lè gbọ́kàn lé. Wọ́n ṣàlàyé fún mi pé Jèhófà rí bí mo ṣe ń jókòó ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, pé ó sì mọ ìṣòro tí adití máa ń ní. Mo mà dúpẹ́ o pé ìfẹ́ fún Jèhófà tá a ní sọ àwa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta dọ̀rẹ́! Bí Jèhófà ṣe bìkítà nípa mi wú mi lórí púpọ̀, mo sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ débi pé mo ya ara mi sí mímọ́ fún un, mo sì ṣe ìrìbọmi ní July 1975 láti fi ṣe ẹ̀rí èyí.
Mo Bẹ̀rẹ̀ Sí Tẹ̀ Lé Ọ̀rẹ́ Mi Ọ̀wọ́n Kiri
Láwọn ọdún tó tẹ̀ lé e, mo bẹ̀rẹ̀ sí mọ ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin sí i. Arákùnrin kan di ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, a sì fẹ́ra wa lọ́dún 1980. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni mo bẹ̀rẹ̀ sí ṣe aṣáájú ọ̀nà, nígbà tó di 1994, wọ́n yan èmi àti Harry ọkọ mi láti lọ sìn bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe láàárín àwọn tó ń sọ Èdè Àwọn Adití lọ́nà ti ilẹ̀ Jámánì. Ní ọdún tó tẹ̀ lé e, iṣẹ́ kan tó jẹ́ ìpèníjà ńlá délẹ̀ fún mi. Ó di pé kí n máa bá ọkọ mi tí kì í ṣe adití lọ káàkiri, bó ṣe ń bẹ onírúurú ìjọ wò gẹ́gẹ́ bí adelé alábòójútó àyíká.
Ọgbọ́n tí mò ń ta sí i rèé. Ìgbà àkọ́kọ́ pàá tá a bá bẹ ìjọ kan wò, mo máa ń tètè sún mọ́ púpọ̀ nínú àwọn ará tó wà níbẹ̀ láti ṣàlàyé ara mi fún wọn. Màá sọ fún wọn pé adití ni mí o pé tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ sí mi kí wọ́n rọra máa sọ ọ́ kí wọ́n sì kọjú sí mi. Mo tún máa ń sapá láti tètè dáhùn láwọn ìpàdé. Bẹ́ẹ̀ ni mo tún máa ń béèrè bóyá mo lè rí ẹnì kan tó máa ṣe ògbufọ̀ fún mi nípàdé àti lóde ẹ̀rí lọ́sẹ̀ náà.
Ọ̀nà yìí gbéṣẹ́ gan-an ni, débi pé àwọn ará tiẹ̀ máa ń gbàgbé nígbà míì pé adití ni mí tọ́rọ̀ á sì dọ̀rọ̀ ẹ̀rín. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n á sọ fún mi
pé táwọn bá rí mi nígboro, àwọn máa ń fun fèrè ọkọ̀ àwọn láti kí mi, àmọ́ èmi á kàn máa lọ ní tèmi. Èmi fúnra mi máa ń gbàgbé pé adití ni mí nígbà míì—bí ìgbà míì tí máa fẹ́ rọra sọ ọ̀rọ̀ àṣírí kan sétí ọkọ mi. Bí mo bá ti rí i pé ó súnra kì, màá ti mọ̀ pé gbogbo ayé ló ń gbọ́ ọ̀rọ̀ “kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́” ti mo rò pé mò ń sọ.Àwọn ọmọdé máa ń ràn mí lọ́wọ́ lọ́nà tí mi ò rò tẹ́lẹ̀. Nígbà àkọ́kọ́ pàá tá a bẹ ìjọ kan wò, ọmọkùnrin ọlọ́dún mẹ́sàn-án kan kíyè sí i pé àwọn kan nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba fẹ́ máa sára fún mi, ló bá pinnu láti ṣe ohun kan nípa rẹ̀. Ó sún mọ́ mi, ó dì mí lọ́wọ́ mú ó sì fà mí lọ sáàárín Gbọ̀ngàn Ìjọba, ló bá gbóhùn sókè pé: “Ẹ̀yin ará ẹ wò ó, Irene rèé o, adití ni o!” Gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ ló wá bá mi tí wọ́n sì kí mi.
Bí mo ṣe ń bá ọkọ mi lọ káàkiri nínú iṣẹ́ àyíká, làwọn ọ̀rẹ́ mi ń pọ̀ sí i. Lónìí, ìgbésí ayé mi ti yàtọ̀ pátápátá sí tìgbà tí mo máa ń nìkan wà bí àṣo! Láti ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ tí Colette àti Hermine ti fi ìwé pélébé yẹn lé mi lọ́wọ́ ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í rí bí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ ti lágbára tó, mo sì ti pàdé àwọn èèyàn tí wọ́n ti di ẹni àtàtà sí mi. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, mo wá mọ Jèhófà tó jẹ́ Ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n jù lọ. (Róòmù 8:38, 39) Áà, ìwé pélébé yẹn yí ìgbésí ayé mi padà o!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Mo rántí bí ohun ìṣeré tí mo fẹ́ràn jù lọ ṣe máa ń dún
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́, àti pẹ̀lú Harry ọkọ mi