Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Òótọ́ Lo Sọ, Ayé Dùn O!”

“Òótọ́ Lo Sọ, Ayé Dùn O!”

“Òótọ́ Lo Sọ, Ayé Dùn O!”

ṢÉ Ó wù ọ́ láti mọ ìdí tá a fi wà láàyè gan-an? Ohun tí Magdalena, ọmọ ọdún méjìdínlógún, tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń gbé ní Szczecin, ilẹ̀ Poland, ran Katarzyna tí wọ́n jọ wà ní kíláàsì kan náà nílé ẹ̀kọ́ gíga lọ́wọ́ láti ṣe gan-an nìyẹn. Aláìgbà-pọ́lọ́run-wà paraku ni Katarzyna, àmọ́ nígbà tí Magdalena bá a sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì, ó fi ojúlówó ìfẹ́ hàn.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Katarzyna mọrírì ohun tí Magdalena ń sọ fún un látinú Bíbélì, síbẹ̀ kò lè fara mọ́ gbogbo ohun tó ń wí. Níwọ̀n bí òun àti Magdalena ti máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́, Katarzyna sọ nígbà kan rí pé: “Ẹ̀yin ní Bíbélì; ẹ mọ àwọn ìlànà tó yẹ kẹ́ ẹ tẹ̀ lé, ẹ sì mọ ibi tẹ́ ẹ ti lè rí àwọn ọ̀rẹ́. Àmọ́ àwọn tí ò lè fara mọ́ àwọn ìlànà wọ̀nyẹn nísinsìnyí ńkọ́?”

Nǹkan yí padà nígbà tí Katarzyna rìnrìn àjò lọ sílùú London, nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Ó lọ sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀, inú rere tí wọ́n fi hàn sí i sì yà á lẹ́nu gan-an. Irú àyẹ́sí bíi kí wọ́n máa ṣílẹ̀kùn fún un àti bí wọ́n ṣe fi ojúlówó ìfẹ́ hàn sí ọ̀rọ̀ tó ń sọ múnú rẹ̀ dùn gan-an.

Nígbà tí ọdún ilé ìwé tuntun bẹ̀rẹ̀ ní September 2001, Katarzyna pinnu láti bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Ó ti wá mọrírì àwọn ìlànà Bíbélì gan-an báyìí, ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí fi wọ́n sílò nínú ìgbésí ayé rẹ̀ ojoojúmọ́. Ẹnu àìpẹ́ yìí ló sọ ọ́ lọ́rọ̀ àṣírí fún Magdalena pé: “Ó dà bíi pé mo ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé tuntun ni.” Ó tún fi ọ̀rọ̀ ṣókí látorí tẹlifóònù alágbèérìn dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “O ṣeun gan-an fún ìkẹ́kọ̀ọ́ wa tòní! Òótọ́ lo sọ, ayé dùn o! Ohun àgbàyanu ni láti mọ ẹni tó yẹ ká máa fi ọpẹ́ fún nítorí ìyẹn.”