Ẹ Wà Lójúfò Nísinsìnyí Ju Ti Ìgbàkígbà Rí Lọ!
Ẹ Wà Lójúfò Nísinsìnyí Ju Ti Ìgbàkígbà Rí Lọ!
“Ẹ má ṣe jẹ́ kí a máa sùn gẹ́gẹ́ bí àwọn yòókù ti ń ṣe, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a wà lójúfò, kí a sì pa agbára ìmòye wa mọ́.”—1 TẸSALÓNÍKÀ 5:6.
1, 2. (a) Irú ìlú wo ni àwọn ìlú olókìkí méjì tó wà nítòsí Róòmù? (b) Ìkìlọ̀ wo ni ọ̀pọ̀ lára àwọn ará ìlú méjì náà kò kà sí, kí ló sì tẹ̀yìn rẹ̀ yọ?
NÍ Ọ̀RÚNDÚN kìíní Sànmánì Tiwa, ìlú olókìkí nìlúu Pompeii àti Herculaneum, tó wà nítòsí Òkè Vesuvius ní ìlú Róòmù. Ibẹ̀ làwọn ará Róòmù tí wọ́n rí já jẹ ti ń lọ gbafẹ́. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbọ̀ngàn ńlá tó wà ńbẹ̀ lè gba èèyàn tó lé lẹ́gbẹ̀rún. Gbọ̀ngàn ńlá kan tó tiẹ̀ wà ní Pompeii tóbi débi pé ó lè gba gbogbo èèyàn tó wà nílùú náà. Àwọn awalẹ̀ nílùú Pompeii ti rí àwọn ilé ọtí méjìdínlọ́gọ́fà [118], èyí tí díẹ̀ lára wọn jẹ́ ilé tẹ́tẹ́ títa tàbí ilé iṣẹ́ aṣẹ́wó. Ìwà ìṣekúṣe àti ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì gbòde kan níbẹ̀, àwọn àwòrán àti egungun òkú tí wọ́n walẹ̀ kàn jẹ́rìí gbe èyí.
2 August 24, ọdún 79 Sànmánì Tiwa ni Òkè Vesuvius bẹ̀rẹ̀ sí bú gbàù. Àwọn onímọ̀ nípa òkè ayọnáyèéfín sọ pé ó ṣeé ṣe kí èérún àpáta àti eérú tó fọ́n sáwọn ìlú méjèèjì nígbà tí òkè náà kọ́kọ́ bú gbàù máà dí àwọn tó ń gbébẹ̀ lọ́wọ́ láti ráyè sá àsálà fún ẹ̀mí wọn. Kódà ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ńṣe làwọn tó fojú kéré ewu náà tí wọn ò kọbi ara sí ìkìlọ̀ jókòó pa sílùú náà. Nígbà tó di ọ̀gànjọ́ òru, atẹ́gùn gbígbóná janjan rọ́ dé, òkè náà bú gbàù ó sì rọ́ lu ìlú Herculaneum, gbogbo èèyàn tó kù nínú ìlú náà ló ṣòfò ẹ̀mí. Láàárọ̀ ọjọ́ kejì, irú ìṣẹ̀lẹ̀ kan náà yìí tún wáyé nílùú Pompeii ó sì gbẹ̀mí gbogbo èèyàn tó wà níbẹ̀. Ẹ ò rí i pé ṣíṣàìka ìkìlọ̀ sí kì í bímọọre!
Òpin Ètò Àwọn Júù
3. Kí ni ìparun Jerúsálẹ́mù àti ti ìlú Pompeii òun Herculaneum fi bára mu?
3 Àjálù búburú tó pa ìlú Pompeii àti ìlú Herculaneum run yìí kéré sí èyí tó wáyé nígbà ìparun Jerúsálẹ́mù lọ́dún mẹ́sàn-án ṣáájú ìgbà yẹn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àfọwọ́fà ẹ̀dá èèyàn nìyẹn. Wọ́n tiẹ̀ sọ pé ó jẹ́ “ọ̀kan lára ìgbóguntì tó burú jù lọ nínú ìtàn,” nítorí wọ́n ròyìn pé ẹ̀mí àwọn Júù tó lọ sí i lé ní mílíọ̀nù kan. Àmọ́ ṣá o, gẹ́gẹ́ bíi ti àjálù tó wáyé nílùú Pompeii àti Herculaneum, kò ṣàì sí àwítẹ́lẹ̀ nípa ìparun Jerúsálẹ́mù kó tó ṣẹlẹ̀.
4. Àmì alásọtẹ́lẹ̀ wo ni Jésù fi ṣèkìlọ̀ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé òpin ètò kan ti sún mọ́lé, báwo sì lèyí ṣe kọ́kọ́ nímùúṣẹ ní ọ̀rúndún kìíní?
4 Jésù Kristi ti sọ ṣáájú pé ìlú náà á pa run, ó sì sọ àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ṣáájú ìparun náà—ìyẹn làwọn ohun tó ń kóni lọ́kàn sókè bí ogun, àìtó oúnjẹ, ìmìtìtì ilẹ̀ àti ìwà ta-ni-yóò-mú-mi. Àwọn wòlíì èké á gbòde kan, síbẹ̀ a ó wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé. (Mátíù 24:4-7, 11-14) Òótọ́ ni pé òde òní ni lájorí ìmúṣẹ àwọn ọ̀rọ̀ Jésù ń wáyé, síbẹ̀ wọn ò ṣàì nímùúṣẹ díẹ̀ nígbà náà lọ́hùn-ún. Ìtàn fi hàn pé ìyàn ńlá mú ní Jùdíà. (Ìṣe 11:28) Òpìtàn Júù nì, Josephus, ròyìn pé ilẹ̀ ríri wáyé lágbègbè Jerúsálẹ́mù nígbà tó kù díẹ̀ kí ìlú náà pa run. Bí òpin Jerúsálẹ́mù ṣe ń sún mọ́lé, onírúurú rògbòdìyàn ló ṣẹlẹ̀, ogun abẹ́lé láàárín ẹgbẹ́ òṣèlú àwọn Júù, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí para wọn nípakúpa láàárín àwọn ìlú táwọn Júù àtàwọn Kèfèrí jọ ń gbé. Síbẹ̀, a ṣì wàásù ìhìn rere Ìjọba náà “nínú gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.”—Kólósè 1:23.
5, 6. (a) Àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Jésù wo ló nímùúṣẹ lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa? (b) Èé ṣe tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ṣòfò ẹ̀mí nígbà ìparun Jerúsálẹ́mù ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa?
5 Níkẹyìn, lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa, àwọn Júù ṣọ̀tẹ̀ sí Róòmù. Nígbà tí Cestius Gallus kó àwọn ọmọ ogun sòdí lọ gbógun ti Jerúsálẹ́mù, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù rántí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Nígbà tí ẹ bá rí tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun adótini bá yí Jerúsálẹ́mù ká, nígbà náà ni kí ẹ mọ̀ pé ìsọdahoro rẹ̀ ti sún mọ́lé. Nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá, kí àwọn tí wọ́n sì wà ní àárín rẹ̀ fi ibẹ̀ sílẹ̀, kí àwọn tí wọ́n sì wà ní àwọn ibi ìgbèríko má ṣe wọ inú rẹ̀.” (Lúùkù 21:20, 21) Àsìkò tó yẹ kí wọ́n sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù rèé, àmọ́ báwo ni wọ́n á ṣe ṣe é? Ohun tí ẹnikẹ́ni ò retí ṣẹlẹ̀, Gallus ṣàdédé kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kúrò nílùú náà èyí sì fún àwọn Kristẹni tó wà ní Jerúsálẹ́mù àti Jùdíà láyè láti tẹ̀lé ọ̀rọ̀ Jésù kí wọ́n sì sá lọ sí àwọn òkè ńlá.—Mátíù 24:15, 16.
6 Ọdún mẹ́rin lẹ́yìn náà, lásìkò àjọ̀dún Ìrékọjá, àwọn ọmọ ogun Róòmù padà dé lábẹ́ Ọ̀gágun Titus, ẹni tó ti pinnu pé dandan òun gbọ́dọ̀ paná ọ̀tẹ̀ àwọn Júù. Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ yí Jerúsálẹ́mù ká wọ́n sì “fi àwọn òpó igi olórí ṣóńṣó ṣe odi yí” i ká tí ẹnikẹ́ni ò fi ní ráyè sá lọ. (Lúùkù 19:43, 44) Pẹ̀lú gbogbo kùkùlajà ogun yìí, ogunlọ́gọ̀ àwọn Júù tó wà ní gbogbo àgbègbè Ilẹ̀ Ọba Róòmù ló ti lọ ṣe àjọ̀dún Ìrékọjá ní Jerúsálẹ́mù. Gbangba wá dẹkùn báyìí, kò sọ́nà àbáyọ. Gẹ́gẹ́ bí òpìtàn nì, Josephus ṣe sọ, àwọn àlejò tí wọ́n rin àrìnfẹsẹ̀sí yìí ló pọ̀ jù lọ lára àwọn tó kàgbákò ìgbóguntini àwọn ará Róòmù. a Nǹkan bí ìdá kan nínú ìdá méje àwọn Júù tó wà ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù ló ṣègbé nígbà tí Jerúsálẹ́mù wá pa run níkẹyìn. Ìparun Jerúsálẹ́mù yìí ló rẹ́yìn orílẹ̀-èdè àwọn Júù àti ètò ìjọsìn wọn tá a gbé karí Òfin Mósè. b—Máàkù 13:1, 2.
7. Èé ṣe táwọn Kristẹni tòótọ́ fi rù ú là nígbà ìparun Jerúsálẹ́mù?
7 Àwọn Júù tí wọ́n jẹ́ Kristẹni ì bá ti ṣòfò ẹ̀mí tàbí kí wọ́n ti kó wọn lẹ́rú pẹ̀lú àwọn tó kù ní Jerúsálẹ́mù lọ́dún 70 Sànmánì Tiwa. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí inú ìtàn ṣe fi hàn, wọ́n ṣègbọràn sí ìkìlọ̀ tí Jésù ṣe ní ọdún mẹ́tàdínlógójì ṣáájú àkókò yẹn. Wọ́n ti kúrò nínú ìlú náà wọn ò sì padà síbẹ̀ mọ́.
Ìkìlọ̀ Àwọn Àpọ́sítélì Bọ́ Sákòókò
8. Kí lohun náà tí Pétérù sọ pé ó ṣe pàtàkì, àwọn ọ̀rọ̀ Jésù wo ló ṣeé ṣe kó ní lọ́kàn?
8 Lónìí, ìparun tó jùyẹn lọ fíìfíì ń fì dùgbẹ̀dùgbẹ̀, òun ló sì máa kásẹ̀ gbogbo ètò nǹkan yìí nílẹ̀. Ní ọdún mẹ́fà ṣáájú ìparun Jerúsálẹ́mù, àpọ́sítélì Pétérù ṣe ìkìlọ̀ kánjúkánjú tó bọ́ sákòókò, èyí tó dìídì kan àwọn Kristẹni lónìí, ìkìlọ̀ náà ni: Ẹ wà lójúfò! Pétérù mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì káwọn Kristẹni ru “agbára ìrònú” wọn tó ṣe “kedere” sókè, kí wọ́n lè kọbi ara sí “àṣẹ Olúwa,” ìyẹn Jésù Kristi. (2 Pétérù 3:1, 2) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ohun tí Pétérù gbọ́ tí Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì Rẹ̀ pé: “Ẹ máa wọ̀nà, ẹ wà lójúfò, nítorí ẹ kò mọ ìgbà tí àkókò tí a yàn kalẹ̀ jẹ́,” ló ní lọ́kàn nígbà tó ń rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n má ṣe sùn.—Máàkù 13:33.
9. (a) Ẹ̀mí tó léwu wo làwọn kan á bẹ̀rẹ̀ sí ní? (b) Èé ṣe tí iyèméjì fi léwu?
9 Tẹ̀gàntẹ̀gàn làwọn kan fi ń béèrè lónìí pé: “Wíwàníhìn-ín rẹ̀ yìí tí a ti ṣèlérí dà?” (2 Pétérù 3:3, 4) Ó ṣe kedere pé èrò àwọn èèyàn yìí ni pé ipò àwọn nǹkan ò tíì fi bẹ́ẹ̀ yí padà, pé bó ṣe wà látìgbà ìwáṣẹ̀ náà ló ṣì ń bá a lọ. Irú ìwà àìdánilójú bẹ́ẹ̀ léwu gan-an. Iyèméjì lè mú kí ẹ̀mí pé nǹkan jẹ́ kánjúkánjú tá a ní bẹ̀rẹ̀ sí lọọlẹ̀, ká sì bẹ̀rẹ̀ síí mú tara wa gbọ́ ní rabidun. (Lúùkù 21:34) Yàtọ̀ sí ìyẹn, gẹ́gẹ́ bí Pétérù ṣe sọ, irú àwọn ẹlẹ́gàn bẹ́ẹ̀ ti gbàgbé Ìkún Omi ọjọ́ Nóà tó pa gbogbo ètò àwọn nǹkan run. Lóòótọ́, ipò àwọn nǹkan yí padà nígbà yẹn!—Jẹ́nẹ́sísì 6:13, 17; 2 Pétérù 3:4-6.
10. Àwọn ọ̀rọ̀ wo ni Pétérù fi gba àwọn kan níyànjú láti má ṣe kánjú ju bó ṣe yẹ?
10 Pétérù ran àwọn tó ń ka lẹ́tà rẹ̀ lọ́wọ́ láti má ṣe kánjú ju bó ṣe yẹ lọ nípa rírán wọn létí ìdí tí Ọlọ́run fi máa ń lọ́ra díẹ̀ láti gbégbèésẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. Lákọ̀ọ́kọ́, Pétérù sọ pé: “Ọjọ́ kan lọ́dọ̀ Jèhófà jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ̀rún ọdún àti ẹgbẹ̀rún ọdún gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ kan.” (2 Pétérù 3:8) Nígbà tó jẹ́ pé ọba àìkú ni Jèhófà, ó lè gbé gbogbo kókó tó jẹ mọ́ ọ̀ràn kan yẹ̀ wò kó sì wá yan àkókò tó dára jù lọ láti gbégbèésẹ̀. Pétérù wá sọ nípa bó ṣe wu Jèhófà pé káwọn èèyàn níbi gbogbo ronú pìwà dà. Sùúrù Ọlọ́run máa túmọ̀ sí ìgbàlà fún ọ̀pọ̀ èèyàn tí ì bá ti pa run ká ní Jèhófà ti yára gbégbèésẹ̀ ni. (1 Tímótì 2:3, 4; 2 Pétérù 3:9) Àmọ́ ṣá, sùúrù Jèhófà ò túmọ̀ sí pé kò ní gbégbèésẹ̀ láé. Pétérù sọ pé: “Ọjọ́ Jèhófà yóò dé gẹ́gẹ́ bí olè.”—2 Pétérù 3:10.
11. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti wà lójúfò nípa tẹ̀mí, báwo lèyí sì ṣe lè mú kó dà bí ẹni pé a mú ọjọ́ Jèhófà ‘túbọ̀ yára’ sí i?
11 Àfiwé tí Pétérù ṣe yẹ fún àfiyèsí. Kò rọrùn rárá láti rí olè mú, àmọ́ ó ṣeé ṣe fún olùṣọ́ tó bá wà lójúfò ní gbogbo òru láti kófìrí olè ju olùṣọ́ tó bá ń tòògbé lọ. Báwo ni olùṣọ́ ṣe lè wà lójúfò? Olùṣọ́ lè wà lójúfò tó bá ń rìn káàkiri ju tó bá kàn jókòó sójú kan ní gbogbo òru. Lọ́nà kan náà, táwa Kristẹni ò bá jókòó gẹlẹtẹ sójú kan nípa tẹ̀mí, àá lè wà lójúfò. Ìdí rèé tí Pétérù fi rọ̀ wá pé ká jẹ́ kí ọwọ́ wa dí nínú “ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run.” (2 Pétérù 3:11) Irú àwọn ìgbòkègbodò bẹ́ẹ̀ á mú ká máa bá a lọ ní ‘fífi wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí.’ A lè tú ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a pè ní “fífi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí” ní ṣáńgílítí sí “mímú kí nǹkan túbọ̀ yára.” (2 Pétérù 3:12; àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé) Òótọ́ ni pé a ò lè yí àkókò tí Jèhófà ti yàn kalẹ̀ padà. Àkókò tó ti fúnra rẹ̀ yàn ni ọjọ́ rẹ̀ máa dé. Àmọ́ tá a bá jẹ́ kọ́wọ́ wa dí nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ láti ìsinsìnyí lọ di ìgbà yẹn, ńṣe ló máa dà bí ẹni pé ọjọ́ ń fò.—1 Kọ́ríńtì 15:58.
12. Báwo ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe lè jàǹfààní sùúrù Jèhófà?
12 Nítorí náà, kí ẹnikẹ́ni tó bá rò pé ọjọ́ Jèhófà ò tètè dé fi ìmọ̀ràn Pétérù sọ́kàn láti fi sùúrù dúró de àkókò tí Jèhófà ti fúnra rẹ̀ yàn kalẹ̀. Ní ti tòótọ́, a lè lo àfikún àkókò tí sùúrù Ọlọ́run pèsè lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu. Bí àpẹẹrẹ, a lè lò ó láti kọ́ àwọn ànímọ́ Kristẹni tó ṣe pàtàkì gan-an, a sì lè lò ó láti mú ìhìn rere náà lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn púpọ̀ sí i ju iye tíì bá ṣeé ṣe fún wa láti bá sọ̀rọ̀ ká ní ọjọ́ náà ti dé ni. Tá a bá wà lójúfò, Jèhófà á lè bá wa “ní àìléèérí àti ní àìlábààwọ́n àti ní àlàáfíà,” nígbà tí ètò àwọn nǹkan yìí bá wá sópin. (2 Pétérù 3:14, 15) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńláǹlà lèyí máa jẹ́!
13. Àwọn ọ̀rọ̀ wo ni Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn Kristẹni ní Tẹsalóníkà tó bá òde òní mu gan-an?
13 Pọ́ọ̀lù náà mẹ́nu kan ìdí tó fi ṣe pàtàkì láti wà lójúfò nínú lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ sáwọn Kristẹni tó wà ní Tẹsalóníkà. Ó gbà wọ́n níyànjú pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a máa sùn gẹ́gẹ́ bí àwọn yòókù ti ń ṣe, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a wà lójúfò, kí a sì pa agbára ìmòye wa mọ́.” (1 Tẹsalóníkà 5:2, 6) Ẹ ò rí i pé èyí ṣe pàtàkì gan-an lónìí tí ìparun gbogbo ètò àwọn nǹkan yìí ti dé tán! Inú ayé kan táwọn èèyàn púpọ̀ ò ti nífẹ̀ẹ́ sóhun tẹ̀mí làwọn Kristẹni ń gbé, èyí sì lè nípa lórí wọn. Ìdí rèé tí Pọ́ọ̀lù fi gbani nímọ̀ràn pé: “Ẹ jẹ́ kí a pa agbára ìmòye wa mọ́, kí a sì gbé àwo ìgbàyà ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ wọ̀ àti ìrètí ìgbàlà gẹ́gẹ́ bí àṣíborí.” (1 Tẹsalóníkà 5:8) Kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé àti bíbá àwọn ará kẹ́gbẹ́ pọ̀ déédéé láwọn ìpàdé á ràn wá lọ́wọ́ láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù ká sì fi sọ́kàn pé ìjáfara léwu.—Mátíù 16:1-3.
Ọ̀kẹ́ Àìmọye Èèyàn Wà Lójúfò
14. Àwọn àkọsílẹ̀ oníṣirò wo ló fi hàn pé ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Pétérù láti wà lójúfò?
14 Ǹjẹ́ a rí ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí tí wọ́n ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run pé ká wà lójúfò? Bẹ́ẹ̀ ni o. Nínú ọdún iṣẹ́ ìsìn 2002, àwọn akéde tí iye wọ́n jẹ́ 6,304,645 fi ẹ̀rí rẹ̀ hàn pé àwọn wà lójúfò nípa tẹ̀mí pẹ̀lú bí wọ́n ṣe fi wákàtí 1,202,381,302 sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn. Iye yìí fi ìpín mẹ́ta àti díẹ̀ nínú ọgọ́rùn-ún ju ti ọdún 2001 lọ. Àwọn èèyàn wọ̀nyí kò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ìgbòkègbodò náà. Wọ́n kà á sí ohun tó ṣe pàtàkì ju lọ nínú ìgbésí ayé wọn. Eduardo àti Noemi tí wọ́n wà ní orílẹ̀-èdè El Salvador, fi àpẹẹrẹ irú ẹ̀mí tí ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn wọ̀nyí ní hàn.
15. Ìrírí wo láti orílẹ̀-èdè El Salvador ló fi hàn pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló wà lójúfò nípa tẹ̀mí?
15 Ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn, Eduardo àti Noemi fiyè sí ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù pé: “Ìrísí ìran ayé yìí ń yí padà.” (1 Kọ́ríńtì 7:31) Wọ́n mú bí wọ́n ṣe ń gbé ìgbésí ayé wọn túbọ̀ rọrùn sí i wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà alákòókò kíkún. Bí àkókò ṣe ń lọ, ìbùkún bẹ̀rẹ̀ sí wọlé fún wọn lọ́tùn-ún lósì, wọ́n tiẹ̀ nípìn-ín nínú iṣẹ́ àyíká àti àgbègbè pàápàá. Ìṣòro yọjú, àmọ́ ó dá Eduardo àti Noemi lójú pé ìpinnu tó tọ́ làwọn ṣe pẹ̀lú báwọn ṣe yááfì ìgbádùn nípa tara láti lè ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Ọ̀pọ̀ lára 29,269 akéde—títí kan 2,454 aṣáájú ọ̀nà—ní orílẹ̀-èdè El Salvador, ló ti firú ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ bẹ́ẹ̀ hàn. Èyí jẹ́ ọ̀kan lára ìdí tí iye akéde tó wà lórílẹ̀-èdè náà fi fi ìpín méjì nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ ju ti ọdún tó kọjá lọ.
16. Irú ẹ̀mí wo ni arákùnrin ọ̀dọ́ kan fi hàn ní orílẹ̀-èdè Ĉote d’Ivoire?
16 Irú ẹ̀mí kan náà ni Kristẹni ọ̀dọ́kùnrin kan fi hàn ní orílẹ̀-èdè Côte d’Ivoire. Ó kọ̀wé sí ọ́fíìsì ẹ̀ka pé: “Ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni mí. Àmọ́ mi ò lẹ́nu àtisọ fáwọn ará pé kí wọ́n ṣe aṣáájú ọ̀nà nítorí pé mi ò fi àpẹẹrẹ rẹ̀ lélẹ̀. Èyí ló jẹ́ kí n fi iṣẹ́ olówó gọbọi tí mò ń ṣe sílẹ̀ tí mo sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ àdáni, èyí tó jẹ́ kí n túbọ̀ ráyè fún iṣẹ́ òjíṣẹ́.” Ọ̀dọ́kùnrin yìí di ọ̀kan lára 983 aṣáájú ọ̀nà tí wọ́n ń sìn ní orílẹ̀-èdè Côte d’Ivoire, tí iye wọn jẹ́ 6,701 akéde lọ́dún tó kọjá, to túmọ̀ sí pé wọ́n fi ìpín márùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.
17. Báwo ni ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí kan ní orílẹ̀-èdè Belgium ṣe fi hàn pé ọ̀ràn ẹ̀tanú ò kó ìpayà bá òun rárá?
17 Àìfàyègba-ẹ̀sìn-mìíràn, ẹ̀tanú àti ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ṣì ń fa ìṣòro fáwọn 24,961 akéde Ìjọba ní orílẹ̀-èdè Belgium. Síbẹ̀, ńṣe ni ìtara wọn ń jó bí iná wọn ò sì bẹ̀rù. Nígbà tí ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí gbọ́ táwọn kan sọ pé ẹgbẹ́ aláwo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbi tí wọ́n ti ń kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ìwà híhù nílé ìwé, ó ní kí wọ́n dákun fóun láyè láti sọ fún wọn nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó fi fídíò Jehovah’s Witnesses—The Organization Behind the Name [Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ètò Àjọ Tí Ń Jẹ́ Orúkọ Yẹn] àti ìwé pẹlẹbẹ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ta Ni Wọ́n?, ṣàlàyé fún wọn nípa irú èèyàn táwọn Ẹlẹ́rìí jẹ́. Wọ́n fara mọ́ ohun tó sọ fún wọn, wọ́n sì mọrírì rẹ̀ gan-an. Gbogbo ìbéèrè tó wà nínú ìdánwò tí wọ́n ṣe fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ yìí lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e ló dá lórí ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
18. Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé ìṣòro ètò ọrọ̀ ajé kò pín ọkàn àwọn akéde ní orílẹ̀-èdè Ajẹntínà àti Mòsáńbíìkì níyà kúrò nínú sísin Jèhófà?
18 Ìṣòro ńláǹlà ló ń dojú kọ ọ̀pọ̀ Kristẹni láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Síbẹ̀, wọ́n ń sapá láti má ṣe jẹ́ kí èyí pín ọkàn wọn níyà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé orílẹ̀-èdè Ajẹntínà tó ti dẹnu kọlẹ̀, síbẹ̀, 126,709 akéde ni iye wọn jẹ́ lọ́dún tó kọjá, iye yẹn sì pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ipò òṣì ṣì gbòde kan ní orílẹ̀-èdè Mòsáńbíìkì. Síbẹ̀, 37,563 èèyàn la sọ pé ó lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù, èyí sì fi ìpín mẹ́rin nínú ọgọ́rùn-ún ròkè sí i. Ìgbésí ayé ò rọrùn fún ọ̀pọ̀ èèyàn ní orílẹ̀-èdè Albania, síbẹ̀ iye akéde tó wà ní orílẹ̀-èdè yẹn ti fi ìpín méjìlá nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, àpapọ̀ iye akéde níbẹ̀ báyìí jẹ́ 2,708. Ó ṣe kedere pé ipò àwọn nǹkan tó le koko kò lè dí ẹ̀mí Jèhófà lọ́wọ́ táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá ti ń fi ire Ìjọba náà sí ipò àkọ́kọ́.—Mátíù 6:33.
19. (a) Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé ọ̀pọ̀ àwọn ẹni bí àgùntàn ṣì wà tébi òtítọ́ Bíbélì ń pa? (b) Kí làwọn nǹkan mìíràn tó wà nínú ìròyìn ọdọọdún tó fi hàn pé àwọn Ìránṣẹ́ Jèhófà wà lójúfò nípa tẹ̀mí? (Wo àtẹ ìsọfúnni tó wà lójú ìwé 12 sí 15)
19 Ìpíndọ́gba 5,309,289 ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, olóṣooṣù tá a ṣe kárí ayé lọ́dún tó kọjá fi hàn pé ọ̀pọ̀ àwọn ẹni bí àgùntàn ló ṣì wà tí ebi òtítọ́ Bíbélì ń pa. Àwọn 15,597,746 èèyàn tó wá síbi Ìṣe Ìrántí pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, iye tó sì pọ̀ jù lára wọn ò tíì bẹ̀rẹ̀ sí jọ́sìn Jèhófà. Ǹjẹ́ kí wọ́n jẹ́ kí ìmọ̀ wọn àti ìfẹ́ wọn fún Jèhófà àti ẹgbẹ́ ara máa pọ̀ sí i. Ó ń wúni lórí láti rí i pé “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti “àwọn àgùntàn mìíràn” ń bá a lọ ní síso èso rere bí wọ́n ṣe ń jọ́sìn Ẹlẹ́dàá wọn “tọ̀sán-tòru nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀,” pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn ẹni àmì òróró.—Ìṣípayá 7:15; Jòhánù 10:16.
Kọ́ Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Lára Lọ́ọ̀tì
20. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Lọ́ọ̀tì àti ìyàwó rẹ̀?
20 Òótọ́ ni pé ẹ̀mí ìjẹ́kánjúkánjú àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run pàápàá lè lọọlẹ̀ nígbà mìíràn. Ronú nípa ọmọ ẹ̀gbọ́n Ábúráhámù, ìyẹn Lọ́ọ̀tì. Áńgẹ́lì méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó wá bẹ̀ ẹ́ wò sọ fún un pé Ọlọ́run fẹ́ pa ìlú Sódómù àti Gòmórà run. Ohun tí Lọ́ọ̀tì gbọ́ yìí kò lè ṣe é ní kàyéfì nítorí pé “ìkẹ́ra-ẹni-bàjẹ́ nínú ìwà àìníjàánu àwọn aṣàyàgbàǹgbà pe òfin níjà [ti] kó wàhálà-ọkàn bá [a] gidigidi.” (2 Pétérù 2:7) Síbẹ̀, nígbà táwọn áńgẹ́lì méjì náà fẹ́ mú un kúrò nínú ìlú Sódómù, ńṣe ló “ń lọ́ra ṣáá.” Kò jọ fífà kò jọ wíwọ́ làwọn áńgẹ́lì náà fi mú òun àti ìdílé rẹ̀ kúrò ní ìlú náà. Ẹ̀yìn ìyẹn ni ìyàwó Lọ́ọ̀tì ò tún tẹ̀ lé ìkìlọ̀ táwọn áńgẹ́lì fún un pé kó má wẹ̀yìn. Lílọ́ tó ń lọ́ tìkọ̀ yìí ló mú kó ṣòfò ẹ̀mí. (Jẹ́nẹ́sísì 19:14-17, 26) Jésù kìlọ̀ pé: “Ẹ rántí aya Lọ́ọ̀tì.”—Lúùkù 17:32.
21. Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì láti wà lójúfò nísinsìnyí ju ti ìgbàkígbà rí lọ?
21 Ìṣẹ̀lẹ̀ aburú tó ṣẹ̀ nílùú Pompeii àti Herculaneum, àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ìparun Jerúsálẹ́mù, àpẹẹrẹ Ìkún Omi ọjọ́ Nóà àti ọ̀ràn Lọ́ọ̀tì, jẹ́ ká mọ bó ti ṣe pàtàkì tó láti kọbi ara sí ìkìlọ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà, a mọ àwọn àmì tó ń fi ìgbà ìkẹyìn hàn. (Mátíù 24:3) A ti ya ara wa kúrò nínú ẹ̀sìn èké. (Ìṣípayá 18:4) A gbọ́dọ̀ ṣe bíi tàwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, ká ‘máa fi wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí.’ (2 Pétérù 3:12) Dájúdájú, àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ wà lójúfò nísinsìnyí ju ti ìgbàkígbà rí lọ! Àwọn ìgbésẹ̀ wo la lè gbé, àwọn ànímọ́ wo ló sì yẹ ká ní ká bà a lè wà lójúfò? Àpilẹ̀kọ tó kàn á ṣàyẹ̀wò àwọn kókó wọ̀nyẹn.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Kò jọ pé iye èèyàn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù ní ọ̀rúndún kìíní ju ọ̀kẹ́ mẹ́fà [120,000] lọ. Eusebius ṣírò iye àwọn tó ti àgbègbè Jùdíà lọ sí Jerúsálẹ́mù fún àjọ̀dún Ìrékọjá lọ́dún 70 Sànmánì Tiwa sí ọ̀kẹ́ márùndínlógún [300,000]. Ó ní láti jẹ́ pé àwọn àgbègbè mìíràn ní ilẹ̀ náà làwọn yòókù tó ṣòfò ẹ̀mí ti wá.
b Dájúdájú, lójú Jèhófà, májẹ̀mú tuntun ti rọ́pò Òfin Mósè lọ́dún 33 Sànmánì Tiwa.—Éfésù 2:15.
Báwo Ni Wàá Ṣe Dáhùn?
• Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni kò jẹ́ káwọn Júù tó jẹ́ Kristẹni ṣòfò ẹ̀mí nígbà ìparun Jerúsálẹ́mù?
• Báwo ni ìmọ̀ràn inú lẹ́tà àpọ́sítélì Pétérù àti Pọ́ọ̀lù ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti wà lójúfò?
• Àwọn wo lónìí ló ń fi hàn pé àwọn wà lójúfò gan-an?
• Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú ìtàn Lọ́ọ̀tì àti ìyàwó rẹ̀?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 12-15]
ÌRÒYÌN ỌDÚN IṢẸ́ ÌSÌN 2002 TI ÀWA ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ KÁRÍ AYÉ
(Wo àdìpọ̀)
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa, àwọn Kristẹni tó wà ní Jerúsálẹ́mù tẹ̀ lé ìkìlọ̀ Jésù
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ṣíṣàì jókòó gẹlẹtẹ sójú kan nípa tẹ̀mí á ran àwọn Kristẹni lọ́wọ́ láti wà lójúfò