Obìnrin Náà Jèrè Ìfaradà Tó Ní
Obìnrin Náà Jèrè Ìfaradà Tó Ní
Ọ̀pọ̀ olódodo èèyàn ló ń fẹ́ kí àwọn tó wà nínú ìdílé òun kẹ́kọ̀ọ́ nípa ète Ọlọ́run kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ gbé ìgbésí ayé aláyọ̀. Nígbà tẹ́nì kan bá ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìwà rere àwọn ẹlòmíràn, lọ́mọdé lágbà ló mú kí onítọ̀hún ṣe ìpinnu yẹn. Bí ọ̀ràn Jearim ṣe rí nìyẹn, ìyẹn ọ̀dọ́mọbìnrin ọlọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ní Mẹ́síkò. Òun ló fún àwọn ara ní àkọsílẹ̀ tó tẹ̀ lé e yìí ní àpéjọ àkànṣe kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe.
“Mo fẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé inú mi dùn ayọ̀ mi sì kún. Ẹ jẹ́ kí n sọ ìdí rẹ̀ fún yín. Àwọn òbí mi kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ní ọdún méjìdínlógún sẹ́yìn, wọn ò tí ì bí mi nígbà yẹn. Màmá mi tẹ̀ síwájú, lẹ́yìn náà èmi àti àbúrò mi ọkùnrin tún ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. A wá gbàdúrà pa pọ̀ pé kí Jèhófà jẹ́ kí bàbá mi náà lè wá sí ọ̀nà tó lọ sí ìyè. Ọdún méjìdínlógún ti kọjá, òní yìí sì jẹ́ ọjọ́ àkànṣe fún wa. Bàbá mi ṣe ìrìbọmi lónìí. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé kò mú òpin náà dé ṣáájú ọjọ́ pàtàkì tá a ti ń retí tipẹ́ yìí. Jèhófà o ṣé o!”
Bí ọdún ti ń gorí ọdún, ó dájú pé ìdílé ọ̀dọ́mọbìnrin yìí ti fi ìlànà tó wà nínú ìmọ̀ràn onímìísí inú 1 Pétérù 3:1, 2 sọ́kàn, èyí tó sọ pé: “Ẹ̀yin aya, ẹ wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ tiyín, kí ó lè jẹ́ pé, bí ẹnikẹ́ni kò bá ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ náà, kí a lè jèrè wọn láìsọ ọ̀rọ̀ kan nípasẹ̀ ìwà àwọn aya wọn, nítorí fífi tí wọ́n fi ojú rí ìwà mímọ́ yín pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.” Ó sì dájú pé Jearim tó jẹ́ ọ̀dọ́ náà á ti fi àwọn ọ̀rọ̀ inú Diutarónómì 5:16 sílò, èyí tó sọ pé: “Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ, gẹ́gẹ́ bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti pàṣẹ fún ọ gan-an.” Ó dájú pé fífi irú ìlànà bẹ́ẹ̀ sílò àti fífi sùúrù dúró de àkókò Jèhófà mú ìbùkún yabuga wá fún Jearim àti ìdílé rẹ̀.