Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ǹjẹ́ Ó Bá Ìlànà Ìwé Mímọ́ Mu Kí Kristẹni Fi Bíbélì Búra ní Kóòtù Pé Òótọ́ Ni Gbogbo Nǹkan Tóun Fẹ́ Sọ?
Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu ohun tó máa ṣe nínú ọ̀ràn yìí o. (Gálátíà 6:5) Àmọ́ ṣá, Bíbélì ò lòdì sí kéèyàn búra ní kóòtù pé òótọ́ lòún fẹ́ sọ.
Kì í ṣòní kì í ṣàná tí àṣà bíbúra ti wà káàkiri. Bí àpẹẹrẹ, láyé àtijọ́, àwọn Gíríìkì máa ń na ọwọ́ kan sókè ọ̀run tàbí kí wọ́n gbé ọwọ́ lé pẹpẹ tí wọ́n bá ń búra. Tí ará Róòmù kan bá fẹ́ búra, ńṣe láá gbé òkúta kan dání tá a wá máa sọ pé: “Tí mo bá mọ̀ọ́mọ̀ ṣẹ̀tàn, bí [òrìṣà] Jupiter ṣe ń dáàbò bo ìlú yìí àti odi rẹ̀ ni kó máa gbé ire gbogbo sọ nù kúrò láyé mi, bí mo ṣe máa sọ òkúta yìí nù.”—Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Cyclopedia of Biblical, Theological, and Ecclesiastical Literature, látọwọ́ John McClintock àti James Strong, Apá Keje, ojú ìwé 260.
Irú àwọn ìgbésẹ̀ yìí fi hàn pé ẹ̀dá èèyàn mọ̀ pé alágbára ńlá kan ń bẹ tó ń wo ẹ̀dá èèyàn òun sì ni wọ́n máa jíhìn fún. Látìgbà ìwáṣẹ̀ láwọn olóòótọ́ olùjọ́sìn Jèhófà ti mọ̀ pé Jèhófà mọ ohun táwọn ń sọ àtèyí táwọn ń ṣe. (Òwe 5:21; 15:3) A lè sọ pé wọ́n máa ń búra níwájú Ọlọ́run tàbí kí wọ́n fi í ṣe ẹlẹ́rìí. Bí àpẹẹrẹ, Bóásì, Dáfídì, Sólómọ́nì àti Sedekáyà, ṣe bẹ́ẹ̀. (Rúùtù 3:13; 2 Sámúẹ́lì 3:35; 1 Àwọn Ọba 2:23, 24; Jeremáyà 38:16) Àwọn olùjọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ pàápàá tiẹ̀ gbà káwọn èèyàn mú wọn wá sábẹ́ ìbúra. Èyí rí bẹ́ẹ̀ nínú ọ̀ràn Ábúráhámù àti Jésù Kristi.—Jẹ́nẹ́sísì 21:22-24; Mátíù 26:63, 64.
Láwọn ìgbà mìíràn, ẹni tó bá ń búra níwájú Jèhófà máa ń ṣe àwọn ohun kan láti fi èyí hàn. Ábúrámù (Ábúráhámù) sọ fún ọba Sódómù pé: “Mo gbé ọwọ́ mi sókè ní ti gidi ní ìbúra sí Jèhófà Ọlọ́run Gíga Jù Lọ, Ẹni tí Ó Ṣe ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 14:22) Áńgẹ́lì kan tó ń bá wòlíì Dáníẹ́lì sọ̀rọ̀ “bẹ̀rẹ̀ sí gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti ọwọ́ òsì rẹ̀ sókè ọ̀run, tí ó sì fi Ẹni tí ó wà láàyè fún àkókò tí ó lọ kánrin búra.” (Dáníẹ́lì 12:7) Kódà, a sọ ọ́ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ pé Ọlọ́run gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè láti búra.—Diutarónómì 32:40; Aísáyà 62:8.
Ìwé Mímọ́ kò lòdì sí kéèyàn búra o. Àmọ́ ṣá, kò yẹ kó jẹ́ pé gbogbo ọ̀rọ̀ tí Kristẹni kan bá ń sọ láá máa fi ìbúra ṣe ẹ̀rí rẹ̀. Jésù sọ pé: “Kí ọ̀rọ̀ yín Bẹ́ẹ̀ ni sáà túmọ̀ sí Bẹ́ẹ̀ ni, Bẹ́ẹ̀ kọ́ yín, Bẹ́ẹ̀ kọ́.” (Mátíù 5:33-37) Ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù tún sọ bẹ́ẹ̀. Nígbà tó sọ pé ẹ “dẹ́kun bíbúra,” ohun tó ní lọ́kàn ni pé kéèyàn ṣọ́ra fún fífi ọ̀ràn ìbúra ṣe nǹkan ṣeréṣeré. (Jákọ́bù 5:12) Kò sí ìkankan nínú Jésù àti Jákọ́bù tó sọ pé kò bójú mu láti búra ní kóòtù gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé òótọ́ lohun téèyàn fẹ́ sọ.
Bí wọ́n bá ní kí Kristẹni kan búra pé òótọ́ ni ẹ̀rí tóun wá jẹ́ ní kóòtù ńkọ́? Ó lè búra tó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀. Tí ò bá sì fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n lè gbà á láyè kó kàn sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan tẹ́ni tí ò fẹ́ búra máa ń sọ láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òótọ́ lohun tóun fẹ́ sọ.—Gálátíà 1:20.
Tó bá di pé èèyàn gbọ́dọ̀ gbé ọwọ́ sókè tàbí gbé e lórí Bíbélì tó bá ń búra nínú kóòtù, Kristẹni kan lè gbà láti ṣe èyí. Ó lè ronú nípa àpẹẹrẹ tó wà nínú Ìwé Mímọ́ nípa báwọn èèyàn ṣe máa ń fara ṣàpèjúwe láti fi hàn pé àwọn ń búra. Ohun tó ṣe pàtàkì ju fífara ṣàpèjúwe nígbà ti Kristẹni kan bá ń búra ni pé kó rántí pé iwájú Ọlọ́run lòun ti ń búra pé òun á sọ òtítọ́. Irú ìbúra bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ọ̀ràn kékeré rárá. Bí Kristẹni kan bá mọ̀ pé òun lè dáhùn àwọn ìbéèrè tí wọ́n bá bi í lákòókò yìí, tó sì pọn dandan pé ó gbọ́dọ̀ dáhùn rẹ̀, onítọ̀hún gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé òun ti búra láti sọ òtítọ́, ohun táwọn Kristẹni sì ń fẹ́ ṣe ní gbogbo ìgbà nìyẹn.