Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Ẹni Rere Ń rí Ojú Rere Ọlọ́run’

‘Ẹni Rere Ń rí Ojú Rere Ọlọ́run’

‘Ẹni Rere Ń rí Ojú Rere Ọlọ́run’

JÈHÓFÀ Ọlọ́run ni orísun gbogbo ìwàláàyè. (Sáàmù 36:9) Dájúdájú, “nípasẹ̀ rẹ̀ ni àwa ní ìwàláàyè, tí a ń rìn, tí a sì wà.” (Ìṣe 17:28) Àbí inú wa kì í dùn tí ẹnu wa sì máa ń kún fún ọpẹ́ nígbà tá a bá wo èrè tó ń fún àwọn tó bá ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀? Àní, “ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni ni ìyè àìnípẹ̀kun.” (Róòmù 6:23) Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì púpọ̀ pé ká sapá ká lè rí ojú rere Jèhófà!

Onísáàmù náà mú un dá wa lójú pé ‘Ọlọ́run ń fi ojú rere fúnni.’ (Sáàmù 84:11) Àmọ́ àwọn wo ló máa ń fi fún? Lóde òní, bí ẹnì kan ṣe kàwé tó, bó ṣe lọ́rọ̀ tó, àwọ̀ rẹ̀, ẹ̀yà rẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ làwọn èèyàn máa ń wò kí wọ́n tó ṣe é lóore. Àmọ́ àwọn wo ni Jèhófà máa ń ṣojú rere sí? Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì dáhùn pé: “Ẹni rere ń rí ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Jèhófà, ṣùgbọ́n ènìyàn elérò-ọkàn burúkú ni ó ń pè ní ẹni burúkú.”Òwe 12:2.

Ó ṣe kedere pé ẹni rere—tó níwà ọmọlúwàbí, ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́ sí. Lára ìwà ọmọlúwàbí tí ẹni rere máa ń ní ni ìsẹ́ra ẹni, àìṣègbè, ìrẹ̀lẹ̀, ìyọ́nú àti òye. Kì í ro ìròkurò lọ́kàn, ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ ń fúnni níṣìírí, kì í ṣègbè, ìwà rẹ̀ sì ń ṣeni láǹfààní. Apá àkọ́kọ́ orí kejìlá ìwé Òwe jẹ́ ká mọ̀ bí ìwà rere ṣe gbọ́dọ̀ máa darí ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́, ó sì tún sọ àwọn àǹfààní tá a lè rí nínú ànímọ́ yìí. Ṣíṣàyẹ̀wò ohun tó wà níbẹ̀ á fún wa ní “ìjìnlẹ̀ òye fún ṣíṣe rere.” (Sáàmù 36:3) Àá rí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run tá a bá fi ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó wà níbẹ̀ sílò.

Ìbáwí Ṣe Kókó

Sólómọ́nì sọ pé: “Olùfẹ́ ìbáwí jẹ́ olùfẹ́ ìmọ̀, ṣùgbọ́n olùkórìíra ìbáwí àfitọ́nisọ́nà jẹ́ aláìnírònú.” (Òwe 12:1) Ẹni rere máa ń fẹ́ ṣe àtúnṣe tó bá yẹ, ìdí nìyẹn tó fi ń fẹ́ ìbáwí. Kíá ló máa ń fi àwọn ìmọ̀ràn tó bá gbà láwọn ìpàdé Kristẹni àtèyí tó rí nínú ìjíròrò pẹ̀lú àwọn mìíràn sílò. Ńṣe làwọn ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ àtàwọn ìtẹ̀jáde tá a gbé karí Bíbélì dà bí ọ̀pá ẹlẹ́nu ṣóṣóró, tó ń gún un ní kẹ́sẹ́ láti máa tọ ọ̀nà tó tọ́. Ó máa ń wá ìmọ̀ ó sì ń lò ó láti tún ipa ọ̀nà rẹ̀ ṣe. Dájúdájú, ẹni tó bá fẹ́ràn ìbáwí á fẹ́ràn ìmọ̀ pẹ̀lú.

Ẹ ò rí i pé ìbáwí ṣe pàtàkì gan-an fáwọn olùjọ́sìn tòótọ́—pàápàá jù lọ ìsẹ́ra ẹni! A lè fẹ́ láti ní ìmọ̀ tó jinlẹ̀ nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó lè máa wù wá láti túbọ̀ di ògbóṣáṣá nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni ká sì lè di olùkọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó gbéṣẹ́ sí i. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Àmọ́ ó gba ìsẹ́ra ẹni kéèyàn tó lè ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí. Ìsẹ́ra ẹni tún ṣe pàtàkì láwọn apá ibòmíràn nínú ìgbésí ayé. Bí àpẹẹrẹ, àìmọye nǹkan làwọn èèyàn ń ṣe lónìí láti ru ẹ̀mí ìṣekúṣe sókè. Ǹjẹ́ kò béèrè fún ìsẹ́ra ẹni láti má ṣe jẹ́ kí ojú wa wo ìwòkuwò? Bákan náà ni èròkerò lè jẹ yọ látinú ọkàn wa lọ́hùn-ún nítorí pé “ìtẹ̀sí èrò ọkàn-àyà ènìyàn jẹ́ búburú láti ìgbà èwe rẹ̀ wá.” (Jẹ́nẹ́sísì 8:21) A nílò ìsẹ́ra ẹni láti má ṣe máa gbé ìrònú wa ka àwọn èrò wọ̀nyí.

Àmọ́ ṣá, ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ ìbáwí kórìíra ìmọ̀ àti ìbáwí. Ó máa ń jẹ́ kí èròkerò ẹ̀dá èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ sún un láti kọ ìbáwí, á wá sọ ara rẹ̀ di ọgbọọgba pẹ̀lú ẹranko tí kì í ronú—ẹranko lásánlàsàn—tí kò níwà rere kọ́bọ̀. A gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá wa kí èyí má bàa ṣẹlẹ̀ sí wa.

“Gbòǹgbò Tí Kò Ṣe É Fà Tu”

Ó dájú pé èèyàn rere kì í hùwà àìṣòdodo, kì í sì í ṣègbè. Èyí fi hàn pé òdodo tún ṣe pàtàkì láti rí ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà. Dáfídì Ọba kọ ọ́ lórin pé: “Ìwọ tìkára rẹ, Jèhófà, yóò bù kún olódodo; ìtẹ́wọ́gbà ni ìwọ yóò fi yí wọn ká bí apata ńlá.” (Sáàmù 5:12) Nígbà tí Sólómọ́nì ń sọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín olódodo àti ẹni búburú, ó sọ pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí yóò fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in nípasẹ̀ ìwà burúkú; ṣùgbọ́n ní ti gbòǹgbò ìpìlẹ̀ àwọn olódodo, a kì yóò mú kí ó ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́.”Òwe 12:3.

Ó lè dà bí ẹni pé nǹkan ń ṣẹnuure fún èèyàn búburú. Gbé àpẹẹrẹ onísáàmù náà Ásáfù yẹ̀ wò. Ó sọ pé: “Ní tèmi, ẹsẹ̀ mi fẹ́rẹ̀ẹ́ yà kúrò lọ́nà, díẹ̀ ló kù kí a mú ìṣísẹ̀ mi yọ̀ tẹ̀rẹ́.” Kí ló fa èyí? Ó dáhùn pé: “Èmi ṣe ìlara àwọn aṣògo, nígbà tí mo rí àlàáfíà àwọn ènìyàn burúkú.” (Sáàmù 73:2, 3) Àmọ́ nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí wá sí tẹ́ńpìlì mímọ́ Ọlọ́run, ó wá rí i pé orí ilẹ̀ yíyọ̀ bọ̀rọ́ ni Jèhófà fi àwọn èèyàn náà sí. (Sáàmù 73:17, 18) Àṣeyọrí èyíkéyìí tó lè dà bí ẹni pé àwọn ẹni búburú ní kò lè tọ́jọ́. Kí la óò wá máa jowú wọn sí?

Àmọ́ ti ẹni tó bá ti rí ojú rere Jèhófà kò rí bẹ́ẹ̀ o, ńṣe ló máa fẹsẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in. Sólómọ́nì lo àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ nípa bí igi ṣe máa ń ní gbòǹgbò tó ṣòro láti fà tu, ó sọ pé: “Àwọn èèyàn rere ní gbòǹgbò tí kò ṣeé fà tu.” (Òwe 12:3, The New English Bible) Igi tó bá tóbi ràbàtà máa ń láwọn gbòǹgbò kan téèyàn ò lè rí, tó lè nasẹ̀ dé ibi tó lé ní hẹ́kítà kan àbọ̀ lábẹ́ ilẹ̀. Àwọn gbòǹgbò yìí lè mú kí igi ńlá náà dúró digbí lásìkò ìkún omi tàbí ìjì ńlá. Ilẹ̀ ríri pàápàá ò lè ṣe ohunkóhun fún igi tó bá tóbi dáadáa.

Bíi ti àwọn gbòǹgbò wọ̀nyí nínú ilẹ̀ ọlọ́ràá tá a fi orí ilẹ̀ ayé ṣàpèjúwe ní èrò inú àti ọkàn-àyà wa ṣe gbọ́dọ̀ ta gbòǹgbò káàkiri nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kó sì máa fa omi rẹ̀ tó ń fúnni ní ìyè mu. Èyí á jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa fìdí múlẹ̀ gbọn-in, ìrètí wa á dájú mìmì kan ò sì ní lè mì ín. (Hébérù 6:19) A ò ní di ẹni tí à “ń gbé síhìn-ín sọ́hùn-ún nípasẹ̀ gbogbo ẹ̀fúùfù ẹ̀kọ́ [èké].” (Éfésù 4:14) Lóòótọ́, kì í ṣe pé àwọn àdánwò tó lágbára ò ní ṣẹlẹ̀ si wa o, ẹ̀rù tiẹ̀ lè bà wá pàápàá nígbà tí ìpọ́njú bá dé. Àwọn nǹkan yìí ò lè mú kí ‘gbòǹgbò’ wa ‘tó ti fìdí múlẹ̀ gbọn-in bẹ̀rẹ̀ sí í mì.’

“Aya Tí Ó Dáńgájíá Jẹ́ Adé fún Olúwa Rẹ̀”

Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń sọ ọ́ pé, “Ọkùnrin ò lè ṣàṣeyọrí láìjẹ́ pé ìyàwó rere tì í lẹ́yìn.” Nígbà tí Sólómọ́nì ń sọ̀rọ̀ nípa obìnrin tó ń ti ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn, ó sọ pé: “Aya tí ó dáńgájíá jẹ́ adé fún olúwa rẹ̀, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìjẹrà nínú egungun olúwa rẹ̀ ni obìnrin tí ń hùwà lọ́nà tí ń tini lójú.” (Òwe 12:4) Ọ̀rọ̀ náà “dáńgájíá” ṣàkópọ̀ oríṣiríṣi ànímọ́ tó túmọ̀ sí ìwà rere. Ìwà rere ìyàwó dáadáa, gẹ́gẹ́ bí Òwe orí kọkànlélọ́gbọ̀n ṣe sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀, ní jíjẹ́ aláápọn, jíjẹ́ olóòótọ́ àti jíjẹ́ ọlọgbọ́n nínú. Obìnrin tó bá láwọn ànímọ́ wọ̀nyí jẹ́ adé fún ọkọ rẹ̀ nítorí pé ìwà rere rẹ̀ á mú káwọn èèyàn bọlá fún ọkọ rẹ̀ wọ́n á sì máa gbé e gẹ̀gẹ̀. Irú obìnrin bẹ́ẹ̀ ò jẹ́ bá ọkọ rẹ̀ du ipò tàbí bá a fẹsẹ̀ wọnsẹ̀ láé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe lá máa kọ́wọ́ ti ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn.

Báwo ni obìnrin kan ṣe lè hùwà lọ́nà tó ń tini lójú, kí ló sì lè tìdí èyí jáde? Ìwà ìtìjú yìí lè jẹ́ látorí ìwà asọ̀ dórí panṣágà. (Òwe 7:10-23; 19:13) Tí ìyàwó bá hu irú ìwà yìí, ńṣe ló fi ń rẹ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀. Ìwé kan tá a ṣe ìwádìí nínú rẹ̀ sọ pé ńṣe ló dà bí “ìjẹrà nínú egungun” fún ọkọ rẹ̀ ní ti pé “ńṣe ló máa bayé ọkọ rẹ̀ jẹ́, bíi ti àrùn kan tó máa ń ba àgọ́ ara jẹ́.” Ìwé mìíràn sọ pé: “Ọ̀rọ̀ mìíràn tó bá a dọ́gba lóde òní lè jẹ́ ‘àrùn jẹjẹrẹ’—tó jẹ́ àrùn burúkú tó rọra máa ń ba tèèyàn jẹ́.” Ǹjẹ́ káwọn aya Kristẹni gbìyànjú láti jèrè ojú rere Ọlọ́run nípa híhu ìwà rere ti aya tó dáńgájíá.

Èrò Ọkàn Ẹni Nìwà Ẹni, Ìwà Ẹni Á sì Lẹ́san

Ohun téèyàn ń rò lọ́kàn ló fi ń hùwà, ìwà tó sì hù kò ní ṣàì ní àbájáde. Sólómọ́nì tún tẹ̀ síwájú nípa sísọ béèyàn ṣe ń fi ohun tó ń rò lọ́kàn ṣèwà hù, ó sì ṣe ìfiwéra láàárín ẹni rere àti ẹni búburú. Ó sọ pé: “Ìrònú àwọn olódodo jẹ́ ìdájọ́; ìdarí láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹni burúkú jẹ́ ẹ̀tàn. Ọ̀rọ̀ àwọn ẹni burúkú jẹ́ lílúgọ de ẹ̀jẹ̀, ṣùgbọ́n ẹnu àwọn adúróṣánṣán ni yóò dá wọn nídè.”Òwe 12:5, 6.

Àwọn èèyàn rere kì í ro èròkerò, àìṣègbè àti òdodo ló máa ń wà lọ́kàn wọn. Ìfẹ́ Ọlọ́run àti tàwọn ẹ̀dá èèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn ló ń sún àwọn adúróṣinṣin ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe, ìdí rèé tí wọn kì í fi í ronú ibi. Àmọ́ ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan ló ń sún àwọn ẹni búburú ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe. Èyí ló fi jẹ́ pé ọ̀nà ẹ̀tàn ni wọ́n ń gbà kọ́wọ́ wọn lè tẹ ohun tí wọ́n ń wá. Ìwà àdàkàdekè ló wà lọ́wọ́ wọn. Ara máa ń yá wọn láti dẹ pàkúté fẹ́ni ẹlẹ́ni tí ò mọwọ́mẹsẹ̀, bóyá nípa fífẹ̀sùn èké kàn án ní kóòtù. Ọ̀rọ̀ ẹnu wọn jẹ́ “lílúgọ de ẹ̀jẹ̀,” nítorí pé ńṣe ni wọ́n fẹ́ ṣe aláìmọwọ́mẹsẹ̀ tó kó sí wọn lọ́wọ́ léṣe. Kìkì àwọn adúróṣánṣán, tí wọ́n ti mọ èrò burúkú tẹ́ni ibi ní, tí wọ́n sì ti mọ ọgbọ́n tí wọ́n á fi máa ṣọ́ra, nìkan ni ò ní kó sínú ewu yìí. Wọ́n tiẹ̀ lè kìlọ̀ fáwọn tí ò mọ̀ pé ewu ń bẹ kí wọ́n sì gbà wọ́n lọ́wọ́ ètekéte ẹni ibi náà.

Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn adúróṣánṣán àtàwọn ẹni ibi? Sólómọ́nì dáhùn pé: “Ìbìṣubú àwọn ẹni burúkú ṣẹlẹ̀, wọn kò sì sí mọ́, ṣùgbọ́n ilé àwọn olódodo yóò máa bá a nìṣó ní dídúró.” (Òwe 12:7) Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé, ilé náà “dúró fún agbo ilé àti gbogbo ohun ṣíṣeyebíye tí ẹni náà ní, èyí á mú kí ẹni náà lè máa wà láàyè.” Ó tiẹ̀ lè tọ́ka sí ìdílé àti àtọmọdọ́mọ olódodo pàápàá. Èyí ó wù ó jẹ́, kókó inú òwe náà ni pé: Àwọn olódodo á dúró gbọn-in lákòókò ìṣòro.

Àlàáfíà fún Onírẹ̀lẹ̀

Nígbà tí ọba Ísírẹ́lì ń sọ bó ti ṣe pàtàkì tó láti ní ìfòyemọ̀, ó sọ pé: “A ó yin ènìyàn nítorí ẹnu rẹ̀ tí ó fi ọgbọ́n inú hàn, ṣùgbọ́n ẹni tí ó jẹ́ onímàgòmágó ní ọkàn-àyà yóò wá di ìfojú-tín-ín-rín.” (Òwe 12:8) Ẹni tó ní ìfòyemọ̀ kì í ṣàdédé lanu gbàgà kí ọ̀rọ̀ sì jáde. Ó máa ń ronú kó tó sọ̀rọ̀, àárín òun àtàwọn ẹlòmíràn sì máa ń tòrò nítorí pé “ẹnu rẹ̀ tí ó fi ọgbọ́n inú hàn” ń jẹ́ kó ro irú ọ̀rọ̀ tóun á sọ jáde lẹ́nu. Táwọn èèyàn bá bẹ̀rẹ̀ sí béèrè àwọn ìbéèrè òpònú àtèyí tí ò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀, ńṣe lẹni tó ní ìfòyemọ̀ ‘má ń fawọ́ àwọn àsọjáde rẹ̀ sẹ́yìn.’ (Òwe 17:27) A máa ń gbóríyìn fún irú ẹni bẹ́ẹ̀, inú Jèhófà sì máa ń dùn sí i. Ẹ ò rí i pé ó yàtọ̀ gan-an sí ẹni tó jẹ́ pé èròkerò ló ń ti ‘ọkàn-àyà rẹ̀ onímàgòmágó’ jáde!

Òótọ́ la máa ń gbóríyìn fún ẹni tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n o, àmọ́ òwe tó kàn báyìí jẹ́ ká mọ bi ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ti ṣe pàtàkì tó. Ó sọ pé: “Ẹni tí a kò fi bẹ́ẹ̀ kà sí, ṣùgbọ́n tí ó ní ìránṣẹ́, sàn ju ẹni tí ń ṣe ara rẹ̀ lógo ṣùgbọ́n tí ó ṣaláìní oúnjẹ.” (Òwe 12:9) Ó dà bí ẹni pé ohun tí Sólómọ́nì ń sọ ni pé ó sàn kéèyàn jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ láìní ọrọ̀, kí olúwarẹ̀ má sì ní ju ìránṣẹ́ kan péré lọ, ju pé kéèyàn máa ná gbogbo nǹkan tí ì bá fi ní àwọn ohun kòṣeémánìí ìgbésí ayé sórí bó ṣe máa gbé ìgbésí ayé ọlọ́lá. Ojúlówó àmọ̀ràn lèyí jẹ́ fún wa o—pé ká ṣe bá a ti mọ!

Ẹ̀kọ́ Nípa Ìwà Rere Ń Bẹ Nínú Iṣẹ́ Àgbẹ̀

Sólómọ́nì fi iṣẹ́ àgbẹ̀ ṣe àkàwé, ó sì kọ́ni ní ẹ̀kọ́ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nípa ìwà rere. Ó sọ pé: “Olódodo ń bójú tó ọkàn ẹran agbéléjẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ìkà ni àánú àwọn ẹni burúkú.” (Òwe 12:10) Olódodo èèyàn máa ń fi inú rere bójú tó àwọn ẹran rẹ̀. Ó mọ ohun tí wọ́n nílò kì í sì í fi ọ̀ràn wọn ṣeré rárá. Èèyàn búburú lè máa sọ ọ́ lẹ́nu pé òun fẹ́ràn àwọn ẹran òun, àmọ́ kì í bìkítà nípa wọn. Gbogbo èrò ọkàn rẹ̀ kò ju ti ìmọtara-ẹni-nìkan, èrè tó sì máa jẹ lórí wọn nìkan lohun tó jẹ ẹ́ lógún. Ohun tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ kà sí ìtọ́jú tó yẹ fún àwọn ẹran náà lè jẹ́ ìwà ìkà tó burú jáì.

Ìlànà tó sọ pé kéèyàn má ṣe hùwà ìkà sáwọn ẹranko tún kan àwọn ẹran ọ̀sìn nínú ilé. Ìwà ìkà gbáà ló máa jẹ́ kéèyàn ní ohun ọ̀sìn àmọ́ kó máa fìyà jẹ wọ́n tàbí kó máa ṣe wọ́n níṣekúṣe! Tó bá sì ṣẹlẹ̀ pé àìsàn líle kọ lu ẹran kan tàbí tó ṣèṣe, tó sì ǹ fa ìrora ńláǹlà fún un, inú rere lè gba pé kéèyàn kúkú pa ẹran náà.

Sólómọ́nì tún mẹ́nu ba oríṣi iṣẹ́ àgbẹ̀ mìíràn—ìyẹn ṣíṣọ̀gbìn—ó sọ pé: “Ẹni tí ń ro ilẹ̀ ara rẹ̀ ni a ó fi oúnjẹ tẹ́ òun fúnra rẹ̀ lọ́rùn.” Lóòótọ́, àǹfààní wà nínú ojúlówó iṣẹ́ àṣekára. “Ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa àwọn ohun tí kò ní láárí jẹ́ ẹni tí ọkàn-àyà kù fún.” (Òwe 12:11) Àìní òye àti ìmọ̀ ló ń mú kí ẹni tí “ọkàn-àyà kù fún” máa sáré lé àwọn okòwò tó ń fàkókò ṣòfò, tó léwu, tí ò sì ní láárí. Ẹ̀kọ́ inú ẹsẹ méjèèjì yìí kò fara sin rárá: Jẹ́ aláàánú kó o sì tẹpá mọ́ṣẹ́.

Olódodo Ń Gbilẹ̀

Ọlọ́gbọ́n ọba náà sọ pé: “Ojú ẹni burúkú wọ ẹran ọdẹ tí a fi àwọ̀n mú tí ó jẹ́ ti àwọn ènìyàn búburú.” (Òwe 12:12a) Báwo ni ẹni burúkú ṣe ń ṣe èyí? Nípa nínífẹ̀ẹ́ sí ohun táwọn kan fi èrú kó jọ.

Àmọ́ ẹni rere wá ń kọ́? Òun ní tiẹ̀ fẹ́ràn ìbáwí ó sì dúró déédéé nínú ìgbàgbọ́. Olódodo ni kì í sì í ṣègbè, ó gbọ́n ó sì níwà ìrẹ̀lẹ̀, ó lójú àánú kì í sì í ṣọ̀lẹ. Àmọ́ Sólómọ́nì sọ pé: “ní ti gbòǹgbò àwọn olódodo, ó ń so,” tàbí “gbilẹ̀.” (Òwe 12:12b) Bíbélì An American Translation sọ pé: “Gbòǹgbò olódodo yóò wà títí láé.” Mìmì kan ò lè mi irú ẹni bẹ́ẹ̀, kò sì séwu fún un. Láìṣe àní-àní, ‘ẹni rere ń rí ojú rere Ọlọ́run.’ Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká ‘gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ká sì máa ṣe rere.’—Sáàmù 37:3.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Ìgbàgbọ́ olódodo fìdí múlẹ̀ dáadáa bí igi tára rẹ̀ le koránkorán