Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Òótọ́ Inú Dára, àmọ́ Ṣé Ó Tó?

Òótọ́ Inú Dára, àmọ́ Ṣé Ó Tó?

Òótọ́ Inú Dára, àmọ́ Ṣé Ó Tó?

ǸJẸ́ ó tiẹ̀ dáa ká máa lo òótọ́ inú nínú ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́? Ohun tí òótọ́ inú túmọ̀ sí ni pé kéèyàn máà díbọ́n, kó má sì ṣe àgàbàgebè; kó jẹ́ aláìlábòsí; tó ń fi òtítọ́ hùwà; ti kì í sì í ṣe onímàgòmágó. Ó hàn gbangba pé ànímọ́ yìí wúlò gan-an láti jẹ́ ká ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbani níyànjú pé: “Ẹ jẹ́ onígbọràn nínú ohun gbogbo sí àwọn tí wọ́n jẹ́ ọ̀gá yín nípa ti ara, kì í ṣe pẹ̀lú àwọn ìṣe àrójúṣe, gẹ́gẹ́ bí olùwu ènìyàn, ṣùgbọ́n pẹ̀lú òtítọ́ ọkàn-àyà, pẹ̀lú ìbẹ̀rù Jèhófà.” (Kólósè 3:22) Ta ni inú rẹ̀ ò ní í dùn láti rí i pé irú olóòótọ́ èèyàn bẹ́ẹ̀ ló ń bá òun ṣiṣẹ́? Lóde òní, àwọn olóòótọ́ èèyàn lè tètè ríṣẹ́ ṣáájú àwọn mìíràn, iṣẹ́ kì í sì í tètè bọ́ lọ́wọ́ wọn.

Àmọ́, ohun tó jẹ́ kí òótọ́ inú dára jù lọ ni ọ̀nà tó gbà ń nípa lórí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì máa ń rí ìbùkún Ọlọ́run nígbà tí wọ́n bá pa àwọn òfin mọ́ dáadáa tí wọ́n sì ṣe àwọn àjọ̀dún tó yẹ ní ṣíṣe. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń jíròrò nípa bí ìjọ ṣe gbọ́dọ̀ wà ní mímọ́ tónítóní, ó rọ àwọn Kristẹni pé: “Ẹ jẹ́ kí a pa àjọyọ̀ mọ́, kì í ṣe pẹ̀lú ògbólógbòó ìwúkàrà, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà burúkú, ṣùgbọ́n pẹ̀lú àkàrà aláìwú ti òtítọ́ inú àti òtítọ́.” (1 Kọ́ríńtì 5:8) Kì í ṣe pé òótọ́ inú dára nìkan ni àmọ́ ó tún ṣe pàtàkì pàápàá tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run gba ìjọsìn wa. Síbẹ̀, mọ̀ dájú pé òótọ́ inú nìkan ò tó. Òtítọ́ gbọ́dọ̀ bá a rìn.

Ó ṣeé ṣe káwọn tó ṣe ọkọ Tìtáníìkì àtàwọn èrò tó wọ̀ ọ́ fi tọkàntọkàn gbà pé ọkọ̀ òkun ńlá náà ò lè rì láé. Àmọ́ ìgbà àkọ́kọ́ tó máa rìn lórí òkun lọ́dún 1912 ló forí sọ òkìtì yìnyín kan tí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ ó lé mẹ́tàdínlógún [1,517] èèyàn sì pàdánù ẹ̀mí wọn. Bẹ́ẹ̀ làwọn Júù kan ní ọ̀rúndún kìíní ti ní láti fi tọkàntọkàn gbà pé ọ̀nà tó tọ́ làwọn gbà ń jọ́sìn Ọlọ́run, àmọ́ tí ìtara wọn kò sí “ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye.” (Róòmù 10:2) Kí Ọlọ́run tó lè tẹ́wọ́ gbà wá, ohun tá a fi tọkàntọkàn gbà gbọ́ ní láti jẹ́ èyí tá a gbé karí ìsọfúnni tó péye. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣàyẹ̀wò ohun tí sísin Ọlọ́run pẹ̀lú òótọ́ inú àti òtítọ́ wé mọ́.