A Dàn Mi Wò Lọ́nà Tó Múná
Ìtàn Ìgbésí Ayé
A Dàn Mi Wò Lọ́nà Tó Múná
GẸ́GẸ́ BÍ PERICLES YANNOURIS ṢE SỌ Ọ́
Ọ̀rinrin inú yàrá ọgbà ẹ̀wọ̀n bíbu náà mú mi lótùútù gan-an. Bí mo ṣe dá nìkan jókòó, pẹ̀lú bùláńkẹ́ẹ̀tì fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí mo fi bora, mò ṣì ń rántí bí ojú ìyàwó mi ṣe fà ro nígbà táwọn kan tó máa ń ṣe bí ológun wá wọ́ mí kúrò nílé mi ní ọjọ́ méjì sẹ́yìn, tí wọ́n fi òun nìkan àtàwọn ọmọ wa méjì tó ń ṣàìsàn sílẹ̀. Nígbà tó yá, ìyàwó mi, tí ìsìn rẹ̀ yàtọ̀ sí tèmi, fi àpò ìwé kan ránṣẹ́ sí mi, ó sì kọ lẹ́tà kan sínú rẹ tó kà pé: “Gba àkàrà òyìnbó tí mo fi ránṣẹ́ sí ọ yìí, mo mọ̀ pé ìwọ náà á máa ṣàìsàn lọ́wọ́ bíi tàwọn ọmọ rẹ.” Ǹjẹ́ màá tún padà sílé láàyè kí n sì tún fojú rí ìdílé mì?
ÌYẸN wulẹ̀ jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ kan lára ìjà líle koko ọlọ́jọ́ gbọọrọ tí mo jà nítorí ìgbàgbọ́ Kristẹni, ìjàkadì tó ní àtakò ìdílé, líléni-kúrò-láwùjọ, ogun, àti inúnibíni líle koko nínú. Àmọ́ báwo lèmi, ti mo tutù lẹ́dàá tí mo sì bẹ̀rù Ọlọ́run ṣe ní láti bá ara mi níbi burúkú yẹn? Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé.
Ọmọdékùnrin Tó Ń Lépa Ohun Tó Ga
Nígbà tí wọ́n bí mi lọ́dún 1909 ní abúlé Stavromeno tó wà ní Kírétè, inú ogun, ipò òṣì, àti ìyàn ni orílẹ̀-èdè náà wà lákòókò yẹn. Nígbà tó yá, díẹ̀ ló kù kí àjàkálẹ̀-àrùn gágá gbẹ̀mí èmi àtàwọn àbúrò mi mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. Mo rántí pé ìgbà kan wà táwọn òbí wa tì wá mọ́lé fún ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ ká má bàa kó àrùn náà.
Bàbá wa tó jẹ́ àgbẹ̀ tí kò sì fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ, kì í fọ̀rọ̀ ìsìn ṣeré rárá àmọ́ kò ní ẹ̀tanú. Ilẹ̀ Faransé àti Madagascar tó gbé ti jẹ́ kó ní èrò tí kò pọ̀n sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan nípa ìsìn. Àmọ́, ìdílé wa kò fi Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì sílẹ̀, àràárọ̀ Sunday la máa ń lọ sí Máàsì, ilé wa sì ni bíṣọ́ọ̀bù àdúgbò máa ń dé sí nígbà tó bá wá ṣèbẹ̀wò tó máa ń ṣe
lọ́dọọdún. Mo wà lára ẹgbẹ́ akọrin nígbà yẹn, ohun tó sì wù mí ni pé kí n di àlùfáà.Mo wọ iṣẹ́ ọlọ́pàá lọ́dún 1929. Ẹnu iṣẹ́ ni mo wà ní Tẹsalóníkà, ní àríwá ilẹ̀ Gíríìsì, nígbà tí Bàbá kú. Nítorí kí n lè rí ìtùnú àti ìlàlóye tẹ̀mí, mo ṣètò pé kí wọ́n gbé mi lọ dara pọ̀ mọ́ agbo ọlọ́pàá ti Òkè Ńlá Athos, ìyẹn ibì kan tí kò jìnnà tí àwùjọ àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé wà. “Òkè mímọ́” a ni àwọn Kristẹni ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì sì máa ń pe ibẹ̀. Ọdún mẹ́rin gbáko ni mo fi ṣiṣẹ́ níbẹ̀, ìyẹn sì jẹ́ kí n mọ̀ nípa àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé dáadáa. Dípò tí màá fi túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run, ńṣe ni ìwà pálapàla àti ìwà ìbàjẹ́ àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé náà ń kó mi nírìíra. Inú mi bà jẹ́ gan-an nígbà tí àlùfáà kan tí mo bọ̀wọ̀ fún gidigidi sọ pé òun fẹ́ máa bá mi lò pọ̀. Pẹ̀lú gbogbo ìjákulẹ̀ yẹn, ó ṣì wù mí tọkàntọkàn láti sin Ọlọ́run kí n sì di àlùfáà. Mo tiẹ̀ gbé aṣọ àlùfáà kan wọ̀, tí mo si fi ya fọ́tò kan tí yóò máa rán mi létí. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, mo padà sí Kírétè.
“Èṣù Ẹ̀dá Ni!”
Ní 1942, mo fẹ́ ọmọbìnrin òrékelẹ́wà kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Frosini, tó tinú ilé rere kan wá. Ìgbéyàwó yìí ló wá túbọ̀ jẹ́ kíṣẹ́ àlùfáà wù mí ṣe gan-an, nítorí pé àwọn àna mi ò fọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ṣeré rárá. b Mo wá pinnu láti lọ sí Áténì kí n lọ kẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ́ àwọn àlùfáà tó wà níbẹ̀. Nígbà tó kù díẹ̀ kí ọdún 1943 parí, mo gúnlẹ̀ sí èbúté Iráklion, ní Kírétè, àmọ́ mi ò lọ sí Áténì. Ìyẹn lè jẹ́ tìtorí pé mo ti rí orísun ìtura tẹ̀mí tó yàtọ̀ síyẹn lákòókò tá à ń wí yìí. Kí ló ṣẹlẹ̀?
Ó tó ọdún bíi mélòó kan tí Emmanuel Lionoudakis, ìyẹn ọ̀dọ́ oníwàásù kan báyìí tára rẹ̀ dá ṣáṣá tó ń dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ti ń fi òye òtítọ́ Bíbélì kọ́ gbogbo àwọn ará Kírétè. c Òye tó ṣe kedere nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run táwọn Ẹlẹ́rìí fi ń kọ́ni fa àwọn kan lọ́kàn mọ́ra, wọ́n sì pa ìsìn èké tì. Àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí kan tí wọ́n nítara kóra jọ sí ìlú Sitía tí kò jìnnà sí wa. Èyí kó ìdààmú bá bíṣọ́ọ̀bù àdúgbò náà, ẹni—tó ti gbé ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà rí—tó sì mọ bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe já fáfá tó nínú iṣẹ́ ìwàásù. Ó wá pinnu pé òun máa lé àwọn “aládàámọ̀” yìí kúrò lágbègbè òun. Nítorí ọkùnrin yìí, gbogbo ìgbà làwọn ọlọ́pàá máa ń wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí lọ sẹ́wọ̀n tí wọ́n sì máa ń fà wọ́n lọ sílé ẹjọ́ lórí onírúurú ẹ̀sùn èké.
Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí náà gbìyànjú láti ṣàlàyé òtítọ́ Bíbélì fún mi, àmọ́ ó rò pé mi ò nífẹ̀ẹ́ sí i. Ó wá rán òjíṣẹ́ mìíràn tó tún nírìírí jù ú lọ pé kó wá bá mi sọ̀rọ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí mo ṣe dáhùn pàrá sí ohun tí ẹnì kejì yìí sọ ló mú kó padà lọ sọ fún àwùjọ kékeré náà pé: “Pericles ò lè di Ẹlẹ́rìí láé. Èṣù ẹ̀dá ni!”
Àtakò Tí Mo Kọ́kọ́ Dojú Kọ
Inú mi dùn pé Ọlọ́run ò fi irú ojú yẹn wò mí. Ní February 1945, Demosthenes, àbúrò mi, tó gbà pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fi òtítọ́ kọ́ni, fún mi ní ìwé kékeré náà, Comfort All That Mourn. d Ohun tó wà nínú rẹ̀ wọ̀ mí lọ́kàn gan-an ni. Ojú ẹsẹ̀ la ṣíwọ́ lílọ sí Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì, a dara pọ̀ mọ́ àwùjọ kékeré tó wà ní Sitía, a sì jẹ́rìí nípa ẹ̀sìn tuntun tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ rí yìí fáwọn ọmọ ìyá wa. Gbogbo wọn ló tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Bíbélì. Bí mo ṣe retí pé ó máa rí, ìpinnu tí mo ṣe láti fi ìsìn èké sílẹ̀ yìí fa ìtanù àti ìkóguntini látọ̀dọ̀ ìyàwó mi àti ìdílé rẹ̀. Bàbá ìyàwó mi tiẹ̀ bá mi yodì fún sáà kan. Inú ilé gbóná janjan torí àìgbọ́ra-ẹni-yé àti pákáǹleke. Láìfi gbogbo èyí pè, Arákùnrin Minos Kokkinakis batisí èmi àti Demosthenes ní May 21, 1945. e
Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, àlá mi nímùúṣẹ, mo wá ń sìn gẹ́gẹ́ bí ojúlówó ìránṣẹ́ Ọlọ́run! Mo ṣì rántí ọjọ́ tí mo kọ́kọ́ jáde òde ẹ̀rí pàá. Mo kó ìwé kékeré márùnlélọ́gbọ̀n sínú àpò mi, mo sì dá nìkan wọ bọ́ọ̀sì lọ sí abúlé kan. Pẹ̀lú ìjayà ni mo bẹ̀rẹ̀ sí lọ láti ilé dé ilé. Bí iṣẹ́ náà ṣe ń tẹ̀ síwájú
ni mo túbọ̀ ń nígboyà sí i. Nígbà tí àlùfáà kan tínú ń bí wá bá mi, ó ṣeé ṣe fún mi láti fi ìgboyà bá a sọ̀rọ̀, láìfi bó ṣe ń sọ pé mo ṣáà gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé òun dé àgọ́ ọlọ́pàá pè. Mo sọ fún un pé màá kúrò níbẹ̀ lẹ́yìn tí mo bá ti bá gbogbo àwọn tó wà lábúlé náà sọ̀rọ̀ tán, ohun tí mo sì ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn. Inú mi dùn gan-an débi pé mi ò tiẹ̀ dúró kí bọ́ọ̀sì wá gbé mi, ẹsẹ̀ ni mo fi rin kìlómítà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún náà padà sílé.Mo Bọ́ Sọ́wọ́ Àwọn Ẹhànnà
Ní September 1945, wọ́n fún mi ní ẹrù iṣẹ́ púpọ̀ sí i nínú ìjọ wa tuntun tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ ní Sitía. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn tí ogun abẹ́lé bẹ́ sílẹ̀ ní Gíríìsì. Àwọn ẹgbẹ́ tó jẹ́ agbawèrèmẹ́sìn ń bá ara wọn jà pẹ̀lú ìkórìíra tí ò ṣe é fẹnu sọ. Àǹfààní yìí ni bíṣọ́ọ̀bù àdúgbò náà wá lò tó fi rọ àwùjọ àwọn adàlúrú pé kí wọ́n ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti rẹ́yìn àwọn Ẹlẹ́rìí. (Jòhánù 16:2) Bí àwọn adàlúrú náà ṣe wọnú bọ́ọ̀sì tí wọ́n fẹ́ máa bọ̀ lábúlé wa ni obìnrin kan tó wà nínú bọ́ọ̀sì náà gbọ́ bí wọ́n ṣe ń wéwèé láti ṣe iṣẹ́ ibi tí wọ́n sọ pé “Ọlọ́run rán àwọn” yìí, ó sì sọ fún wa nípa rẹ̀. Bá a ṣe lọ sá pa mọ́ nìyẹn, ọ̀kan lára àwọn mọ̀lẹ́bí wa sì gbèjà wa. Wọn ò rí wa gbé ṣe.
Èyí ló wá múra wa sílẹ̀ de ọ̀pọ̀ ìpọ́njú tó wà níwájú. Ojoojúmọ́ ni wọ́n ń lù wá tí wọ́n sì ń dáyà fò wá. Àwọn tó ń ṣàtakò wa ń gbìyànjú láti fagbára mú wa padà sí ṣọ́ọ̀ṣì, ká lọ sàmì fún àwọn ọmọ wa, ká sì lọ fọwọ́ ṣe àmì àgbélébùú síwájú orí wa. Ìgbà kan wà tí wọ́n lu àbúrò mi débi tí wọ́n fi rò pé ó ti kú. Ó dùn mi gan-an láti rí i tí wọ́n fa aṣọ àwọn àbúrò mi obìnrin méjèèjì ya tí wọ́n sì lù wọ́n. Láàárín àkókò yẹn, ṣọ́ọ̀ṣì náà fi tipátipá sàmì fún àwọn mẹ́jọ tí wọ́n jẹ́ ọmọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Ọdún 1949 ni màmá mi kú. Bí àlùfáà náà tún ṣe wá gbógun tì wá nìyẹn, tó fẹ̀sùn kàn wá pé a ò ṣe ohun tí òfin béèrè nípa ààtò ìsìnkú. Wọ́n gbẹ́jọ́ mi nílé ẹjọ́ wọ́n sì dá mi sílẹ̀. Èyí sì jẹ́ ẹ̀rí àtàtà, níwọ̀n báwọn èèyàn ti gbọ́ orúkọ Jèhófà nínú ọ̀rọ̀ tí wọ́n kọ́kọ́ sọ nígbà tí wọ́n fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́jọ́ náà. Ohun kan ṣoṣo tó kù fáwọn ọ̀tá wa láti “fi hàn pé àwọn lágbára” ni pé kí wọ́n mú wa kí wọ́n sì rán wa lọ sígbèkùn. Wọ́n sì ṣe èyí ní April 1949.
Ó Di Inú Ìléru
Mo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn arákùnrin mẹ́ta tí wọ́n mú. Ìyàwó mi ò tiẹ̀ wá wò mí ní àgọ́ ọlọ́pàá àdúgbò wa. Ọgbà ẹ̀wọ̀n kan ní Iráklion la ti kọ́kọ́ dúró. Bí mo ṣe ṣàpèjúwe rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀, ńṣe ni mo dá nìkan wà níbẹ̀ tí ìbànújẹ́ sì dorí mi kodò. Ìyàwó tó ṣì jẹ́ ọ̀dọ́mọbìnrin tí ẹ̀sìn rẹ̀ yàtọ̀ sí tèmi àtàwọn ọmọ ọwọ́ méjì ni mo fi sílẹ̀ nílé. Mo gbàdúrà tìtaratìtara pé kí Jèhófà ràn mí lọ́wọ́. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó wà nínú Hébérù 13:5 wá wá sí mi lọ́kàn pé: “Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.” Mo wá rí ọgbọ́n tó wà nínú gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà tọkàntọkàn.—Òwe 3:5.
A gbọ́ pé wọ́n máa kó wa nígbèkùn lọ sí Makrónisos, ìyẹn erékùṣù kan tó jẹ́ aṣálẹ̀ ní etíkun Attica tó wà nílẹ̀ Gíríìsì. Mímẹ́nu kan Makrónisos nìkan ti tó láti kó ìpayà báni, nítorí pé bí wọ́n ṣe ń dáni lóró tí wọ́n sì ń kóni ṣe iṣẹ́ ẹrú níbẹ̀ ò ṣeé fẹnu sọ. Nígbà tá à ń lọ sọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ọkọ̀ wa dúró ní Piraeus. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ wà lọ́wọ́ wa, síbẹ̀ inú wa dùn nígbà táwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa wá sínú ọkọ̀ ojú omi náà tí wọ́n sì dì mọ́ wa.—Ìṣe 28:14, 15.
Nǹkan burú jáì fún wa ní Makrónisos. Ńṣe làwọn sójà máa ń fìyà jẹ àwọn ẹlẹ́wọ̀n látàárọ̀ ṣúlẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí ló ya wèrè, àwọn mìíràn kú, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ sì di aláàbọ̀ ara. A máa ń gbọ́ igbe àti ìkérora àwọn tí wọ́n ń fìyà jẹ́ lọ́gànjọ́ òru. Ìwọ̀nba díẹ̀ ni bùláńkẹ́ẹ̀tì fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí mo fi ń bora lè gbà lára òtútù tó máa ń mú mi lóru.
Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwọn èèyàn wá mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bí ẹní mowó nínú ọgbà náà nítorí pé wọ́n máa ń dárúkọ yẹn nígbà tí wọ́n bá ń pe orúkọ lárààárọ̀. Ìyẹn wá fún wa láǹfààní tó pọ̀ láti jẹ́rìí. Mo tiẹ̀ láǹfààní àtiṣe ìrìbọmi fún ẹnì kan tó ń ṣẹ̀wọ̀n nítorí ọ̀ràn òṣèlú, àmọ́ tó ti wá kẹ́kọ̀ọ́ dórí yíya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà.
Gbogbo ìgbà tí mo fi wà nígbèkùn yẹn ni mo máa ń kọ lẹ́tà sí aya mi ọ̀wọ́n láìrí èsì kankan gbà látọ̀dọ̀ rẹ̀. Èyí ò sì dá mi dúró pé kí n má kọ̀wé sí i pẹ̀lú ẹ̀mí ìbánikẹ́dùn, tí mò ń tù ú nínú, tí mo sì ń mú un dá a lójú pé ipò tí mo wà yìí ò ní máa bá a lọ bẹ́ẹ̀ àti pé ayọ̀ ṣì ń bọ̀.
Bí àkókò ti ń lọ, iye wa túbọ̀ ń pọ̀ sí i báwọn arákùnrin ṣe ń dé. Bí mo ṣe ń ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì, mo sọ ara mi dọ̀rẹ́ ọ̀gá àgbà ọgbà ẹ̀wọ̀n náà. Níwọ̀n bí ọkùnrin yìí ti bọ̀wọ̀ fún àwa Ẹlẹ́rìí, mo fi ìgboyà béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bóyá ó lè jẹ́ ká gba àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bíi mélòó kan láti ọ́fíìsì wa ní Áténì. Ó ní “ìyẹn ò lè ṣeé ṣe, àmọ́ àwọn èèyàn yín tó wà ní Áténì ò ṣe dì í sínú ẹrù yín, kí wọ́n kọ orúkọ mi sí i, kí wọ́n sì fi ránṣẹ́ sí mi?” Ìyàlẹ́nu ńlá lèyí jẹ́ fún mi! Ọjọ́ bíi mélòó kan lẹ́yìn ìyẹn, bá a ṣe ń kó ẹrù jáde látinú ọkọ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé ni ọlọ́pàá kan wá bẹ́rí fún ọ̀gá àgbà náà tó sì sọ fún un pé: “Ọ̀gá, ẹrù yín ti dé.” Ó fèsì pé: “Ẹrù wo?” Ó wá bọ́ sí àsìkò tí mo wà nítòsí, mo sì gbọ́ ohun tí wọ́n jọ ń sọ, mo wá rọra sọ fún un pé: “Bóyá ẹrù wa ni, èyí tẹ́ ẹ ní kí wọ́n
fi ránṣẹ́ lórúkọ yín.” Ìyẹn jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀nà tí Jèhófà gbà rí i dájú pé à ń rí oúnjẹ tẹ̀mí jẹ.Ìbùkún Tí N Kò Retí —Lẹ́yìn Náà Ìpọ́njú Púpọ̀ Sí I
Wọ́n dá mi sílẹ̀ ní òpin ọdún 1950. Orí àìsàn ni mo wà nígbà tí mò ń padà bọ̀ nílé, mo ti ṣì, mo sì rù kan egungun, mi ò tún mọ bí wọ́n ṣe máa ṣe sí mi nígbà tí mo bá délé. Inú mi dùn gan-an láti tún padà rí ìyàwó mi àtàwọn ọmọ mi! Yàtọ̀ síyẹn, pabanbarì rẹ̀ ni pé àtakò tí Frosini máa ń ṣe ti pòórá. Àwọn lẹ́tà tí mo kọ láti ọgbà ẹ̀wọ̀n yẹn ṣiṣẹ́ gan-an ni. Bí mo ṣe ní ìfaradà tí mi ò sì juwọ́ sílẹ̀ yẹn wú Frosini lórí gan-an. Kété lẹ́yìn ìyẹn ni mo fi sùúrù bá a jíròrò fún àkókò gígùn. Ó gbà láti ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì nígbàgbọ́ nínú Jèhófà àtàwọn ìlérí rẹ̀. Ọ̀kan lára ọjọ́ tí inú mi dùn jù lọ láyé ni ọjọ́ tí mo batisí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà!
Ní 1955, a bẹ̀rẹ̀ sí pín ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan ìwé kékeré náà, Christendom or Christianity—Which One Is “the Light of the World”? fún gbogbo àlùfáà. Wọ́n mú mi, wọ́n sì gbẹ́jọ́ èmi àtàwọn bíi mélòó kan tá a jọ jẹ́ Ẹlẹ́rìí. Ẹjọ tí wọ́n pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pọ̀ gan-an débi pé ilé ẹjọ́ náà ní láti ṣètò ọjọ́ kan pàtó láti gbọ́ gbogbo wọn. Ní ọjọ́ tá à ń wí yìí, gbogbo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ láwọn ilé ẹjọ́ tó wà ní gbogbo ẹkùn-ìpínlẹ̀ náà ló péjú, àwọn àlùfáà sì kún inú ilé ẹjọ́ náà fọ́fọ́. Ńṣe ni bíṣọ́ọ̀bù náà ń lọ sókè-sódò tínú rẹ̀ sì ń ru gùdù nínú kóòtù ọ̀hún. Ọ̀kan lára àwọn àlùfáà náà ti fẹ̀sùn kàn mí pé mo fẹ́ yí òun ní ẹ̀sìn padà. Adájọ́ náà wá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ṣé bẹ́ẹ̀ ni ìgbàgbọ́ rẹ ò lera tó tí kíka ìwé pẹlẹbẹ kan lásán á fi wá mú ọ yí ẹ̀sìn rẹ̀ padà?” Ni kẹ́kẹ́ bá pa mọ́ àlùfáà náà lẹ́nu. Wọ́n dá mi sílẹ̀ àmọ́ wọ́n dá ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà fáwọn arákùnrin bíi mélòó kan.
Láwọn ọdún tó tẹ̀ lé e, wọ́n mú wa léraléra, ẹjọ́ wa sì ń pọ̀ sí i nílé ẹjọ́. Ńṣe ni ọwọ́ àwọn agbẹjọ́rò wa máa ń dí ní gbogbo ìgbà nítorí ọ̀pọ̀ ẹjọ́ tí wọ́n ń bójú tó. Ìgbà mẹ́tàdínlógún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n mú mi lọ sílé ẹjọ́. Pẹ̀lú gbogbo àtakò yìí, iṣẹ́ ìwàásù wa ń lọ déédéé. Tayọ̀tayọ̀ la fi tẹ́wọ́ gba ìpèníjà yìí, àwọn àdánwò tó dà bí iná náà sì sọ ìgbàgbọ́ wa dọ̀tun.—Jákọ́bù 1:2, 3.
Àwọn Àǹfààní àti Ìpèníjà Tuntun
Nígbà tó di 1957, a kó lọ sí Áténì. Kété lẹ́yìn ìyẹn ni wọ́n yàn mi láti sìn nínú ìjọ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀. Nítorí pé ìyàwó mi kọ́wọ́ tì mí lẹ́yìn tọkàntọkàn, ó ṣeé ṣe fún wa láti gbé ìgbésí ayé ṣe-bó-o-ti-mọ a sì fi àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí sí ipò kìíní. Nípa báyìí, ó ṣeé ṣe fún wa láti yọ̀ǹda èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àkókò wa fún iṣẹ́ ìwàásù náà. Láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá, wọ́n ti ní ká lọ sí onírúurú ìjọ ti wọ́n ti nílò ìrànlọ́wọ́.
Ní ọdún 1963, ọmọ mi ọkùnrin pé ọmọ
ọdún mọ́kànlélógún, ó sì ní láti lọ forúkọ sílẹ̀ fún iṣẹ́ ológun. Nítorí pé àwọn Ẹlẹ́rìí kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun, gbogbo wọn ni wọ́n lù, tí wọ́n fi ṣẹ̀sín, tí wọ́n dójú tì. Ìrírí tí ọmọ mi náà tún ní nìyẹn. Mo wá fún un ní bùláńkẹ́ẹ̀tì mi tí mo mú bọ̀ láti Makrónisos, kíyẹn lè fún un níṣìírí lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ pé òun náà ní láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn olùpàwàtítọ́mọ́ ayé ọjọ́un. Wọ́n máa ń kó àwọn arákùnrin tí wọ́n bá pè lọ sílé ẹjọ́ àwọn ológun, wọ́n sì sábà máa ń fi wọ́n sẹ́wọ̀n ọdún méjì sí mẹ́rin. Lẹ́yìn tí wọ́n bá dá wọn sílẹ̀, wọ́n á tún pè wọ́n padà, wọ́n á sì tún rán wọn lọ sẹ́wọ̀n. Gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ ìsìn, ó ṣeé ṣe fún mi láti bẹ ọ̀kan-kò-jọ̀kan ọgbà ẹ̀wọ̀n wò, ìyẹn sì ń jẹ́ kí n dé ọ̀dọ̀ ọmọ mi àtàwọn Ẹlẹ́rìí olóòótọ́ yòókù lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ọmọ mi lo ohun tó lé ní ọdún mẹ́fà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n.Jèhófà Mẹ́sẹ̀ Wa Dúró
Nígbà tí ilẹ̀ Gíríìsì wá di ibi táwọn èèyàn ti ní òmìnira ìjọsìn, mo láǹfààní àtisìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe onígbà díẹ̀ ní erékùṣù Ródésì. Nígbà tó di ọdún 1986, wọ́n tún nílò ìrànlọ́wọ́ ní Sitía, Kírétè, níbi tí mo ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ Kristẹni mi. Inú mi dùn láti tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ yìí kí n lè jọ́sìn pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ bíi tèmi tá a ti jọ mọ ara wa látìgbà tí mo ti wà lọ́mọdé.
Gẹ́gẹ́ bí ẹni tó dàgbà jù lọ nínú ìdílé mi, inú mi dùn láti rí àpapọ̀ àwọn bí àádọ́rin nínú àwọn ẹbí mi tí wọ́n ń sin Jèhófà tọkàntọkàn. Iye yẹn sì ń pọ̀ sí i. Àwọn kan lára wọn ti sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, aṣáájú ọ̀nà, mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì, àti alábòójútó arìnrìn àjò. A ti dán ìgbàgbọ́ mi wò lọ́nà tó múná fún ohun tó lé ní ọdún méjìdínlọ́gọ́ta. Mo ti di ẹni ọdún mẹ́tàléláàádọ́rùn-ún báyìí, bí mo sì ti ń fojú inú wo ohun tí mo ti ṣe sẹ́yìn, mi ò kábàámọ̀ kankan nípa bí mo ṣe sin Ọlọ́run. Ó ti fún mi lókun láti dáhùn ìkésíni onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tó sọ pé: “Ọmọ mi, fi ọkàn-àyà rẹ fún mi, kí àwọn ojú tìrẹ wọ̀nyẹn sì ní ìdùnnú sí àwọn ọ̀nà tèmi.”—Òwe 23:26.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Ilé Ìṣọ́, December 1, 1999, ojú ìwé 30 sí 31.
b Wọ́n gba àwọn àlùfáà Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Gíríìkì láyè láti gbéyàwó.
c Láti ka ìtàn ìgbésí ayé Emmanuel Lionoudakis, wo Ilé Ìṣọ́, September 1, 1999, ojú ìwé 25 sí 29.
d Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde, àmọ́ a ò tún un tẹ̀ mọ́.
e Láti kà nípa ìgbẹ́jọ́ kan tí Minos Kokkinakis ti jàre, wo Ilé Ìṣọ́nà, September 1, 1993, ojú ìwé 27 sí 31.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 27]
Makrónisos—Erékùṣù Ìpayà
Ọdún mẹ́wàá gbáko, láti 1947 sí 1957, ni erékùṣù Makrónisos tó gbẹ táútáú téèyàn ti máa ń dá wà fi jẹ́ ilé àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó lé ní ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000]. Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn Ẹlẹ́rìí olóòótọ́ tí wọ́n kó lọ síbẹ̀ nítorí jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ Kristẹni tí kò dá sí tọ̀túntòsì wà lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n wọ̀nyí. Àwọn àlùfáà Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Gíríìkì tí wọ́n purọ́ pé Kọ́múníìsì làwọn Ẹlẹ́rìí ló súnná sí lílé tí wọ́n ń lé wọn kúrò nílùú.
Ohun tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Gíríìkì ni, Papyros Larousse Britannica sọ nípa ọ̀nà tí wọ́n gbà “ń báni wí” ní Makrónisos, ni pé: “Bí wọ́n ṣe ń dá wọn lóró níbẹ̀ burú jáì, . . . ibi tí wọ́n ń gbé níbẹ̀ jẹ́ èyí tí orílẹ̀-èdè tó lajú ò lè fọwọ́ sí rárá, ìwà sísọ èèyàn dẹni yẹpẹrẹ táwọn ẹ̀ṣọ́ ibẹ̀ ń hù sáwọn ẹlẹ́wọ̀n . . . jẹ́ ohun tó bẹnu àtẹ́ lu ìtàn ilẹ̀ Gíríìsì.”
Wọ́n sọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí kan pé wọn ò ní dá wọn sílẹ̀ láé, àyàfi tí wọ́n bá sẹ́ ìgbàgbọ́ wọn. Pẹ̀lú gbogbo èyí, àwọn Ẹlẹ́rìí náà pa ìwà títọ́ wọn mọ́. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn kan lára àwọn tó ń ṣẹ̀wọ̀n nítorí ọ̀ràn ìṣèlú wá tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Bíbélì nítorí pé àwọn àtàwọn Ẹlẹ́rìí jọ wà pa pọ̀.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Minos Kokkinakis (ìkẹta láti apá ọ̀tún) àti èmi (ìkẹrin láti apá òsì) ni erékùṣù Makrónisos tá a ti jẹ palaba ìyà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Mò ń sìn ní Sitía, Kírétè pẹ̀lú Ẹlẹ́rìí bíi tèmi níbi tí mo ti sìn nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́