Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bá A Ṣe Lè Ní Èrò Tó Yẹ Nípa Iṣẹ́

Bá A Ṣe Lè Ní Èrò Tó Yẹ Nípa Iṣẹ́

Bá A Ṣe Lè Ní Èrò Tó Yẹ Nípa Iṣẹ́

LÁYÉ òde òní tí ètò okòwò àgbáyé ti ń ròkè, tí ìdíje ńláǹlà ti wà káàkiri, tó sì jẹ́ pé àwọn ẹ̀rọ ńláńlá làwọn ilé iṣẹ́ fi ń ṣe àwọn nǹkan jáde, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kì í yá lára láti lọ síbi iṣẹ́ bí ilẹ̀ bá ti mọ́. Bẹ́ẹ̀ ńṣe ló yẹ ká máa gbádùn iṣẹ́ wa. Kí nìdí? Nítorí pé ní àwòrán Ọlọ́run ni a dá wa—inú Ọlọ́run máa ń dùn sí iṣẹ́ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó wo àwọn iṣẹ́ tó ti ṣe lẹ́yìn “ọjọ́” mẹ́fà ìṣẹ̀dá tàbí lẹ́yìn àkókò gígùn tó lò fún ìṣẹ̀dá, Jẹ́nẹ́sísì 1:31 sọ pé “Ọlọ́run rí ohun gbogbo tí ó ti ṣe, sì wò ó! ó dára gan-an ni.”

Ó dájú pé ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí iṣẹ́ ṣíṣe jẹ́ ọ̀kan lára ìdí tá a fi pè é ní “Ọlọ́run aláyọ̀.” (1 Tímótì 1:11) Ǹjẹ́ kò bọ́gbọ́n mu nígbà náà pé bá a ṣe túbọ̀ ń fara wé e, la ó túbọ̀ máa láyọ̀ sí i? Tìtorí èyí ni Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì, tó tayọ nínú ilé kíkọ́ àti nínú ṣíṣètò nǹkan, fi kọ̀wé pé: “Kí olúkúlùkù ènìyàn máa jẹ, kí ó sì máa mu ní tòótọ́, kí ó sì rí ohun rere nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀. Ẹ̀bùn Ọlọ́run ni.”—Oníwàásù 3:13.

Ó lè máà rọrùn láti ní èrò tó tọ́ tó sì yẹ nípa iṣẹ́ ṣíṣe nínú ayé tí ibi iṣẹ́ ti ń yí padà léraléra yìí. Àmọ́ Jèhófà Ọlọ́run ń bù kún àwọn tó ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀ onífẹ̀ẹ́. (Sáàmù 119:99, 100) Irú wọn ló ń di òṣìṣẹ́ tó ṣeyebíye tó sì ṣeé fọkàn tán, ìdí sì nìyẹn tí irú wọn kì í fi í sábà pàdánù iṣẹ́ wọn. Wọ́n tún máa ń ṣọ́ irú ìgbésí ayé tí wọ́n ń gbé, wọn kì í ṣiṣẹ́ fún nǹkan ti ara nìkan àmọ́ fún nǹkan tẹ̀mí pẹ̀lú. Èyí mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti ṣe àwọn ìpinnu tó ní láárí nínú ìgbésí ayé wọn àti láti rí i pé kì í ṣe inú iṣẹ́ wọn tàbí inú ọrọ̀ ajé tí kò ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé nìkan làwọn ti ń rí ayọ̀ àti ìfọ̀kànbalẹ̀. (Mátíù 6:31-33; 1 Kọ́ríńtì 2:14, 15) Ó ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní ẹ̀mí tó dára nípa iṣẹ́.

Ní Ẹ̀mí Iṣẹ́ Tó Bá Ìfẹ́ Ọlọ́run Mu

Àwọn kan wà tí wọ́n jẹ́ oníṣẹ́ àṣekúdórógbó, tó jẹ́ pé iṣẹ́ ni wọ́n fí sípò kìíní nínú ìgbésí ayé wọn. Ibẹ̀ làwọn mìíràn wà tó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n máa ń wo aago pé kíṣẹ́ ọjọ́ náà ṣáà parí káwọn lè lọ sílé. Kí wá ni èrò tó yẹ ká ní nípa iṣẹ́? Bíbélì dáhùn pé: “Ẹ̀kúnwọ́ kan ìsinmi sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì iṣẹ́ àṣekára àti lílépa ẹ̀fúùfù.” (Oníwàásù 4:6) Ká sọ tòótọ́, ṣíṣe àṣekúdórógbó iṣẹ́ tàbí ṣíṣiṣẹ́ fún àkókò tó gùn jù kì í sábà bímọọre, wàhálà ló máa ń mú wá—asán ló jẹ́ àti “lílépa ẹ̀fúùfù.” Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé a lè máa pa àwọn ohun tó jẹ́ orísun ayọ̀ wa jù lọ gan-an lára, ìyẹn ni, àjọṣe àárín àwa àti ìdílé wa àtàwọn ọ̀rẹ́ wa, ipò wa nípa tẹ̀mí, ìlera wa, kódà ó lè dá ẹ̀mí àwa fúnra wa pàápàá légbodò. (1 Tímótì 6:9, 10) Èrò tó yẹ nípa iṣẹ́ ni pé kéèyàn ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan ti ara tó mọ níwọ̀nba pa pọ̀ pẹ̀lú àlàáfíà dípò téèyàn á fi jẹ́ kí iṣẹ́ àṣekúdórógbó, gbọ́nmi-si omi-ò-to àti ìbànújẹ́ sọ òun dìdàkudà.

Gbígbà tí Bíbélì gbà wá níyànjú láti ní èrò tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nípa iṣẹ́ kò túmọ̀ sí pé ó fẹ́ ká jẹ́ ọ̀lẹ. (Òwe 20:4) Ìwà ọ̀lẹ ò ní jẹ́ ká níyì, á sì mú ká pàdánù ọ̀wọ̀ táwọn ẹlòmíràn fi ń wọ̀ wá. Èyí tó burú jù lọ ni pé á ba àjọṣe àárín àwa àti Ọlọ́run jẹ́. Bíbélì là á mọ́lẹ̀ kedere pé ẹnikẹ́ni tó bá kọ̀ láti ṣiṣẹ́ kò yẹ kó jẹ oúnjẹ táwọn ẹlòmíràn ṣiṣẹ́ fún. (2 Tẹsalóníkà 3:10) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbọ́dọ̀ yí ọ̀nà rẹ̀ padà, kó ṣiṣẹ́ àṣekára, kó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pèsè fún ara rẹ̀ àtàwọn tó gbára lé e. Ó tiẹ̀ lè tipasẹ̀ iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ pèsè fáwọn tó jẹ́ aláìní—ìyẹn sì jẹ́ ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbani níyànjú láti máa ṣe.—Òwe 21:25, 26; Éfésù 4:28.

A Kọ́ Wọn Láti Mọyì Iṣẹ́ Látìgbà Ọmọdé

Níní ẹ̀mí tó dára nípa iṣẹ́ kì í ṣàdédé wá; ńṣe lèèyàn máa ń kọ́ ọ láti kékeré. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi gba àwọn òbí níyànjú pé: “Tọ́ ọmọdékùnrin ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí yóò tọ̀; nígbà tí ó bá dàgbà pàápàá, kì yóò yà kúrò nínú rẹ̀.” (Òwe 22:6) Yàtọ̀ sí fífi àpẹẹrẹ rere ti pé àwọn fúnra wọn jẹ́ òṣìṣẹ́ lélẹ̀, láti kékeré làwọn òbí tó gbọ́n ti máa ń kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ nípa fífún wọn láwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ ṣe nínú ilé bí ọjọ́ orí wọn bá ṣe mọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọdé lè máa rojú àtiṣe àwọn iṣẹ́ kan, síbẹ̀ wọ́n á wá fúnra wọn rí i pé àwọn náà ṣe pàtàkì nínú ilé—àgàgà nígbà tí ìyá àti bàbá wọn bá yìn wọ́n fún iṣẹ́ àtàtà tí wọ́n ṣe. Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn òbí kan wà tí wọ́n máa ń kẹ́ àwọn ọmọ wọn lákẹ̀ẹ́bàjẹ́, wọ́n lè máa ronú pé àwọn ń ṣe àwọn ọmọ yìí lóore. Ì bá dára kírú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ ronú lórí ohun tó wà nínú ìwé Òwe 29:21, tó kà pé: “Bí ènìyàn bá ń kẹ́ ìránṣẹ́ [tàbí ọmọ] rẹ̀ ní àkẹ́jù láti ìgbà èwe rẹ̀ wá, ní ìkẹyìn ìgbésí ayé rẹ̀, yóò di aláìmọ ọpẹ́ dá pàápàá.”

Àwọn òbí tó gbọ́n tún máa ń kọbi ara sí ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ wọn, tí wọ́n á máa gbà wọ́n níyànjú láti fojú sí ẹ̀kọ́ wọn dáadáa nígbà tí wọ́n bá ń lọ sílé ìwé. Èyí lè ṣe àwọn ọmọ wọ̀nyí láǹfààní nígbà tí wọ́n bá dàgbà tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́.

Fi Ọgbọ́n Yan Iṣẹ́ Rẹ

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ò sọ irú iṣẹ́ tá a gbọ́dọ̀ ṣe fún wa, síbẹ̀ ó fún wa ní ìlànà rere tá a lè tẹ̀ lé, kí ewu má bàa wu ìlọsíwájú wa nípa tẹ̀mí, iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run, àti àwọn ẹrù iṣẹ́ pàtàkì mìíràn. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Àkókò tí ó ṣẹ́ kù ti dín kù. Láti ìsinsìnyí lọ, kí àwọn . . . tí ń lo ayé [dà] bí àwọn tí kò lò ó dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́; nítorí ìrísí ìran ayé yìí ń yí padà.” (1 Kọ́ríńtì 7:29-31) Kò sí ohun kan tó lè wà pẹ́ títí tàbí tí kò lè yí padà nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Kíkó gbogbo àkókò wa àti gbogbo agbára wa lé e dà bíi kéèyàn fi gbogbo ohun tó ní láyé rẹ̀ kọ́lé sí àgbègbè tí omi ti máa ń ya bo ilé. Òwò àṣedànù gbáà nìyẹn!

Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì mìíràn pe gbólóhùn náà “tí kò lò ó dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́,” ní “tí kò jẹ́ kí ó gbà wọ́n lọ́kàn pátápátá” àti “tí kò jẹ́ kí ó gba gbogbo àkókò wọn.” (The Jerusalem Bible; Today’s English Version) Àwọn tó gbọ́n kò jẹ́ gbójú fo kókó náà dá pé àkókò ti “dín kù” fún ètò nǹkan ìsinsìnyí, wọ́n sì mọ̀ pé jíjẹ́ “kí ó gbà wọ́n lọ́kàn pátápátá” tàbí “kí ó gba gbogbo àkókò wọn” yóò yọrí sí ìjákulẹ̀ tàbí àbámọ̀.—1 Jòhánù 2:15-17.

‘Ọlọ́run Kò Ní Fi Ọ́ Sílẹ̀ Lọ́nàkọnà’

Jèhófà mọ ohun tá a nílò, ó mọ̀ ọ́n ju àwa fúnra wa pàápàá. Ó tún mọ ibi tí ọjọ́ dé nínú àkókò tí yóò mú ète rẹ̀ ṣẹ. Ìdí nìyẹn tó fi rán wa létí pé: “Kí ọ̀nà ìgbésí ayé yín wà láìsí ìfẹ́ owó, bí ẹ ti ń ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Nítorí [Ọlọ́run] ti wí pé: ‘Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.’” (Hébérù 13:5) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn mà ń tuni nínú o! Tìtorí pé Jésù fara wé àníyàn onífẹ̀ẹ́ tí Ọlọ́run ní fún àwọn èèyàn rẹ̀ ló mú kó lo apá tó pọ̀ gan-an nínú Ìwàásù rẹ̀ olókìkí Lórí Òkè láti kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nípa irú ojú tó yẹ kí wọ́n máa fi wo àwọn nǹkan ti ara.—Mátíù 6:19-33.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sapá láti tẹ̀ lé àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀nyẹn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ọ̀gá ibi iṣẹ́ kan sọ pé kí Ẹlẹ́rìí kan, tó ń ṣiṣẹ́ iná mànàmáná, wá máa ṣe àṣekún iṣẹ́ ní gbogbo ìgbà, òṣìṣẹ́ yìí kò gbà fún un. Kí nìdí? Ìdí ni pé kò fẹ́ kí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ òun ṣèdíwọ́ fún àkókò tóun fi máa ń wà pẹ̀lú ìdílé òun àti àkókò tóun máa ń lò fún àwọn nǹkan tẹ̀mí. Níwọ̀n bó ti jẹ́ òṣìṣẹ́ tó tayọ tó sì ṣeé fọkàn tán, ọ̀gá rẹ̀ gbà pẹ̀lú rẹ̀. Àmọ́ ṣá o, nǹkan kì í fi gbogbo ìgbà rí bíi tiẹ̀ yẹn, ó lè jẹ́ pé ńṣe lèèyàn máa lọ wáṣẹ́ mìíràn kó tó lè gbé ìgbésí ayé lọ́nà tó tọ́ tó sì yẹ. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn tó ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Jèhófà sábà máa ń rí i pé ìwà rere wọn àti ọwọ́ tí wọ́n fi mú iṣẹ́ máa ń jẹ́ kí wọ́n rí ojú rere àwọn tó gbà wọ́n síṣẹ́.—Òwe 3:5, 6.

Ìgbà Tí Gbogbo Iṣẹ́ Yóò Mérè Wá

Nínú ètò àwọn nǹkan tó jẹ́ aláìpé tá a wà yìí, kò sí bí iṣẹ́ téèyàn ń ṣe àti èyí téèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ ń wá ṣe lè ṣàìní ìṣòro àti àìdánilójú tirẹ̀. Ká sọ tòótọ́, àwọn nǹkan lè máa burú sí i bí ayé ṣe túbọ̀ ń yí padà tí ètò ọrọ̀ ajé ò sì dúró lójú kan tàbí tó ń dẹnu kọlẹ̀. Àmọ́ fúngbà díẹ̀ lèyí fi máa rí bẹ́ẹ̀. Láìpẹ́, kò ní sí ẹnì kan tí kò ní níṣẹ́ lọ́wọ́ mọ́. Kò mọ síbẹ̀ o, gbogbo iṣẹ́ ni yóò tẹ́ni lọ́rùn tí yóò sì mérè wá. Báwo nìyẹn ṣe lè rí bẹ́ẹ̀? Kí ni yóò mú irú ìyípadà bẹ́ẹ̀ wá?

Jèhófà tọ́ka sí irú àkókò bẹ́ẹ̀, nípasẹ̀ Aísáyà wòlíì rẹ̀. Jèhófà sọ pé: “Èmi yóò dá ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun; àwọn ohun àtijọ́ ni a kì yóò sì mú wá sí ìrántí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wá sí ọkàn-àyà.” (Aísáyà 65:17) Ó ń sọ̀rọ̀ nípa ìjọba tuntun ti òun yóò dá, lábẹ́ èyí tí àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn tuntun tó yàtọ̀ pátápátá yóò wà.—Dáníẹ́lì 2:44.

Àsọtẹ́lẹ̀ náà tún sọ síwájú sí i nípa irú ìgbésí ayé táwọn èèyàn yóò gbé àti irú iṣẹ́ tí wọn ó ṣe níbẹ̀, ó ní: “Dájúdájú, wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn. Wọn kì yóò kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé; wọn kì yóò gbìn fún ẹlòmíràn jẹ. Nítorí pé bí ọjọ́ igi ni ọjọ́ àwọn ènìyàn mi yóò rí; iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn ni àwọn àyànfẹ́ mi yóò sì lò dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Wọn kì yóò ṣe làálàá lásán, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò bímọ fún ìyọlẹ́nu; nítorí pé àwọn ni ọmọ tí ó para pọ̀ jẹ́ alábùkún lọ́dọ̀ Jèhófà, àti àwọn ọmọ ìran wọn pẹ̀lú wọn.”—Aísáyà 65:21-23.

Ẹ ò rí i pé ayé tí Ọlọ́run ṣètò yẹn á yàtọ̀ pátápátá! Àbí o ò ní fẹ́ gbé nínú irú ayé bẹ́ẹ̀, níbi tó ò ti ní “ṣe làálàá lásán” àmọ́ tí wàá gbádùn “èso” iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́? Àmọ́ o, kíyè sí àwọn tó máa gbádùn irú àwọn ìbùkún bẹ́ẹ̀: “Àwọn ni ọmọ tí ó para pọ̀ jẹ́ alábùkún lọ́dọ̀ Jèhófà.” Ìwọ náà lè wà lára irú àwọn tó jẹ́ “alábùkún” bẹ́ẹ̀ tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà tó o sì ṣe ohun tó béèrè lọ́wọ́ wa. Jésù sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè jèrè ìmọ̀ tí ń fúnni ní ìyè yẹn nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀ lé.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

“ÀWỌN NI Ọ̀PỌ̀ ÈÈYÀN Ń FẸ́ GBÀ SÍṢẸ́”

Bíbélì sọ pé: “Ohun yòówù tí ẹ bá ń ṣe, ẹ fi tọkàntọkàn ṣe é bí ẹni pé fún Jèhófà, kì í sì í ṣe fún ènìyàn.” (Kólósè 3:23) Ó hàn gbangba pé ẹni tó bá ní irú ẹ̀mí yìí nípa iṣẹ́ rẹ̀ yóò jẹ òṣìṣẹ́ tó ṣeyebíye gan-an lójú ọ̀gá rẹ̀. Nítorí ìdí yìí, nínú ìwé How to Be Invisible, tí J. J. Luna kọ, ó gba àwọn tó ń wá òṣìṣẹ́ níyànjú láti gba àwọn tó jẹ́ ògbóṣáṣá nínú ẹ̀sìn kan pàtó síṣẹ́, àmọ́ ó fi kún un pé: “Ní ti gidi, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà la sábà máa ń gbà ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀.” Lára ohun tó sọ pé ó mú kí ọ̀ràn rí bẹ́ẹ̀ ni pé gbogbo èèyàn ló mọ̀ wọ́n bí ẹní mowó pé wọn kì í ṣàbòsí, ìyẹn ló fà á tó fi jẹ́ pé “àwọn ni ọ̀pọ̀ èèyàn ń fẹ́ gbà” ní onírúurú ẹ̀ka iṣẹ́.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Jíjẹ́ kí iṣẹ́, ìgbòkègbodò tẹ̀mí àti eré ìtura wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì ń mú ayọ̀ wá