Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kí nìdí tí Aísáyà 30:21 fi sọ pé wàá gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà “lẹ́yìn rẹ,” níwọ̀n bí ẹsẹ tó ṣáájú rẹ̀ ti jẹ́ ká gbà pé iwájú ni Jèhófà wà nítorí ó sọ pé, “ojú rẹ yóò sì di ojú tí ń rí Olùkọ́ni rẹ Atóbilọ́lá”?

Aísáyà 30:20, 21 kà pé: “Olùkọ́ni rẹ Atóbilọ́lá kì yóò tún fi ara rẹ̀ pa mọ́, ojú rẹ yóò sì di ojú tí ń rí Olùkọ́ni rẹ Atóbilọ́lá. Etí rẹ yóò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn rẹ tí ń sọ pé: ‘Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀,’ bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ lọ sí apá ọ̀tún tàbí bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ lọ sí apá òsì.”

Bí òǹkàwé bá gba ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ ẹsẹ yẹn sí bó ṣe fara hàn níbẹ̀ gẹ́lẹ́, a jẹ́ pé á máa wo Jèhófà níwájú rẹ̀ ṣùgbọ́n á máa gbóhùn Rẹ̀ látẹ̀yìn. Ṣùgbọ́n o, èdè ìṣàpẹẹrẹ ni ẹsẹ yìí lò, kò sì yẹ ká gbà á sí pé bó ṣe sọ ọ́ gẹ́lẹ́ yẹn náà ló ṣe jẹ́.

Èdè ìṣàpẹẹrẹ tó wà ní ẹsẹ ogún múni ronú lọ sọ́dọ̀ ìránṣẹ́ kan tó ń ṣiṣẹ́ fún ọ̀gá, tó sì ṣe tán nígbà gbogbo láti tẹ̀ lé ìtọ́ni ọ̀gá rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ kan tó ń fara balẹ̀ kíyè sí ọwọ́ tí ọ̀gá rẹ̀ fi ń júwe láti lè fòye mọ ohun tí ọ̀gá rẹ̀ ń fẹ́ kó ṣe, bẹ́ẹ̀ làwọn èèyàn Jèhófà ń fara balẹ̀ kíyè sí ìtọ́ni tá a gbé karí Bíbélì tí Jèhófà ń tipa ètò àjọ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé pèsè ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. (Sáàmù 123:1, 2) Wọ́n ń tẹ̀ lé ìtọ́ni rẹ̀ dájúdájú, wọ́n sì ń wà lójúfò nígbà gbogbo sí ohunkóhun tí Jèhófà bá tipasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” tọ́ka wọn sí.—Mátíù 24:45-47.

Ọ̀rọ̀ táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wá ń gbọ́ látẹ̀yìn ńkọ́? Ó bọ́gbọ́n mu láti sọ pé ohùn tó ń wá látẹ̀yìn jẹ́ ohùn ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run ti sọ sẹ́yìn, tí à ń gbọ́ látinú àkọsílẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ bí “ìríjú” rẹ̀ “olóòótọ́” ṣe ń ṣàlàyé wọn fún wa. (Lúùkù 12:42) Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run òde òní ń gbọ́ ohùn rẹ̀ bí wọ́n ṣe ń ṣakitiyan láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí wọ́n sì ń jẹ́ kí àwọn ìtẹ̀jáde látọ̀dọ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” tí í ṣe “ìríjú olóòótọ́” náà kọ́ wọn bí wọ́n ṣe máa fi àwọn ìlànà rẹ̀ sílò nígbèésí ayé wọn. Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ń rí i níwájú wọn lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, wọ́n sì ń gbóhùn rẹ̀ lẹ́yìn wọn lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ nígbà tí wọ́n bá ń kíyè sí ìtọ́sọ́nà tó bá àkókò mu tí Olùkọ́ni wọn Atóbilọ́lá ń pèsè, tí wọ́n ń gbára lé e, tí wọ́n sì tún ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá a ti kọ láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn.—Róòmù 15:4.