Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Gbígbà Pé Ọlọ́run Wà Láìmọ Irú Ẹni Tó Jẹ́

Gbígbà Pé Ọlọ́run Wà Láìmọ Irú Ẹni Tó Jẹ́

Gbígbà Pé Ọlọ́run Wà Láìmọ Irú Ẹni Tó Jẹ́

ÈÈYÀN méjì nínú mẹ́ta ní orílẹ̀-èdè Jámánì ló gbà pé Ọlọ́run wà. Àmọ́ nígbà tí wọ́n sọ pé kí àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan wá ṣàlàyé bí Ọlọ́run tí wọ́n gbà pé ó wà yìí ṣe jẹ́, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo wọn ló sọ ohun tó yàtọ̀ síra. Ìwé ìròyìn FOCUS sọ pé: “Báwọn ará Jámánì ṣe yàtọ̀ síra wọn lẹ́nìkọ̀ọ̀kan náà ni èrò tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ní lọ́kàn nípa Ọlọ́run ṣe yàtọ̀ síra.” Òótọ́ ni pé ohun tó dáa ni kéèyàn gbà pé Ọlọ́run wà, àmọ́ ǹjẹ́ kì í ṣe ohun tó burú ni pé kéèyàn gbà pé Ọlọ́run wà tí olúwarẹ̀ ò sì mọ irú ẹni tó jẹ́?

Àìmọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ yìí kò mọ sí ilẹ̀ Jámánì nìkan o, ó tún wà bẹ́ẹ̀ láwọn ibòmíràn nílẹ̀ Yúróòpù náà. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní Austria, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Netherlands ló jẹ́ ká mọ èrò tó gbòde kan báyìí pé Ọlọ́run jẹ́ “agbára ńlá kan tàbí ohun ìkọ̀kọ̀ tí ò ṣeé ṣàlàyé.” Àdììtú làwọn èèyàn ka Ọlọ́run sí, àgàgà àwọn èwe, títí dórí àwọn tó gbà pé ó wà pàápàá.

Ǹjẹ́ O Mọ Ọlọ́run Dáadáa?

Ìyàtọ̀ ńláǹlà ló wà láàárín kéèyàn kàn gbọ́ nípa ẹnì kan àti kéèyàn dìídì mọ ẹni náà dáadáa. Téèyàn bá kàn gbọ́ nípa ẹnì kan—bóyá ọba kan tó wà lọ́nà jíjìn réré, gbajúgbajà eléré ìdárayá kan, tàbí òṣèré táwọn èèyàn gba tiẹ̀—olúwarẹ̀ kàn mọ̀ pé onítọ̀hún wà ni. Àmọ́ ohun tó túmọ̀ sí láti mọ ẹnì kan dáadáa ju ìyẹn lọ. Ó ní kéèyàn mọ̀wà ẹni náà nínú, kéèyàn mọ ìṣe rẹ̀, bí nǹkan ṣe ń rí lára rẹ̀, ohun tó fẹ́ àtèyí tí kò fẹ́, àti ohun tó ń wéwèé láti ṣe lọ́jọ́ iwájú. Mímọ ẹnì kan dáadáa túmọ̀ sí pé èèyàn á ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú onítọ̀hún.

Ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn ló ti sọ pé kéèyàn kàn mọ Ọlọ́run lóréfèé tàbí kéèyàn kàn ṣáà gbà pé ó wà, kò tó. Wọ́n ti tẹ̀ síwájú gan-an nípa mímọ Ọlọ́run dáadáa. Ǹjẹ́ wọ́n kábàámọ̀ ohun tí wọ́n ṣe yìí? Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Paul, tó ń gbé ní àríwá ilẹ̀ Jámánì, wulẹ̀ gbà nígbà kan rí pé Ọlọ́run ṣáà wà, àmọ́ ó wá pinnu pé òun fẹ́ mọ Ọlọ́run dáadáa. Paul ṣàlàyé pé: “Ó ń gba àkókò àti ìsapá láti mọ Ọlọ́run dáadáa, àmọ́ èrè ibẹ̀ kúrò ní kékeré. Níní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá máa ń mú kí ìgbésí ayé èèyàn sunwọ̀n sí i lójoojúmọ́.”

Ǹjẹ́ mímọ Ọlọ́run dáadáa tó ohun téèyàn ń torí ẹ̀ lo àkókò àti okun? Jọ̀wọ́ ka àpilẹ̀kọ tó kàn.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 3]

Ìyàtọ̀ ńláǹlà ló wà láàárín kéèyàn kàn gbọ́ nípa ẹnì kan àti kéèyàn dìídì mọ ẹni náà dáadáa