Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Gbin Ohun Tó Dáa Sọ́kàn Ọmọ Rẹ Láti Kékeré!

Gbin Ohun Tó Dáa Sọ́kàn Ọmọ Rẹ Láti Kékeré!

Gbin Ohun Tó Dáa Sọ́kàn Ọmọ Rẹ Láti Kékeré!

BÍ AMỌ̀ tí kò jọni lójú rárá bá bọ́ sọ́wọ́ amọ̀kòkò tó mọṣẹ́ dunjú, ó lè sọ ọ́ di ohun èlò tó lẹ́wà gan-an. Àwọn oníṣẹ́ ọwọ́ tó lè mú ohun tó dáa rèǹtèrente bẹ́ẹ̀ jáde látinú nǹkan tí kò fi bẹ́ẹ̀ já mọ́ nǹkan ò pọ̀. Ọpẹ́lọpẹ́ àwọn amọ̀kòkò tó ti ń jẹ́ kí àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn máa rí ife, abọ́, ìkòkò ìseńjẹ, ìṣà omi, àti orù tá a fi ń gbin òdòdó tó ń ṣe ilé lọ́ṣọ̀ọ́ lò láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn.

Àwọn òbí pẹ̀lú ń ṣe àwùjọ láǹfààní lọ́nà tó ga nípa títọ́ àwọn ọmọ wọn lọ́nà tí ìwà àti ìṣe wọn á fi dára. Bíbélì fi gbogbo wa wé amọ̀, Ọlọ́run sì ti gbé iṣẹ́ bàǹtàbanta ti mímọ “amọ̀” àwọn ọmọ lé àwọn òbí lọ́wọ́. (Jóòbù 33:6; Jẹ́nẹ́sísì 18:19) Bíi ti ìgbà téèyàn bá ṣe ohun èlò amọ̀ kan tó lẹ́wà náà ni kì í ṣe iṣẹ́ kékeré rárá láti yí ọmọ kan padà kí ó lè di àgbà tó ṣeé fọkàn tán, tó sì mọ ohun tí ó tọ́ àti èyí tí ó yẹ. Irú ìyípadà sí rere bẹ́ẹ̀ kì í ṣàdédé wáyé.

Àwọn nǹkan tó lè nípa lórí ọkàn àwọn ọmọ wa pọ̀ rẹpẹtẹ. Ó sì dunni pé, àwọn kan lára àwọn nǹkan wọ̀nyí burú bí eléèmọ̀. Nítorí náà, dípò jíjẹ́ kí onírúurú nǹkan wọ ọmọ kan lọ́kàn, àwọn òbí tó gbọ́n máa ń tọ́ ọmọ “ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí yóò tọ̀,” pẹ̀lú ìdánilójú pé “nígbà tí ó bá dàgbà pàápàá, kí yóò yà kúrò nínú rẹ̀.”—Òwe 22:6.

Láàárín àkókò gígùn tó ṣe pàtàkì gan-an téèyàn fi ń tọ́ ọmọ kan, àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni ní láti ya àkókò sọ́tọ̀ láti wá nǹkan ṣe sí àwọn ipá búburú tó ń wu ọkàn ọmọ wọn léwu. A ó mọ̀ bí ìfẹ́ wọn ṣe pọ̀ tó bí wọ́n ṣe ń fi sùúrù fún ọmọ náà ní “ìtọ́ni, àti ìbáwí, tí í ṣe ìtọ́sọ́nà ti Kristẹni.” (Éfésù 6:4, The New English Bible) Àmọ́, ohun tó máa mú kí iṣẹ́ àwọn òbí túbọ̀ rọrùn ni pé kí wọ́n tètè bẹ̀rẹ̀.

Títètè Bẹ̀rẹ̀

Àwọn amọ̀kòkò máa ń fẹ́ fi amọ̀ tó lẹ̀ dáadáa mọ ohun tí wọ́n bá fẹ́ mọ, síbẹ̀ wọ́n á fẹ́ kó jẹ́ èyí tó múrọ̀ọ́ dáadáa kí ohun tí wọ́n mọ náà má bàa tẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá ṣe é tán. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti yọ òkúta àtàwọn ìdọ̀tí inú amọ̀ kúrò, wọ́n máa ń fẹ́ lò ó kó tó kọjá oṣù mẹ́fà. Bákan náà, àkókò tí ọ̀pọ̀ nǹkan lè wọnú ọkàn ọmọ tó sì rọrùn láti tọ́ sọ́nà tó dáa ló dára jù lọ káwọn òbí bẹ̀rẹ̀ sí tọ́ wọn.

Àwọn ògbógi nínú ọ̀ràn àwọn ọmọdé sọ pé láti ọmọ oṣù mẹ́jọ ni ọmọ náà á ti mọ bí èdè ìbílẹ̀ rẹ̀ ṣe ń dún, á ti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn òbí rẹ̀, á ti máa ní agbára lílóye nǹkan, á sì ti bẹ̀rẹ̀ sí mọ ohun tó ń lọ láyìíká rẹ̀. Àkókò tó dára ju lọ láti bẹ̀rẹ̀ sí gbin nǹkan tó dáa sínú ọkàn rẹ̀ ni ìgbà tó bá ṣì kéré. O ò rí i pé àǹfààní ńlá ni ọmọ rẹ máa ní tó bá jẹ́ bíi ti Tímótì ni òun náà ‘ti mọ Ìwé Mímọ́ láti ìgbà ọmọdé jòjòló!’—2 Tímótì 3:15. a

Gbogbo wa la mọ̀ pé àwọn ọmọ ọwọ́ máa ń fara wé àwọn òbí wọn. Yàtọ̀ sí kí wọ́n máa tún ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá gbọ́ sọ, kí wọ́n sì máa fara ṣàpèjúwe bíi tàwọn òbí wọn, wọ́n tún máa ń kọ́ béèyàn ṣe ń nífẹ̀ẹ́, béèyàn ṣe ń jẹ́ onínúure àti aláàánú nígbà tí wọ́n bá rí i pé àwọn òbí wọn ní irú àwọn ànímọ́ wọ̀nyí. Bá a bá fẹ́ tọ́ àwọn ọmọ wa níbàámu pẹ̀lú àwọn òfin Jèhófà, àwọn àṣẹ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ wà ní ọkàn àwa fúnra wa. Irú ìmọrírì àtọkànwá bẹ́ẹ̀ yóò mú kí àwọn òbí máa bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ déédéé nípa Jèhófà àti nípa Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bíbélì gbani níyànjú pé: “Máa sọ̀rọ̀ nípa wọn nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.” (Diutarónómì 6:6, 7) Francisco àti Rosa ṣàlàyé ọ̀nà tí wọ́n gbà ṣe èyí pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn méjèèjì. b

“Yàtọ̀ sí bá a ṣe jọ máa ń fọ̀rọ̀ wérọ̀ lójoojúmọ́, a tún gbìyànjú láti máa fi ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lójúmọ́ bá àwọn ọmọ wa sọ̀rọ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Tá a bá rí i pé ìṣòro kan fẹ́ yọjú, a máa ń lo àkókò tó gùn jùyẹn lọ—a sì máa ń kojú ìṣòro ní ti gidi. Bí àpẹẹrẹ, ẹnu àìpẹ́ yìí ni ọmọ wa tó jẹ́ ọmọ ọdún márùn-ún dé láti ilé ìwé tó sọ fún wa pé òun ò gbà pé Jèhófà wà. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé ọ̀kan lára àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ ti fi í ṣe ẹlẹ́yà tó sì sọ fún un pé kò sí Ọlọ́run.”

Àwọn òbí wọ̀nyí rí i pé àwọn ọmọ wọn ní láti ní ìgbàgbọ́ nínú Ẹlẹ́dàá wọn. Irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ lè dá lórí bí wọ́n ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn ohun tí Ọlọ́run dá. Àwọn ọmọdé sì fẹ́ràn kí wọ́n máa fọwọ́ kan ẹranko, kí wọ́n máa já òdòdó, tàbí kí wọ́n máa fi iyẹ̀pẹ̀ tó wà létíkun ṣeré bí nǹkan míì! Àwọn òbí lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ ìsopọ̀ tó wà láàárín ìṣẹ̀dá àti Ẹlẹ́dàá fúnra rẹ̀. (Sáàmù 100:3; 104:24, 25) Ẹ̀rù àti ọ̀wọ̀ tí wọ́n bá ní fún ohun tí Jèhófà dá lè wà nínú wọn ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn. (Sáàmù 111:2, 10) Irú ìmọrírì bẹ́ẹ̀ lè mú kí ọmọ kan fẹ́ láti mú inú Ọlọ́run dùn, kó sì máa bẹ̀rù pé kí òun má bà á nínú jẹ́. Èyí yóò wá sún un ‘láti yí padà kúrò nínú ohun búburú.’—Òwe 16:6.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ló máa ń tọ pinpin tí nǹkan sì tètè máa ń yé wọn, síbẹ̀ ó lè máà rọrùn fún wọn láti ṣègbọràn. (Sáàmù 51:5) Wọ́n lè fẹ́ wà lómìnira ara wọn nígbà mìíràn tàbí kí wọ́n fẹ́ kí ohunkóhun tí wọ́n bá fẹ́ tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́. Àwọn òbí ní láti fi àìgbagbẹ̀rẹ́, sùúrù, àti ìbáwí dènà irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ kó tó di èyí tí ọwọ́ ò lè ká mọ́. (Éfésù 6:4) Ohun tí Phyllis àti Paul tí wọ́n ti tọ́ ọmọ márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní àtọ́yanjú ṣe nìyẹn.

Phyllis rántí pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ kọ̀ọ̀kan ló ní ànímọ́ tirẹ̀, síbẹ̀ olúkúlùkù ló fẹ́ kó jẹ́ pé gbogbo ohun tóun bá sọ labẹ́ gé. Kò rọrùn rárá o, àmọ́ ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ wọ́n wá mọ ohun tí ọ̀rọ̀ náà ‘rárá’ túmọ̀ sí.” Paul, ọkọ rẹ̀ sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń ṣàlàyé ìdí tá a fi ṣe àwọn ìpinnu wa fún wọn, ìyẹn tí wọ́n bá ti dàgbà tó láti lóye ohun tá à ń sọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a máa ń gbìyànjú láti fi inú rere hàn sí wọn, síbẹ̀ a kọ́ wọn láti bọ̀wọ̀ fún ọlá àṣẹ tí Ọlọ́run fún wa.”

Lóòótọ́ ni ọmọdé kan lè láwọn ìṣòro nígbà tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà, àmọ́ ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn òbí ló ti rí i pé ìṣòro tó ga jù lọ máa ń yọjú láwọn ọdún tí ọmọ náà ń di ọ̀dọ́langba nígbà tí ọkàn rẹ̀ tí kò tíì dàgbà dénú máa ń kojú ọ̀pọ̀ ìdánwò tuntun.

Dídé Inú Ọkàn Ọ̀dọ́langba Kan

Amọ̀kòkò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ rẹ̀ kí àmọ́ náà tó gbẹ. Tí ò bá tíì ṣe tán àtibẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, ó lè fi omi díẹ̀ sí i, kí àmọ́ náà má bàa gan kó sì múrọ̀ọ́ síbẹ̀. Bákan náà làwọn òbí gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ àṣekára kí ọkàn ọmọ wọn tó jẹ́ ọ̀dọ́langba má bàa yigbì. Láìsí àní-àní, Bíbélì ni ohun èlò tó dára jù lọ, tí wọ́n lè lò fún ‘ìbáwí, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, àti fún mímú kí àwọn ọmọ wọn gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.’—2 Tímótì 3:15-17.

Àmọ́, ọ̀dọ́langba kan lè máà fẹ́ gba ìmọ̀ràn àwọn òbí rẹ̀ mọ́ bó ṣe ń gbà á láìjanpata nígbà tó wà ní kékeré. Àwọn ọ̀dọ́langba lè bẹ̀rẹ̀ sí fetí sóhun táwọn ojúgbà wọn ń sọ, kó wá di pé ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn òbí wọn di èyí tó mẹ́hẹ. Àkókò láti túbọ̀ lo sùúrù àti ọgbọ́n ló délẹ̀ yìí, nítorí pé ipa tí àwọn òbí ń kó àti èyí táwọn ọmọ ń kó ti yí padà báyìí. Ọ̀dọ́langba náà ní láti kojú bí ara rẹ̀ àti ìrònú rẹ̀ ṣe ń yí padà. Ó ní láti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwọn ìpinnu kó sì máa gbé àwọn góńgó tó máa nípa lórí ìyókù ìgbésí ayé rẹ̀ kalẹ̀. (2 Tímótì 2:22) Gbogbo àkókò tó fi ń kojú àwọn ìṣòro yìí ló gbọ́dọ̀ máa kápá ohun kan tó lè ní ipa búburú lórí ọkàn rẹ̀—ìyẹn ni ẹ̀mí ṣe-ohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe.

Irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ kì í ṣàdédé wá nígbà ìṣẹ̀lẹ̀ kan pàtó. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa ń yọjú nínú onírúurú ọ̀rọ̀ àtàwọn ipò tó lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì báni. Ibi tí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ti lè tètè ṣubú ni ohun tá à ń wí yìí ti máa ń ri wọn mú—ìyẹn ni ìbẹ̀rù tó máa ń wà lọ́kàn wọn pé káwọn ẹgbẹ́ wọn yòókù má pa wọ́n tì. Ibi tí ọ̀dọ́ kan bá ti ń làkàkà láti fi hàn pé òun náà ò kẹ̀rẹ̀, tí ò sì fẹ́ káwọn ẹgbẹ́ òun pa òun tì, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí lọ́wọ́ nínú “àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé” èyí táwọn ọ̀dọ́ yòókù ń gbé lárugẹ.—1 Jòhánù 2:15-17; Róòmù 12:2.

Ohun tó tún máa jẹ́ kí ọ̀ràn náà burú sí i ni pé ìfẹ́ ọkàn aláìpé ẹ̀dá lè jẹ́ kí ohun táwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ ń sọ bẹ̀rẹ̀ sí wù ú. Àwọn ọ̀rọ̀ bíi “Jayé orí ẹ” àti “Ṣe ohunkóhun tó bá wù ẹ́” lè wá máa mórí ẹ̀ wú. María rántí ìrírí tirẹ̀, ó ní: “Mo fetí sí àwọn ọ̀dọ́langba ẹgbẹ́ mi, àwọn tí wọ́n rò pé àwọn ọ̀dọ́ lẹ́tọ̀ọ́ láti gbádùn ara wọn débi tó bá wù wọ́n, láìka ohun tó lè tẹ̀yìn rẹ̀ jáde sí. Nítorí pé mo fẹ́ ṣe ohun táwọn ọ̀rẹ́ mi nílé ìwé ń ṣe, díẹ̀ ló kù kí n kó sínú ìṣòro bíburú jáì.” Gẹ́gẹ́ bí òbí, wàá fẹ́ ran ọmọ rẹ tó jẹ́ ọ̀dọ́langba lọ́wọ́ láti borí irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀, àmọ́ ọ̀nà wo lo lè gbé e gbà?

Nípa ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ, mú un dá a lójú, kó o sì fi í lọ́kàn balẹ̀ pé o ò fọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣeré rárá. Gbìyànjú láti mọ èrò rẹ̀ nípa àwọn nǹkan, kó o sì wá bó o ṣe máa lóye àwọn ìṣòro rẹ̀, èyí tó lè le koko ju àwọn ìṣòro tí ìwọ alára ní nígbà tó o wà nílé ìwé. Àkókò yìí gan-an ló yẹ kí ọmọ rẹ máa wò ọ́ bí ẹni tí òun lè sọ ọ̀rọ̀ àṣírí fún. (Òwe 20:5) O lè mọ ìgbà tó wà nínú wàhálà tàbí ìgbà tí ọkàn rẹ̀ dà rú tó o bá ń kíyè sí ìṣarasíhùwà rẹ̀ tàbí bójú rẹ̀ ṣe rí. Wá nǹkan ṣe sí ohun tó ń bà á nínú jẹ́, kó o sì ‘tu ọkàn rẹ̀ nínú.’—Kólósè 2:2.

Ní ti tòótọ́, ó ṣe pàtàkì láti dúró gbọn-in lórí ohun tó tọ́. Ọ̀pọ̀ òbí ló rí i pé ohun táwọn fẹ́ àtèyí tí ọmọ àwọn fẹ́ sábà máa ń ta kora, àmọ́ wọn ò lè yí ohun tí wọ́n sọ padà tí ìpinnu wọn bá jẹ́ èyí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, rí i dájú pé o lóye ọ̀ràn náà dáadáa kó o tó pinnu bóyá kó o fìfẹ́ bá wọn wí àti ọ̀nà tó o máa gbé ìbáwí náà gbà tó bá pọn dandan.—Òwe 18:13.

Ó Lè Wá Látinú Ìjọ Pàápàá

Ìkòkò kan tá a fi amọ̀ ṣe lè dà bí èyí tá a ti parí iṣẹ́ lórí rẹ̀, àmọ́ tá ò bá tíì finá sun ún dáadáa, ó lè jẹ́ nǹkan olómi tá a tìtorí ẹ̀ ṣe ìkòkò náà gan-an ló máa bà á jẹ́. Bíbélì fi àwọn àdánwò àti ìṣòro wé irú fífi iná sun nǹkan bẹ́ẹ̀, nítorí pé àwọn ló máa ń fi irú ẹni tá a jẹ́ gan-an hàn. Ká sọ tòótọ́, ọ̀rọ̀ nípa àdánwò ìgbàgbọ́ wa ni Bíbélì ń sọ o, àmọ́ lápapọ̀, kókó náà tún ṣeé mú lò nínú àwọn àdánwò mìíràn. (Jákọ́bù 1:2-4) Ó yani lẹ́nu pé, àwọn àdánwò líle koko kan táwọn ọ̀dọ́ máa ń kojú lè wá látinú ìjọ pàápàá.

Ọmọ rẹ tó jẹ́ ọ̀dọ́langba lè dà bí ẹni tó dúró sán-ún nípa tẹ̀mí, síbẹ̀ ohun tó ń bá a fínra nínú lọ́hùn-ún lè jẹ́ ti ọkàn rẹ̀ tó ń ro tibí ro tọ̀hún. (1 Àwọn Ọba 18:21) Bí àpẹẹrẹ, Megan kojú àwọn èrò ti ayé tó wá látọ̀dọ̀ àwọn ọ̀dọ́ mìíràn tó ń wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, ó ní:

“Mo rí i pé ohun tí àwùjọ àwọn ọ̀dọ́ kan, tó ka ẹ̀sìn Kristẹni sí ohun tó ń máyé súni tí kì í ṣì í jẹ́ kéèyàn gbádùn ara ẹ̀ ń sọ, bẹ̀rẹ̀ sí nípa lórí mi. Wọ́n máa ń sọ àwọn nǹkan bíi: ‘Bí mo bá ti pé ọmọ ọdún méjìdínlógún gẹ́ẹ́ ni mo máa kúrò nínú òtítọ́,’ tàbí ‘Ńṣe ló ń ṣe mí bíi pé kí n ti kúrò nínú ètò.’ Wọn kì í fẹ́ bá àwọn ọ̀dọ́ tó bá ń sọ ohun tó yàtọ̀ sí tiwọn rìn, wọ́n a máa pè wọ́n ní àwọn olódodo.”

Kìkì ẹnì kan tàbí méjì tó níwà burúkú ti tó láti sọ àwọn tó kù dìdàkudà. Ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn bá ń ṣe láwùjọ làwọn tó kù sábà máa ń ṣe. Ìwà òmùgọ̀ àti ìṣàyàgbàǹgbà lè múni ṣàìka ọgbọ́n àti ìwà ọmọlúwàbí sí. Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ni ọ̀ràn ìbànújẹ́ ti ń ṣẹlẹ̀ nípa àwọn Kristẹni ọ̀dọ́ tó kó sínú wàhálà nítorí pé wọ́n ṣe ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe.

Lóòótọ́, àwọn ọ̀dọ́langba nílò ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ aládùn dé ààyè kan. Báwo ni ìwọ gẹ́gẹ́ bí òbí ṣe lè pèsè rẹ̀ fún wọn? Má fi ọ̀rọ̀ nípa eré ìnàjú wọn ṣeré rárá, ṣètò àwọn ìgbòkègbodò alárinrin pẹ̀lú ìdílé tàbí kó o ṣètò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ àtàwọn àgbà bíi mélòó kan. Rí i dájú pé o mọ àwọn ọ̀rẹ́ ọmọ rẹ. Pè wọ́n pé kí wọ́n wá báa yín jẹun, tàbí kí wọ́n wá báa yín ṣeré ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan. (Róòmù 12:13) Gba ọmọ rẹ níyànjú láti ṣe àwọn ìgbòkègbodò tó gbámúṣé, bíi kíkọ́ bá a ṣe ń lo ohun èlò orin kan tàbí kó gbìyànjú láti mọ èdè mìíràn sọ tàbí kó kọ́ iṣẹ́ ọwọ́ kan. Dé ààyè kan, ó lè ṣeé ṣe fún un láti ṣe èyí láàárín ilé níbi tí kò ti séwu.

Lílọ sí Ilé Ìwé Lè Jẹ́ Ààbò

Ilé ìwé tí ọ̀dọ́langba kan ń lọ lè máà jẹ́ kó ráyè ṣeré ìnàjú láṣejù. Loli, tó ti jẹ́ ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ ńlá kan fún ogún ọdún sọ pé: “Mo ti rí àìmọye àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ń lọ sílé ìwé. Ọ̀pọ̀ lára wọn ló níwà tó dáa gan-an, àmọ́ àwọn kan wà tí wọn ò yàtọ̀ sáwọn akẹ́kọ̀ọ́ yòókù. Ó dájú pé àwọn tó fojú sí ẹ̀kọ́ wọn làwọn àpẹẹrẹ rere wọ̀nyí. Màá rọ àwọn òbí láti nífẹ̀ẹ́ gidigidi sí ìlọsíwájú àwọn ọmọ wọn nílé ìwé, kí wọ́n mọ àwọn olùkọ́ wọn, kí wọ́n sì jẹ́ káwọn ọmọ wọn mọ̀ pé máàkì tó dáa àti orúkọ rere ṣe pàtàkì gan-an. Àwọn kan lè ta yọ o, àmọ́ gbogbo wọn ló lè ṣe dáadáa kí wọ́n sì gba oríyìn àwọn olùkọ́.”

Irú lílọ sílé ìwé bẹ́ẹ̀ tún lè mú káwọn ọ̀dọ́langba tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Ó lè kọ́ wọn ní ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ tó jíire, bí wọ́n ṣe lè máa kó èrò wọn níjàánu, àti bí wọ́n ṣe lè mọ iṣẹ́ níṣẹ́. Ó dájú pé ìwé tí wọ́n mọ̀ ọ́n kà àti òye tí wọ́n lè tètè ní yóò fún wọn níṣìírí láti túbọ̀ jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó túbọ̀ dáńgájíá. (Nehemáyà 8:8) Ohun tí iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ wọn béèrè àti àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ní láti ṣe nípa tẹ̀mí lè máà jẹ́ kí wọ́n ṣe eré ìtura ju bó ṣe yẹ.

Ògo fún Òbí àti fún Jèhófà

Ọ̀pọ̀ orù tá a fi ń gbin òdòdó tí wọ́n ṣe nílẹ̀ Gíríìsì ìgbàanì ni wọ́n kọ àmì ìdánimọ̀ ẹni tó mọ ọ́n àti ti ẹni tó ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ sí lára. Ní ìfiwéra, àwọn méjì ló sábà máa ń ṣe iṣẹ́ títọ́ àwọn ọmọ nínú ìdílé. Bàbá àti ìyá ló máa ń jùmọ̀ ṣe iṣẹ́ dídarí ọkàn ọmọ síbi tó yẹ, tó túmọ̀ sí pé “àmì ìdánimọ̀” ẹ̀yin méjèèjì la kọ sára ọmọ yín lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Bíi ti amọ̀kòkò àti ẹni tí ń ṣe ọ̀ṣọ́ sára ìkòkò tíṣẹ́ wọn dá wọn lójú ni ìwọ náà ṣe lè fi iṣẹ́ rẹ yangàn tó o bá tọ́ ọmọ kékeré kan di ẹni iyì àti ẹni ẹ̀yẹ.—Òwe 23:24, 25.

Àṣeyọrí iṣẹ́ ribiribi yìí sinmi lórí bó o bá ṣe darí ọkàn ọmọ rẹ tó. A nírètí pé ìwọ náà á lè sọ pé: “Òfin Ọlọ́run rẹ̀ ń bẹ ní ọkàn-àyà rẹ̀; àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ kì yóò gbò yèpéyèpé.” (Sáàmù 37:31) Ọkàn ọmọdé ṣe pàtàkì gan-an ju pé kéèyàn máà gbin ohun tó dára sí i láti kékeré.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn òbí kan máa ń ka Bíbélì sétí ọmọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí. Ohùn atunilára tó ń gbọ́ àti bí ìwé kíkà náà ṣe ń gbádùn mọ́ ọn lè mú kí ọmọ náà fẹ́ràn ìwé kíkà gan-an ní gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀.

b A ti yí àwọn orúkọ kan padà.