Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà—Ọlọ́run Tó Yẹ Ká Mọ̀ Dáadáa

Jèhófà—Ọlọ́run Tó Yẹ Ká Mọ̀ Dáadáa

Jèhófà—Ọlọ́run Tó Yẹ Ká Mọ̀ Dáadáa

ṢÉ kì í ṣe pé ire ńlá kan ló ń fò ẹ́ dá yìí? Tó bá jẹ́ pé ohun tó o mọ̀ nípa Ọlọ́run ò pọ̀, a jẹ́ pé ire ńlá ló ń fò ọ́ dá yẹn o. Kí nìdí? Ìdí ni pé gẹ́gẹ́ bí ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn èèyàn ṣe mọ̀, àǹfààní ńláǹlà ló wà nínú kéèyàn mọ Ọlọ́run Bíbélì. Ojú ẹsẹ̀ làwọn àǹfààní yìí máa bẹ̀rẹ̀ sí í dé, kò sì ní tán títí ayé.

Jèhófà Ọlọ́run, Ẹni tó ni Bíbélì, fẹ́ ká mọ òun dáadáa. Onísáàmù náà kọ̀wé pé: “Kí àwọn ènìyàn lè mọ̀ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” Ó mọ̀ pé àwa la máa jàǹfààní rẹ̀ tá a bá mọ òun. “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní.” Báwo la ṣe máa jàǹfààní nínú mímọ Jèhófà Ọlọ́run, Ẹni Gíga Jù Lọ náà?—Sáàmù 83:18; Aísáyà 48:17.

Ọ̀kan lára àǹfààní ibẹ̀ ni pé àá rí ìtọ́sọ́nà tá a lè fi rí ojútùú sí àwọn ìṣòro ojoojúmọ́, àá ní ìrètí tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ fún ọjọ́ iwájú, àá sì tún ni ìbàlẹ̀ ọkàn. Kò tán síbẹ̀ o, mímọ Jèhófà dáadáa á jẹ́ ká ní èrò tó yàtọ̀ nípa àwọn ìbéèrè pàtàkì tó ń dojú kọ àwọn èèyàn kárí ayé lónìí. Irú àwọn ìbéèrè wo nìyẹn?

Ǹjẹ́ Ìgbésí Ayé Rẹ Ní Ète?

Pẹ̀lú bí ẹ̀dá èèyàn ṣe tẹ̀ síwájú tó nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, síbẹ̀ àwọn èèyàn òde òní ò yé béèrè ìbéèrè pàtàkì náà pé: ‘Kí ni mo wá ṣe láyé? Ibo ni ìgbésí ayé mi forí lé? Kí ni ète ìgbésí ayé?’ Bí ẹnì kan ò bá rí ìdáhùn tó ń tẹ́ni lọ́rùn sáwọn ìbéèrè yìí, ìgbésí ayé rẹ̀ ò lè nítumọ̀. Àmọ́ ǹjẹ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ èyí? Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe nílẹ̀ Jámánì lápá ìparí àwọn ọdún 1990 fi hàn pé ìlàjì àwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ló máa ń ronú nígbà gbogbo tàbí lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan pé ó dà bí ẹni pé ìgbésí ayé ò nítumọ̀. Ó ṣeé ṣe kó rí bákan náà níbi tó ò ń gbé.

Téèyàn ò bá mọbi tí ìgbésí ayé rẹ̀ ń dorí kọ, kò ní lè ṣètò àwọn ohun tó fẹ́ gbé ṣe láyé. Kéyìí má bàa ṣẹlẹ̀ ni ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń sáré kiri láti ríṣẹ́ táá máa rọ̀jò owó fún wọn tàbí kí wọ́n máa kó ọrọ̀ jọ. Síbẹ̀, àìmọ ibi tí ìgbésí ayé ẹni dorí kọ máa ń kó ẹ̀dùn ọkàn púpọ̀ báni. Àìmọ ohun téèyàn ń gbélé ayé ṣe máa ń ba àwọn kan nínú jẹ́ débi pé ayé á tiẹ̀ sú wọn pátápátá ni. Bọ́ràn òrékelẹ́wà obìnrin kan tí ìwé ìròyìn International Herald Tribune, sọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe rí nìyẹn. Inú “ibú owó ni wọ́n bí i sí, ó sì láwọn àǹfààní tó jẹ́ pé kìkì àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn ló máa ń ní i.” Òótọ́ ló ní ọlá tó sì ní ọlà, síbẹ̀ ó máa ń nìkan wà kò sì mọ ibi tí ìgbésí ayé rẹ̀ dorí kọ. Bó ṣe lọ kó oògùn oorun jẹ nìyẹn, ibẹ̀ ló sì bá kú. Ó ṣeé ṣe kó o mọ àwọn kan tí wọ́n nìkan wà bẹ́ẹ̀ tí wọ́n sì ti kú ikú gbígbóná.

Àmọ́ ṣá, ǹjẹ́ o ti gbọ́ ọ rí táwọn èèyàn sọ pé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì lè sọ gbogbo ohun tá a fẹ́ mọ̀ nípa ìgbésí ayé fún wa? Ìwé ìròyìn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ilẹ̀ Jámánì náà Die Woche sọ pé: “Sáyẹ́ǹsì lè jẹ́ òótọ́ o, àmọ́ tó bá kan ọ̀ràn tẹ̀mí, òfìfo àgbá lásán ni. Irọ́ ló ń bẹ nídìí ẹfolúṣọ̀n, ẹ̀kọ́ físíìsì tòun ti ọgbọ́n mẹ̀bẹ́mẹ̀yẹ̀ rẹ̀ pàápàá ò lè fúnni ní ìtùnú àti ààbò.” Àwọn àwárí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ṣe bẹbẹ láti ṣàlàyé bí ìwàláàyè ṣe rí lónírúurú ọ̀nà, àti láti ṣàlàyé ẹgbàágbèje àwọn ohun àdáyébá tó ń darí ìwàláàyè. Pẹ̀lú gbogbo ẹ̀ náà, sáyẹ́ǹsì ò tíì lè ṣàlàyé ìdí tá a fi wà nílé ayé àti ibi tá à ń lọ fún wa. Tó bá jẹ́ pé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì nìkan ṣoṣo la gbára lé, a ò lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wa nípa ìdí tá a fi wà nílé ayé. Èyí á sì yọrí sí ohun tí ìwé ìròyìn Süddeutsche Zeitung pè ní “ọ̀wọ́ngógó ìtọ́sọ́nà.”

Ta lẹni tó tún lè fún wa nírú ìtọ́sọ́nà yìí lẹ́yìn Ẹlẹ́dàá? Nígbà tó kúkú jẹ́ pé òun ló dá ẹ̀dá èèyàn sáyé níbẹ̀rẹ̀, kò sí ni kó má mọ ìdí tí wọ́n fi wà láyé. Bíbélì ṣàlàyé pé Jèhófà dá èèyàn kí wọ́n bàa lè kún orí ilẹ̀ ayé kí wọ́n sì máa ṣàbójútó rẹ̀. Nínú ohun gbogbo tí ẹ̀dá èèyàn bá sì ń ṣe, wọ́n gbọ́dọ̀ máa lo àwọn ànímọ́ Ọlọ́run bí àìṣègbè, ọgbọ́n àti ìfẹ́. Tá a bá ti lè mọ ìdí tí Jèhófà fi ṣẹ̀dá wa, a ti mọ ìdí tá a fi wà láyé nìyẹn.—Jẹ́nẹ́sísì 1:26-28.

Kí Lo Lè Ṣe?

Ká sọ pé tẹ́lẹ̀, o ò rí ìdáhùn tó tẹ́ ọ lọ́rùn sáwọn ìbéèrè bíi: ‘Kí ni mo wá ṣe láyé? Ibo ni ìgbésí ayé mi forí lé? Kí ni ète ìgbésí ayé mi?’ Bíbélì dámọ̀ràn pé kó o túbọ̀ mọ Jèhófà dáadáa. Àní Jésù tiẹ̀ sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” A tún gbà ọ́ níyànjú pé kó o ní àwọn ànímọ́ bíi ti Ọlọ́run, pàápàá jù lọ ìfẹ́, kó o sì fi ṣe góńgó rẹ láti wà lábẹ́ Ìjọba Mèsáyà náà tó ń bọ̀ lọ́nà. Èyí á jẹ́ kí ìgbésí ayé rẹ ní ète, wàá sì ní àgbàyanu ìrètí tó dájú fún ọjọ́ iwájú. Ó ṣeé ṣe kí èyí dáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì tó ti ń jẹ ọ́ lọ́kàn títí di àkókò yìí.—Jòhánù 17:3; Oníwàásù 12:13.

Àmọ́ ipa wo ni èyí máa ní lórí ìgbésí ayé rẹ? Ọ̀gbẹ́ni kan tó ń jẹ́ Hans ní láti mọ bí èyí ṣe lè nípa lórí ìgbésí ayé ẹni. a Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, Hans ní ìgbàgbọ́ kúẹ́kúẹ́ kan nínú Ọlọ́run, àmọ́ ìgbàgbọ́ rẹ̀ yìí kò nípa kankan lórí ìgbésí ayé rẹ̀. Hans fẹ́ràn oògùn olóró, ó kúndùn àwọn obìnrin oníṣekúṣe, ìwà ọ̀daràn díẹ̀díẹ̀, bẹ́ẹ̀ ló tún fẹ́ràn alùpùpù. Àmọ́ òun fúnra rẹ̀ sọ pé: “Ìgbésí ayé ò nítumọ̀, kò sì dùn.” Nígbà tí Hans tó nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, ó pinnu láti mọ Ọlọ́run dáadáa nípa fífara balẹ̀ ka Bíbélì. Nígbà tí Hans wá túbọ̀ mọ Jèhófà sí i tó sì wá lóye ohun tí ìgbésí ayé túmọ̀ sí, ó yí bó ṣe ń gbé ìgbésí ayé rẹ̀ padà ó sì ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Láti odidi ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn báyìí ló ti ń ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Ó là á mọ́lẹ̀ pé: “Sísin Jèhófà ni ọ̀nà ìgbésí ayé tó dára jù lọ. Kò sóhun mìíràn tó dà bíi rẹ̀. Mímọ Jèhófà ti jẹ́ kí n mọ ohun tí mò ń fi ìgbésí ayé mi ṣe.”

Ní ti gidi, kì í ṣe ọ̀ràn ète ìgbésí ayé nìkan ló ń da ọ̀pọ̀ èèyàn láàmú o. Bí ipò àwọn nǹkan ṣe ń burú sí i nínú ayé yìí ti mú kí ọ̀ràn pàtàkì mìíràn tún bẹ̀rẹ̀ sí da àwọn èèyàn láàmú.

Kí Nìdí Tó Fi Ṣẹlẹ̀?

Tí láburú bá ṣẹlẹ̀, ìbéèrè tó máa ń wá sọ́kàn àwọn to ṣẹlẹ̀ sí ni pé: Kí nìdí tó fi ṣẹlẹ̀? Rírí ìdáhùn tó tọ́ sí ìbéèrè yìí ló lè ran èèyàn lọ́wọ́ láti fara da ẹ̀dùn ọkàn tí ìṣẹ̀lẹ̀ láabi máa ń fà. Bí kò bá sí ìdáhùn tó ń tẹ́ni lọ́rùn, ẹ̀dùn ọkàn ẹni tọ́rọ̀ náà ṣẹlẹ̀ sí ò ní lọ, inú á sì máa bí i ṣáá ni. Bí àpẹẹrẹ, gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Bruni yẹ̀ wò.

Bruni, tó ti ń sún mọ́ ẹni àádọ́ta ọdún báyìí sọ pé: “Ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn, ọmọbìnrin mi kékeré kú. Mo gba Ọlọ́run gbọ́, èyí ló mú kí n wá ìtùnú lọ sọ́dọ̀ àlùfáà. Ó sọ fún mi pé Ọlọ́run ti mú Susanne lọ sọ́run, pé ó ti di áńgẹ́lì lọ́hùn-ún báyìí. Yàtọ̀ sí pé ikú ọmọ yìí mú kí gbogbo ìgbésí ayé mi dorí kodò, ó tún mú kí n kórìíra Ọlọ́run fún mímú tó mú ọmọ mi lọ sọ́run.” Bruni ní ẹ̀dùn ọkàn àti ìrora yìí fún ọ̀pọ̀ ọdún. “Ṣùgbọ́n Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan fi hàn mí nínú Bíbélì pé kò yẹ kí n kórìíra Ọlọ́run. Pé Jèhófà kọ́ ló mú Susanne lọ sọ́run, àti pé Susanne kì í ṣe áńgẹ́lì. Àbájáde àìpé ẹ̀dá ló fa àìsàn tó ṣe é. Pé ńṣe ni ikú Susanne dà bí ìgbà tó ń sùn, tó sì ń dúró de àkókò tí Jèhófà á jí i dìde. Mo tún kẹ́kọ̀ọ́ pé ńṣe ni Ọlọ́run ṣẹ̀dá èèyàn láti wà nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé títí láé, pé èyí máa to nímùúṣẹ láìpẹ́. Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí lóye irú ẹni tí Jèhófà jẹ́, mo bẹ̀rẹ̀ sí sún mọ́ ọn, ẹ̀dùn ọkàn mi sì bẹ̀rẹ̀ sí lọọlẹ̀.”—Sáàmù 37:29; Ìṣe 24:15; Róòmù 5:12.

Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ni ìṣẹ̀lẹ̀ láabi ń ṣẹlẹ̀ sí lọ́nà kan tàbí òmíràn: jàǹbá, ogun, ìyàn tàbí ìjábá tó ṣàdédé ṣẹlẹ̀. Ara Bruni wá rọlẹ̀ nígbà tó rí i nínú Bíbélì pé Jèhófà kọ́ ló ń fa ìṣẹ̀lẹ̀ láabi, pé kò wù ú kí ẹ̀dá èèyàn máa jìyà àti pé ó máa fòpin sí aburú láìpẹ́. Bí ìwà ibi ṣe ń pọ̀ sí i yìí jẹ́ àmì pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò àwọn nǹkan yìí la wà báyìí. Ìyípadà pípabanbarì tí gbogbo wa ń retí pé ó máa mú káyé dáa kò ní pẹ́ ṣẹlẹ̀ mọ́.—2 Tímótì 3:1-5; Mátíù 24:7, 8.

Mímọ Ọlọ́run

Èrò tí ò fi bẹ́ẹ̀ lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ni Hans àti Bruni ní nípa Ọlọ́run tẹ́lẹ̀. Wọ́n gbà gbọ́ pé ó wà àmọ́ wọn ò mọ̀ ọ́n dáadáa. Nígbà tí wọ́n wá àkókò láti mọ Jèhófà dáadáa, wọ́n rí èrè ìsapá tí wọ́n ṣe. Wọ́n rí ìdáhùn tó ń tẹ́ni lọ́rùn sáwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì jù lọ lákòókò tá a wà yìí. Èyí fún wọn ní ìbàlẹ̀ ọkàn àti ìrètí ọjọ́ iwájú tí mìmì kan ò lè mì. Ọ̀kẹ́ àìmọye ìránṣẹ́ Jèhófà ni irú èyí ti ṣẹlẹ̀ sí.

Sísapá láti mọ Jèhófà bẹ̀rẹ̀ látorí fífara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn ìwé tó sọ fún wa nípa rẹ̀ àti nípa àwọn ohun tó fẹ́ ká ṣe. Ohun táwọn kan ṣe ní ọ̀rúndún kìíní nìyẹn. Lúùkù tó jẹ́ òpìtàn àti oníṣègùn ròyìn pé àwọn Júù nínú ìjọ Bèróà, nílẹ̀ Gíríìsì, “gba ọ̀rọ̀ náà [látẹnu Pọ́ọ̀lù àti Sílà] pẹ̀lú ìháragàgà ńláǹlà nínú èrò inú, tí wọ́n ń fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ ní ti pé bóyá bẹ́ẹ̀ ni nǹkan wọ̀nyí rí.”—Ìṣe 17:10, 11.

Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní tún máa ń kóra jọ pọ̀ nínú àwọn ìjọ. (Ìṣe 2:41, 42, 46; 1 Kọ́ríńtì 1:1, 2; Gálátíà 1:1, 2; 2 Tẹsalóníkà 1:1) Bákan náà ló ṣe rí lónìí. Ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń pàdé pọ̀ fún àwọn ìpàdé tá a dìídì ṣètò láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà kí wọ́n sì láyọ̀ bí wọ́n ṣe ń jọ́sìn rẹ̀. Dídara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí tún ní àǹfààní mìíràn. Nígbà tó jẹ́ pé díẹ̀díẹ̀ lèèyàn máa bẹ̀rẹ̀ sí dà bí Ọlọ́run tó ń jọ́sìn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àwọn ànímọ́ tí Jèhófà fúnra rẹ̀ ní bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò tíì ní i débi tó yẹ. Nítorí náà, pípé jọ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí á túbọ̀ jẹ́ ká mọ Jèhófà sí i.—Hébérù 10:24, 25.

Ǹjẹ́ kò dà bí ẹni pé ìsapá téèyàn á ṣe láti lè mọ Ẹnì kan ṣoṣo péré yìí ti pọ̀ jù? Òótọ́ ni pé ó gba ìsapá. Àmọ́ ǹjẹ́ a rí ohun kan tó o fẹ́ ní láyé yìí tó ò ní sapá kọ́wọ́ rẹ tó tẹ̀ ẹ́? Ronú nípa ìsapá ńláǹlà tí eléré ìdárayá kan tó ti di àgbà ọ̀jẹ̀ máa ń ṣe láti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́. Bí àpẹẹrẹ, Jean-Claude Killy, ọmọ ilẹ̀ Faransé tó gba ẹ̀bùn góòlù nínú eré orí yìnyín tí wọ́n ń ṣe nígbà ìdíje Òlíńpíìkì, sọ pé kéèyàn tó lè di olùdíje táwọn èèyàn mọ̀ lágbàáyé: “Tí ìdíje yìí bá ti ku ọdún mẹ́wàá ni wàá ti bẹ̀rẹ̀ sí múra sílẹ̀, ọ̀pọ̀ ọdún ni wàá fi ṣe ìmúrasílẹ̀ yìí, wàá máa ronú nípa rẹ̀ lójoojúmọ́ . . . Ọjọ́ kan ò gbọ́dọ̀ kọjá kó o má ronú nípa rẹ̀ kó o má sì máa gbára dì fún un.” Tìtorí àtikópa nínú ìdíje tó lè má kọjá ìṣẹ́jú mẹ́wàá péré ni gbogbo wàhálà àṣekúdórógbó yìí o! Ẹ ò wá rí i nígbà náà pé ohun tá a máa jèrè tá a bá mọ Jèhófà á ju èyí lọ fíìfíì.

Àjọṣe Tí Ò Lópin

Ta ló fẹ́ kí ire fo òun dá nígbèésí ayé òun? Kò sírú ẹni bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, tó o bá rí i pé ìgbésí ayé rẹ ò ní ète tàbí tó o bá fẹ́ mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ìdí tí láburú fi ń ṣẹlẹ̀, pinnu láti mọ Jèhófà ẹni tí í ṣe Ọlọ́run Bíbélì. Kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ lè yí ìgbésí ayé rẹ padà sí rere títí láé.

Ǹjẹ́ ìgbà kan máa wà tá ò ní kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà mọ́? Àwọn tó ti ń sìn ín láti ọ̀pọ̀ ọdún wá máa ń kọ háà nípa ohun tí wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ àtàwọn ohun tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ nípa rẹ̀. Kíkẹ́kọ̀ọ́ àwọn ohun tuntun bẹ́ẹ̀ máa ń fún wa láyọ̀ ó sì ń jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ ọn. Ǹjẹ́ kí àwa náà fara mọ́ èrò àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ẹni tó kọ̀wé pé: “Ìjìnlẹ̀ àwọn ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run mà pọ̀ o! Àwọn ìdájọ́ rẹ̀ ti jẹ́ àwámáridìí tó, àwọn ọ̀nà rẹ̀ sì ré kọjá àwákàn! Nítorí ‘ta ni ó ti wá mọ èrò inú Jèhófà, tàbí ta ní ti di agbani-nímọ̀ràn rẹ̀?’”—Róòmù 11:33, 34.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ padà.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]

Àwọn èèyàn ò yé béèrè ìbéèrè pàtàkì náà pé: ‘Kí ni mo wá ṣe láyé? Ibo ni ìgbésí ayé mi forí lé? Kí ni ète ìgbésí ayé?’

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]

“Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí lóye irú ẹni tí Jèhófà jẹ́, mo bẹ̀rẹ̀ sí sún mọ́ ọn”

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 7]

“Sísin Jèhófà ni ọ̀nà ìgbésí ayé tó dára jù lọ. Kò sóhun mìíràn tá a lè fi wé. Mímọ Jèhófà ti jẹ́ kí n mọ ohun tí mò ń fi ìgbésí ayé mi ṣe”