Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ni Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa Túmọ̀ Sí Fún Ọ?

Kí Ni Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa Túmọ̀ Sí Fún Ọ?

Kí Ni Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa Túmọ̀ Sí Fún Ọ?

“Ẹnì yòówù tí ó bá jẹ ìṣù búrẹ́dì náà tàbí tí ó bá mu ife Olúwa láìyẹ yóò jẹ̀bi nípa ara àti ẹ̀jẹ̀ Olúwa.”—1 KỌ́RÍŃTÌ 11:27.

1. Ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣe pàtàkì jù lọ wo la wéwèé fún ọdún 2003, báwo ló sì ṣe bẹ̀rẹ̀?

 ÌṢẸ̀LẸ̀ tó ṣe pàtàkì jù lọ tá a wéwèé fún ọdún 2003 yóò wáyé lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀ ní April 16. Ìgbà yẹn làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò pàdé pọ̀ láti ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ikú Jésù Kristi. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe fi hàn nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, Jésù ló dá àṣeyẹ yìí, tá a tún ń pè ní Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa sílẹ̀, lẹ́yìn tí òun àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ti ṣayẹyẹ Ìrékọjá tán ní Nísàn 14, ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ Ìṣe Ìrántí náà tó jẹ́ búrẹ́dì aláìwú àti wáìnì pupa dúró fún ara aláìlẹ́ṣẹ̀ ti Kristi àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tí a ta sílẹ̀—ìyẹn ni ẹbọ kan ṣoṣo tó lè ra ìran ènìyàn padà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.—Róòmù 5:12; 6:23.

2. Ìkìlọ̀ wo ló wà nínú 1 Kọ́ríńtì 11:27?

2 Àwọn tó ń jẹ nínú àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ tá a fi ń ṣe Ìṣe Ìrántí náà gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ kí èyí ṣe kedere nígbà tó ń kọ̀wé sáwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì ìgbàanì, níbi tí wọ́n ti ń ṣayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa náà lọ́nà tí kò bójú mu. (1 Kọ́ríńtì 11:20-22) Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá jẹ ìṣù búrẹ́dì náà tàbí tí ó bá mu ife Olúwa láìyẹ yóò jẹ̀bi nípa ara àti ẹ̀jẹ̀ Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 11:27) Kí ni àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn túmọ̀ sí?

Àwọn Kan Ń Ṣe É Láìyẹ

3. Báwo ni ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ara Kọ́ríńtì ṣe ń ṣe níbi ayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa?

3 Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ará Kọ́ríńtì ló kópa nínú Ìṣe Ìrántí náà láìyẹ. Ìyapa wà láàárín wọn, ìgbà kan tiẹ̀ wà táwọn kan ń gbé oúnjẹ alẹ́ wọn wá tí wọ́n sì ń jẹ ẹ́ ṣáájú ìpàdé náà tàbí nígbà tí ìpàdé náà bá ń lọ lọ́wọ́, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń jẹ àjẹkì tí wọ́n sì máa ń mu àmupara. Wọn ò wà lójúfò rárá, yálà nínú èrò inú wọn tàbí nípa tẹ̀mí. Èyí ló fà á tí wọ́n fi “jẹ̀bi nípa ara àti ẹ̀jẹ̀ Olúwa.” Ebi wá bẹ̀rẹ̀ sí pa àwọn tí kò tí ì jẹun alẹ́, wọn ò sì lè pọkàn pọ̀ mọ́. Àní, ọ̀pọ̀ ló ń jẹ ohun ìṣàpẹẹrẹ lọ́nà tí kò fi ọ̀wọ̀ hàn fún àṣeyẹ náà, wọn ò sì mọ bó ti ṣe pàtàkì tó. Abájọ tí wọ́n fi mú ẹ̀bi wá sórí ara wọn!—1 Kọ́ríńtì 11:27-34.

4, 5. Kí nìdí tó fi pọn dandan pé káwọn tó máa ń jẹ nínú àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ tá a fi ń ṣe Ìṣe Ìrántí yẹ ara wọn wò dáadáa?

4 Bí Ìṣe Ìrántí náà bá ti ń sún mọ́lé lọ́dọọdún, ó ṣe pàtàkì gan-an káwọn tó máa ń jẹ nínú àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ náà yẹ ara wọn wò dáadáa. Tí wọ́n bá fẹ́ jẹ nínú oúnjẹ àjọjẹ yìí, wọ́n gbọ́dọ̀ wà nípò tó dára nípa tẹ̀mí. Ẹnikẹ́ni tó bá fi ìwà àìlọ́wọ̀ hàn, kódà ẹni tó bá fojú tẹ́ńbẹ́lú ẹbọ Jésù lè di ẹni tá a “ké kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀,” bíi ti ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ nínú oúnjẹ àjọjẹ kan nígbà tó jẹ́ aláìmọ́.—Léfítíkù 7:20; Hébérù 10:28-31.

5 Pọ́ọ̀lù fi Ìṣe Ìrántí náà wé oúnjẹ àjọjẹ kan ní Ísírẹ́lì ìgbàanì. Ó sọ nípa bí àwọn tó ń jẹ ẹ́ ṣe ń jùmọ̀ ṣàjọpín nínú Kristi, ó wá sọ pé: “Ẹ kò lè máa mu ife Jèhófà àti ife àwọn ẹ̀mí èṣù; ẹ kò lè máa ṣalábàápín ‘tábìlì Jèhófà’ àti tábìlì àwọn ẹ̀mí èṣù.” (1 Kọ́ríńtì 10:16-21) Bí ẹnì kan tó máa ń jẹ nínú ohun ìṣàpẹẹrẹ Ìṣe Ìrántí náà bá dá ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo, ó gbọ́dọ̀ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fún Jèhófà kó sì tún wá bóun ṣe máa rí ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí gbà lọ́dọ̀ àwọn àgbà ọkùnrin tó wà nínú ìjọ. (Òwe 28:13; Jákọ́bù 5:13-16) Tó bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, tó sì mú àwọn èso tó yẹ fún ìrònúpìwàdà jáde, jíjẹ tó ń jẹ nínú ohun ìṣàpẹẹrẹ náà kò ní jẹ́ láìyẹ.—Lúùkù 3:8.

Wíwá Síbẹ̀ Gẹ́gẹ́ Bí Òǹwòran Tí Ń Fi Ọ̀wọ̀ Hàn

6. Àwọn wo ni Ọlọ́run fún láǹfààní láti jẹ nínú Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa náà?

6 Ṣé ó yẹ káwọn tó ń ṣe rere sáwọn ìyókù lára àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí wọ́n jẹ́ arákùnrin Kristi máa jẹ nínú Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa náà? (Mátíù 25:31-40; Ìṣípayá 14:1) Rárá o. Ọlọ́run ti ṣètò àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ yẹn fún kìkì àwọn tó ti fi ẹ̀mí mímọ́ yàn láti di “ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi.” (Róòmù 8:14-18; 1 Jòhánù 2:20) Ipò wo làwọn tó nírètí gbígbé títí láé nínú Párádísè tí yóò kárí ayé lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run yóò wá wà? (Lúùkù 23:43; Ìṣípayá 21:3, 4) Níwọ̀n bí wọn ò ti sí lára àwọn ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Jésù tó nírètí ti ọ̀run, wọ́n wá síbi Ìṣe Ìrántí náà gẹ́gẹ́ bí òǹwòran tí ń fi ọ̀wọ̀ hàn ni.—Róòmù 6:3-5.

7. Kí nìdí táwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní fi mọ̀ pé àwọn lè jẹ nínú àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ tá a fi ń ṣe Ìṣe Ìrántí?

7 Ẹ̀mí mímọ́ la fi yan àwọn Kristẹni tòótọ́ ní ọ̀rúndún kìíní. Ọ̀pọ̀ lára wọn ló láǹfààní àtilo ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lára àwọn àgbàyanu ẹ̀bùn ẹ̀mí náà, bíi fífi èdè fọ̀. Nítorí náà, kò lè ṣòro rárá fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ láti mọ̀ pé a ti fi ẹ̀mí yàn wọ́n àti pé wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ nínú àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ tá a fi ń ṣe Ìṣe Ìrántí. Àmọ́, ohun tá a fi lè pinnu èyí lákòókò tá a wà yìí sinmi lórí àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí bí ìwọ̀nyí: “Gbogbo àwọn tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń ṣamọ̀nà, àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Ọlọ́run. Nítorí ẹ kò gba ẹ̀mí ìsìnrú tí ó tún ń fa ìbẹ̀rù, ṣùgbọ́n ẹ̀yin gba ẹ̀mí ìsọdọmọ, ẹ̀mí tí ń mú kí a ké jáde pé: ‘Ábà, Baba!’”—Róòmù 8:14, 15.

8. Àwọn wo ló dúró fún “àlìkámà” àti “àwọn èpò” tá a mẹ́nu kàn nínú Mátíù orí kẹtàlá?

8 Láti àwọn ọ̀rúndún wọ̀nyí wá ni àwọn ojúlówó ẹni àmì òróró ti ń gbilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “àlìkámà” nínú pápá “èpò,” tàbí àwọn èké Kristẹni. (Mátíù 13:24-30, 36-43) Láti àwọn ọdún 1870, ni “àlìkámà” náà ti wá fara hàn dáadáa, wọ́n sì sọ ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn náà fáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó jẹ́ alábòójútó pé: “Àwọn alàgbà . . . gbọ́dọ̀ fi kókó yìí tó àwọn tó kóra jọ [fún Ìṣe Ìrántí] létí,—(1) ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ [Kristi]; àti (2) ìyàsímímọ́ sí Olúwa àti iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ kódà títí dójú ikú. Kí wọ́n wá ké sí gbogbo àwọn tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, tí wọ́n sì ya ara wọn sí mímọ́ láti nípìn-ín nínú ṣíṣe ayẹyẹ ikú Olúwa.”—Ìwé Studies in the Scriptures, Ẹ̀dà Kẹfà, The New Creation, ojú ìwé 473. a

Wíwá Àwọn “Àgùntàn Mìíràn”

9. Báwo la ṣe dá àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” mọ̀ ní ọdún 1935, báwo lèyí sì ṣe nípa lórí àwọn kan tí wọ́n ti ń jẹ nínú ohun ìṣàpẹẹrẹ Ìṣe Ìrántí náà tẹ́lẹ̀?

9 Bí àkókò ti ń lọ, ètò àjọ Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí darí àfiyèsí sórí àwọn mìíràn ní àfikún sí àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Kristi. Ìṣẹ̀lẹ̀ tó gba àfiyèsí jù lọ lórí ọ̀ràn yìí ni èyí tó wáyé ní àárín àwọn ọdún 1930. Ṣáájú àkókò yẹn, ohun táwọn èèyàn Ọlọ́run rò nípa àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” inú Ìṣípayá 7:9 ni pé wọ́n jẹ́ ẹgbẹ́ tẹ̀mí onípò kejì tí yóò wà pà pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ẹni àmì òróró tá a jí dìde sí ọ̀run—gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ ìyàwó tàbí àwọn alábàákẹ́gbẹ́ ìyàwó Kristi. (Sáàmù 45:14, 15; Ìṣípayá 7:4; 21:2, 9) Àmọ́ ní May 31, 1935, nínú àsọyé kan tá a sọ ní àpéjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Washington, D.C., Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, a fi Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé níbẹ̀ pé “ogunlọ́gọ̀ ńlá” (ògìdìgbó ńláǹlà,” King James Version) ń tọ́ka sí “àgùntàn mìíràn” tó wà láàyè ní àkókò òpin. (Jòhánù 10:16) Lẹ́yìn àpéjọ náà, àwọn kan tí wọ́n máa ń jẹ ohun ìṣàpẹẹrẹ Ìṣe Ìrántí náà tẹ́lẹ̀ ṣíwọ́ jíjẹ ẹ́ nítorí wọ́n ti wá mọ̀ pé ìrètí ti ilẹ̀ ayé làwọn ní kì í ṣe ti ọ̀run.

10. Báwo lo ṣe máa ṣàpèjúwe ìrètí àti ẹrù iṣẹ́ àwọn “àgùntàn mìíràn” òde òní?

10 Àgàgà láti ọdún 1935 la ti ń wá àwọn tó wá di “àgùntàn mìíràn,” tí wọ́n nígbàgbọ́ nínú ìràpadà, tí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń ti àwọn ẹni àmì òróró “agbo kékeré” náà lẹ́yìn nínú ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà. (Lúùkù 12:32) Àwọn àgùntàn mìíràn wọ̀nyí ní ìrètí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé, àmọ́ láwọn ọ̀nà mìíràn, wọ́n jọ àwọn ìyókù ajùmọ̀jogún Ìjọba náà lóde òní. Bíi ti àwọn àtìpó tó wà ní Ísírẹ́lì ìgbàanì tí wọ́n ń jọ́sìn Jèhófà tí wọ́n sì ń pa Òfin rẹ̀ mọ́, àwọn àgùntàn mìíràn ti òde òní náà tẹ́wọ́ gba àwọn ẹrù iṣẹ́ Kristẹni, bíi wíwàásù ìhìn rere náà pẹ̀lú àwọn tó jẹ́ mẹ́ńbà Ísírẹ́lì tẹ̀mí. (Gálátíà 6:16) Àmọ́ ṣá o, bó ṣe jẹ́ pé kò sí àtìpó tó lè di ọba tàbí àlùfáà ní Ísírẹ́lì, bẹ́ẹ̀ náà nì kò sí èyíkéyìí nínú àwọn àgùntàn mìíràn tó lè ṣàkóso nínú Ìjọba ọ̀run tàbí kó sìn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà níbẹ̀.—Diutarónómì 17:15.

11. Kí nìdí tí ìgbà tẹ́nì kan ṣe batisí fi ní í ṣe pẹ̀lú ìrètí tó ní?

11 Àwọn ọdún 1930 ló wá bẹ̀rẹ̀ sí hàn gbangba pé a ti yan ẹgbẹ́ ti ọ̀run. Láti nǹkan bí àádọ́rin ọdún báyìí ló ti jẹ́ pé kìkì àwọn àgùntàn mìíràn tí wọ́n ní ìrètí ti orí ilẹ̀ ayé là ń wá. Bí ọ̀kan nínú àwọn ẹni àmì òróró bá sì ṣi ẹsẹ̀ gbé, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹnì kan tó ti ń fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà fún ìgbà pípẹ́ lára àwọn àgùntàn mìíràn la máa pè láti dí àyè tó ṣófo láàárín àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì náà.

Ohun Tó Ń Mú Káwọn Kan Fi Àṣìṣe Rò Pé Ìrètí Ti Ọ̀run Làwọn Ní

12. Kí ló lè mú kí ẹnì kan jáwọ́ nínú jíjẹ àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ tá a fi ń ṣe Ìṣe Ìrántí, kí sì nìdí?

12 Ó dá àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lójú hán-únhán-ún pé àwọn ti rí ìpè ti ọ̀run gbà. Àmọ́ bí àwọn kan tí kò rí irú ìpè yìí gbà bá ti ń jẹ nínú àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ tá a fi ń ṣe Ìṣe Ìrántí náà ńkọ́? Nísinsìnyí tí wọ́n ti wá mọ̀ pé àwọn ò nírètí ti ọ̀run, ó dájú pé ẹ̀rí ọkàn wọn yóò sún wọn láti ṣíwọ́ jíjẹ nínú rẹ̀. Ọlọ́run kò ní fi ojú tó dáa wo ẹnikẹ́ni tó bá ń ṣe bí ẹni pé a ti pe òun láti wá di ọba àti àlùfáà lọ́run nígbà tó sì mọ̀ pé òun ò rí irú ìpè bẹ́ẹ̀ gbà. (Róòmù 9:16; Ìṣípayá 20:6) Pípa ni Jèhófà pa Kórà tó jẹ́ ọmọ Léfì nítorí pé ó ń fi ìkùgbù wá ọ̀nà láti gba ipò àlùfáà tó jẹ́ ti Áárónì. (Ẹ́kísódù 28:1; Númérì 16:4-11, 31-35) Bí Kristẹni kan bá rí i pé òun ti ń fi àṣìṣe jẹ àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ tá a fi ń ṣe Ìṣe Ìrántí, irú ẹni bẹ́ẹ̀ gbọ́dọ̀ jáwọ́ ńbẹ̀, kó sì tọrọ ìdáríjì tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ lọ́dọ̀ Jèhófà.— Sáàmù 19:13.

13, 14. Kí ló lè mú káwọn kan fi àṣìṣe ronú pé àwọn ti gba ìpè ti ọ̀run?

13 Kí ló lè mú káwọn kan fi àṣìṣe ronú pé àwọn ti gba ìpè ti ọ̀run? Ikú ọkọ tàbí ti aya tàbí ohun ìbànújẹ́ mìíràn tó ṣẹlẹ̀ sí wọn lè mú kí gbígbé lórí ilẹ̀ ayé sú wọn. Tàbí kẹ̀, ó lè jẹ́ pé ìrètí ti ọ̀run tí ọ̀rẹ́ wọ́n tímọ́tímọ́ kan tó sọ pé òun jẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró ní ló ń wu àwọn náà. Àmọ́, Ọlọ́run ò tíì yan ẹnikẹ́ni láti pe àwọn ẹlòmíràn pé kí wọ́n wá jàǹfààní yìí. Kò sì fàmì òróró yan àwọn ajogún Ìjọba náà nípa mímú kí wọ́n gbọ́ ohùn kan tó máa sọ fún wọn pé a ti pè wọ́n.

14 Èrò tí ìsìn èké ti gbìn sọ́kàn àwọn èèyàn pé gbogbo ẹni rere ló ń lọ sí ọ̀run lè mú káwọn kan ronú pé àwọn ti gba ìpè ti ọ̀run. Nítorí náà, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn èrò èké tá a ti ní tẹ́lẹ̀ tàbí àwọn nǹkan mìíràn nípa lórí wa. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan lè bi ara wọn pé: ‘Ṣé kì í ṣe pé mò ń lo àwọn egbòogi tó ń nípa lórí ìrònú mi? Ṣé n kì í ṣe ẹni tó máa ń ronú àròjù tí màá fi máa rò pé ẹni àmì òróró ni mí?’

15, 16. Kí ló lè mú káwọn kan fi àṣìṣe rò pé ẹni àmì òróró làwọn?

15 Àwọn díẹ̀ lè bi ara wọn pé: ‘Ṣé mo fẹ́ di olókìkí ni? Ṣé mò ń kánjú àtiwà ní ipò àṣẹ nísinsìnyí ni àbí mò ń kánjú àtidi ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi lọ́jọ́ iwájú?’ Nígbà tá a pe àwọn ajogún Ìjọba náà ní ọ̀rúndún kìíní, kì í ṣe gbogbo wọn la fún ní ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ nígbà náà. Àwọn tó sì gba ipè ti ọ̀run kì í wá òkìkí fún ara wọn bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í fi jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró ṣe fọ́rífọ́rí. Ńṣe ni wọ́n máa ń ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, irú èyí tá a retí pé káwọn tó ní “èrò inú ti Kristi” ní.—1 Kọ́ríńtì 2:16.

16 Àwọn kan lè rò pé àwọn ti gba ìpè ti ọ̀run nítorí pé wọ́n nímọ̀ Bíbélì gan-an. Àmọ́ jíjẹ́ ẹni àmì òróró kò sọni di ẹni tó ní òye tó ṣàrà ọ̀tọ̀, nítorí pé Pọ́ọ̀lù tiẹ̀ tọ́ àwọn ẹni àmì òróró kan sọ́nà ó sì fún wọn nímọ̀ràn pẹ̀lú. (1 Kọ́ríńtì 3:1-3; Hébérù 5:11-14) Ọlọ́run ti ṣètò kan tó fi ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀. (Mátíù 24:45-47) Nítorí náà, kò sí ẹnikẹ́ni tó gbọ́dọ̀ ronú pé jíjẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró ti jẹ́ kóun ní ọgbọ́n tó ga ju ti àwọn tó ní ìrètí gbígbé lórí ilẹ̀ ayé. Kì í ṣe mímọ bá a ṣe ń dáhùn àwọn ìbéèrè tó jẹ mọ́ Ìwé Mímọ́, mímọ bá a ṣe ń jẹ́rìí, tàbí mímọ àwọn àsọyé Bíbélì sọ la fi ń mọ̀ pé a ti fi ẹ̀mí yan ẹnì kan. Àwọn Kristẹni tó ní ìrètí gbígbé lórí ilẹ̀ ayé náà ò kẹ̀rẹ̀ nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí.

17. Jíjẹ́ ẹni tá a fi ẹ̀mí yàn sinmi lórí kí ni, ta ló sì ń ṣe yíyàn náà?

17 Bí onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni kan bá béèrè nípa ìpè ti ọ̀run, alàgbà kan tàbí Kristẹni mìíràn tó dàgbà dénú lè jíròrò ọ̀ràn náà pẹ̀lú rẹ̀. Àmọ́ ṣá, ẹni kan kò lè ṣe ìpinnu yìí fún ẹlòmíràn o. Ẹni tó bá dìídì gba ìpè yìí kò ní í máa bi àwọn ẹlòmíràn bóyá lóòótọ́ lòun ní irú ìrètí bẹ́ẹ̀. A ti fún àwọn ẹni àmì òróró “ní ìbí tuntun, kì í ṣe nípasẹ̀ irú-ọmọ tí ó lè díbàjẹ́, bí kò ṣe nípasẹ̀ èyí tí kò lè díbàjẹ́, nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run alààyè, tí ó sì wà pẹ́ títí.” (1 Pétérù 1:23) Ọlọ́run ti ipasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀ àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbin “irú ọmọ” tó sọ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ di “ìṣẹ̀dá tuntun,” tí ó ní ìrètí ti ọ̀run. (2 Kọ́ríńtì 5:17) Jèhófà ló sì ń ṣe yíyàn náà. Jíjẹ́ ẹni àmì òróró “kò sinmi lé ẹni tí ń fẹ́ tàbí lé ẹni tí ń sáré, bí kò ṣe lé Ọlọ́run.” (Róòmù 9:16) Báwo wá lẹnì kan ṣe lè ní ìdánilójú pé òun ti gba ìpè ti ọ̀run?

Ìdí Tó Fi Dá Wọn Lójú

18. Báwo ni ẹ̀mí Ọlọ́run ṣe ń jẹ́rìí pẹ̀lú ẹ̀mí àwọn ẹni àmì òróró?

18 Ẹ̀rí tí ẹ̀mí Ọlọ́run jẹ́ ló mú un da àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lójú pé wọ́n ní ìrètí lílọ sí ọ̀run. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin gba ẹ̀mí ìsọdọmọ, ẹ̀mí tí ń mú kí a ké jáde pé: ‘Ábà, Baba!’ Ẹ̀mí tìkára rẹ̀ ń jẹ́rìí pẹ̀lú ẹ̀mí wa pé àwa jẹ́ ọmọ Ọlọ́run. Nígbà náà, bí àwa bá jẹ́ ọmọ, ajogún ni wá pẹ̀lú: àwọn ajogún Ọlọ́run ní tòótọ́, ṣùgbọ́n àwọn ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi, kìkì bí a bá jọ jìyà pa pọ̀, kí a lè ṣe wá lógo pa pọ̀ pẹ̀lú.” (Róòmù 8:15-17) Lábẹ́ ìdarí ẹ̀mí mímọ́, ẹ̀mí náà, tàbí ìṣarasíhùwà àwọn ẹni àmì òróró náà á jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa àwọn ọmọ Jèhófà nípa tẹ̀mí kan àwọn. (1 Jòhánù 3:2) Ẹ̀mí Ọlọ́run ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé àwọn jẹ́ ọmọ fún un, ó sì fi ìrètí àrà ọ̀tọ̀ kan sí wọn lọ́kàn. (Gálátíà 4:6, 7) Bẹ́ẹ̀ ni o, ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn pípé tí tẹbí tọ̀rẹ́ máa yíni ká yóò dùn gan-an ni, àmọ́ ìyẹn kì í ṣe ìrètí tí Ọlọ́run fún wọn. Ọlọ́run ti tipasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀ fi ìrètí tó lágbára ti lílọ sí ọ̀run sí wọn lọ́kàn débi pé wọ́n múra tán láti yááfì gbogbo nǹkan ayé yìí àtàwọn ohun téèyàn lè máa wọ̀nà fún.—2 Kọ́ríńtì 5:1-5, 8; 2 Pétérù 1:13, 14.

19. Ipa wo ni májẹ̀mú tuntun ń kó nínú ìgbésí ayé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró?

19 Ó dá àwọn ẹni àmì òróró lójú hán-únhán-ún pé àwọn ní ìrètí ti ọ̀run, àti pé a ti mú wọn wá sínú májẹ̀mú tuntun náà. Jésù mẹ́nu kan èyí nígbà tó dá Ìṣe Ìrántí náà sílẹ̀ tó sọ pé: “Ife yìí túmọ̀ sí májẹ̀mú tuntun nípa agbára ìtóye ẹ̀jẹ̀ mi, tí a óò tú jáde nítorí yín.” (Lúùkù 22:20) Ọlọ́run àtàwọn ẹni àmì òróró ló wà nínú májẹ̀mú tuntun náà. (Jeremáyà 31:31-34; Hébérù 12:22-24) Jésù ni alárinà rẹ̀. Nítorí pé ẹ̀jẹ̀ Kristi tá a ta sílẹ̀ ló mú kí májẹ̀mú tuntun náà fẹsẹ̀ múlẹ̀, kì í ṣe inú àwọn Júù nìkan ló ti mú àwọn ènìyàn, ó tún mú àwọn ènìyàn fún orúkọ Jèhófà jáde láti inú àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú, ó sì sọ wọ́n di “irú ọmọ” Ábúráhámù. (Gálátíà 3:26-29; Ìṣe 15:14) “Májẹ̀mú àìnípẹ̀kun” yìí mú kó ṣeé ṣe fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tẹ̀mí láti di ẹni tá a jí dìde sí ìyè àìleèkú ní ọ̀run.—Hébérù 13:20.

20. Inú májẹ̀mú wo la mú àwọn ẹni àmì òróró wọ̀ pẹ̀lú Kristi?

20 Ìrètí táwọn ẹni àmì òróró ní dá wọn lójú. A tún ti mú wọn wọnú májẹ̀mú mìíràn, ìyẹn ni májẹ̀mú Ìjọba náà. Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa àjọpín tí wọ́n ní pẹ̀lú Kristi, ó ní: “Ẹ̀yin ni ẹ ti dúró tì mí gbágbáágbá nínú àwọn àdánwò mi; èmi sì bá yín dá májẹ̀mú kan, gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba mi ṣe bá mi dá májẹ̀mú kan, fún ìjọba kan.” (Lúùkù 22:28-30) Májẹ̀mú tó wà láàárín Kristi àtàwọn tí yóò bá a jọba jẹ́ èyí tí yòó wà títí láé.—Ìṣípayá 22:5.

Àkókò Ìṣe Ìrántí Jẹ́ Àkókò Ayọ̀

21. Báwo la ṣe lè jàǹfààní tó ga lákòókò Ìṣe Ìrántí?

21 Ọ̀pọ̀ nǹkan tí ń múnú ẹni dùn ló máa ń wáyé lákòókò Ìṣe Ìrántí. A lè jàǹfààní látinú ètò tá a ṣe fún Bíbélì kíkà lákòókò tá à ń wí yìí. Ó tún jẹ́ àkókò àtàtà láti gbàdúrà, láti ṣàṣàrò lórí ìgbésí ayé Jésù lórí ilẹ̀ ayé àti ikú rẹ̀, àti láti kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà. (Sáàmù 77:12; Fílípì 4:6, 7) Ayẹyẹ náà fúnra rẹ̀ ń rán wa létí ìfẹ́ tí Ọlọ́run àti Kristi fi hàn nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù. (Mátíù 20:28; Jòhánù 3:16) Ìpèsè yìí fún wa ní ìrètí àti ìtùnú, ó sì gbọ́dọ̀ jẹ kí ìpinnu wa láti tẹ̀ lé ipa ọ̀nà tí Kristi tọ̀ túbọ̀ lágbára sí i. (Ẹ́kísódù 34:6; Hébérù 12:3) Bákan náà, ó tún yẹ kí Ìṣe Ìrántí náà fún wa lókun láti mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run ṣẹ, ká sì jẹ́ adúróṣinṣin ọmọlẹ́yìn Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n.

22. Ẹ̀bùn gíga jù lọ wo ni Ọlọ́run fún ìran ènìyàn, kí sì ni ọ̀nà kan tá a lè gbà fi ìmọrírì hàn fún un?

22 Ẹ̀bùn àtàtà ni Jèhófà mà fún wa yìí o! (Jákọ́bù 1:17) À ń gba ìtọ́sọ́nà látinú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ń ràn wá lọ́wọ́, a sì tún ní ìrètí ìyè ayérayé. Ẹ̀bùn tó ga lọ́lá jù lọ tí Ọlọ́run fún wa ni fífi tó fi Jésù rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹni àmì òróró àti ti gbogbo àwọn mìíràn tó bá lo ìgbàgbọ́. (1 Jòhánù 2:1, 2) Nítorí náà, báwo ni ikú Jésù ti ṣe pàtàkì tó lójú rẹ? Ṣé wàá wà lára àwọn tó fi ìmọrírì hàn fún un nípa pípéjọ láti ṣayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀ ní April 16, 2003?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde àmọ́ a ò ṣe é jáde mọ́.

Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?

• Àwọn wo ló yẹ kó jẹ nínú àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ tá a fi ń ṣe Ìṣe Ìrántí?

• Kí nìdí táwọn “àgùntàn mìíràn” fi ń wá síbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa kìkì láti wá jẹ́ òǹwòran tí ń fi ọ̀wọ̀ hàn?

• Báwo làwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ṣe mọ̀ pé àwọn ní láti jẹ nínú búrẹ́dì káwọn si mu nínú wáìnì ibi Ìṣe Ìrántí ikú Kristi?

• Àkókò Ìṣe Ìrántí jẹ́ àkókò tó dára jù lọ fún kí ni?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Graph/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Àwọn Tó Wá Síbi Ìṣe Ìrántí

NÍ MÍLÍỌ̀NÙ MÍLÍỌ̀NÙ

15,597,746

15

14

13,147,201

13

12

11

10

 9

 8

 7

 6

 5

4,925,643

 4

 3

 2

 1

878,303

63,146

1935 1955 1975 1995 2002

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Ṣé wàá wà níbi ayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa ti ọdún yìí?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Àkókò Ìṣe Ìrántí jẹ́ àkókó tó dára jù lọ láti túbọ̀ ka Bíbélì sí i ká sì kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà