“Mi Ò Fi Bẹ́ẹ̀ Mọ̀ Nípa Ọlọ́run”
“Mi Ò Fi Bẹ́ẹ̀ Mọ̀ Nípa Ọlọ́run”
ỌKÙNRIN kan tó ń gbé Kerala, ní Íńdíà kọ̀wé pé: “Láti ọdún tó kọjá làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wá ń sọ àgbàyanu ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run fún mi. Ọdún mẹ́jọ gbáko ni mo fi ṣe ẹ̀sìn Kátólíìkì, àmọ́ mi ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa Ọlọ́run. Ohun tí mo kọ́ láàárín ọdún kan péré yìí kì í ṣe díẹ̀ rárá.” Ọ̀gbẹ́ni yìí tẹ̀ síwájú pé: “Inú mi dùn gan-an láti gbọ́ pé à ń tẹ Ilé Ìṣọ́ jáde lédè mọ́kàndínlógóje [139] [ó ti di mẹ́rìndínláàádọ́jọ [146] báyìí]. Ìyàlẹ́nu ńlá ló jẹ́ pé àwọn èèyàn látinú èdè gbogbo ń dẹni tó mọ̀ nípa ìhìn Ọlọ́run.”
Lóòótọ́ ọ̀pọ̀ onímọ̀ ọgbọ́n orí sọ pé kò ṣeé ṣe láti mọ Ọlọ́run, àmọ́ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi hàn gbangba gbàǹgbà pé a lè mọ̀ ọ́n. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń bá àwọn kan tó jẹ́ ará Áténì sọ̀rọ̀, àwọn tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ lára wọn ló máa ń jọ́sìn níbi pẹpẹ kan tí wọ́n yà sí mímọ́ fún “Ọlọ́run Àìmọ̀,” ó sọ pé: “Ohun tí ẹ ń fún ní ìfọkànsin Ọlọ́run láìmọ̀, èyí ni mo ń kéde fún yín. Ọlọ́run tí ó dá ayé àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀ . . . fún gbogbo ènìyàn ní ìyè àti èémí àti ohun gbogbo. Láti ara ọkùnrin kan ni ó sì ti dá gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn ènìyàn, láti máa gbé ní ojú gbogbo ilẹ̀ ayé pátá.”—Ìṣe 17:23-26.
Pọ́ọ̀lù rọ àwọn olùgbọ́ rẹ̀ pé kí wọ́n wá ọ̀nà láti mọ Ẹlẹ́dàá yìí, nítorí “kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.” (Ìṣe 17:27) Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè mọ Ọlọ́run tòótọ́ àti àwọn ànímọ́ rẹ̀ fífanimọ́ra.