Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Pẹpẹ—Kí Ni Ìlò Rẹ̀ Nínú Ìjọsìn?

Pẹpẹ—Kí Ni Ìlò Rẹ̀ Nínú Ìjọsìn?

Pẹpẹ—Kí Ni Ìlò Rẹ̀ Nínú Ìjọsìn?

ǸJẸ́ o ka pẹpẹ sí apá pàtàkì nínú ìjọsìn rẹ? Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù ló jẹ́ pé pẹpẹ gan-an ni wọ́n máa ń pàfiyèsí sí jù. Ǹjẹ́ o tíì fìgbà kankan rí ronú nípa ohun tí Bíbélì fi hàn nípa ìlò pẹpẹ nínú ìjọsìn?

Pẹpẹ àkọ́kọ́ tí Bíbélì mẹ́nu kàn ni èyí tí Nóà mọ láti fàwọn ẹran rúbọ nígbà tó jáde kúrò nínú ọkọ̀ áàkì tó gbé wọn la Ìkún Omi já. aJẹ́nẹ́sísì 8:20.

Bí Jèhófà ṣe da èdè èèyàn rú ní Bábélì, aráyé tàn ká orí gbogbo ilẹ̀ ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 11:1-9) Nígbà tí ọmọ èèyàn sì ti ní ẹ̀mí ìsìn, olúkúlùkù wọn ń wá bí wọ́n á ṣe sún mọ́ Ọlọ́run, bó tilẹ̀ jẹ́ pé òye wọn nípa rẹ̀ ń rẹ̀yìn sí i látọjọ́ dé ọjọ́. Wọ́n wá ń táràrà kiri bí afọ́jú. (Ìṣe 17:27; Róòmù 2:14, 15) Láti ìgbà ayé Nóà wá ni àwọn èèyàn onírúurú ẹ̀yà ti ń mọ pẹpẹ fún òrìṣà wọn. Onírúurú ẹ̀sìn àti àwọn ẹ̀yà sì ń mọ pẹpẹ ẹ̀sìn èké tiwọn. Nítorí pé àwọn èèyàn kan ti kẹ̀yìn sí Ọlọ́run tòótọ́, wọ́n sábà máa ń lo pẹpẹ wọn fún àwọn ààtò tó kóni nírìíra gidigidi, títí kan fífi èèyàn rúbọ, àtàwọn ọmọdé pàápàá. Nígbà táwọn ọba kan ní Ísírẹ́lì kẹ̀yìn sí Jèhófà, wọ́n mọ pẹpẹ fún àwọn òrìṣà, irú bíi Báálì. (1 Àwọn Ọba 16:29-32) Àmọ́ àwọn pẹpẹ tí wọ́n ń lò fún ìsìn tòótọ́ ńkọ́?

Pẹpẹ àti Ìsìn Tòótọ́ ní Ísírẹ́lì

Lẹ́yìn ti Nóà, àwọn olóòótọ́ èèyàn mìíràn pẹ̀lú mọ pẹpẹ tí wọ́n ń lò láti fi jọ́sìn Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́. Ábúráhámù mọ pẹpẹ ní Ṣékémù, níbì kan lẹ́bàá Bẹ́tẹ́lì ní Hébúrónì, àti lórí Òkè Móráyà níbi tó ti fi àgbò tí Ọlọ́run pèsè rúbọ dípò Ísákì. Lẹ́yìn náà, Ísákì, Jékọ́bù àti Mósè fi ìdánúṣe mọ pẹpẹ tí wọ́n lò fún ìjọsìn Ọlọ́run.—Jẹ́nẹ́sísì 12:6-8; 13:3, 18; 22:9-13; 26:23-25; 33:18-20; 35:1, 3, 7; Ẹ́kísódù 17:15, 16; 24:4-8.

Nígbà tí Ọlọ́run fún àwọn èèyàn Ísírẹ́lì ní Òfin rẹ̀, ó pàṣẹ pé kí wọ́n kọ́ àgọ́ ìjọsìn, ìyẹn àgọ́ tó ṣeé gbé kiri, tí wọ́n tún pè ní “àgọ́ ìpàdé.” Ó ní kí ibẹ̀ jẹ́ ojúkò ìgbòkègbodò tó bá jẹ mọ́ títọ Ọlọ́run lọ. (Ẹ́kísódù 39:32, 40) Pẹpẹ méjì ló wà nínú àgọ́ ìjọsìn yìí. Wọ́n gbé èyí tó wà fún ọrẹ ẹbọ sísun, tí a fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe, tá a sì wá fi bàbà bò, síbi àbáwọlé. Orí rẹ̀ ni wọ́n ti ń fi ẹran rúbọ. (Ẹ́kísódù 27:1-8; 39:39; 40:6, 29) Wọ́n gbé pẹpẹ tùràrí, tí wọ́n fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe bákan náà ṣùgbọ́n tí wọ́n da wúrà bò, síwájú aṣọ ìkélé Ibi Mímọ́ Jù Lọ nínú àgọ́ ìjọsìn. (Ẹ́kísódù 30:1-6; 39:38; 40:5, 26, 27) Wọ́n máa ń sun tùràrí àkànṣe lórí rẹ̀ lẹ́ẹ̀mejì lójúmọ́, ìyẹn láàárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́. (Ẹ́kísódù 30:7-9) Ìgbékalẹ̀ àgọ́ ìjọsìn yìí ni Sólómọ́nì Ọba tẹ̀ lé nígbà tó ń kọ́ tẹ́ńpìlì, tó jẹ́ pé ó ní pẹpẹ méjì.

“Àgọ́ Tòótọ́” àti Pẹpẹ Ìṣàpẹẹrẹ

Nígbà tí Jèhófà fún Ísírẹ́lì ní Òfin, kì í ṣe kìkì ìlànà nípa bí àwọn èèyàn rẹ̀ á ṣe máa gbé ìgbésí ayé wọn àti bí wọ́n á ṣe máa rúbọ àti bí wọ́n á ṣe máa gbàdúrà sí òun ló kàn pèsè fún wọn. Púpọ̀ nínú ìṣètò yẹn jẹ́ ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pè ní “àwòrán ìṣàpẹẹrẹ,” “àpèjúwe,” tàbí “òjìji àwọn ohun ti ọ̀run.” (Hébérù 8:3-5; 9:9; 10:1; Kólósè 2:17) Lọ́rọ̀ kan ṣá, ọ̀pọ̀ lára Òfin yẹn ni kò mọ sórí ṣíṣamọ̀nà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí dìgbà tí Kristi á fi dé nìkan, ṣùgbọ́n ó tún jẹ́ àpẹẹrẹ ìṣáájú nípa ète Ọlọ́run tí yóò ní ìmúṣẹ nípasẹ̀ Jésù Kristi. (Gálátíà 3:24) Ní tòótọ́, ńṣe làwọn apá kan lára Òfin yìí dà bí àsọtẹ́lẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀dọ̀ àgùntàn Ìrékọjá, tí wọ́n fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ṣe àmì ìgbàlà fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, dúró fún Jésù Kristi. Òun ni “Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run, tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ,” tó jẹ́ pé a ta ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ láti fi gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀.—Jòhánù 1:29; Éfésù 1:7.

Ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n ń ṣe nínú àgọ́ ìjọsìn àti ní tẹ́ńpìlì ló jẹ́ àpẹẹrẹ àwọn nǹkan tẹ̀mí tó wà lóòótọ́. (Hébérù 8:5; 9:23) Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa “àgọ́ tòótọ́, tí Jèhófà gbé ró, kì í sì í ṣe ènìyàn.” Ó sọ síwájú sí i pé: “Kristi dé gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àgbà àwọn ohun rere tí ó ti ṣẹlẹ̀, nípasẹ̀ àgọ́ títóbi jù àti pípé jù tí a kò fi ọwọ́ ṣe, èyíinì ni pé, kì í ṣe ti ìṣẹ̀dá yìí.” (Hébérù 8:2; 9:11) “Àgọ́ títóbi jù àti pípé jù” tí ibí yìí ń sọ ni ìṣètò tẹ́ńpìlì tẹ̀mí títóbi ti Jèhófà. Àlàyé Ìwé Mímọ́ fi hàn pé ìṣètò tẹ́ńpìlì tẹ̀mí títóbi yìí jẹ́ ètò tí ọmọ èèyàn yóò máa tẹ̀ lé tí wọ́n á fi lè tọ Jèhófà wá lórí ìpìlẹ̀ ètùtù ẹbọ Jésù Kristi.—Hébérù 9:2-10, 23-28.

Bí òye rẹ̀ bá ti yé wa látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, pé àwọn kan nínú ètò àti ìlànà Òfin jẹ́ àpẹẹrẹ àwọn nǹkan tẹ̀mí tó wà lóòótọ́, tó jẹ́ pé ó túbọ̀ tóbi tó sì nítumọ̀, ó máa ń jẹ́ ká túbọ̀ gbà gbọ́ pé Ọlọ́run mí sí Bíbélì lóòótọ́. Ó sì máa ń jẹ́ ká túbọ̀ mọyì ọgbọ́n Ọlọ́run tí Ìwé Mímọ́ gbé yọ lọ́nà tí kò láfiwé.—Róòmù 11:33; 2 Tímótì 3:16.

Pẹpẹ ọrẹ ẹbọ sísun tún jẹ mọ́ àsọtẹ́lẹ̀. Ó jọ pé ó dúró fún “ìfẹ́” Ọlọ́run, tàbí fífẹ́ tí Ọlọ́run ń fẹ́ láti tẹ́wọ́ gba ẹbọ Jésù tó fi ara èèyàn pípé rẹ̀ rú.—Hébérù 10:1-10.

Ní apá ìgbẹ̀yìn ìwé Hébérù, Pọ́ọ̀lù ṣe àlàyé pàtàkì yìí, pé: “Àwa ní pẹpẹ kan láti orí èyí tí àwọn tí ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ níbi àgọ́ kò ní ọlá àṣẹ láti jẹ.” (Hébérù 13:10) Pẹpẹ wo ló ń sọ?

Ọ̀pọ̀ àwọn ògbufọ̀ tó jẹ́ ọmọ ìjọ Kátólíìkì sọ pé pẹpẹ tí Hébérù 13:10 ń sọ ni tábìlì inú ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n ń lò fún ààtò gbígba ara Olúwa, ìyẹn “sákírámẹ́ńtì” tí wọ́n ló ń sọ ẹbọ Kristi dọ̀tun nígbà ayẹyẹ gbígba ara Olúwa. Ṣùgbọ́n, látinú àlàyé tí Pọ́ọ̀lù ń ṣe níbi tó ti sọ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ lè rí i pé pẹpẹ ìṣàpẹẹrẹ ló ń tọ́ka sí. Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ mélòó kan sọ pé ìlò tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ń lo “pẹpẹ” níhìn-ín jẹ́ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàngbé kan tó ń jẹ́ Giuseppe Bonsirven sọ pé “èyí ló bá àwọn ọ̀nà yòókù tí lẹ́tà sí àwọn ará Hébérù gbà lo ohun ìṣàpẹẹrẹ mu rẹ́gí.” Ọ̀gbẹ́ni yìí kọ̀wé pé: “Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, táwọn Kristẹni bá ń sọ̀rọ̀ nípa ‘pẹpẹ,’ pẹpẹ nípa tẹ̀mí ló sábà máa ń tọ́ka sí. Ẹ̀yìn ìgbà ayé Irenaeus, pàápàá lẹ́yìn ayé Tertullian àti ti Cyprian Ẹni Mímọ́, ló di pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ka pẹpẹ yìí mọ́ ara ààtò gbígba ara Olúwa, pàápàá jù lọ tábìlì inú ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n ń lò fún ààtò gbígba ara Olúwa.”

Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn ìjọ Kátólíìkì kan ṣe sọ, ìgbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí “kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì ńláńlá” ní “ayé ìgbà Kọnsitatáìnì” ni ìlò pẹpẹ gbilẹ̀. Ìwé ìròyìn Rivista di Archeologia Cristiana (Àtúnyẹ̀wò Ẹ̀kọ́ Ìwalẹ̀pìtàn ti Àwọn Kristẹni) sọ pé: “Ó dájú pé kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé nígbà ọ̀rúndún kìíní àti ìkejì wọ́n kọ́ àwọn ibi pàtó kan fún ìpàdé ìjọsìn. Yàrá inú ilé àdáni ni wọ́n ti ń kóra jọ láti ṣe ìsìn . . . , lẹ́yìn ìsìn náà, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni onílé tún padà máa ń lo yàrá rẹ̀ bó ṣe ń lò ó tẹ́lẹ̀.”

Ìlò Tí Àwọn Oníṣọ́ọ̀ṣì Ń Lo Pẹpẹ

Ìwé ìròyìn ìjọ Kátólíìkì náà La Civiltà Cattolica sọ pé: “Yàtọ̀ sí pé pẹpẹ jẹ́ ibi tó gbàfiyèsí jù lọ nínú ṣọ́ọ̀ṣì, ó tún jẹ́ ibi tó gbàfiyèsí jù lọ lọ́kàn àwọn ọmọ ìjọ pẹ̀lú.” Bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ mọ̀ pé Jésù ò dá ààtò ìsìn kankan sílẹ̀ rárá tá a ó lọ máa ṣe nídìí pẹpẹ; bẹ́ẹ̀ ni kò pàṣẹ pé káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ṣe ààtò kankan nídìí pẹpẹ. Nígbà tí Jésù mẹ́nu kan pẹpẹ nínú Mátíù 5:23, 24 àti láwọn ibòmíràn, ńṣe ló kàn fìyẹn tọ́ka sí àṣà tó wọ́pọ̀ nínú ìsìn àwọn Júù, kò sì sọ pé káwọn ọmọlẹ́yìn òun máa lo pẹpẹ nínú ìjọsìn wọn sí Ọlọ́run.

Òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà kan tó ń jẹ́ George Foot Moore (1851 sí 1931) kọ̀wé pé: “Tẹ́lẹ̀, ọ̀nà táwọn Kristẹni ń gbà ṣe ìjọsìn kì í yàtọ̀, àmọ́ nígbà tó yá, àwọn èèyàn sọ ààtò pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tí Justin mẹ́nu kàn ní ọ̀rúndún kejì di nǹkan bàbàrà nínú ààtò ìsìn.” Ààtò ìsìn ìjọ Kátólíìkì àti ayẹyẹ ìsìn tàwọn aráàlú wá pọ̀, wọ́n sì lọ́jú pọ̀ gan-an débi tó fi wá di pé káwọn èèyàn lọ máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ṣẹ́ àlùfáà àwọn Kátólíìkì. Moore ń bọ́rọ̀ lọ pé: “Ohun tó túbọ̀ pa kún ẹ̀mí sísọ ààtò ìsìn di bàbàrà, tó wọ́pọ̀ nínú gbogbo ààtò ṣíṣe, ni àṣà inú Májẹ̀mú Láéláé táwọn àlùfáà Kristẹni ń fẹ́ máa tẹ̀ lé nítorí pé àwọn èèyàn ti gbà pé àlùfáà Kristẹni ló rọ́pò ẹgbẹ́ àlùfáà tó wà láyé àtijọ́. Ìyẹn ló mú káwọn èèyàn gbà pé ẹ̀wù oyè ńlá ti àlùfáà àgbà, ẹ̀wù ayẹyẹ ìsìn tàwọn àlùfáà yòókù, ìtọ́wọ̀ọ́rìn lọ sóde nígbà ìsìn, ẹgbẹ́ akọrin àwọn ọmọ Léfì tó ń ka sáàmù nígbà orin, èéfín tùràrí tó ń rú jáde látinú ìkóná tí wọ́n ń fì sọ́tùn-ún sósì, jẹ́ àpẹẹrẹ ọ̀nà ìjọsìn tí Ọlọ́run là sílẹ̀ fúnni láti tẹ̀ lé. Ṣọ́ọ̀ṣì wá ń lépa bí yóò ṣe máa ṣe ààtò wọ̀nyí bíi ti ìgbà láéláé gẹ́lẹ́ tàbí kí wọ́n tiẹ̀ ta wọ́n yọ.”

Ó lè yà ọ́ lẹ́nu láti mọ̀ pé kì í ṣe ẹ̀kọ́ ìsìn Kristẹni tó wà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere ni ọ̀pọ̀ ààtò ìsìn, ayẹyẹ ìsìn, aṣọ oyè, àtàwọn nǹkan yòókù tí onírúurú ìsìn ń lò nínú ìsìn wọn ń tẹ̀ lé bí kò ṣe àṣà àti ààtò ìsìn àwọn Júù àti tàwọn abọ̀rìṣà. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà Enciclopedia Cattolica sọ pé “inú ìsìn àwọn Júù àti ara ìsìn àwọn abọ̀rìṣà” ni ẹ̀sìn Kátólíìkì ti “jogún àṣà lílo pẹpẹ.” Minucius Felix tó jẹ́ agbèjà ìgbàgbọ́ kan ní ọ̀rúndún kẹta Sànmánì Tiwa kọ̀wé pé àwọn Kristẹni ‘kò ní tẹ́ńpìlì tàbí pẹpẹ rárá.’ Ìwé atúmọ̀ èdè náà Religioni e Miti (Àwọn Ẹ̀sìn àti Ìtàn Àròsọ) náà tún sọ pé: “Àwọn Kristẹni kọ̀ láti lo pẹpẹ kí ìsìn wọn bàa lè yàtọ̀ sí ìsìn àwọn Júù àti tàwọn abọ̀rìṣà.”

Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ní pàtàkì, ẹ̀sìn Kristẹni jẹ́ èyí tá a gbé karí àwọn ìlànà tó yẹ ká tẹ́wọ́ gbà ká sì máa lò nínú ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́ ní ilẹ̀ gbogbo, kò sídìí fún yíya ìlú kan sí mímọ́ lórí ilẹ̀ ayé tàbí níní tẹ́ńpìlì tòun ti pẹpẹ tàbí àwọn àlùfáà ọmọ èèyàn tó wà nípò àkànṣe tó ń wọ ẹ̀wù àrà ọ̀tọ̀. Ohun tí Jésù sọ ni pé: “Wákàtí náà ń bọ̀ nígbà tí kì í ṣe ní òkè ńlá yìí tàbí ní Jerúsálẹ́mù ni ẹ ó ti máa jọ́sìn Baba. . . . Àwọn olùjọsìn tòótọ́ yóò máa jọ́sìn Baba ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòhánù 4:21, 23) Àwọn ààtò ìsìn dídíjú pọ̀ àti pẹpẹ tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ń lò lòdì sí ohun tí Jésù sọ nípa ọ̀nà tó yẹ ká máa gbà sin Ọlọ́run tòótọ́.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ṣáájú ìgbà náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé orí pẹpẹ ni Kéènì àti Ébẹ́lì pẹ̀lú ti rú ẹbọ wọn sí Jèhófà.—Jẹ́nẹ́sísì 4:3, 4.